Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fífi Ìfẹ́ Hàn Nígbà Ìṣòro

Fífi Ìfẹ́ Hàn Nígbà Ìṣòro

Fífi Ìfẹ́ Hàn Nígbà Ìṣòro

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ NÀÌJÍRÍÀ

SUNDAY, January 27, 2002, jẹ́ ọjọ́ tí wọ́n pè ní Ọjọ́ Burúkú ní ìlú Èkó, lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìbúgbàù tó wáyé nínú ibi tí àwọn ológun ń kó ohun ìjà pa mọ́ sí lábẹ́ ilẹ̀ mú kí ìmìtìtì ilẹ̀ bíburú jáì wáyé káàkiri ìlú náà, tí gbogbo ojú ọ̀run sì mọ́lẹ̀ yòò lálẹ́ ọjọ́ náà. Fún bíi wákàtí mélòó kan ni ìbúgbàù náà fi ń rọ̀jò àwọn ohun abúgbàù àti pàǹtírí sórí ibi tó fẹ̀ tó kìlómítà mẹ́ta lágbègbè ibẹ̀, èyí sì kó ìpayà bá àwọn èèyàn inú ìlú náà.

Àhesọ lóríṣiríṣi tún dá kún ìbẹ̀rù àwọn èèyàn. Ẹgbàágbèje àwọn èèyàn tí jìnnìjìnnì ti bò tú yáyá sí ojú pópó, láìmọ ohun tí wọ́n ń torí ẹ̀ sá tàbí ibi tí wọ́n ń sá lọ. Nínú òkùnkùn alẹ́ náà, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn, títí kan àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ tí ìpayà ti bá, rọ́ wọnú omi ẹrọ̀fọ̀ adágún kan, wọ́n sì kú síbẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé, ilé ìwé, àwọn ibi ìtajà, àtàwọn ọ́fíìsì ló bà jẹ́ gan-an, àwọn mìíràn kò sì ṣeé gbé mọ́, tí èyí sì sọ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn di aláìrílégbé àti aláìníṣẹ́lọ́wọ́. Wọ́n fojú bù ú pé ẹgbẹ̀rún kan èèyàn ló bá àjálù náà rìn. Àwọn ìwádìí tí wọ́n ṣe lẹ́yìn èyí tiẹ̀ fi hàn pé iye àwọn tó kú jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Nǹkan bí àádọ́ta dín légbèje [1,350] àwọn ohun ìjà tí kò bú gbàù, irú bíi bọ́ǹbù, rọ́kẹ́ẹ̀tì, àtàwọn bọ́ǹbù àfọwọ́jù, ni wọ́n lọ ṣà lẹ́yìn náà nínú ilé àwọn èèyàn nítòsí bárékè àwọn ológun tí ìbúgbàù náà ti wáyé. Ọkùnrin kan rí nǹkan onírin kan nínú pálọ̀ rẹ̀. Láìmọ̀ pé bọ́ǹbù ni, o gbé e sẹ́yìn búùtù ọkọ̀ rẹ̀, ó sì lọ dá a padà fún àwọn aláṣẹ.

Nígbà tí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Nàìjíríà gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n kàn sí alàgbà kan ní ìlú Èkó, tí wọ́n sì sọ pé kí àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò mẹ́rìndínlógún tó wà lágbègbè náà fojú díwọ̀n ipò tí àwọn Ẹlẹ́rìí ní ìlú Èkó wà, tí iye wọn tó ẹgbàá méjìdínlógún [36,000]. Ẹ̀ka iléeṣẹ́ náà wá fi mílíọ̀nù kan náírà ránṣẹ́, wọ́n sì tún fún wọn ní ìtọ́ni pé kí wọ́n dá ìgbìmọ̀ aṣèrànwọ́ kan sílẹ̀ láti pèsè ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tí ọ̀ràn kàn.

Láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí, àfọ́kù bọ́ǹbù ṣe ọkùnrin kan léṣe gan-an; ó ṣeni láàánú pé, àwọn ọ̀dọ́bìnrin méjì pàdánù ẹ̀mí wọn; Gbọ̀ngàn Ìjọba méjì àtàwọn ilé tí ìdílé márùnlélógójì ń gbé ló sì bà jẹ́.

Ọjọ́ mẹ́fà lẹ́yìn tí àwọn ohun ìjà náà bú gbàù, ìyẹn February 2, 2002, ìjà ẹlẹ́yàmẹ̀yà kan tún bẹ́ sílẹ̀ ní àgbègbè mìíràn nínú ìlú náà. Níbàámu pẹ̀lú ìsọfúnni tó wá látọ̀dọ̀ Ẹgbẹ́ Alágbèélébùú Pupa, tó ń bójú tó àwọn tó fara pa nígbà ogun àti ìjábá, ìjà náà gbẹ̀mí ọgọ́rùn-ún èèyàn, ọgbọ̀n ó lé nírínwó [430] èèyàn ló sì fara pa, ó sì mú kí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] èèyàn sá fi ilé wọn sílẹ̀ lọ sí àgbègbè mìíràn, bákan náà ni wọ́n dáná sun àádọ́ta ilé nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Lọ́gán ni ìgbìmọ̀ aṣèrànwọ́ tó ti ń bójú tó àwọn tó fara gbá ìṣẹ̀lẹ̀ “Ọjọ́ Burúkú” náà tún wá àwọn Kristẹni arákùnrin wọn rí ní àgbègbè tí ìjà ti ṣẹlẹ̀ yìí.

Kò sí èyíkéyìí lára àwọn Ẹlẹ́rìí tó pàdánù ẹ̀mí wọn nígbà tí ìjà náà ń lọ lọ́wọ́, níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ti lọ sí àpéjọ àyíká nígbà tí ìjà náà bẹ̀rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ìjọ márùn-ún tó wà lágbègbè náà ni kò ní ilé tí wọ́n máa padà sí mọ́. Tinútinú làwọn Kristẹni arákùnrin wọn fi gbà wọ́n sílé. Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ dókítà àti ìyàwó rẹ̀ pèsè ibùgbé fún àwọn èèyàn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n tí ilé wọn ò ṣeé gbé mọ́.

Àwọn Ẹlẹ́rìí ní ìlú Èkó tí kò fara gbá ìṣẹ̀lẹ̀ bọ́ǹbù àti ìjà ẹlẹ́yàmẹ̀yà náà fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ ṣètọrẹ oúnjẹ, aṣọ àtàwọn ohun èlò inú ilé. Alábòójútó fún gbogbo àwọn ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìlú náà kọ̀wé pé: “Ohun tí àwọn ará ní ìlú Èkó fi tọrẹ pọ̀ ré kọjá ohun tí àwọn tí ọ̀ràn kàn nílò.” Ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní láti kọ lẹ́tà sí àwọn ìjọ pé kí wọ́n má ṣe fi ohunkóhun ṣètọrẹ mọ́. Ọkọ̀ akẹ́rù ńlá mẹ́ta ni wọ́n fi kó àwọn ẹrù tó ṣẹ́ kù lára èyí tí wọ́n fi ṣètọrẹ náà, wọ́n sì kó wọn ránṣẹ́ sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ níbi tí a tọ́jú wọn sí.

Àwọn alàgbà ìjọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ lára àwọn tí ọ̀ràn kàn àtàwọn tó jẹ́ ara ìdílé àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn. Wọ́n gbìyànjú láti fi ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ tù wọ́n nínú. Ìgbìmọ̀ aṣèrànwọ́ náà ṣètò láti tún àwọn ilé tó bà jẹ́ ṣe. Wọ́n pèsè àwọn ohun èlò inú ilé, aṣọ, àti oúnjẹ fún àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kàn, wọ́n sì ṣèrànwọ́ fún àwọn tí kò nílé láti rí ibùgbé. Àwọn ìdílé àtàwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan tí iye wọn lápapọ̀ tó àádọ́rùn-ún ni ìgbìmọ̀ náà ṣèrànwọ́ fún.

Ọ̀pọ̀ àwọn tí ọ̀ràn kàn ni ìrànwọ́ tí wọ́n ṣe fún wọn mú orí wọn wú. Ẹlẹ́rìí kan sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀ fún ìgbìmọ̀ aṣèrànwọ́ náà, ó ní: “Ní gbogbo ìgbà tí mo bá fi wà láàyè, Jèhófà ni màá fi ṣe ‘ibi ìsádi àti okun’ mi!”—Sáàmù 46:1, 2.

Àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí kíyè sí bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ran ara wọn lọ́wọ́ nígbà ìṣòro náà. Ọkùnrin kan tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí tó kú náà sọ fún àwọn alàgbà ìjọ àbúrò rẹ̀ pé: “Màá padà wá dúpẹ́ lọ́wọ́ yín gidigidi, màá sì wá kẹ́kọ̀ọ́ síwájú sí i.” Ó sọ fún ìdílé rẹ̀ pé: “Ohun tí mo rí ní Èkó jọ mí lójú gan-an ni. Kódà àwọn tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí gan-an kò ṣe ohun táwọn èèyàn wọ̀nyí ṣe.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwọn ohun èlò tí wọ́n fi ṣèrànwọ́ kún inú ọkọ̀ akẹ́rù yìí bámúbámú

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Díẹ̀ lára àwọn tí wọ́n ràn lọ́wọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Tọkọtaya yìí pèsè ibùgbé fún àwọn èèyàn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n tí ilé wọn ò ṣeé gbé mọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Àwọn Ẹlẹ́rìí ń tún ilé kan tó bà jẹ́ ṣe

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 23]

Òkè: Sam Olusegun – Ìwé ìròyìn The Guardian