Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ìgbà Yìí Gan-an Ni Mo Ṣẹ̀ṣẹ̀ Wá Mọ Bó Ṣe Wúlò Tó”

“Ìgbà Yìí Gan-an Ni Mo Ṣẹ̀ṣẹ̀ Wá Mọ Bó Ṣe Wúlò Tó”

“Ìgbà Yìí Gan-an Ni Mo Ṣẹ̀ṣẹ̀ Wá Mọ Bó Ṣe Wúlò Tó”

Lọ́dún 1994, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ ìwé pẹlẹbẹ kan jáde tó sọ̀rọ̀ lórí bó ṣe máa ń ṣòro tó láti kojú àdánù èèyàn wa tó kú. Àtìgbà náà wá ni ìwé pẹlẹbẹ náà ti ń pèsè ìtùnú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, a gba lẹ́tà kan látọ̀dọ̀ òǹkàwé kan tó mọrírì ìwé pẹlẹbẹ náà ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó kọ̀wé pé: “Nígbà tí mo kọ́kọ́ gba ìwé pẹlẹbẹ náà, ohun tó wá sí mi lọ́kàn ni pé, ‘Ìtẹ̀jáde yìí dára gan-an ni.’ Àmọ́, ìgbà tí ọmọbìnrin mi kú ní ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mọyì rẹ̀. Níwọ̀n bí ìbànújẹ́ ti dorí mi kodò, tí mo sì ń wá ìrànlọ́wọ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí ka ìwé pẹlẹbẹ náà. Ìgbà yìí gan-an ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mọ bó ṣe wúlò tó. Ó sọ̀rọ̀ lórí gbogbo ohun tó ń bà mí nínú jẹ́, ó sì tù mí nínú.”

Ìwé pẹlẹbẹ náà Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú dáhùn àwọn ìbéèrè bíi: Báwo ni mo ṣe lè fara da ẹ̀dùn ọkàn mi? Báwo làwọn ẹlòmíràn ṣe lè ṣèrànwọ́? Ìrètí wo ló wà fún àwọn tó ti kú?

Ó ṣeé ṣe kí ìwọ tàbí ẹnì kan tó o mọ̀ rí ìtùnú nípa kíka ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 yìí. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.