Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ayé Kan Tó Bọ́ Lọ́wọ́ Oògùn Olóró Yóò Dé Láìpẹ́

Ayé Kan Tó Bọ́ Lọ́wọ́ Oògùn Olóró Yóò Dé Láìpẹ́

Ayé Kan Tó Bọ́ Lọ́wọ́ Oògùn Olóró Yóò Dé Láìpẹ́

Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo ayé kan níbi táwọn èèyàn ò ti ní lo oògùn olóró?

Ọ̀GÁ ÀGBÀ fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ọ̀gbẹ́ni Kofi Annan, ké sí gbogbo orílẹ̀-èdè àgbáyé pé kí wọ́n sa ipá wọn láti rí i pé irú ayé bẹ́ẹ̀ wà. Ó kéde pé: “A gbọ́dọ̀ gbé àwọn ìgbésẹ̀ tuntun tìgboyàtìgboyà, láti gbógun ti ìṣòro burúkú yìí tó ń ba ayé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ọmọ wa jẹ́.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aṣáájú lè fohùn ṣọ̀kan láti dín àwọn oògùn tí kò bófin mu táwọn èèyàn ń mú jáde jákèjádò ayé kù àti bí wọ́n ṣe ń pín wọn kiri, èyí kì í ṣe iṣẹ́ kékeré rárá. Hennadiy Udovenko, ọmọ orílẹ̀-èdè Ukraine tó jẹ́ alága Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Gíga Jù Lọ fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ pé, “pẹ̀lú iye tí wọ́n fojú bù pé ó lé ní irínwó bílíọ̀nù dọ́là tí àwọn tó ń ṣòwò oògùn olóró ń rí lọ́dún, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òwò tí kò bófin mu tó ń mówó wọlé jù lọ̀, . . . ó sì lè ba àwọn okòwò àgbáyé yòókù jẹ́ tàbí kó dojú wọn dé.” Ó wá fi kún un pé, ìṣòro oògùn olóró “ti di ọ̀ràn ńlá lágbàáyé, kò sì sí orílẹ̀-èdè kan tó lè sọ pé ewu yìí yọ òun sílẹ̀.”

Ó ṣòro láti ronú nípa ayé kan níbi tí kò ti sí àwọn oògùn olóró wọ̀nyí. Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n pé akitiyan àwọn ìjọba èèyàn láti mú un kúrò ti já sí òtúbáńtẹ́. Àmọ́ ṣá o, kò sẹ́ni tó lè dí Ọlọ́run Olódùmarè lọ́wọ́ láti má ṣe mú ète rẹ̀ ṣẹ, ìyẹn ni láti mú párádísè orí ilẹ̀ ayé kan wá, níbi tí gbogbo ohun tí ẹ̀dá èèyàn nílò nípa ti ìmí ẹ̀dùn, nípa ti ara, àti nípa tẹ̀mí yóò ti tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́. (Sáàmù 145:16; Lúùkù 23:43; 2 Pétérù 3:13) Gẹ́gẹ́ bí wòlíì Aísáyà ti sọ, ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ ‘kì yóò padà sọ́dọ̀ rẹ̀ láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tó ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí ó tìtorí rẹ̀ rán an.’—Aísáyà 55:11.

Níní ìrètí nínú àwọn ìlérí wọ̀nyẹn lè mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní wá, kódà nísinsìnyí pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, Edmundo ti jẹ́ ajoògùnyó nígbà kan rí. Àmọ́ títẹ́wọ́ gba ìlérí Bíbélì nípa ayé tuntun tí òdodo á máa gbé ti mú kó tún ìgbésí ayé rẹ̀ gbé yẹ̀ wò. Ohun tí Edmundo wá ń sọ ní báyìí ni pé: “Ìwà agọ̀ pátápátá ló jẹ́ fún mi pé mo ti fi àkókò mi ṣòfò.” Nítorí pé ọkùnrin náà fẹ́ máa bá a lọ ní rírí ojú rere Ọlọ́run, èyí ti sún un láti má ṣe yà sídìí oògùn olóró mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni, ìmọ̀ nípa Ọlọ́run àtàwọn ìlérí rẹ̀ lè sún wa nísinsìnyí láti “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.”—Éfésù 4:24.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn mìíràn, táwọn náà ti jẹ́ ajoògùnyó nígbà kan rí, ti wá dẹni tó ń gbádùn àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wọn. Ọ̀rọ̀ onísáàmù ti ní ìtumọ̀ pàtàkì sí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, èyí tó sọ pé: “Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi àti àwọn ìdìtẹ̀ mi. Gẹ́gẹ́ bí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ni kí ìwọ rántí mi, nítorí oore rẹ, Jèhófà. Ẹni rere àti adúróṣánṣán ni Jèhófà. Ìdí nìyẹn tí ó fi ń fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ìtọ́ni ní ọ̀nà náà.” (Sáàmù 25:7, 8) Ohun ìtùnú ló mà jẹ́ fún àwọn òbí tó ní àwọn ọmọ tó ti yàyàkuyà o, pé àwọn ọmọ náà lè yí padà! Pẹ̀lú ìsapá aláápọn, àwọn òbí lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró tó ti di àjàkálẹ̀ àrùn yìí, kí wọ́n sì dẹni tó di “ìyè tòótọ́ mú gírígírí,” èyí tí yóò tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ nínú ayé tuntun Ọlọ́run.—1 Tímótì 6:19.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ìrètí gbígbé nínú ayé tuntun Ọlọ́run ti sún ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lo oògùn olóró láti yí ìgbésí ayé wọn padà