Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Àgbàyanu Ni Ṣíṣílọ Àwọn Ẹranko Wildebeest

Ohun Àgbàyanu Ni Ṣíṣílọ Àwọn Ẹranko Wildebeest

Ohun Àgbàyanu Ni Ṣíṣílọ Àwọn Ẹranko Wildebeest

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ KẸ́ŃYÀ

ILẸ̀ mì tìtì bí pátákò ẹsẹ̀ àwọn ẹranko tó tó mílíọ̀nù kan ṣe ń ró nílẹ̀. Àìlóǹkà àwọn ẹranko ń sáré kọjá lọ, wọ́n sì ń fẹsẹ̀ tú eruku pupa sókè. Àwọn ẹranko náà ń bẹ́ lọ gìjàgìjà lórí ẹsẹ̀ wọn tó gùn tó sì tín-ń-rín bí gbogbo wọn ti ń rọ́ kọjá ní àwọn àfonífojì àtàwọn òkè tó da gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, tí wọ́n ń la àwọn ilẹ̀ oníkoríko títẹ́jú kọjá, tí wọ́n sì ń sọdá àwọn odò àtàwọn ìṣàn omi. Ogunlọ́gọ̀ ni wọ́n, bí wọ́n sì ti ń lọ ni wọ́n ń fi àwọn ipa ọ̀nà gbígbòòrò sẹ́yìn, èyí tí wọ́n ti fẹsẹ̀ tẹ koríko wọn rẹ́. Agbo ńlá àwọn ẹranko tó ń ké bíi màlúù yìí, tí gbogbo wọn ń sáré kíkankíkan, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìran àrímáleèlọ tó wúni lórí jù lọ lórí ilẹ̀ ayé tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ẹranko igbó, ìyẹn bí ṣíṣílọ àwọn ẹranko wildebeest ilẹ̀ Áfíríkà ṣe jẹ́ àgbàyanu.

Ọgbà Édẹ́nì Ilẹ̀ Áfíríkà

Àgbègbè Serengeti jẹ́ igbó ńlá kan táwọn èèyàn kò dáko sí. Orílẹ̀-èdè Tanzania àti Kẹ́ńyà ló wà, ó jẹ́ ilẹ̀ oníkoríko tó fẹ gan-an tó sì ní àwọn òkè tó da gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, èyí tó fẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [30,000] kìlómítà. Níbẹ̀, àwọn erùpẹ̀ lẹ́búlẹ́bú ló bo ojú ilẹ̀, èyí tó mú kí ilẹ̀ náà lè máa hu ọ̀pọ̀ yanturu koríko títutù yọ̀yọ̀ jáde. Àwọn àgbègbè igbó kan wà níbẹ̀ tó jẹ́ pé àwọn igi bọn-ọ̀n-ní ló kún ibẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀dàn sì wà pẹ̀lú, èyí tó ní àwọn igi ẹlẹ́gùn-ún, tí àwọn igi wọ̀nyí sì ń pèsè ewé fún agbo àwọn erin tí wọ́n ń jẹ̀ kiri. Àwọn àgùnfọn pàápàá ò gbẹ́yìn, bí wọ́n ti rọra ń fi ẹsẹ̀ wọn gígùn rìn-lọ rìn-bọ̀ lọ́nà tó wuni lórí nínú ọ̀dàn náà.

Àwọn òkúta tí ẹ̀fúùfù àti òjò ti sọ orí wọn di dídán, tí wọ́n yọrí jáde láti inú ilẹ̀ láwọn apá ibì kan, mú kí ibẹ̀ jẹ́ ibi tó dára gan-an fún àwọn kìnnìún àti àmọ̀tẹ́kùn láti lé téńté sí kí wọ́n lè máa ṣọ́ àwọn ẹranko. Àwọn odò tó ń yára ṣàn gba àárín igbó náà kọjá kún fún àwọn erinmi àtàwọn ọ̀nì. Láwọn apá ibi tí ilẹ̀ ti tẹ́jú pẹrẹsẹ, èèyàn lè rí agbo àwọn ẹranko wildebeest, ìrá kùnnùgbá, àwọn ẹranko topis, àti ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀ya ẹtu mìíràn tí wọ́n ń jẹ koríko. Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà tí òùngbẹ ń gbẹ kóra jọ síbi àwọn ihò omi, wọ́n sì tò yí àwọn ihò náà ká bí ìgbà tí ìlẹ̀kẹ̀ tó ní àwọ̀ dúdú àti funfun bá tò yíká ọrùn. Àwọn àgbàlàǹgbó àtàwọn ẹranko impala ń fìrọ̀rùn bẹ́ gìjàgìjà káàkiri ilẹ̀ títẹ́jú náà pẹ̀lú ẹ̀yìn wọn tó tẹ̀ kòlòbà. Agbo àwọn ẹfọ̀n ńlá orí ọ̀dàn náà wà níbẹ̀, pẹ̀lú ìwo wọn lílọ́, tó rí gàgàrà àti ara wọn yíyi tó kún fún iṣan, tí wọ́n rọra ń jẹko, tí wọ́n sì ń fi ẹnu wọn títóbi fa koríko tu.

Agbo kìnnìún pọ̀ gan-an nínú igbó Serengeti. Nígbà tí oòrùn bá mú ganrín-ganrín lọ́sàn-án, wọ́n á rọra nà sábẹ́ ìbòòji tó wà lábẹ́ àwọn igi àtàwọn koríko igbó, wọ́n á sì máa dúró kí ọjọ́ rọ̀ láti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọdẹ. Èèyàn fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè rí àwọn àmọ̀tẹ́kùn aláwọ̀ tó-tò-tó níbi tí wọ́n dùbúlẹ̀ sí, tí wọ́n rọ̀gbọ̀kú bí ọba sórí àwọn ẹ̀ka tó wà lápá òkè àwọn igi, tí ìmọ́lẹ̀ oòrùn tó ṣe tó-tò-tó láàárín àwọn ewé orí igi sì bá ara wọn mu gẹ́lẹ́. Ilẹ̀ koríko tó fẹ̀ lọ salalu dára gan-an fún àwọn ẹranko cheetah tó jẹ́ ayára-bí-àṣá, níwọ̀n bí ó ti fún wọn láyè láti sá eré ẹsẹ̀ wọn. Kíá ni ara rẹ̀ lẹ́gẹ́lẹ́gẹ́ máa ń pòórá mọ́ èèyàn lójú bó ti ń kùn lọ bọ̀n-ùn la ilẹ̀ fífẹ̀ náà já nígbà tó bá ń lé ẹran tó fẹ́ pa jẹ.

Ká sòótọ́, párádísè ni igbó Serengeti jẹ́ fún onírúurú àwọn ẹranko tó fibẹ̀ ṣelé, àrímáleèlọ sì ni ìran wọn. Àmọ́, agbo títóbi àwọn ẹranko wildebeest ni ìran tó jẹ́ àrímáleèlọ jù lọ nínú igbó tó kún fún oríṣiríṣi ẹranko yìí.

Apanilẹ́rìn-ín Inú Igbó

Àwọn ẹranko wildebeest tí wọ́n fojú bù pé wọ́n wà nínú igbó Serengeti á tó mílíọ̀nù kan ààbọ̀. Àràmàǹdà ẹ̀dá ni ẹranko yìí. Orí rẹ̀ gùn ó sì ní ojú tó ń tàn yanran tí ọ̀kan jìnnà sí èkejì lókè agbárí rẹ̀. Àwọn ìwo rẹ̀ tó dà bíi ti màlúù yọ sẹ́gbẹ̀ẹ́, ó sì tẹ̀ sókè. Apá ìbàdí rẹ̀ rí paṣoro, ó sì kéré sí èjìká àti ọrùn rẹ̀ tó ki. Àwọn ẹsẹ̀ tín-ín-rín ló gbé ara ẹranko wildebeest wíwúwo náà dúró. Pẹ̀lú irùngbọ̀n funfun lágbọ̀n rẹ̀, gọ̀gọ̀ dúdú lókè ọrùn rẹ̀, àti ìrù bíi ti ẹṣin tó ní, ńṣe ló dà bíi pé onírúurú ẹranko ló para pọ̀ di ẹranko wildebeest.

Ìṣesí àwọn ẹranko wildebeest sábà máa ń pani lẹ́rìn-ín ó sì máa ń dáni lára yá. Nígbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹranko yìí bá kóra jọ síbì kan náà, ariwo tí wọ́n máa ń pa máa ń dà bí ìgbà tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀pọ̀lọ́ bá ń ké pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà. Bí wọ́n bá dúró nínú igbó tó tẹ́ lọ rẹrẹẹrẹ tí wọ́n sì ń wòye ohun tó ń lọ láyìíká, ńṣe ni wọ́n máa ń wò bí ẹni tí ṣìbáṣìbo bá tí ohun kan sì ń yà lẹ́nu.

Nígbà míì, akọ ẹranko wildebeest kan á sáré kíkankíkan la àárín ilẹ̀ oníkoríko náà já, tí yóò máa fi àwọn ẹsẹ̀ ẹ̀yìn rẹ̀ fò sọ́tùn-ún fò sósì, tí yóò sì máa sáré yí po. Bó ti ń ju orí síwá-sẹ́yìn bẹ́ẹ̀ ni yóò máa fò sókè tí yóò sì máa fẹsẹ̀ rẹ̀ ta erùpẹ̀ sókè lọ́nà tí ń pani lẹ́rìn-ín. Àwọn kan sọ pé ìdí tó fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí ni láti fa abo mọ́ra tàbí láti fi ìṣe akọni yìí kìlọ̀ fún àwọn akọ ẹgbẹ́ rẹ̀. Àmọ́ nígbà míì, ó jọ pé ńṣe ni ẹranko náà wulẹ̀ ń ṣeré ní tiẹ̀.

Inú Ayé Oníṣòro Ni Wọ́n Ń Bímọ Wọn Sí

Nígbà tí àkókò ìbímọ wọn bá tó, àwọn ẹranko wildebeest á bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ. Wọ́n ní agbára àrà ọ̀tọ̀ kan, ìyẹn ni láti bí gbogbo àwọn ọmọ wọn láàárín àkókò kan náà. Wọ́n lè bí ìdá ọgọ́rin sí ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ wọn láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́ta péré. Láàárín àkókò yìí, agbo wọn máa ń tóbi sí i, tí igbe àwọn ọmọ wọn kéékèèké tó ń lọ sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún tí wọ́n ń ké mẹ̀ẹ́ẹ̀-mẹ̀ẹ́ẹ̀ á sì gba àárín wọn kan. Ìyá kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ tètè fara yí ọmọ rẹ̀, nítorí bí gbogbo agbo náà bá ṣàdéédéé bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ nítorí ìpayà, ìyá àti ọmọ lè pínyà, kò sì dájú pé ọmọ náà á wà láàyè láìsí ìtọ́jú ìyá rẹ̀.

Inú ayé oníṣòro ni wọ́n ń bí àwọn ọmọ náà sí, níbi táwọn ẹranko tó fẹ́ pa wọ́n jẹ ti ń ṣọ́ wọn lójú méjèèjì. Àwọn abo máa ń dúró dìgbà tó bá dà bíi pé kò sí ewu kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí bímọ. Àmọ́ bó bá ṣẹlẹ̀ pé ọ̀kan lára àwọn ẹranko tó máa ń pa ẹranko mìíràn jẹ yọ lójijì, wọ́n ní agbára arà ọ̀tọ̀ láti dá ìbímọ náà dúró kí wọ́n sì fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ. Lẹ́yìn ìgbà náà, tí ewu kankan kò bá sí mọ́, wọn lè wá parí ìbímọ náà.

Ó jọ pé ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí náà ti mọ̀ pé ewu ń bẹ, torí pé àárín ìṣẹ́jú díẹ̀ tí wọ́n bí i ni yóò ti máa dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan tí ọmọ náà dáyé, yóò ti lè máa sáré kiri ilẹ̀ títẹ́jú náà ní àádọ́ta kìlómítà ní wákàtí kan.

Ìlọ Yá

Àwọn ẹranko wildebeest máa ń ṣí lọ ní agbo ńláńlá la igbó Serengeti já. Ìdí tí wọ́n fi máa ń ṣí lọ láìṣẹ́kù bẹ́ẹ̀ jẹ́ nítorí òjò. Bí ojú ọjọ́ ṣe máa ń yí po lọ́dọọdún ló ń pinnu rírọ̀ òjò. Jálẹ̀ ọdún, òjò sábà máa ń rọ̀ ní àgbègbè kan tàbí òmíràn nínú ilẹ̀ oníkoríko tó fẹ̀ lọ rẹrẹẹrẹ yìí.

Àwọn ẹranko wildebeest gbọ́dọ̀ máa rí omi mu lójoojúmọ́ bẹ́ẹ̀ ni koríko kò gbọ́dọ̀ wọ́n wọn. Níwọ̀n ìgbà tí oúnjẹ àti omi bá ṣì wà, wọn ò ní ṣí kúrò níbi tí wọ́n wà. Àmọ́ bí ẹ̀ẹ̀rùn ṣe ń mú sí i ni àwọn koríko ilẹ̀ títẹ́jú náà á bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ, tí àwọn ibi tí wọ́n ti máa ń rí omi mu kò sì ní sí mọ́. Àwọn agbo ẹran náà kò lè dúró títí di ìgbà tí àkókò òjò mìíràn máa dé. Wọ́n gbọ́dọ̀ ṣí lọ síbi tí òjò bá ti ń rọ̀.

Níbikíbi tí òjò bá ti ń rọ̀, kíákíá ni ilẹ̀ máa ń yíra padà. Láàárín ọjọ́ díẹ̀ péré, àwọn koríko kéékèèké á bẹ̀rẹ̀ sí hù jáde nínú ilẹ̀ náà, wọ́n á sì pọ̀ gidigidi. Àwọn koríko ọ̀mùnú náà máa ń ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan aṣaralóore nínú wọ́n sì máa ń tutù yọ̀yọ̀, èyí sì máa ń fa àwọn ẹranko wildebeest mọ́ra gan-an.

Àwọn ẹranko yìí ní agbára àrà ọ̀tọ̀ kan tí wọ́n fi máa ń mọ̀ pé òjò ń rọ̀ níbì kan, kódà láwọn ibi jíjìnnà pàápàá. Kò sẹ́ni tó dá lójú bí wọ́n ṣe máa ń mọ̀ pé òjò ń rọ̀ ní àgbègbè ibòmíràn nínú igbó Serengeti—bóyá nípa rírí ìkùukùu tó ń gbára jọ lójú ọ̀run lọ́nà jíjìn ni o tàbí nínímọ̀lára atẹ́gùn tútù tó ń fẹ́ ni o. Èyí ó wù kó jẹ́, àwọn agbo ẹran náà gbọ́dọ̀ ṣí lọ kí wọ́n lè máa wà láàyè nìṣó. Bẹ́ẹ̀ ni o, ṣíṣí ni wọ́n máa ń ṣí lọ!

Ìrìn Àjò Eléwu

Níbẹ̀rẹ̀, díẹ̀díẹ̀ ni wọ́n máa ń ṣí lọ. Àwọn ẹranko wildebeest jẹ́ ẹ̀dá tó máa ń fẹ́ láti wà pẹ̀lú ara wọn; nígbà tí ọ̀kan nínú wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí apá ibì kan, àwọn yòókù láyìíká rẹ̀ á dáwọ́ koríko tí wọ́n ń jẹ dúró, wọ́n á sì tẹ̀ lé e. Láìpẹ́ láìjìnnà, gbogbo agbo náà á bẹ̀rẹ̀ sí sáré lọ lọ́nà kíkàmàmà. Nítorí ebi tó ń pa wọ́n àti òùngbẹ tó ń gbẹ wọ́n, wọn kì í padà sẹ́yìn, ńṣe ni wọ́n á máa lọ síwájú. Nígbà míì wọ́n á ki eré mọ́lẹ̀. Ìgbà míì sì rèé, ńṣe ni wọ́n á máa tò tẹ̀ léra wọn lọ́wọ̀ọ̀wọ́, tí wọ́n á sì máa fi ipa ẹsẹ̀ wọn sílẹ̀ sẹ́yìn lórí erùpẹ̀ eléruku náà.

Ìrìn àjò wọn máa ń kún fún ewu. Àwọn ẹranko apẹranjẹ máa ń tẹ̀ lé àwọn agbo ẹran ńlá náà lẹ́yìn, tí wọ́n á máa ṣọ́ èyíkéyìí nínú wọn tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò bá yá tàbí tó yarọ tàbí tó ń ṣàìsàn. Bí àwọn ẹranko wildebeest náà ṣe ń bá ìrìn àjò wọn nìṣó, wọ́n á dé àwọn àgbègbè tí agbo àwọn kìnnìún máà ń wà, tí wọ́n lúgọ sínú igbó. Àwọn kìnnìún tó ti sá pa mọ́ sẹ́yìn àwọn koríko tó ga sókè náà yóò já wọ àárín ogunlọ́gọ̀ àwọn ẹranko tó ń jẹko yìí, ni ṣìbáṣìbo á bá bá wọn tí wọ́n á sì tú ká. Gbogbo àwọn ẹranko bí àmọ̀tẹ́kùn, ẹranko cheetah, ìkookò, àtàwọn ẹranko apẹranjẹ mìíràn ló máa ń lo àǹfààní náà láti pa ẹran èyíkéyìí tó bá wà lẹ́yìn jẹ tàbí èyí tó ti rìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tó kù. Nígbà tí wọ́n bá pa ọ̀kan lára wọn, àwọn ẹyẹ igún á ṣàdéédéé yọ síbẹ̀. Bí wọ́n ti ń pariwo ni wọ́n á máa jà lórí òkú ẹran náà, wọn ò sì ní fi ohunkóhun sílẹ̀ lára rẹ̀ àyàfi àwọn egungun rẹ̀, èyí tí yóò wá funfun pìn-ìn bí oòrùn gbígbóná ilẹ̀ Áfíríkà ti ń ràn sí i lórí.

Àwọn odò tó ń yára ṣàn táwọn agbo ẹran náà gbọ́dọ̀ gba inú rẹ̀ kọjá máa ń dá ìṣòro ńlá sílẹ̀ fún wọn. Ìran wọn máa ń dùn ún wò tí wọ́n bá ń sọdá odò, bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹranko náà ti ń kán lu omi látorí àwọn etídò gíga. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn máa ń sọdá sódìkejì láìséwu. Ìṣàn omi sì máa ń gbé àwọn mìíràn lọ tàbí kí àwọn ọ̀nì tó ti lanu sílẹ̀ nísàlẹ̀ odò gbé wọn jẹ. Ọdọọdún ni wọ́n máa ń rìnrìn àjò eléwu yìí. Nígbà tí wọ́n bá sì parí rẹ̀, wọ́n lè ti rin ẹgbẹ̀rún mẹ́ta kìlómítà.

Èèyàn Ni Olórí Ọ̀tá Wọn

Fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, àwọn èèyàn kò fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìṣòro fún àwọn ẹranko wildebeest nígbà tí wọ́n bá ń ṣí lọ. Àmọ́ báyìí, àwọn èèyàn gan-an ló wá jẹ́ ewu títóbi jù lọ fún àwọn ẹranko yìí. Láwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí, àwọn ìjọba ilẹ̀ Tanzania àti ilẹ̀ Kẹ́ńyà ti gbìyànjú láti dáàbò bo àwọn ẹranko inú igbó Serengeti. Síbẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ibi tí ẹranko wildebeest máa ń gbà tí wọ́n bá ń ṣí lọ wà lára àwọn ibi tí wọ́n ń dáàbò bò nínú igbó náà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹranko náà làwọn apẹran láìgbàṣẹ máa ń dẹkùn mú tí wọ́n sì ń pa. Páńpẹ́ onírin, ọfà onímájèlé àti ìbọn ni wọ́n máa ń fi ṣọdẹ àwọn ẹranko inú igbó náà láti tà wọ́n fún àwọn tó fẹ́ jẹ wọ́n àtàwọn tó máa ń fẹ́ láti ra àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ ara ẹran. Ogunlọ́gọ̀ àwọn aṣọ́gbó àtàwọn tó ń mójú tó àwọn ẹranko ló máa ń rìn-lọ rìn-bọ̀ láwọn àgbègbè tí wọ́n ń dáàbò bò náà, àmọ́ igbó Serengeti fẹ̀ débi pé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà ṣeé ṣe láti dáàbò bo gbogbo rẹ̀ tán. Bí iye èèyàn ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni ìṣòro tó ń bá ilẹ̀ oníkoríko tó lọ́ràá yìí náà ń pọ̀ sí i. Yíyà tí wọ́n ya àwọn àgbègbè títóbi lára ilẹ̀ náà sọ́tọ̀ fún àwọn ẹranko igbó jẹ́ kókó kan tó ń fa arukutu nígbà gbogbo.

Nígbà kan rí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹfọ̀n ló ń rìn káàkiri inú igbó Àríwá Amẹ́ríkà. Àmọ́ báyìí, wọn ò sí mọ́. Àwọn kan ń kọminú pé àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé ohun kan náà ló ṣì máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn agbo wildebeest ńlá tó ṣẹ́ kù ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà. Nǹkan burúkú gbáà ló máa jẹ́ lọ́jọ́ tá a bá lọ mọ̀ pé ohun àgbàyanu inú ìṣẹ̀dá yìí ti dàwátì. À ń wọ̀nà fún àkókò náà, lábẹ́ ìṣàkóso òdodo ti Ọlọ́run, nígbà tí èèyàn àti ẹranko yóò máa gbé pọ̀ ní àlàáfíà àti ìṣọ̀kan. (Aísáyà 11:6-9) Kí àkókò náà tó dé, ìran àrímáleèlọ yìí yóò ṣì máa jẹ́ ohun ìwúrí fún wa, ìyẹn bí ṣíṣílọ àwọn ẹranko wildebeest ṣe jẹ́ àgbàyanu.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Àwọn agbo ẹran yìí ní láti gba inú àwọn odò tó ń yára ṣàn kọjá