Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àkóbá Tí Oògùn Olóró Ń Ṣe fún Àwọn Ọ̀dọ́

Àkóbá Tí Oògùn Olóró Ń Ṣe fún Àwọn Ọ̀dọ́

Àkóbá Tí Oògùn Olóró Ń Ṣe fún Àwọn Ọ̀dọ́

“Ṣé ó yẹ kí wọ́n kú?”

Ìbéèrè yìí ló fara hàn níwájú ìwé ìròyìn ilẹ̀ Brazil náà, Veja. Fọ́tò àwọn ọmọ tí ò gé lápá, tí ò gé lẹ́sẹ̀, tí wọ́n dùn ún wò wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ gbólóhùn náà. Oògùn olóró ló pa wọ́n.

LÁÌKA àwọn ewu tó dájú pé ó wà nínú lílo oògùn olóró sí, àwọn èèyàn ò jáwọ́ nínú lílò ó, èyí sì ń bà wọ́n láyé jẹ́ nìṣó, kódà ó ń ṣekú pa wọn pàápàá. Owó tí wọ́n fojú bù pé orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ń ná lọ́dọọdún lórí ìṣòro lílo oògùn olóró wọ ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù dọ́là, ìyẹn owó tí wọ́n fi ń tọ́jú àwọn tí oògùn olóró ti ba ayé wọn jẹ́, owó tí wọ́n ń pàdánù nítorí àkóbá tó ń ṣe fún iṣẹ́, owó tó yẹ kó wọlé sápò ìjọba àmọ́ tí kò wọlé àti owó tí wọ́n ń ná lórí ìwà ipá táwọn tó ń lo oògùn olóró ń hù. Ṣùgbọ́n, àfàìmọ̀ ni kì í ṣe pé àwọn èwe, ìyẹn àwọn ọmọdé, ló ń forí fá èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àkóbá tí lílo oògùn olóró ń ṣe. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Brazil ti fi hàn, èyí tí wọ́n gbé jáde nínú ìwé ìròyìn Jornal da Tarde, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́wàá sí ọdún mẹ́tàdínlógún tí wọ́n ti tọ́ irú àwọn oògùn olóró kan wò.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà kí àwọn ọ̀dọ́langba máa lo oògùn olóró ti lọ sílẹ̀ lọ́nà kan ṣáá ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn ọ̀dọ́ tí lílo oògùn olóró ti di bárakú fún kì í ṣe kékeré. Gbé àpẹẹrẹ àwọn ọ̀dọ́ tó máa tó jáde ní ilé ẹ̀kọ́ gíga yẹ̀ wò. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ti fi hàn, ìdá mẹ́tàdínlógójì nínú ọgọ́rùn-ún wọn ló ti fi igbó dánra wò ní ọdún kan ṣáájú. Ọ̀kan nínú márùn-ún wọn ló mu ún ní oṣù kan ṣáájú. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀kan nínú mẹ́wàá wọn tó ti gbìyànjú oògùn olóró tí wọ́n ń pè ní ecstasy wò ní ọdún kan ṣáájú. Ohun tó lé ní ìdá mẹ́fà nínú ọgọ́rùn-ún wọn ló sì ti dán oògùn olóró tó ń jẹ́ LSD wò.

Àwọn ìròyìn tá à ń gbọ́ káàkiri ayé pàápàá kò bójú mu rárá. Ẹ̀ka Tó Ń Rí Sí Ṣíṣe Ìwádìí ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ròyìn pé, “ìdá méjìlá nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ iléèwé tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mọ́kànlá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ti lo oògùn olóró ní ọdún kan ṣáájú . . . Oògùn olóró tí kò sí àní-àní pé wọ́n á ti lò ni cannabis [igbó].” Ohun tó wá dẹ́rù bani jù lọ ni pé, “iye tó ju ìdá mẹ́ta nínú ọgọ́rùn-ún wọn làwọn kan ti rọ̀ láti dán oògùn olóró kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ wò.”

Bákan náà, ìròyìn kan tí Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé láàárín àwọn ọ̀dọ́, “mímutíyó kẹ́ri ti di ohun tó wọ́pọ̀ gan-an.” Ìròyìn náà tún sọ pé, “mímutí nímukúmu yìí ló ń fa oríṣiríṣi àwọn àkóbá kan tó ń ṣẹlẹ̀, irú bíi jàǹbá ọkọ̀, ìwà ipá àti gbígbé májèlé jẹ, títí kan kí àwọn èwe má lè dàgbà bó ṣe yẹ àti híhùwà lódìlódì.” Ìròyìn kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Japan sọ pé, “oògùn olóró tí àwọn ọ̀dọ́langba orílẹ̀-èdè Japan sábà máa ń lò ni fífa òórùn oríṣiríṣi kẹ́míkà símú, èyí tó lè yọrí sí lílo àwọn oògùn olóró mìíràn.”

Abájọ, nígbà náà, tí Ọ̀gá Àgbà fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ọ̀gbẹ́ni Kofi Annan fi sọ pé: “Oògùn olóró ń ba àwùjọ wa jẹ́, ó ń fa ìwà ipá, ó ń tan àrùn kálẹ̀, irú bí àrùn éèdì, ó sì ń pa àwọn ọ̀dọ́ wa àti ọjọ́ iwájú wa run.” Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn èèyàn tó ń lo oògùn olóró ló máa ń wà nídìí àwọn ìwà ọ̀daràn bíi ṣíṣòwò oògùn olóró àtàwọn ìpànìyàn tí lílo oògùn olóró ń fà. Yàtọ̀ síyẹn, nítorí lílo oògùn olóró, ọ̀pọ̀ èèyàn ni wọ́n máa ń hùwà ipá sí, tí wọ́n máa ń ṣe léṣe, tàbí tí wọ́n máa ń bá ní ìbálòpọ̀ tó léwu, èyí tí wọn ò wéwèé rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Tó o bá sì ń rò pé ìṣòro yìí yọ ìdílé rẹ sílẹ̀, á dáa kó o ronú wò dáadáa! Ìròyìn kan tí ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà tẹ̀ jáde sọ pé: “Oògùn olóró kì í ṣe ìṣòro àwọn akúṣẹ̀ẹ́, àwọn àwùjọ tó kéré, tàbí àwọn kòlàkòṣagbe tó ń gbé àárín ìgboro ìlú nìkan. . . . Onírúurú ipò làwọn tó ń lo oògùn olóró ti wá wọ́n sì wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin orílẹ̀-èdè yìí. Kò sẹ́ni tí ìṣòro oògùn olóró yọ sílẹ̀.”

Síbẹ̀, lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn òbí kì í tètè kíyè sí ìṣòro yìí, ó dìgbà tó bá ti bọ́ sórí tán. Gbé ọ̀ràn ọ̀dọ́mọbìnrin ilẹ̀ Brazil kan yẹ̀ wò. Regina, tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n ọmọbìnrin náà sọ pé: “Ó ti máa ń mu ọtí líle tẹ́lẹ̀.” a Ìdílé wa rò pé kò sóhun tó burú nínú ìyẹn. Àmọ́ èyí yọrí sí kó máa dán àwọn oògùn olóró wò lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ńṣe làwọn òbí mi máa ń bá a lò bíi pé àwọn ìṣòro tó ń dá sílẹ̀ kò jẹ́ nǹkan kan, ọ̀rọ̀ rẹ̀ wá di ohun tí apá ò ká mọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà la kàn máa ṣàdédé wá a tì nílé. Gbogbo ìgbà tí àwọn ọlọ́pàá bá sì ti rí ọmọbìnrin tó kú ni wọ́n máa ń ké sí bàbá mi pé kó wá wò ó bóyá òun ni! Ìbànújẹ́ kékeré kọ́ ni èyí ń mú bá ìdílé mi.”

Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ ìdí márùn-ún pàtàkì tí lílo oògùn olóró fi máa ń wu àwọn ọ̀dọ́:

(1) Wọ́n fẹ́ máa ṣe bí àgbàlagbà kí wọ́n sì máa dá ṣèpinnu

(2) Wọ́n fẹ́ bẹ́gbẹ́ mu

(3) Wọ́n fẹ́ kí ara tù wọ́n kí inú wọn sì máa dùn ṣáá

(4) Wọ́n fẹ́ máa fẹ̀mí wọn wewu kí wọ́n sì máa ṣọ̀tẹ̀

(5) Wọ́n fẹ́ mọ bí oògùn olóró ṣe máa ń rí lára.

Bí oògùn olóró ṣe wà káàkiri àti ẹ̀mí-ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe tún lè mú kí ọ̀dọ́ kan dáwọ́ lé àṣà fífi ọwọ́ ara ẹni ba tara ẹni jẹ́ yìí. Luiz Antonio, ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Brazil sọ pé: “Àwọn òbí mi kò bá mi sọ ohunkóhun rí nípa oògùn olóró. Ní iléèwé, àwọn olùkọ́ máa ń mẹ́nu kan ìṣòro yìí àmọ́ wọn kì í sọ ọ́ kúnnákúnná.” Nígbà tí àwọn ọmọléèwé Luiz sì fi oògùn olóró lọ̀ ọ́, bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí lò ó nìyẹn lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá. Nígbà tó gbìyànjú láti jáwọ́ lẹ́yìn náà, ọ̀bẹ làwọn “ọ̀rẹ́” tó ń kó oògùn olóró fún un yọ sí i, wọ́n sọ pé kò tó bẹ́ẹ̀!

Ṣé o ti gbà pé àwọn ọmọ tìrẹ náà lè wà nínú ewu yìí? Kí làwọn ohun tó o ti ṣe kí wọ́n má bàa dẹni tó ń lo oògùn olóró? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e á jíròrò àwọn ọ̀nà kan tí àwọn òbí lè gbà dáàbò bo àwọn ọmọ wọn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

“Oògùn olóró ń ba àwùjọ wa jẹ́, ó ń fa ìwà ipá, ó ń tan àrùn kálẹ̀, irú bí àrùn éèdì, ó sì ń pa àwọn ọ̀dọ́ wa àti ọjọ́ iwájú wa run.”—KOFI ANNAN, Ọ̀GÁ ÀGBÀ FÚN ÀJỌ ÌPARAPỌ̀ ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

©Veja, Editora Abril, May 27, 1998