Àwọn Ìṣòro Ńlá Tó Ń fà Á Àti Ibi Tí Àbájáde Rẹ̀ Nasẹ̀ Dé
Àwọn Ìṣòro Ńlá Tó Ń fà Á Àti Ibi Tí Àbájáde Rẹ̀ Nasẹ̀ Dé
“Ebi ń pa mí ẹ lọ dá ìgbìmọ̀ kan sílẹ̀ láti ṣèwádìí lórí ohun tó fa ebi mi. Mi ò nílé lórí ẹ lọ kọ ìròyìn lórí ìṣòro mi. Àìsàn ń ṣe mí ẹ pe àpérò lórí ìṣòro àwọn mẹ̀kúnnù. Ẹ ṣèwádìí lórí gbogbo ìṣòro tí mo ní, síbẹ̀ ebi ṣì ń pa mí, mi ò tíì nílé lórí, bẹ́ẹ̀ ni àìsàn mi ṣì wà síbẹ̀.”—A ò mọ orúkọ ẹni tó kọ ọ́.
BÓ TILẸ̀ jẹ́ pé àwọn àjọ kan lágbàáyé ti ṣe akitiyan lóríṣiríṣi láti fòpin sí àìjẹunrekánú, àwọn àṣeyọrí tí wọ́n ti ṣe ṣì kéré gan-an sí ohun tí wọ́n ní lọ́kàn láti ṣe. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1996, níbi Àpérò Àgbáyé Lórí Oúnjẹ, èyí tí Àjọ Tí Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Oúnjẹ àti Iṣẹ́ Àgbẹ̀ fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣètò rẹ̀, wọ́n gbé góńgó kan kalẹ̀ tí wọ́n ń retí láti lé bá kó tó di ọdún 2015. Góńgó náà ni pé wọ́n fẹ́ láti dín iye àwọn èèyàn tí kò rí oúnjẹ tó dára tó jẹ lágbàáyé kù sí ìdajì—ìyẹn nǹkan bí irínwó mílíọ̀nù èèyàn. a
Ó dùn mọ́ni pé, wọ́n ti ṣe àwọn àṣeyọrí díẹ̀.
Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé, Àjọ Tí Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Oúnjẹ àti Iṣẹ́ Àgbẹ̀ sọ nínú ìwé kan tí wọ́n gbé jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìyẹn ìwé The State of Food Insecurity in the World 2001, pé: “Ó ṣe kedere pé, akitiyan wa láti dín iye àwọn tí kò rí oúnjẹ tó dára tó jẹ kù lágbàáyé ṣì falẹ̀ gan-an.” Látàrí èyí, ó jọ pé àléèbá ni góńgó tí wọ́n gbé kalẹ̀ níbi àpérò náà ṣì jẹ́ síbẹ̀. Ní ti gidi, ìròyìn náà sọ pé “iye àwọn tí kò rí oúnjẹ tó dára tó jẹ ti lọ sókè gan-an ní ọ̀pọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà.”Kí nìdí tó fi nira láti fòpin sí àìjẹunrekánú? Láti rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ ohun tí àìjẹunrekánú túmọ̀ sí, lẹ́yìn náà ká wá ṣàyẹ̀wò ibi tí àbájáde rẹ̀ nasẹ̀ dé àtàwọn okùnfà rẹ̀ tó ta gbòǹgbò.
Kí Ló Ń Fa Àìjẹunrekánú?
Ohun tó máa ń fa àìjẹunrekánú ni kí àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ara máà rí àwọn èròjà aṣaralóore tó pọ̀ tó. Àpapọ̀ àwọn ohun méjì ló sì sábà máa ń fà á: (1) bí àwọn èròjà bíi protein, calorie, fítámìn àti mineral inú ara kò bá pọ̀ tó, àti (2) bí àwọn àrùn kan bá máa ń yọni lẹ́nu nígbà gbogbo.
Àwọn àìsàn bí ìgbẹ́ gbuuru, àrùn èèyi, ibà, àtàwọn àrùn tó jẹ mọ́ mímí máa ń tán ara lókun púpọ̀, wọ́n sì máa ń mú kí ara pàdánù àwọn èròjà aṣaralóore. Wọn kì í jẹ́ kí oúnjẹ wuni láti jẹ tàbí kéèyàn fẹ́ láti jẹ púpọ̀, èyí á sì dá kún àìjẹunrekánú. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, àwọn ọmọ tí kò bá rí oúnjẹ tó dára tó jẹ máa ń tètè kó àrùn. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ìṣòro wọ̀nyí yóò jẹ́ kí àìjẹunrekánú tètè ṣekú pa irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀.
Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn ọmọdé ni àìjẹunrekánú sábà máa ń pa lára jù? Ìdí ni pé wọ́n wà ní sáà tí ìdàgbàsókè ti máa ń yára kánkán, tí èyí sì ń mú kí ara wọn nílò ọ̀pọ̀ èròjà calorie àti protein. Kókó yìí kan náà lè mú kí àwọn aboyún àtàwọn ìyá tó ń tọ́mọ lọ́wọ́ ní ìṣòro àìjẹunrekánú.
Gẹ́gẹ́ bó ṣe sábà máa ń rí, kí wọ́n tó bí ọmọ tí àìjẹunrekánú ń yọ lẹ́nu ni ìṣòro rẹ̀ ti máa ń bẹ̀rẹ̀. Bí ìyá kan kò bá rí oúnjẹ aṣaralóore tó tó jẹ ṣáájú kó tó lóyún àti nígbà tó lóyún, ọmọ tó bá bí kò ní tẹ̀wọ̀n tó bó ṣe yẹ. Lẹ́yìn náà, títètè gba ọmú lẹ́nu ọmọ, ṣíṣàì fún un ní oúnjẹ lọ́nà tó tọ́, àti àìsí ìmọ́tótó lè mú kí ọmọ náà ní ìṣòro àìjẹunrekánú.
Àìsí àwọn èròjà aṣaralóore tí ọmọ náà nílò kò ní jẹ́ kó dàgbà bó ṣe yẹ. Ọmọ náà á kàn máa ké ṣáá ni, àìsàn sì lè kọ lù ú nígbàkigbà. Bí ipò rẹ̀ bá ti ń burú sí i làwọn ìṣòro mìíràn á máa fara hàn. Ọmọ náà á máa tín-ín-rín sí i, ojú rẹ̀ á kó wọnú, àwùjẹ̀ rẹ̀ á tẹ̀ wọnú, awọ ara rẹ̀ á hun jọ, ara rẹ̀ kò sì ní lè fi bẹ́ẹ̀ móoru mọ́.
Ìṣòro yìí tún lè fara hàn láwọn ọ̀nà mìíràn. Ìwọ̀nyí pẹ̀lú tún lè ṣàkóbá fún ìdàgbàsókè àwọn ọmọdé. Bí àpẹẹrẹ, bí wọn ò bá ní àwọn èròjà mineral tó pọ̀ lára—àwọn èròjà bíi iron, iodine, àti zinc—àtàwọn fítámìn—pàápàá vitamin A—èyí lè fa irú àbájáde kan náà. Àjọ Tí Ń Bójú Tó Àkànlò Owó Tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ṣètò fún Àwọn Ọmọdé ṣàkíyèsí pé àìtó èròjà vitamin A nínú ara jẹ́ ìṣòro tó ń bá nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù ọmọ wẹ́wẹ́ fínra lágbàáyé, ó sì máa ń fa ìfọ́jú. Ó tún máa ń sọ agbára tí ń dènà àrùn nínú ara di ahẹrẹpẹ, èyí tí kò ní jẹ́ kí ara ọmọ náà lè fi bẹ́ẹ̀ dènà àrùn.
Ibi Tí Àbájáde Rẹ̀ Nasẹ̀ Dé
Àìjẹunrekánú máa ń fa ìṣòro bá gbogbo ara ẹni tó bá ń yọ lẹ́nu, pàápàá ara àwọn ọmọdé. Gbogbo ẹ̀yà ara, irú bí ọkàn, kíndìnrín, ikùn, ìfun, ẹ̀dọ̀fóró àti ọpọlọ lọ̀ràn máa ń kàn.
Onírúurú ìwádìí ti fi hàn pé bí ọpọlọ àwọn ọmọdé kì í ṣeé jí pépé tí wọn kì í sì jáfáfá nílé ẹ̀kọ́ kò ṣẹ̀yìn ìdàgbàsókè wọn tí kò ṣe déédéé. Ìròyìn kan tí Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tẹ̀ jáde pe àwọn nǹkan wọ̀nyí ní àbájáde ọlọ́jọ́-pípẹ́ tó burú jù lọ tí àìjẹunrekánú ń fà.
Ní ti àwọn ọmọdé tí àìjẹunrekánú kò bá pa, àwọn àbájáde rẹ̀ lè máa bá a lọ bí wọ́n ṣe ń di àgbàlagbà. Ìdí nìyẹn tí Àjọ Tí Ń Bójú Tó Àkànlò Owó Tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ṣètò fún Àwọn Ọmọdé fi kédàárò pé: “Bí agbára ìrònú ẹ̀dá èèyàn ṣe ń dín kù lọ́nà tó kàmàmà bẹ́ẹ̀ jẹ́ àdánù tó pabanbarì, àní tó burú jáì pàápàá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe gan-an fún wa láti dènà rẹ̀.” Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn àbájáde ọlọ́jọ́-pípẹ́ tó burú jù lọ tí àìjẹunrekánú ń fà jẹ́ ohun tó ń kọni lóminú gidigidi. Àwọn ìwádìí ẹnu àìpẹ́ yìí fi hàn pé, àìjẹunrekánú nígbà téèyàn wà ní ọmọ ọwọ́ wà lára ohun tó lè fa àwọn àìsàn tí kì í lọ bọ̀rọ̀ béèyàn bá dàgbà, irú bí àrùn ọkàn, àtọ̀gbẹ, àti ẹ̀jẹ̀ ríru.
Àmọ́ o, kì í ṣe àìjẹunrekánú tó burú jáì ni ìṣòro tó le koko jù lọ. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Tí Ń Bójú Tó Àkànlò Owó Tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ṣètò fún Àwọn Ọmọdé ṣe ṣàlàyé: “Èyí tó pọ̀ jù lọ lára ikú tí àìjẹunrekánú ń fà ló jẹ́ pé kì í ṣe àìjẹunrekánú tó burú jáì ló ń fà á bí kò ṣe àìjẹunrekánú tó mọ níwọ̀n.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Ó ṣeé ṣe kí ràbọ̀ràbọ̀ àìsàn tó ti kọ lu àwọn ọmọdé tó ní ìṣòro àìjẹunrekánú tó mọ níwọ̀n má lọ bọ̀rọ̀. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn òbí ṣàkíyèsí àwọn àmì tó ń fi hàn pé ọmọ kan
ní ìṣòro àìjẹunrekánú kí wọ́n bàa lè fún un ní ìtọ́jú yíyẹ.—Wo àpótí tó wà lójú ìwé 7.Àwọn Ìṣòro Ńlá Tó Ń Fà Á
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ṣáájú, àìsí oúnjẹ ni lájorí ohun tó ń fa àìjẹunrekánú. Àmọ́ àwọn ìṣòro ńlá mìíràn tún wà tó ń fà á, irú bí ìṣòro tó wà láwùjọ, ti ọrọ̀ ajé, ti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ti àyíká. Èyí tó ga jù lọ láàárín wọn ni àìrówóná, tó jẹ́ ìṣòro ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn, pàápàá jù lọ láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Àmọ́ o, yàtọ̀ sí pé àìrówóná máa ń fa àìjẹunrekánú, ó tún lè jẹ́ àbájáde àìjẹunrekánú nítorí pé ìṣòro yìí kò ní jẹ́ káwọn èèyàn lè ṣiṣẹ́ tó pójú owó, tí èyí á sì mú kí ipò òṣì túbọ̀ pọ̀ sí i.
Àwọn nǹkan mìíràn tún wà tó ń dá kún àìjẹunrekánú. Àìsí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ máa ń mú káwọn èèyàn jẹun lọ́nà tí kò ní ṣara wọn lóore. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ lókè, àkóràn náà lè fa ìṣòro yìí. Àwọn ìṣòro àwùjọ àti ti ọrọ̀ ajé tún wà níbẹ̀, irú bíi, kí wọ́n máà pín oúnjẹ kárí àti ṣíṣàì ka àwọn obìnrin kún. Àwọn obìnrin ló sábà máa ń jẹun “gbẹ̀yìn àti pé oúnjẹ wọn ló máa ń kéré jù lọ”—ìyẹn ni pé, ẹ̀yìn táwọn ọkùnrin bá jẹun tán ni wọ́n máa ń jẹun, oúnjẹ wọn sì máa ń kéré sí tàwọn ọkùnrin. Bákan náà, àwọn obìnrin kì í láǹfààní láti kàwé, èyí tí ì bá ṣèrànwọ́ fún wọn láti lè bójú tó àwọn ọmọ wọn dáadáa.
Láfikún sí i, àwọn ìṣòro àyíká máa ń dín ìpèsè oúnjẹ kù. Lára ìwọ̀nyí ni ìjábá àti ogun. Gẹ́gẹ́ bí ìwé The State of Food Insecurity in the World 2001 ti sọ, láti oṣù October 1999 sí June 2001 nìkan, orílẹ̀-èdè méjìlélógún ló ní ìṣòro ọ̀dá, mẹ́tàdínlógún ló ní ìṣòro ìjì líle tàbí omíyalé, mẹ́rìnlá ló ní ìṣòro ogun abẹ́lé tàbí rúkèrúdò, mẹ́ta ló ní ìṣòro kí ìgbà òtútù tutù ju bó ṣe yẹ lọ, méjì ló sì ní ìṣòro ìmìtìtì ilẹ̀.
Wíwá Ojútùú sí Àìjẹunrekánú àti Dídènà Rẹ̀
Báwo la ṣe lè tọ́jú ọmọ tí àìjẹunrekánú bá ń yọ lẹ́nu? Bí ọmọ náà bá ní ìṣòro àìjẹunrekánú tó burú jáì, gbígbé e lọ sí ilé ìwòsàn ni ìtọ́jú àkọ́kọ́ tó dára jù lọ. Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan tó wà fún àwọn oníṣègùn, èyí tí Àjọ Ìlera Àgbáyé tẹ̀ jáde ti wí, àwọn dókítà yóò ṣàyẹ̀wò ipò ọmọ náà, wọn yóò sì ṣètọ́jú àìsàn èyíkéyìí tó bá wà lára rẹ̀ tàbí kí wọ́n ṣètọ́jú rẹ̀ fún ìpàdánù omi ara. Wọ́n lè máa fi oúnjẹ bọ́ ọ díẹ̀díẹ̀, èyí máa ń sábà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú lílo ọ̀pá oníhò kan tí wọ́n á tì bọ imú rẹ̀ tí yóò sì máa gbé oúnjẹ lọ sí ikùn rẹ̀. Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ yìí lè gbà tó odindi ọ̀sẹ̀ kan.
Bí ara ọmọ náà ṣe máa padà bọ̀ sípò ni ìgbésẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Ìyá ọmọ náà á tún bẹ̀rẹ̀ sí fún un lọ́mú, á sì máa rọ̀ ọ́ láti jẹun bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Rírọ ọmọ náà láti jẹun àti fífún un ní ìtọ́jú yíyẹ ṣe pàtàkì gan-an níbi tí ọ̀ràn dé yìí. Ṣíṣaájò ọmọ náà àti fífi ìfẹ́ hàn sí i lè ṣèrànwọ́ gan-an fún ìdàgbàsókè ọmọ náà. Ìgbà yìí ni wọ́n lè dá ìyá náà lẹ́kọ̀ọ́ nípa bó ṣe lè máa tọ́jú ọmọ rẹ̀ nípa fífún un ní oúnjẹ tó ṣara lóore àti ṣíṣe ìmọ́tótó, kí ìṣòro àìjẹunrekánú tí ọmọ náà ti ní má bàa tún padà wá. Lẹ́yìn èyí, ọmọ náà á kúrò nílé ìwòsàn. Ó ṣe pàtàkì kí wọ́n máa gbé ọmọ náà lọ sí ilé ìwòsàn fún àyẹ̀wò látìgbàdégbà.
Bó ti wù kó rí, ó ṣe kedere pé, dídènà ìṣòro yìí lohun tó dára jù lọ. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ìjọba àtàwọn àjọ kan tí kì í ṣe ti ìjọba ti ṣe àwọn ètò kan tó wà fún fífi àwọn èròjà aṣaralóore kún àwọn oúnjẹ tí àwọn aráàlú ń jẹ. Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn ará àdúgbò tún lè ṣe láti fi dènà àìjẹunrekánú. Lára rẹ̀ ni pípèsè ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa oúnjẹ aṣaralóore, bíbójútó ìpèsè omi wọn kí ẹ̀gbin má bàa wọnú rẹ̀, kíkọ́ ilé ìyàgbẹ́, jíjẹ́ kí àyíká wọn mọ́ tónítóní, ṣíṣe onígbọ̀wọ́ onírúurú ètò abẹ́rẹ́ àjẹsára, àti kíkíyèsí bí àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ ṣe ń dàgbà.
Àmọ́ kí lohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan lè ṣe láti dènà àìjẹunrekánú? Àwọn ìdámọ̀ràn tó lè ṣeni láǹfààní wà nínú àpótí tó wà lójú ìwé 8. Láfikún sí i, Georgina Toussaint, tó jẹ́ onímọ̀ nípa oúnjẹ aṣaralóore fún àwọn ọmọdé, dábàá pé kí ìyá ọmọ padà lọ bá olùtọ́jú ọmọ rẹ̀ tàbí kó padà lọ sí ilé ìwòsàn lọ́jọ́ keje lẹ́yìn tó bá bímọ, kó tún lọ nígbà tí ọmọ náà bá ti pé ọmọ oṣù kan, kó sì máa lọ síbẹ̀ lóṣooṣù lẹ́yìn èyí. Ìyá náà tún gbọ́dọ̀ wá ìtọ́jú lọ sọ́dọ̀ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ bó bá ṣàkíyèsí àwọn àmì kan lára ọmọ náà, irú bíi pé ó ń pàdánù omi ara, ó ń yàgbẹ́ gbuuru tàbí pé ó ní ibà.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìdámọ̀ràn wọ̀nyí yóò ṣèrànwọ́ láti jẹ́ kí àwọn òbí máa fún àwọn ọmọdé ní oúnjẹ aṣaralóore, a ní láti gbà pé ìṣòro ńlá ni àìjẹunrekánú—ìṣòro tó tóbi débi pé kò ṣeé ṣe fún àwọn ẹ̀dá èèyàn láti yanjú. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé: “Pípèsè oúnjẹ tó tó gbogbo èèyàn láti jẹ àti dídá gbogbo èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa oúnjẹ aṣaralóore ṣì jẹ́ ìṣòro bàǹtà-banta síbẹ̀.” Nígbà náà, ǹjẹ́ ìrètí wà pé “ìṣòro àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí táráyé ò kọbi ara sí” yìí máa dópin láé?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìsọfúnni síwájú sí i lórí Àpérò Àgbáyé Lórí Oúnjẹ, wo ìtẹ̀jáde Jí! ti August 8, 1997, ojú ìwé 12-14.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
ǸJẸ́ ÀÌJẸUNREKÁNÚ Ń YỌ ỌMỌ RẸ LẸ́NU?
Báwo làwọn oníṣègùn ṣe ń mọ̀ bóyá àìjẹunrekánú ń yọ ọmọ kan lẹ́nu? Wọ́n lè ṣàyẹ̀wò onírúurú àmì tí wọ́n bá rí lára rẹ̀, kí wọ́n béèrè àwọn ìbéèrè nípa bó ṣe ń jẹun sí, kí wọ́n sì ṣètò pé kó lọ fún àyẹ̀wò síwájú sí i. Bó ti wù kó rí, àwọn ìlànà tó wà fún gbogbo èèyàn ni wọ́n sábà máa ń lò. Wọ́n á wọn ara ọmọ náà, wọ́n á sì fi àbájáde ìwọ̀n náà wéra pẹ̀lú ìlànà tí wọ́n ń lò fún gbogbo èèyàn. Ìyẹn ló máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ irú ìṣòro àìjẹunrekánú tí ọmọ náà ní àti bó ṣe rinlẹ̀ tó.
Àwọn ìdíwọ̀n tó ṣe pàtàkì jù lọ ni bó ṣe tẹ̀wọ̀n tó, bó ṣe ga sí, àti bí apá rẹ̀ ṣe ki tó. Ṣíṣe ìfiwéra bó ṣe tẹ̀wọ̀n tó pẹ̀lú ọjọ́ orí rẹ̀ yóò fi bí àìjẹunrekánú náà ti rinlẹ̀ tó hàn; bó bá burú gan-an, ńṣe ni ọmọ náà máa rù kan eegun. Wọ́n máa ń sọ pé àìsàn náà burú gan-an bí ọmọ náà bá fi ohun tó lé ní ìdá ogójì nínú ọgọ́rùn-ún dín sí ohun tó yẹ kó wọ̀n, wọ́n á ní àìsàn náà kò fi bẹ́ẹ̀ burú bó bá fi ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sí ogójì nínú ọgọ́rùn-ún dín sí bó ṣe yẹ, wọ́n á sì sọ pé àìsàn náà mọ níwọ̀n bó bá fi ìdá mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n dín sí bó ṣe yẹ. Bí ọmọ náà bá kúrú jù sí ọjọ́ orí rẹ̀, èyí fi hàn pé ó ti pẹ́ tí ìṣòro àìjẹunrekánú ti ń bá a fínra, àìsàn náà sì ti ṣàkóbá fún ìdàgbàsókè rẹ̀.
Àwọn ìṣòro àìjẹunrekánú tó burú jù lọ ni kí ọmọ máa joro díẹ̀díẹ̀, èyí tí wọ́n ń pè ní marasmus, àti òmíràn tó ń jẹ́ kwashiorkor, tàbí kí ìṣòro méjèèjì yìí pa pọ̀. Ìṣòro kí ọmọ máa joro díẹ̀díẹ̀ yìí máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ ọwọ́ nígbà tí wọ́n bá jẹ́ ọmọ oṣù mẹ́fà sí ọdún kan ààbọ̀. Ó máa ń bẹ̀rẹ̀ díẹ̀díẹ̀ nígbà tí calorie àtàwọn èròjà aṣaralóore mìíràn kò bá sí lára ọmọ náà fún ìgbà pípẹ́, ó sì máa ń wáyé bí ìyá ọmọ náà kò bá fún un ní ọmú mu tó tàbí kó jẹ́ pé àwọn èròjà olómiṣooro ló ń fún un dípò wàrà. Ọmọ náà á joro gan-an débi pé á gbẹ kan eegun, kò sì ní dàgbà sókè bó ṣe yẹ. Ojú ọmọ náà á dà bí “ojú arúgbó,” á máa kanra, á sì máa sunkún ṣáá.
Ọ̀rọ̀ náà kwashiorkor, tó wá látinú èdè ilẹ̀ Áfíríkà kan, túmọ̀ sí “ọmọ tí wọ́n tètè já lẹ́nu ọmú.” Èyí ń tọ́ka sí bí ọmọ kékeré kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ṣe máa ń gba ọmú lẹ́nu èyí tó wà ńlẹ̀ láìtọ́jọ́. Ìṣòro yìí máa ń fara hàn lẹ́yìn tí wọ́n bá gba ọmú lẹ́nu ọmọ kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lára ohun tó ń fà á ni àìtó calorie lára ọmọ, ṣùgbọ́n lájorí okùnfà rẹ̀ ni kí èròjà bíi protein inú ara kéré jọjọ. Àìsàn yìí kì í jẹ́ kí omi jáde lára ọmọdé, tí á wá mú kí tapátẹsẹ̀ ọmọ náà wú kí ikùn rẹ̀ sì rí gbẹndu. Nígbà míì, ìṣòro yìí tún lè hàn lójú ọmọ náà pàápàá, tí ojú rẹ̀ á wú tí yóò sì rí rìbìtì bí òṣùpá àrànmọ́jú. Àléfọ́ á yọ sí i lára, awọ ara rẹ̀ á bẹ̀rẹ̀ sí ṣì, irun orí rẹ̀ á sì máa fẹ́lẹ́ sí i. Àwọn ọmọdé tó bá wà nínú ipò yìí máa ń ní ìṣòro ẹ̀dọ̀ wíwú, wọ́n á kàn máa wò duu, wọn kì í sì í láyọ̀. Irú ìṣòro yìí ni Erik tá a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ní, torí pé oṣù àkọ́kọ́ tó dáyé nìkan ni ìyá rẹ̀ fún un ní ọmú mọ; lẹ́yìn náà, wàrà màlúù tí wọ́n ti pò ṣàn ló ń fún un. Nígbà tó di ọmọ oṣù mẹ́ta, ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ àti omi tí wọ́n ti fi ṣúgà sí ni wọ́n ń fún un, wọ́n á sì gbé e sọ́dọ̀ aládùúgbò kan.
Oríṣi ìṣòro àìjẹunrekánú kẹta ni kí àwọn àmì àìsàn marasmus àti kwashiorkor fara hàn pa pọ̀ lára ọmọ náà lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Àwọn nǹkan mẹ́ta yìí lè ṣekú pa ọmọ náà bí wọn kò bá tètè tọ́jú rẹ̀ lásìkò.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
DÁÀBÒ BO ỌMỌ RẸ LỌ́WỌ́ ÀÌJẸUNREKÁNÚ!
◼ Ó ṣe pàtàkì pé kí ìyá ọmọ máa jẹ oúnjẹ tó ń ṣara lóore. Ó yẹ kí àwọn obìnrin tó lóyún àtàwọn tó ń tọ́mọ lọ́wọ́ máa jẹ àwọn oúnjẹ tó ní àwọn èròjà calorie àti protein. Èròjà protein gan-an ni ohun tó ń pèsè wàrà tí ìyá ń fún ọmọ. Nítorí náà, bí oúnjẹ ò bá pọ̀ tó láti jẹ, ẹ rí i dájú pé àwọn obìnrin tí wọ́n wà ní ọjọ́ orí ọmọ bíbí àtàwọn ọmọ wẹ́wẹ́ kọ́kọ́ jẹun yó ná.
◼ Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ní gbogbo gbòò, wàrà ìyá ni oúnjẹ tó dára jù lọ fún ọmọ ọwọ́. Èyí ṣe pàtàkì gan-an pàápàá ní àwọn ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bí i, nítorí pé wàrà ìyá máa ń ní àwọn èròjà kan nínú tó jẹ́ agbóguntàrùn. Ní nǹkan bí oṣù mẹ́rin àkọ́kọ́, wàrà ìyá máa ń pèsè gbogbo èròjà aṣaralóore tí ọmọ ọwọ́ nílò láti dàgbà sókè bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.
◼ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wàrà ìyá ló ṣì máa jẹ́ pàtàkì oúnjẹ tí ọmọ ọwọ́ náà á máa jẹ, bó bá fi máa di oṣù kẹrin sí ìkẹfà, ó ti ṣeé ṣe fún ọmọ náà láti máa jẹ àwọn oúnjẹ mìíràn. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, bẹ̀rẹ̀ sí fún un ní èso àti ewébẹ̀ tí o ti lọ̀ dáadáa. Jẹ́ kí ọmọ ọwọ́ náà máa dán oúnjẹ tuntun wò, ẹyọ kan lẹ́ẹ̀kan. Ní ọjọ́ méjì tàbí mẹ́ta lẹ́yìn náà, bó bá ti mọ oúnjẹ yẹn jẹ, jẹ́ kó tọ́ òmíràn wò. Àmọ́ ṣá o, ó gba sùúrù àti ọ̀pọ̀ ìsapá kí ọmọ ọwọ́ kan tó bẹ̀rẹ̀ sí gba oúnjẹ tuntun kan. Nígbà tó o bá ń ṣe irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀, máa rántí pé gbogbo ohun tó ò ń lò gbọ́dọ̀ mọ́ tónítóní, ó gbọ́dọ̀ mọ́ gan-an! Fọ oúnjẹ náà àti gbogbo ohun èlò tó o fẹ́ fi sè é dáradára!
◼ Láàárín oṣù karùn-ún sí ìkẹsàn-án tí ọmọ kan bá dáyé ló máa ń sábà bẹ̀rẹ̀ sí nílò ọ̀pọ̀ calorie àti protein ju èyí tí wàrà ń pèsè lọ. Máa bá a nìṣó ní fífi àwọn oúnjẹ mìíràn dán an lẹ́nu wò. O lè kọ́kọ́ máa fún un ní àwọn oúnjẹ oníhóró tí wọ́n ti lọ̀ àti ewébẹ̀ tó ṣeé jẹ fún àwọn ọmọ ọwọ́, lẹ́yìn náà kó o wá máa fún un ní ẹran àti mílíìkì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn oúnjẹ tí wọ́n ti lọ̀ tí wọ́n sì ti sẹ́ ló máa kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀ oúnjẹ, láti nǹkan bí oṣù mẹ́fà lọ, o lè máa gé wọn wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ kó o sì máa fún un jẹ. Kò pọn dandan láti fi iyọ̀ tàbí ṣúgà sínú oúnjẹ náà.
◼ Lẹ́yìn oṣù mẹ́jọ, kì í ṣe wàrà ìyá ló máa jẹ́ oúnjẹ pàtàkì tí ọmọ náà á máa jẹ, kàkà bẹ́ẹ̀, yóò kàn jẹ́ àfikún lásán ni. Ọmọ náà ti lè bẹ̀rẹ̀ sí jẹ oúnjẹ tí gbogbo ìdílé ń jẹ báyìí. Kí a rí i pé oúnjẹ náà mọ́ tónítóní, kí a sì gé e wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ kó lè ṣeé jẹ lẹ́nu fún un. Lára àwọn oúnjẹ tó ní èròjà aṣaralóore tó yẹ kó máa jẹ ni èso àti ewébẹ̀, oúnjẹ oníhóró àti onírúurú ẹ̀wà, ẹran àti mílíìkì. b Ní pàtàkì, àwọn ọmọdé nílò àwọn oúnjẹ tó bá ní èròjà vitamin A. Àpẹẹrẹ irú àwọn oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ni wàrà ìyá, àwọn ewébẹ̀ tí ewé wọn dúdú dáadáa, àtàwọn èso tí wọ́n ní àwọ̀ ìyeyè àti ewébẹ̀ bíi máńgòrò, kárọ́ọ̀tì, àti ìbẹ́pẹ. Ó yẹ kí àwọn ọmọ tí ọjọ́ orí wọn ò tíì tó ọdún mẹ́ta máa jẹun ní ìgbà márùn-ún tàbí mẹ́fà lójúmọ́.
◼ Jíjẹ oríṣiríṣi oúnjẹ tí a sè pa pọ̀ mọ́ra wọn, tá a sì ń ṣe lọ́nà tó yàtọ̀ síra yóò pèsè àwọn èròjà aṣaralóore tó lè dáàbò bo ọmọ rẹ. Ìyá ní láti rí i dájú pé òun ń fún ọmọ òun ní oúnjẹ tó dára, kó má ṣe fipá mú ọmọ náà láti jẹun tó bá ti yó, kó má sì kọ̀ láti fún ọmọ náà lóúnjẹ sí i bó bá fẹ́ jẹ sí i.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
b O lè rí ìsọfúnni púpọ̀ sí i nínú àpilẹ̀kọ náà, “Oúnjẹ Aṣaralóore Ń Bẹ Níkàáwọ́ Rẹ,” nínú ìtẹ̀jáde Jí! ti May 8, 2002.
[Àwòrán]
Àwọn ògbógi gbà pé wàrà ìyá ló dára jù lọ fún ọmọ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí
[Credit Line]
© Fọ́tò Caroline Penn/Panos Pictures
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn ọmọ tó ń jẹ àlìkámà gbígbẹ àti ewébẹ̀ ní ilé ìwé kan ní orílẹ̀-èdè Bhutan
[Credit Line]
Fọ́tò FAO/WFP Photo: F. Mattioli
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
O lè gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan láti mú kí ohun tó ò ń fún ọmọ rẹ jẹ túbọ̀ ṣara rẹ̀ lóore
[Credit Line]
Fọ́tò FAO