Ọkùnrin Kan Tó Yàn Láti Ṣègbọràn Sí Ọlọ́run
Ọkùnrin Kan Tó Yàn Láti Ṣègbọràn Sí Ọlọ́run
LÁWỌN àkókò tí nǹkan le gan-an lọ́dún 1937, tí àwọn èròǹgbà yíyàtọ̀síra ń fa arukutu ní ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Yúróòpù, àwọn ìpinnu tó ṣòroó ṣe dojú kọ àwọn Kristẹni tòótọ́. Ṣé Ọlọ́run ni kí wọ́n ṣègbọràn sí ni àbí àwọn èèyàn? (Ìṣe 5:29) Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n ti wọ ọjọ́ orí ogun jíjà mọ̀ pé ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run lè ná wọn ní ìwàláàyè wọn.
Antonio Gargallo, ọmọ ilẹ̀ Sípéènì kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún náà ní láti ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀. Ó ti ń lọ sí bí ọdún kan tí ogun abẹ́lé ti ń jà nílẹ̀ Sípéènì nígbà tí àwọn ọmọ ogun ajàjàgbara lábẹ́ Ọ̀gágun Franco ké sí i láti wá wọ iṣẹ́ ológun. Ọdún kan ṣáájú ìgbà yẹn ni Antonio ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì ti ka ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ tó sọ pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kò gbọ́dọ̀ dá sí tọ̀tún-tòsì bẹ́ẹ̀ ni wọn ò tiẹ̀ gbọ́dọ̀ kọ́ iṣẹ́ ogun jíjà. (Aísáyà 2:4; Jòhánù 17:16) Níwọ̀n bí Antonio kò ti fẹ́ láti di sójà kó sì máa pa àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ó gbìyànjú láti sá lọ sí ilẹ̀ Faransé. Àmọ́ ọwọ́ tẹ̀ ẹ́ wọ́n sì mú un lọ sí bárékè àwọn ológun tó wà ní ìlú Jaca, ní ìpínlẹ̀ Huesca, nítòsí ẹnubodè ilẹ̀ Faransé.
Ilé ẹjọ́ àwọn ológun sọ fún un pé ó ní láti ṣe ìpinnu kan: Ìyẹn ni yálà kó gbé ìbọn tàbí kí wọ́n pa á. Antonio yàn láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Nígbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n pa á, ó kọ lẹ́tà tó wà nísàlẹ̀ yìí sí màmá rẹ̀ àti arábìnrin rẹ̀, tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà:
“Wọ́n ti mú mi, wọn ò sì gbọ́ ẹjọ́ mi tí wọ́n fi dájọ́ ikú fún mi. Lálẹ́ òní, màá kí ayé pé ó dìgbóṣe. Ẹ má ṣe jẹ́ kí inú yín bà jẹ́, ẹ má sì sunkún . . . , nítorí pé Ọlọ́run ni mo ṣègbọràn sí. Ó ti dé, ó ti dé ná, àmọ́ ohun tí mo pàdánù kò pọ̀, nítorí pé bó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, mo ṣì tún máa padà wà láàyè, yóò sì jẹ́ ìwàláàyè tó sàn ju ti ìsinsìnyí lọ. . . . Ọkàn mi balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ bí wákàtí ikú mi ṣe ń sún mọ́. Bí mo ti ń kọ ìwé yìí, mo nímọ̀lára pé ńṣe lẹ gbá mi mọ́ra. Èmi ni ọmọkùnrin yín àti arákùnrin yín tó nífẹ̀ẹ́ yín gidigidi.” a
Àwọn sójà mẹ́ta ròyìn pé, bí Antonio ṣe ń lọ sí ibi tí wọ́n ti máa pa á, àwọn orin ìyìn ló ń kọ sí Jèhófà. Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ máa ń kíyè sí irú àwọn ìrúbọ bí èyí. Ìdánilójú wa ni pé, àwọn Kristẹni olóòótọ́, bí Antonio, yóò gba èrè wọn nípasẹ̀ àjíǹde.—Jòhánù 5:28, 29.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lẹ́tà Antonio, èyí tó wà nípamọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún nínú ibi ìkówèésí àwọn ológun ilẹ̀ Sípéènì, kò tẹ ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.