Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Aráàlú Ṣèbẹ̀wò Tó Mórí Wọn Wú

Aráàlú Ṣèbẹ̀wò Tó Mórí Wọn Wú

Aráàlú Ṣèbẹ̀wò Tó Mórí Wọn Wú

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ JÁMÁNÌ

“Ó GA jù! Àní sẹ́, ó ti lọ wà jù!” “Ẹ kú àlejò wa, a mọrírì àwọn nǹkan mèremère tẹ́ ẹ fi hàn wá. Ńṣe lara tù wá pẹ̀sẹ̀.” Kí ló mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olùṣèbẹ̀wò máa sọ irú àwọn ọ̀rọ̀ ìmọrírì wọ̀nyí? Ìbẹ̀wò tó wáyé lópin ọ̀sẹ̀ ni, èyí tí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Jámánì ṣètò rẹ̀ fún gbogbo èèyàn. Fún ọjọ́ mẹ́ta gbáko, ìyẹn láti ọjọ́ Friday, May 24, sí ọjọ́ Sunday, May 26, 2002, ni àwọn ilẹ̀kùn ẹ̀ka iléeṣẹ́ náà tó wà ní àgbègbè Selters-Taunus fi wà ní ṣíṣísílẹ̀ fún àwọn olùṣèbẹ̀wò láti wá dara pọ̀ mọ́ àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni tí wọ́n lé lẹ́gbẹ̀rún kan tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, láti ṣe ayájọ́ ọgọ́rùn-ún ọdún kan tí wọ́n ti dá ẹ̀ka iléeṣẹ́ ilẹ̀ Jámánì sílẹ̀.

Tìtaratìtara ni àwọn ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní àgbègbè ẹ̀ka iléeṣẹ́ náà fi kópa nínú fífún àwọn èèyàn ní àkànṣe ìkésíni. Ní ọ̀sẹ̀ méjì ṣáájú ọjọ́ ayẹyẹ ńlá náà, ó lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] ìwé ìkésíni tí wọ́n pín fún àwọn èèyàn tàbí tí wọ́n fi sílẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà ilé wọn. Láfikún sí fífún àwọn èèyàn ní ìwé ìkésíni, wọ́n gbé àwọn ìkéde àtàwọn àpilẹ̀kọ gígùn lórí ìbẹ̀wò náà jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tún kéde rẹ̀ lórí rédíò. Wọ́n mú ìwé ìkésíni lọ fún àwọn oníṣòwò tó máa ń ta ọjà fún ẹ̀ka iléeṣẹ́ náà àtàwọn tó jẹ́ aláṣẹ. Ó lé ní ẹgbẹ̀rún méje [7,000] èèyàn tó tẹ́wọ́ gba ìwé ìkésíni náà—ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ni kì í sì ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Àwọn olùṣèbẹ̀wò rìn kọjá láwọn ibi ìtẹ̀wé, ibi ìdìwépọ̀, ẹ̀ka ìkówèéránṣẹ́, àwọn ibi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ọwọ́, àti ibi ìfọṣọ, títí kan apá kan lára ilé tó ní àwọn ọ́fíìsì tí wọ́n ti ń bójú tó iṣẹ́ ibẹ̀. Àwọn àwòrán tí wọ́n fi hàn jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ nípa bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ àwọn ìlànà Bíbélì nílẹ̀ Jámánì nígbà ìṣàkóso ìjọba Násì àti lábẹ́ ìjọba Kọ́múníìsì. Àfihàn kan lórí Bíbélì fi ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ hàn nínú Bíbélì, èyí tó ń pe àfiyèsí sí ìdí tó fi yẹ láti lo orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà. Kò ṣeé ṣe láti kọ gbogbo ọ̀rọ̀ ìmọrírì táwọn èèyàn sọ sínú àpilẹ̀kọ yìí, àmọ́ díẹ̀ rèé lára ohun táwọn èèyàn sọ.

“Gbogbo àwọn tó wà níbí lara wọn yọ̀ mọ́ọ̀yàn. Ohun gbogbo ló mọ́ tónítóní wọ́n sì rí nigínnigín. Gbogbo nǹkan rí bó ṣe yẹ—àwọn èèyàn tó ń gbé níbí bá àyíká yìí mu. Ó wù wá pé kí àwa náà lè ní díẹ̀ lára irú ẹ̀mí ọ̀yàyà tẹ́ ẹ ní.”—Tọkọtaya àgbàlagbà kan.

“Ẹ ṣeun gan-an fún oúnjẹ aládùn tẹ́ ẹ fún wa àti bẹ́ ẹ ṣe tọ́jú wa tọ̀yàyàtọ̀yàyà. A gbádùn rẹ̀ gan-an ni, àá sì fẹ́ láti tún padà wá. Àwọn èèyàn tó wà níbí yìí dára gan-an ni, tẹ̀gàn kọ́!”—Ìwé táwọn àlejò ń kọ ọ̀rọ̀ sí, èyí tí àwùjọ kan láti yunifásítì ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ gíláàsì fi ṣètọrẹ.

“Ẹ ṣeun gan-an ni fún gbígbà tẹ́ ẹ gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀ ní iléeṣẹ́ yín. [A] gbádùn ìbẹ̀wò tá a ṣe síbẹ̀ gan-an ni. Ẹ bá wa kí àwọn tó wà ní ẹ̀ka ìfọṣọ dáadáa, torí a kò tíì ṣèbẹ̀wò sí iléeṣẹ́ tó mọ́ tónítóní tó sì rí nigínnigín bẹ́ẹ̀ rí.”—Lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà tí aṣojú láti iléeṣẹ́ kan tó ń ṣe ọṣẹ ìfọṣọ àtàwọn ohun èèlò mìíràn fi ránṣẹ́.

Eva, tó mú àwọn olùṣèbẹ̀wò káàkiri lọ́jọ́ náà, sọ pé: “Nígbà kọ̀ọ̀kan tí mo bá kó àwọn èèyàn lọ, ẹnì kan á wà ṣáá tí yóò sọ nípa àwọn iyàrá tí à ń gbé pé: ‘Ẹ jẹ́ ká lọ kó ẹrù wa wá. À ń kó bọ̀!’”

Nígbà tí obìnrin kan tó wà nínú àga onítáyà ń wo àwòrán ẹ̀ka iléeṣẹ́ náà nínú ìwé, olùyọ̀ǹda-ara-ẹni kan lọ béèrè bóyá òun lè ràn án lọ́wọ́. Obìnrin náà dáhùn pé: “Rárá, má ṣèyọnu!” Ó sọ pé láti wákàtí márùn-ún sẹ́yìn lòún ti wà nínú ọgbà náà àti pé òun kò lè jókòó sára mọ́ nínú àga onítáyà náà. Orí ibùsùn ló sábà máa ń wà, ara sì ti ń ni ín gan-an lákòókò yẹn. Àmọ́ ó ṣàlàyé pé: “Ǹ bá ní kí n sùn sílé jẹ́jẹ́, àmọ́ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni irú àǹfààní ìbẹ̀wò yìí máa ń yọjú!” Ó fi kún un pé: “Gbogbo nǹkan tó wà níbí ló gbádùn mọ́ni débi pé, mo fẹ́ rí i dájú pé ohun kan kò ṣẹ́ kù tí n kò rí!”

Wọ́n béèrè lọ́wọ́ Georg tó jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún pé kí ló wù ú jù lọ. Níwọ̀n bó ti nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ńlá tó rí, ó dáhùn pé: “Àwọn bébà yẹn ni! Wọ́n á fi wọ́n sínú ẹ̀rọ náà lápá kan, wọ́n á sì jáde lápá kejì bí ìwé ìròyìn. Ìyẹn wù mí gan-an ni!”

Nǹkan ìyàlẹ́nu kan ṣẹlẹ̀ sí Ẹlẹ́rìí kan. Ọkọ rẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, tó jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ló tíì lọ sípàdé Kristẹni rí, gbà láti bá a lọ síbi àbẹ̀wò náà lọ́jọ́ Sátidé. Lọ́jọ́ Sunday, nígbà tí ìyàwó rẹ̀ dé sílé láti ìpàdé ìjọ, ó ti múra dẹ́dẹ́ ó sì ti ṣe tán láti jáde. Ni ìyàwó rẹ̀ bá béèrè pé: “Kí ló ń ṣẹlẹ̀ kẹ̀?” Ó dá a lóhùn pé: “Ṣó o rí i, àkókò kò tó lánàá láti rí gbogbo nǹkan tán. Torí náà, bó o bá ti ṣe tán, ká máa lọ sí Selters ló kù. Mo fẹ́ lọ wo àwọn ohun tó wà níbẹ̀ dáadáa.”

Níbi tí wọ́n ti ṣe àfihàn lórí Bíbélì, obìnrin àgbàlagbà kan tó múra dáadáa fìtìjú béèrè ibi tó ti lè rí fóònù lò torí pé ó fẹ́ bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ ní kíákíá. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, iṣẹ́ dídi ìwé pọ̀ ni ọkọ rẹ̀ ń ṣe, ó mọ̀ nípa ká sọ àwọn ìwé tó ti di ògbólógbòó di tuntun padà. Òun àti ọkọ̀ rẹ̀ máa ń pàdé déédéé pẹ̀lú àwùjọ àwọn èèyàn kan táwọn náà fẹ́ràn ìwé, tí ọ̀kan lára wọn jẹ́ pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì kan, ẹni tó nífẹ̀ẹ́ láti máa ṣa àwọn Bíbélì tó bá ti já kiri. Ẹni yẹn gan-an ló ń wá ọ̀nà láti pè lójú méjèèjì. Níwọ̀n bí ìyẹn kò ti sí nílé, ó ránṣẹ́ sílẹ̀ lórí ẹ̀rọ tẹlifóònù tó máa ń gba ohun sílẹ̀ pé: “Rí i pé o wá síbí yìí lónìí bó bá ti lè ṣeé ṣe fún ọ tó. Ó dá mi lójú pé o ò tíì rí irú nǹkan tí mò ń rí níbí yìí rí. O ò gbọ́dọ̀ má rí i o!”

Tọkọtaya kan àti ọmọ wọn wá ṣèbẹ̀wò láti ìlú Limburg tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà. Wọn ò tíì gbọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí títí di ìgbà tí wọ́n gba ìkésíni nílé wọn. Tọkọtaya náà gbà láti wá wo iléeṣẹ́ ńlá yìí tó wà ní Selters. Marlon àti Leila tí wọ́n jẹ́ olùyọ̀ǹda-ara-ẹni ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ ilẹ̀ Jámánì lọ bá wọn, wọ́n sì ṣàlàyé síwájú sí i fún wọn nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ náà. Gbogbo ìwọ̀nyí wú ìdílé náà lórí débi pé, àwọn òbí náà sọ pé kí ẹnì kan wá sílé àwọn láti wá máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé.

“Ibí yìí ti lọ wà jù, ọ̀pọ̀ nǹkan tó sì ń gbádùn mọ́ni ló kún ibí. Ẹ̀rọ̀ ìtẹ̀wé nìkan ni mo rí, àmọ́ ó tóbi gan-an ni. Èèyàn dáadáa gbáà ni yín, ara yín yọ̀ mọ́ọ̀yàn, ohun tó sì wù mí nìyẹn.”—Ọ̀rọ̀ tí Stefanie (ọmọ ọdún méjìlá) kọ sílẹ̀ nínú ìwé táwọn àlejò ń kọ ọ̀rọ̀ sí.

Obìnrin kan tó wá láti abúlé tó wà nítòsí sọ pé: “Mo gbọ́dọ̀ jẹ́ kẹ́ ẹ mọ nǹkan kan. Mùsùlùmí ni mí, àmọ́ ó ti pẹ́ tí mo ti fẹ́ mọ bí ibí yìí ṣe rí. Gbogbo yín pátá lẹ yááyì léèyàn, tára yín sì balẹ̀. Ẹ jẹ́ kí àwa tá a jẹ́ [àjèjì] nímọ̀lára pé ẹ nífẹ̀ẹ́ wa. Ẹ̀ ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn. Ìyẹn ti lọ wà jù! Èmi àtọkọ mi tún ń bọ̀ lọ́la.” Ohun tí obìnrin náà kọ sínú ìwé àwọn àlejò ni pé: “Inú mi dùn gan-an ni! Ńṣe ló dà bíi pé inú Párádísè ni mo wà.”

Awakọ̀ tó ń wa ọ̀kan lára àwọn bọ́ọ̀sì tó ń kó àwọn èrò láti ibi kan sí òmíràn láàárín ọgbà náà gbọ́ tí ọ̀kan lára àwọn èrò tó gbé ń sọ fún òmíràn pé: “Ara àwọn aráabí yìí mà yọ̀ mọ́ọ̀yàn o! Ìyẹn ni pé nǹkan tó tó báyìí ni wọ́n ń ṣe níbí tí mi ò mọ̀ láti ọjọ́ yìí. Ìsinsìnyí ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mọ ohun táwọn èèyàn wọ̀nyí ń ṣe níbí yìí. O ò rí i bí ìwà wọn ṣe dára. Kò lè ṣẹ̀yìn inú ìsìn tí wọ́n ti tọ́ wọn dàgbà àti ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń fi kọ́ wọn.”

Wákàtí méjì lẹ́yìn tí ayẹyẹ náà parí, ọkùnrin kan ń rìn lọ rìn bọ̀ ní gbàgede náà, níwájú ilé tó ní àwọn ọ́fíìsì tí wọ́n ti ń bójú tó iṣẹ́ ibẹ̀. Ó ń ronú jinlẹ̀ lórí nǹkan kan, bẹ́ẹ̀ ló ń mi orí rẹ̀ tó sì tún ń bojú wẹ̀yìn wo ilé náà. Ló bá sún mọ́ ọ̀kan lára àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni tó wà níbẹ̀, ó sì sọ pé: “Ó hàn gbangba pé ìfẹ́ ló ń sún un yín ṣe gbogbo ohun tẹ́ ẹ̀ ń ṣe níbí. N kì í ṣe ọ̀kan lára ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ mo gbàdúrà pé kí Jèhófà máa bù kún un yín.”

Ẹnì kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí sì kọ̀wé pé: “Pẹ̀lú lẹ́tà kékeré yìí, mo fẹ́ láti fi ìmọrírì àtọkànwá mi hàn sí i yín. Kò sì ohun kan tí ẹ kò ṣe láti mú kí ìbẹ̀wò sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ yìí pinminrin. . . . Gbogbo rẹ̀ látòkèdélẹ̀ jẹ́ ìtọ́wò fún àkókò náà, nígbà tí gbogbo ìran èèyàn á máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan! . . . Dájúdájú, àwọn ọjọ́ ìbẹ̀wò wọ̀nyí sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ yìí ti fi kún ògo Ọlọ́run wa, Jèhófà.”—Sandra.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Wọ́n ṣètò ohun tí wọ́n fi ń gbé àwọn èèyàn lọ sókè lọ sódò, àwọn tó jẹ́ arúgbó, àwọn aláàbọ̀ ara, àtàwọn tò bá kàn ṣáà ti rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Àfihàn àwọn ọ̀nà tí wọ́n ń gbà wàásù láwọn àkókò tó ti kọjá

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Ẹ káàbọ̀ sí àbẹ̀wò ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Àfihàn lórí Bíbélì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Olùyọ̀ǹda-ara-ẹni kan ń ṣàlàyé nípa ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ lọ́nà tó rọrùn láti yéni