Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Jí! Gba Ẹ̀mí Mi Là!”

“Jí! Gba Ẹ̀mí Mi Là!”

Jí! Gba Ẹ̀mí Mi Là!”

Àwọn òǹtẹ̀wé ìwé ìròyìn Jí! gba lẹ́tà kan látọ̀dọ̀ òǹkàwé kan tó mọrírì ìwé ìròyìn náà ní orílẹ̀-èdè Ítálì. Lẹ́tà náà kà lápá kan pé:

“Mo ti ń ka Jí! láti nǹkan bí ogójì ọdún sẹ́yìn, mo sì fẹ́ràn bó ṣe máa ń jíròrò ọ̀kan-kò-jọ̀kan kókó ẹ̀kọ́ tó wúlò. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ibi iṣẹ́ ni mo wà nígbà tí ikùn àti àyà bẹ̀rẹ̀ sí ro mí gooro. Mo pinnu láti lọ sílé, àmọ́ nígbà tí ìrora gógó náà tún dé lẹ́ẹ̀kejì, nǹkan kan wá sí mi lọ́kàn. Mo rántí ní kedere, àpilẹ̀kọ kan nínú Jí! tó ṣàlàyé àwọn àmì tó ń fi hàn pé èèyàn ní àrùn ọkàn. a Ni mo bá pinnu láti lọ sí ilé ìwòsàn. Inú iyàrá tí màá ti rí dókítà ni mo ṣì wà nígbà tí orí mi yẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, tí mo sì dákú lọ rangbọndan. Ọjọ́ kejì ni wọ́n ń sọ èyí fún mi nínú iyàrá ìtọ́jú àkànṣe tí wọ́n gbé mi lọ.

“Ohun tó jẹ́ kí n wà láàyè lónìí ni pé àwọn dókítà amọṣẹ́dunjú gbé ìgbésẹ̀ láìjáfara. Àmọ́ o, mo tún ní láti kan sáárá sí ìwé ìròyìn yín, èyí tó pèsè ìsọfúnni tó ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu ọlọ́gbọ́n pé ó yẹ kí n lọ sí ilé ìwòsàn. Jí! gba ẹ̀mí mi là!”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ìtẹ̀jáde wa ti December 8, 1996, ojú ìwé 6.