Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìpàdé Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nínú Ọdún

Ìpàdé Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nínú Ọdún

Ìpàdé Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nínú Ọdún

Fojú inú wò ó pé àìsàn kan tó lè gbẹ̀mí ẹni ń ṣe ọ́. Iṣẹ́ abẹ ló lè wò ọ́ sàn, àmọ́ owó táwọn oníṣègùn fẹ́ gbà ju agbára ẹ lọ. Wàyí o, ká ní o wá rí olóore kan tó ní òun á bá ọ san owó iṣẹ́ abẹ́ náà. Ǹjẹ́ o ò ní dúpẹ́ oore tó ṣe láti gbẹ̀mí rẹ là?

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ náà, Ádámù àti Éfà, ta ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú látaré sórí gbogbo àwọn àtọmọdọ́mọ wọn. Nígbà náà, a lè kúkú sọ pé, gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan la bí pẹ̀lú àrùn kan tí kò gbóògùn—kò sì sẹ́nì kankan nínú wa tó lè sanwó tó máa tó láti fi rí ìwòsàn. (Sáàmù 49:7-9) Síbẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run pèsè Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ láti rà wá padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa. Torí ẹ̀bùn tí ń gbẹ̀mí là yìí, a ní àǹfààní láti gbé títí láé nínú Párádísè.—Róòmù 6:23.

Ní Wednesday, April 16, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò ṣayẹyẹ ìrántí ikú Jésù. Lọ́dún tó kọjá, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15,000,000] èèyàn tó wá síbi ayẹyẹ náà—ọ̀pọ̀ jù lọ lára iye yìí sì ni kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A ké sí ọ láti wá síbi Ìṣe Ìrántí ikú Kristi ti ọdún yìí. Ní tòótọ́, ìpàdé yìí ló ṣe pàtàkì jù lọ nínú ọdún. Jọ̀wọ́ béèrè àkókò ìpàdé náà àti ibi tá a ti máa ṣe é lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní àdúgbò rẹ.