Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí O Ṣe Lè Dáàbò Bo Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Lílo Oògùn Olóró

Bí O Ṣe Lè Dáàbò Bo Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Lílo Oògùn Olóró

Bí O Ṣe Lè Dáàbò Bo Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Lílo Oògùn Olóró

“Àwọn òbí ni iṣẹ́ dídáàbò bo àwọn ọmọ kí wọ́n má bàa lo oògùn olóró já lé léjìká jù lọ. Wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ tó dára fún àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì ní láti máa fún wọn ní ìtọ́ni.”—DONNA SHALALA, Ọ̀GÁ ÀGBÀ ILÉEṢẸ́ ÌJỌBA AMẸ́RÍKÀ TÍ Ń BÓJÚ TÓ ÌLERA ÀTI Ọ̀RÀN ÀWỌN ARÁÀLÚ.

NÍPA BẸ́Ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òbí, ìwọ lẹni àkọ́kọ́ láti dáàbò bò ọmọ rẹ lọ́wọ́ lílo oògùn olóró. Àmọ́, ó dunni pé, kì í ṣe gbogbo òbí ló lóye bí ojúṣe wọn yìí ṣe ṣe pàtàkì tó. Ireneu, ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Brazil sọ pé: “Gbogbo ìgbà lọwọ́ bàbá mi máa ń dí. Ọ̀rọ̀ tó máa ń bá wa sọ kì í tó nǹkan. Kò fún wa nímọ̀ràn rí nípa oògùn olóró.”

Àmọ́ ní ìdàkejì, gbọ́ ohun tí Alecxandros, ọ̀dọ́ mìíràn láti ilẹ̀ Brazil sọ, ó ní: “Nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àwọn ètò kan lórí tẹlifíṣọ̀n nípa àwọn tó ti jingíri sínú lílo oògùn olóró, ńṣe ni bàbá mi máa ń pe èmi àtàwọn àbúrò mi ọkùnrin sí yàrá pé ká wá wò ó. Ó máa ń ṣàlàyé fún wa nípa ipò ìbànújẹ́ táwọn ajoògùnyó náà bára wọn. Nígbà míì, ó máa ń lo àkókò náà láti béèrè lọ́wọ́ wa bóyá a ti ń rí àwọn ọ̀dọ́ kan níléèwé tí wọ́n ń lo oògùn olóró. Lọ́nà yìí, ó ń kì wá nílọ̀ nípa àwọn ewu tó wà nínú lílo oògùn olóró.”

Ṣé o ti jíròrò àwọn ewu tó wà nínú oògùn olóró pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ? Kó o tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ fúnra rẹ ní láti kọ́kọ́ mọ̀ nípa àwọn ewu náà. Àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti mọ̀ pé lílo àwọn oògùn tí kò bófin mu lè ṣàkóbá fún wọn nípa tẹ̀mí. Bíbélì rọ̀ wá pé ká mú ara wa wà ní mímọ́ tónítóní kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin, ti ara àti ti ẹ̀mí. (2 Kọ́ríńtì 7:1) Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé pẹ̀lú àwọn ọmọ wa lè ṣèrànwọ́ gidigidi láti dáàbò bò wọ́n. a

‘Ọ̀rẹ́ Tó Ṣeé Finú Hàn’

Ó tún ṣe pàtàkì pé kó o jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ rí ọ bí ẹni tí wọ́n lè fọkàn tán. Jèhófà jẹ́ “ọ̀rẹ́ àfinúhàn” sí àwọn ọmọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé. (Jeremáyà 3:4) Ṣe ọ̀rẹ́ tó ṣe é finú hàn lo jẹ́ sí ọmọ rẹ? Ṣé lóòótọ́ lo máa ń tẹ́tí sílẹ̀ sí ọmọ rẹ? Ǹjẹ́ ó máa ń rọrùn fún ọmọ rẹ láti wá sọ àwọn ìṣòro rẹ̀ fún ọ? Ṣé ó máa ń yá ọ lára láti dá a lẹ́bi ju kó o máa yìn ín lọ? Fi ọ̀pọ̀ àkókò sílẹ̀ láti mọ ọmọ rẹ. Ǹjẹ́ ọmọ náà ní àwọn ọ̀rẹ́? Irú èèyàn wo ni wọ́n? Ó ṣe tán, Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Má ṣe bẹ̀rù láti gbé àwọn ààlà tó ṣe gbòógì kalẹ̀, kó o sì rí i pé ò ń fi ìfẹ́ bá wọn wí. Bíbélì ṣáà sọ pé: “Na ọmọ rẹ, yóò sì mú ìsinmi bá ọ, yóò sì fún ọkàn rẹ ní ọ̀pọ̀ adùn.”—Òwe 29:17.

Síwájú sí i, má ṣe fojú kéré àwọn ewu tó ń dojú kọ ọmọ rẹ. Àwọn òbí kan lè fi àìbìkítà ronú pé, nítorí pé ilé rere lọmọ wọn ti jáde, wọn kì í ṣe ẹni tó lè lọ́wọ́ nínú lílo oògùn olóró rárá. Àmọ́, Dókítà José Henrique Silveira ṣàlàyé pé: “Àwọn ọmọ àwọn èèyàn ńláńlá làwọn tó ń ṣòwò oògùn olóró máa ń fẹ́ láti bá dọ́rẹ̀ẹ́ nítorí pé ìyẹn máa ń mówó wọlé fún wọn dáadáa.” Nítorí náà, bí ọ̀dọ́ kan táwọn èèyàn mọ̀ sí ọmọ gidi bá lè di ẹni tí wọ́n tì sínú lílo oògùn olóró, ó ṣeé ṣe gan-an pé àwọn ọ̀dọ́ mìíràn lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.

Nítorí náà, má tan ara rẹ jẹ rárá. Rí i pé o mọ díẹ̀ lára àwọn àmì àkọ́kọ́ tó máa ń fi hàn pé ọmọ kan ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró. Bí àpẹẹrẹ, ṣé ọmọ rẹ ti ṣàdédé di ẹni tí kì í dá sí ẹnì kankan mọ́, ṣé ó ń ní ìdààmú ọkàn, ṣé ó ń ṣe gbúngbùngbún, tàbí ṣé ó ti di ẹni tí kì í fọwọ́ sowọ́ pọ̀ mọ́? Ṣé ó ti pa àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ tàbí àwọn tó jẹ́ ara ìdílé rẹ̀ tì, láìsí àlàyé kan pàtó? Nígbà náà, á dára kó o wá nǹkan ṣe sí ọ̀ràn náà.

Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé, láìka àwọn ìsapá tó yẹ fún ìgbóríyìn tí àwọn òbí ń ṣe sí, àwọn èwe kan ṣì máa ń juwọ́ sílẹ̀ nígbà táwọn kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í fúngun mọ́ wọn, wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi oògùn olóró dánra wò. Kí ló yẹ kó o ṣe bí èyí bá ṣẹlẹ̀ sí ọmọ rẹ?

Bí Ọ̀dọ́ Kan Bá Ń Lo Oògùn Olóró

Ireneu sọ pé: “Nígbà tí àwọn òbí mi fi máa mọ̀ pé àbúrò mi ọkùnrin ń lo oògùn olóró, ó ti ń lò ó fún ọ̀pọ̀ oṣù. Nítorí pé wọn ò ronú rẹ̀ rí láé pé ọmọ wọn kankan lè di ẹni tó ń lo oògùn olóró, ńṣe làyà wọn já pàà nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ mọ̀. Níbẹ̀rẹ̀, ohun tí bàbá mi ronú láti ṣe kò ju láti fi ọwọ́ líle mú arákùnrin mi kó sì fìyà jẹ ẹ́.”

Nígbà táwọn òbí bá mọ̀ pé ọmọ wọn ń lo oògùn olóró, ìmọ̀lára tí wọ́n máa kọ́kọ́ ní lè jẹ́ ìbínú, ìbànújẹ́, tàbí ìkábàámọ̀. Àmọ́ ṣá o, ìsọfúnni kan tí Ẹ̀ka Ètò Ẹ̀kọ́ Lórílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tẹ̀ jáde gbà wọ́n nímọ̀ràn pé: “Má ṣe jẹ́ kí ìpayà mú ọ! Má sì ṣe dá ara rẹ lẹ́bi. Ohun tó ṣe pàtàkì lákòókò náà ni pé, kó o sinmẹ̀dọ̀ kó o [sì] mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an. . . . Àṣà tó ṣeé jáwọ́ nínú rẹ̀ ni lílo oògùn olóró. Àrùn tó sì ṣeé wò sàn ni jíjoògùnyó.”

Bẹ́ẹ̀ ni, má ṣe le koko mọ́ ọn, má sì ṣe fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ọ̀ràn náà kó má bàa burú sí i. Bíbínú lábìíjù tàbí jíjuwọ́sílẹ̀ lè máà jẹ́ kí ọmọ rẹ tètè padà bọ̀ sípò. Ó ṣe tán, ńṣe lo fẹ́ ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó lè di àgbàlagbà tó ní láárí, tí yóò lè máa dá ronú fúnra rẹ̀. Nítorí náà, lo àkókò tó tó láti bá ọ̀dọ́ náà sọ̀rọ̀ látọkàn wá, kó bàa lè ṣeé ṣe fún un láti rí àwọn àǹfààní tó máa rí bó bá jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró. Gbìyànjú láti mọ ohun tó wà lọ́kàn ọmọ tó ti ṣáko lọ náà, kó o sì múra tán láti tẹ́tí sílẹ̀ sí i.—Òwe 20:5.

Ireneu sọ síwájú sí i pé: “Lẹ́yìn ìgbà náà, àwọn òbí mi yíwọ́ padà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gba arákùnrin mi níyànjú, wọ́n fi òté lé àwọn ibì kan pé kò lè lọ, wọ́n ń yí kíláàsì rẹ̀ padà kó má bàa ṣeé ṣe fún un láti máa pàdé àwọn ọmọléèwé kan náà lójoojúmọ́. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kíyè sí àwọn tó ń bá rìn wọ́n sì wá ń fún òun àti àwa yòókù nínú ìdílé ní àfiyèsí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.”

Wo ìgbésẹ̀ tí àwọn òbí kan gbé tí wọ́n sì ṣàṣeyọrí nígbà tí wọ́n mọ̀ pé ọmọ wọn ń lo oògùn olóró.

Àwọn Ìgbésẹ̀ Tó Mú Àṣeyọrí Wá

Marcelo, ọkùnrin kan tó ń gbé ní ìlú São Paulo, lórílẹ̀-èdè Brazil sọ pé: “Òun ni nǹkan tó burú jù lọ tó tíì ṣẹlẹ̀ sí wa rí. Èmi àti ìyàwó mi kò ṣàkíyèsí nǹkan kan tó ṣàjèjì nínú ìwà àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wa méjèèjì. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń lọ jẹun nílé àrójẹ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ mìíràn tá a lérò pé a mọ̀ dáadáa. Ìbànújẹ́ ńláǹlà ló jẹ́ fún wa nígbà tí ọ̀rẹ́ wa kan sọ fún wa pé àwọn ọmọkùnrin wa méjèèjì náà ń mugbó. Àmọ́ nígbà tá a bi wọ́n, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n jẹ́wọ́ pé lóòótọ́ làwọ́n ń mu ún.”

Kí ni Marcelo ṣe sí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ yìí? Ó sọ pé: “Èmi àti ìyàwó mi kò lè mú ìbànújẹ́ wa mọ́ra. Àmọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé nǹkan burúkú gbáà ni ohun tí wọ́n ṣe náà, a ò jẹ́ kí wọ́n ronú pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan. A fẹnu kò pé ohun tó máa jẹ́ góńgó wa látìgbà náà lọ ni láti ran àwọn ọmọkùnrin wa lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú àṣà lílo oògùn olóró. A jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó wà lọ́kàn wa, àwọn méjèèjì sì fara mọ́ ìgbésẹ̀ tá a fẹ́ gbé náà. Wọ́n á máa bá ẹ̀kọ́ wọn lọ nílé ẹ̀kọ́ wọ́n á sì máa bá bàbá wọn lọ síbi iṣẹ́. Àmọ́ wọn ò ní dá nìkan lọ sóde mọ́. Ojoojúmọ́ là ń jẹ́ kí wọ́n rí i pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, kì í kàn ṣe láwọn àkókò pàtàkì nìkan. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kọ́lékọ́lé ni mí, mo máa ń mú wọn dání bó bá ṣe lè ṣeé ṣe tó. A bẹ̀rẹ̀ sí í jọ ṣe ọ̀pọ̀ àwọn ohun tó ń mú ìgbádùn wá, à ń lo ọ̀pọ̀ àkókò láti jọ sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ iwájú àti ìdí tó fi yẹ kéèyàn ní àwọn góńgó tó ní láárí tí yóò máa lépa nígbèésí ayé.” Marcelo àti ìyàwó rẹ̀ tipa báyìí ran àwọn ọmọkùnrin wọn lọ́wọ́ láti bọ́ lọ́wọ́ oògùn olóró.

Tún gbé ìrírí bàbá mìíràn láti ilẹ̀ Brazil yẹ̀ wò. Ọmọkùnrin rẹ̀ tó ń jẹ́ Roberto sọ pé: “Nígbà tí bàbá mi mọ̀ pé arákùnrin mi ń lo oògùn olóró, dípò tí ì bá fi bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ burúkú sí i tàbí kó bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí, Bàbá fi hàn pé ọ̀rẹ́ rẹ̀ lòun jẹ́, èyí sì mú kí arákùnrin mi finú hàn án. Ó gbìyànjú láti mọ àwọn tí arákùnrin mi máa ń bá rìn àtàwọn ibi tó sábà máa ń lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pàrọwà fún un pé kò nílò oògùn olóró, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tó fẹ́ fi irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ ṣe. Bàbá mi sọ fún un pé òun ò fẹ́ láti máa wá a kiri lóru nígbà tó yẹ kóun máa sùn.” Kí ọmọ tó ní ìdààmú ọkàn náà lè padà bọ̀ sípò, ìyàwó bàbá rẹ̀ kọ́wọ́ ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn gbágbáágbá. Àwọn méjèèjì jọ pohùn pọ̀ pé kò yẹ kí àwọn tún fi àkókò ṣòfò mọ́, wọ́n sì pinnu láti ràn án lọ́wọ́ nílé.—Wo àpótí náà “Rírí Ìrànlọ́wọ́ Gbà.”

Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀!

Títọ́ ọmọ ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” yìí kì í ṣe ohun tó rọrùn rárá ó sì lè tánni lókun. (2 Tímótì 3:1) Síbẹ̀, ìwọ alára kò gbọ́dọ̀ ṣàìnáání àwọn ohun tó o nílò ní ti ìmí ẹ̀dùn àti nípa tẹ̀mí. (Mátíù 5:3) Òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Òwe 24:10 sọ pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” O lè rí ọ̀pọ̀ okun gbà nípa kíkẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn Kristẹni tòótọ́. Ní àwọn ìpàdé tí à ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o lè rí ìtìlẹyìn àti ìṣírí gbà.—Hébérù 10:24, 25.

Kò sí àní-àní pé kíkọ́ ìdílé rẹ lẹ́kọ̀ọ́ láti nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ni ohun tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ jù lọ láti dènà lílo oògùn olóró. Lóòótọ́, Ọlọ́run kò fipá mú àwọn ọ̀dọ́ láti máa gbé ìgbésí ayé lọ́nà kan pàtó. Àmọ́, ó pèsè ìmọ̀ràn tó ṣeé gbára lé fún wọn. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ Sáàmù 32:8 ti sọ, Ọlọ́run sọ pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.” Nítorí pé Ọlọ́run jẹ́ Baba ọ̀run onífẹ̀ẹ́, ó fẹ́ láti dáàbò bo àwọn èwe lọ́wọ́ ìparun, ní ti ìmí ẹ̀dùn, nípa tara, àti nípa tẹ̀mí. (Òwe 2:10-12) Síwájú sí i, jẹ́ kó dá ọ lójú pé Ọlọ́run yóò ṣèrànwọ́ fún àwọn òbí tó bá pinnu láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà,” yóò sì tì wọ́n lẹ́yìn.—Éfésù 6:4.

Síbẹ̀, àwọn ìṣòro tó so mọ́ títọ́ àwọn ọmọ nínú àwùjọ tí à ń gbé lónìí lè mú kí gbogbo nǹkan súni nígbà míì. Ǹjẹ́ ìrànlọ́wọ́ kankan tiẹ̀ wà nítòsí?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tẹ àwọn ìsọfúnni kan jáde tó lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti jíròrò àwọn kókó pàtàkì, irú bí ewu tó wà nínú oògùn líle, pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Bí àpẹẹrẹ, wo orí 33 àti 34 nínú ìwé náà, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè-Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]

“Àṣà tó ṣeé jáwọ́ nínú rẹ̀ ni lílo oògùn olóró. Àrùn tó sì ṣeé wò sàn ni jíjoògùnyó.”—Ẹ̀KA ÈTÒ Ẹ̀KỌ́ LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Rírí Ìrànlọ́wọ́ Gbà

Àwọn òbí kan lè pinnu pé yóò dára kí ọmọ wọn máa gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn nígbà táwọn nǹkan tó máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ara nígbà tẹ́nì kan bá jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀ sí i. Àwọn òbí ló ni ìpinnu nípa irú ìtọ́jú wo gan-an ló yẹ kí àwọn wá fún ọmọ wọn. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ìtọ́jú tí wọ́n ń fún àwọn ajoògùnyó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń padà bọ̀ sípò láwọn ilé ìtọ́jú ti máa ń dára jura wọn lọ tó sì máa ń yàtọ̀ síra wọn gan-an, á dára kí àwọn òbí ṣèwádìí dáadáa kí wọ́n tó lọ máa gba ìtọ́jú ní ilé ìtọ́jú kan pàtó. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Arthur Guerra de Andrade, tó jẹ́ oníṣègùn ọpọlọ àti ọ̀jọ̀gbọ́n ní Yunifásítì ìlú São Paulo lórílẹ̀-èdè Brazil sọ, ìdá ọgbọ̀n péré nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n máa ń tọ́jú láwọn ilé ìtọ́jú ni kì í padà sídìí lílo oògùn olóró mọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn òbí gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe kí ọmọ wọn lè padà bọ̀ sípò, kódà bí wọ́n bá tiẹ̀ ń gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ dókítà.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ìrànwọ́ fún Àwọn Ajoògùnyó Tó Ń Padà Bọ̀ Sípò

Ṣé ọ̀dọ́ tó ń tiraka láti já ara rẹ̀ gbà lọ́wọ́ lílo oògùn olóró ni ọ́? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, wàá rí i pé kíka Bíbélì àti fífi ohun tí ò ń kà sílò lè ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú ìsapá rẹ láti bọ̀ sípò. Kíka ìwé Sáàmù lè ràn ọ́ lọ́wọ́ gan-an, níwọ̀n bó ti sọ púpọ̀ nípa àwọn ìrora ọkàn tó o lè máa kojú rẹ̀ báyìí. Gbígbàdúrà látọkànwá sí Ọlọ́run, nípa sísọ gbogbo àwọn èrò inú rẹ lọ́hùn-ún fún un, yóò tún ṣèrànwọ́ pẹ̀lú. (Fílípì 4:6, 7) Wàá bẹ̀rẹ̀ sí í nímọ̀lára pé ó bìkítà fún ọ gan-an àti pé ó fẹ́ kó o kẹ́sẹ járí. Àmọ́, níwọ̀n bí Ọlọ́run kò ti ń fipá mú ẹnikẹ́ni láti ṣe ohun tí kò tinú onítọ̀hún wá, ó ṣe pàtàkì pé kí ìwọ fúnra rẹ nífẹ̀ẹ́ gidigidi láti jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró. Onísáàmù náà, Dáfídì, ẹni tó rí ọwọ́ Ọlọ́run nínú ìgbésí ayé rẹ̀ láìmọye ìgbà, sọ pé: “Taratara ni mo fi ní ìrètí nínú Jèhófà, nítorí náà, ó dẹ etí rẹ̀ sí mi, ó sì gbọ́ igbe mi fún ìrànlọ́wọ́. Ó sì tẹ̀ síwájú láti mú mi gòkè pẹ̀lú láti inú kòtò tí ń ké ramúramù, láti inú ẹrẹ̀ pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀. Nígbà náà ni ó gbé ẹsẹ̀ mi sókè sórí àpáta gàǹgà; ó fi àwọn ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.” (Sáàmù 40:1, 2) Lọ́nà kan náà lónìí, àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ láti jáwọ́ nínú àwọn àṣà ẹlẹ́gbin tí wọ́n sì fẹ́ láti sin Ọlọ́run máa ń rí ìrànlọ́wọ́ gbà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

“Bàbá mi máa ń kì wá nílọ̀ nípa àwọn ewu tó wà nínú rẹ̀”—Alecxandros

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Lo àkókò láti kìlọ̀ fún àwọn ọmọ rẹ nípa àwọn ewu tara àti tẹ̀mí tó wà nínú lílo oògùn olóró

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Mọ irú àwọn tí ọmọ rẹ ń bá rìn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Bíbójú tó ọ̀ràn yìí lọ́nà pẹ̀lẹ́tù lè mú kí ipò tó ti burú tẹ́lẹ̀ má ṣe di èyí tó túbọ̀ burú sí i