Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí O Ṣe Lè Túbọ̀ Máa Sùn Dáadáa

Bí O Ṣe Lè Túbọ̀ Máa Sùn Dáadáa

Bí O Ṣe Lè Túbọ̀ Máa Sùn Dáadáa

ÌṢÒRO ÀÌRÓORUNSÙN kì í ṣe ohun tuntun. Ní ọ̀rúndún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Tiwa, ìránṣẹ́ kan láàfin Ahasuwérúsì Ọba ti ilẹ̀ Páṣíà ròyìn pé, lóru ọjọ́ kan, “oorun dá lójú ọba.”—Ẹ́sítérì 6:1.

Lóde òní, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni kì í lè sùn dáadáa. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Rubens Reimão tó jẹ́ onímọ̀ nípa oorun lórílẹ̀-èdè Brazil sọ, àwọn ògbógi fojú bù ú pé nǹkan bí ìdá márùndínlógójì nínú ọgọ́rùn-ún àwọn èèyàn tó wà lágbàáyé ló ní ìṣòro àìróorunsùn. a Dókítà David Rapoport, tó ń ṣiṣẹ́ ní Ibùdó Tó Ń Rí sí Ìṣòro Àìróorunsùn ní Yunifásítì New York, sọ pé àìróorunsùn jẹ́ “ọ̀kan lára àwọn àjàkálẹ̀ àrùn bíburú jáì ní ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí.”

Ohun tó mú kí ọ̀ràn yìí túbọ̀ burú ni pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ní ìṣòro àìróorunsùn ni kò tiẹ̀ mọ ìdí tí wọ́n fi ní ìṣòro ọ̀hún. Gẹ́gẹ́ bí ohun táwọn olùṣèwádìí ní Yunifásítì Ìjọba Àpapọ̀ tó wà ní ìlú São Paulo, lórílẹ̀-èdè Brazil sọ, àwọn tí wọ́n mọ ohun tó dìídì jẹ́ ìṣòro wọn kò ju ìdá mẹ́ta nínú ọgọ́rùn-ún lọ. Ọ̀pọ̀ èèyàn wulẹ̀ gbà pé kò sóhun tí àwọn lè ṣe sí àìróorunsùn, àti bí èyí ṣe máa ń fa kí wọ́n máa kanra ṣáá kí wọ́n sì máa tòògbé lọ́wọ́ ọ̀sán.

Ìṣòro Àìróorunsùn Lóru

Kì í ṣe ọ̀rẹ́ ara kéèyàn kàn máa yí kiri lórí ibùsùn lóru fún ọ̀pọ̀ wákàtí, kó lajú sílẹ̀ kí oorun má sì wá, nígbà tí gbogbo àwọn ará ilé yòókù ń sun oorun àsùngbádùn. Síbẹ̀, àìróorunsùn fún bí ọjọ́ mélòó kan máa ń ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, èyí sì sábà máa ń jẹ́ nítorí ságbàsúlà ìgbésí ayé. Àmọ́ bí àìróorunsùntó bá wá di bárakú fún ẹnì kan, ó lè jẹ́ pé onítọ̀hún ní ìrora ọkàn tàbí àìsàn kan, nípa bẹ́ẹ̀ ó ṣe pàtàkì kó tètè lọ gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn.—Wo àpótí tó wà lókè.

Ǹjẹ́ o ní ìṣòro oorun sísùn? Bó bá jẹ́ pé lẹ́yìn tó o dáhùn àwọn ìbéèrè inú àpótí tó wà lójú ìwé 17, o gbà pé o ní ìṣòro oorun sísùn, má ṣe jẹ́ kí ìyẹn bà ọ́ lọ́kàn jẹ́. Mímọ̀ pé o ní ìṣòro oorun sísùn yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti wá nǹkan ṣe sí ìṣòro náà. Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Geraldo Rizzo, ẹni tó jẹ́ onímọ̀ nípa ètò iṣan ara lórílẹ̀-èdè Brazil ti sọ, ó ṣeé ṣe láti wo ìdá mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá àwọn tó ní ìṣòro àìróorunsùntó sàn dáadáa.

Àmọ́ ṣá o, kí àwọn oníṣègùn tó lè fún aláìsàn náà ní ìtọ́jú yíyẹ, ó ṣe pàtàkì láti mọ lájorí ohun tó ń fa ìṣòro náà gan-an. Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ oníṣègùn máa ń ṣe àwọn àyẹ̀wò kan lórí ìlera ẹni láti mọ ohun tó ń fa àìróorunsùn àti bí wọ́n ṣe lè wò ó sàn.—Wo àpótí tó wà nísàlẹ̀.

Ohun kan tó sábà máa ń fa àìróorunsùn fún àwọn àgbàlagbà jẹ mọ́ híhan-anrun. Bó o bá ti sùn nítòsí ẹnì kan tó ń han-anrun rí, wàá mọ̀ pé kì í ṣe ohun tó ń gbádùn mọ́ni páàpáà. Híhan-anrun lè jẹ́ àmì pé ẹnì kan ní ìṣòro mímí lójú oorun, ìyẹn ni kí ọ̀fun rẹ̀ dí, kí afẹ́fẹ́ má sì lè ráyè wọnú ẹ̀dọ̀fóró rẹ̀. Àwọn ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ láti kápá ìṣòro yìí ni kéèyàn rí i pé òun kò sanra jù, kó yẹra fún ọtí líle, àtàwọn oògùn tó ń mú kí iṣan dẹ̀. Àwọn ògbóǹtagí oníṣègùn tún lè dámọ̀ràn àwọn àkànṣe egbòogi kan tàbí kí wọ́n sọ pé kí onítọ̀hún máa lo àwọn ẹ̀rọ tó wà fún títún eyín tò tàbí kó máa lo ẹ̀rọ kan tó máa ń rọra fẹ́ atẹ́gùn sínú ihò imú àti ẹnu. b

Bí ìṣòro náà bá le gan-an, àwọn oníṣègùn lè ṣe iṣẹ́ abẹ fún un láti fi ṣàtúnṣe sí ọ̀fun, àgbọ̀n, ahọ́n, tàbí imú rẹ̀, kó bàa lè ṣeé ṣe fún afẹ́fẹ́ láti máa wọlé kó sì máa jáde nígbà tí onítọ̀hún bá ń mí.

Àwọn ọmọdé náà lè ní ìṣòro àìróorunsùn. Àwọn àmì tó ń fi hàn pé ọmọ kan kì í sùn dáadáa lè fara hàn ní ilé ẹ̀kọ́—bóyá kí ọmọ náà máà já fáfá nínú iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́, kó máa kanra ṣáá, tàbí kó má lè pọkàn pọ̀—èyí tiẹ̀ lè yọrí sí kí àwọn dókítà fi àṣìṣe rò pé ìṣòro kí ọmọdé máa ṣe wọ́nranwọ̀nran ni ọmọ náà ní.

Àwọn ọmọdé kan kì í fẹ́ sùn rárá, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n fẹ́ràn kí wọ́n máa kọrin, kí wọ́n máa sọ̀rọ̀, tàbí kí wọ́n máa tẹ́tí sí ẹnì kan tó ń sọ ìtàn fún wọn. Ó tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n máa ṣe ohunkóhun tí kò ṣáà ní jẹ́ kí wọ́n lọ sùn. Wọ́n lè máa ṣe èyí kí òbí wọn bàa lè wà pẹ̀lú wọn. Àmọ́, nínú àwọn ọ̀ràn kan, ọmọ kan lè máa bẹ̀rù láti sùn torí pé àwọn sinimá ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tó ń wò, àwọn ìròyìn orí rédíò tàbí tẹlifíṣọ̀n tó kún fún ìwà ipá tó ń gbọ́, tàbí bí ìjà ṣe ń ṣẹlẹ̀ nínú ilé, lè máa mú kó lá àlá burúkú lemọ́lemọ́. Bí àwọn òbí bá jẹ́ kí ilé tòrò kí ìfẹ́ sì jọba, wọ́n á lè dènà àwọn ìṣòro wọ̀nyí. Àmọ́ ṣá o, wọ́n gbọ́dọ̀ fọ̀ràn lọ àwọn oníṣègùn bí àwọn àmì ìṣòro yìí ò bá tètè lọ. Láìsí àní-àní, bí oorun àsùngbádùn lóru ṣe ṣe pàtàkì fún àwọn ọmọdé náà ló ṣe pàtàkì fún àwọn àgbàlagbà pẹ̀lú.

Bí O Ṣe Lè Máa Rí Oorun Sùn Dáadáa Lóru

Láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn làwọn èèyàn ti mọ̀ pé oorun àsùngbádùn kì í ṣàdédé wá. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń mú kéèyàn sùn dáadáa yàtọ̀ sí pé kéèyàn kápá àníyàn tàbí ẹ̀dùn ọkàn èyíkéyìí.

Ó yẹ kí sísùn dáadáa lóru jẹ́ ohun téèyàn máa jẹ́ kó mọ́ òun lára. Lára ohun tó sì lè ṣèrànwọ́ ni ṣíṣe eré ìmárale ní àkókò yíyẹ lóòjọ́. Ṣíṣe eré ìmárale ní òwúrọ̀ tàbí ní ọ̀sán lè jẹ́ kí oorun kunni lálẹ́. Àmọ́, ṣíṣe eré ìmárale bó bá kù díẹ̀ kéèyàn sùn lè ṣèdíwọ́ fún oorun.

Wíwo eré alárinrin lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí kíka ìwé tó ń wọni lọ́kàn gan-an lè jẹ́ kí oorun dá lójú ẹni. Ṣáájú kó o tó lọ sùn, o lè ka ìwé àkàgbádùn, o lè gbọ́ orin atura, tàbí kó o fi omi tó lọ́ wọ́ọ́rọ́ wẹ̀.

Àwọn ògbógi sọ pé ó ṣeé ṣe fún ẹnì kan láti kọ́ ọpọlọ rẹ̀ pé tí òun bá ti dé orí ibùsùn, òun fẹ́ sùn nìyẹn. Ó lè ṣe èyí nípa rírí i pé ìgbà tí òun bá fẹ́ sùn nìkan ni òun ń dùbúlẹ̀. Kì í rọrùn fún àwọn tó máa ń jẹun, kàwé, ṣiṣẹ́, wo tẹlifíṣọ̀n, tàbí ṣeré ìdárayá orí fídíò lórí ibùsùn láti rí oorun sùn.

Ṣíṣọ́ ohun téèyàn ń jẹ àti ohun téèyàn ń mu yóò ṣèrànwọ́ láti jẹ́ kí ara múra sílẹ̀ fún oorun amáratuni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọtí líle lè jẹ́ kéèyàn máa tòògbé, ó lè mú kó ṣòro gan-an láti sun oorun àsùngbádùn. Kò yẹ kéèyàn máa mu àwọn nǹkan bíi kọfí, tíì, ohun mímu tí wọ́n fi kòkó ṣe, ṣokoléètì, tàbí àwọn ọtí ẹlẹ́rìndòdò tí wọ́n fi obì tàbí ewé coca ṣe ṣáájú kéèyàn tó sùn torí pé wọn kì í jẹ́ kí oorun kunni. Kàkà bẹ́ẹ̀, jíjẹ àwọn èso kan níwọ̀nba, irú bíi máńgòrò, ànàmọ́, ọ̀gẹ̀dẹ̀, èso persimmon, ewébẹ̀ palm cabbage, ẹ̀wà tàbí ìrẹsì, tàbí ẹ̀pà yóò ṣèrànwọ́ láti mú kí oorun kun èèyàn. Ìkìlọ̀ kan rèé o: Jíjẹ oúnjẹ púpọ̀ nígbà tí ilẹ̀ bá ti ṣú gan-an lè ṣèdíwọ́ fún oorun bó ṣe jẹ́ pé lílọ sùn pẹ̀lú inú òfo lè mú kí oorun dá lójú ẹni.

Bí àwọn ohun téèyàn ń ṣe kó tó sùn ṣe ṣe pàtàkì náà ni àyíká téèyàn ń sùn ṣe ṣe pàtàkì. Bí iyàrá kò bá tutù jù tàbí kó móoru jù, bó bá ṣókùnkùn tí kò sì sí ariwo èyíkéyìí, tèèyàn sì lo tìmùtìmù àti ìrọ̀rí tó tuni lára, àwọn nǹkan wọ̀nyí á jẹ́ kí oorun gbádùn mọ́ni gan-an. Kódà, níbi tí ara bá tu onítọ̀hún dé, kò tiẹ̀ ní fẹ́ dìde lórí ibùsùn ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì. Àmọ́ rántí pé, bó o bá ń sùn ju bó ṣe yẹ lọ, kódà ní òpin ọ̀sẹ̀ pàápàá, èyí lè ṣèdíwọ́ fún ọ̀nà tó ò ń gbà sùn déédéé, ó sì lè mú kó túbọ̀ ṣòro fún ọ láti sùn lọ́jọ́ kejì.

Ó dájú pé o ò ní mọ̀ọ́mọ̀ ṣèpalára fún èyíkéyìí lára àwọn ẹ̀yà ara rẹ tó o nílò láti wà láàyè. Oorun sísùn náà ṣe kókó, ó jẹ́ ohun pàtàkì kan nínú ìgbésí ayé tá ò gbọ́dọ̀ pa tì tàbí ká fojú kéré. Ó ṣe tán, ìdá mẹ́ta ìgbésí ayé wa la fi ń sùn. Ǹjẹ́ o lè ṣe é kó o túbọ̀ máa sùn dáadáa? O ò ṣe bẹ̀rẹ̀ lálẹ́ yìí!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àìróorunsùn ni kó má ṣeé ṣe fún ẹnì kan láti sun oorun àsùngbádùn.

b Ẹ̀rọ yìí máa ń tú afẹ́fẹ́ jáde gba inú ohun kékeré kan tí aláìsàn náà fi bo imú, afẹ́fẹ́ yìí á sì máa gba inú rọ́bà kan. Afẹ́fẹ́ tó ń kọjá sí imú rẹ̀ yìí ló máa jẹ́ kí ọ̀nà ọ̀fun ẹni náà ṣí sílẹ̀, tí yóò sì máa mí dáadáa.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

ÀWỌN OHUN TÓ SÁBÀ MÁA Ń FA ÀÌRÓORUNSÙN

ÌṢÒRO INÚ ARA: àrùn Alzheimer; ìṣòro apnea, ìyẹn ni kí ọ̀nà ọ̀fun ẹni dí kí afẹ́fẹ́ má sì ráyè wọnú ẹ̀dọ̀fóró nígbà téèyàn bá ń sùn; ìṣòro kí ẹsẹ̀ máa rinni wìnnìwìnnì, ìyẹn ni pé kéèyàn máa mi ẹsẹ̀ rẹ̀ nígbà tó ń sùn torí pé nǹkan kan ń rìn ín lẹ́sẹ̀ láìdáwọ́dúró; àrùn Parkinson; ìṣòro kéèyàn máa ju apá àti ẹsẹ̀ sókè sódò látìgbàdégbà, kó sì tún máa jí lójú oorun nígbà tó bá ń jarunpá; ikọ́ ẹ̀gbẹ; àrùn ọkàn àti ìṣòro kí oúnjẹ má lè dà.

ÌṢÒRO ỌPỌLỌ: ìsoríkọ́, àníyàn, kí jìnnìjìnnì máa báni, kéèyàn má lè ṣàkóso ìrònú àti ìṣesí rẹ̀, ìpayà tí ìrírí bíbanilẹ́rù kan dá síni lára.

ÌṢÒRO ÀYÍKÁ: ìmọ́lẹ̀, ariwo, ooru, otútù, ibùsùn tí kò tuni lára, kí ọkọ tàbí aya ẹni máa jarunpá luni.

ÀWỌN OKÙNFÀ MÌÍRÀN: ọtí líle tàbí oògùn olóró, àwọn àbájáde tí àwọn egbòogi téèyàn lò fà.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16]

MÍMỌ OHUN TÓ Ń FA ÌṢÒRO OORUN

Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ oníṣègùn máa ń ṣe onírúurú àyẹ̀wò lórí oorun aláìsàn kan nígbà tó bá ń sùn lọ́wọ́. Wọ́n máa ń lo onírúurú ẹ̀rọ láti fi ṣàyẹ̀wò ohun tó fa ìṣòro oorun ẹni náà.

◼ Ẹ̀rọ kan máa ń ṣàyẹ̀wò bí ọpọlọ ṣe ń ṣiṣẹ́ dáadáa sí, wọ́n sì máa ń lò ó láti fi pinnu bí ìpele oorun kọ̀ọ̀kan ṣe gùn tó.

◼ Òmíràn wà tó máa ń gba iye ìgbà tí ojú yí lọ yí bọ̀ sílẹ̀ nígbà tí oorun bá ti wọ ìpele yìí.

◼ Ọ̀kan wà tí wọ́n máa ń lò láti kíyè sí bí àwọn iṣan tó wà ní àgbọ̀n àti ẹsẹ̀ ṣe ń sún kì nígbà téèyàn bá sún dé ìpele oorun tí ojú ti ń yí lọ yí bọ̀.

◼ Ọ̀kan sì tún wà tó máa ń kíyè sí bí ọkàn ṣe ń lù kìkì ní gbogbo òru.

◼ Wọ́n tún máa ń ṣàyẹ̀wò bí afẹ́fẹ́ ṣe ń wọnú ẹ̀dọ̀fóró aláìsàn náà àti bó ṣe ń mí—Wọ́n máa ń díwọ̀n èyí nípa ṣíṣe àyẹ̀wò bí afẹ́fẹ́ ṣe ń gba imú àti ẹnu rẹ̀ wọlé àti bí ikùn àti àyà rẹ̀ ṣe ń lọ sókè lọ sódò.

◼ Wọ́n máa ń ṣàyẹ̀wò bí afẹ́fẹ́ oxygen ṣe pọ̀ tó nínú ẹ̀jẹ̀ aláìsàn náà nípa lílo ẹ̀rọ kékeré kan tí wọ́n á so mọ́ ìka rẹ̀.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]

ÀYẸ̀WÒ LÓRÍ OORUN SÍSÙN

Báwo ló ṣe rọrùn fún ọ tó láti máa tòògbé nínú àwọn ipò tá a mẹ́nu kàn nísàlẹ̀ yìí? Nípa lílo ìlànà ìdíwọ̀n tí a ṣe sísàlẹ̀ yìí, fàmì sí àwọn ìdáhùn tó bá ipò rẹ mu, kó o wá ro gbogbo máàkì tó o gbà pọ̀.

0 O ò ní tòògbé rárá

1 Kò rọrùn fún ọ láti tòògbé

2 Ó ṣeé ṣe kó o tòògbé

3 Ó dájú pé wàá tòògbé

a Kíkàwé lórí ìjókòó 0 1 2 3

b Wíwo tẹlifíṣọ̀n 0 1 2 3

c Jíjókòó láìṣe ohunkóhun nínú gbọ̀ngàn 0 1 2 3

ìṣeré tàbí níbi ìpàdé kan

d Jíjókòó nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ fún odindi wákàtí kan 0 1 2 3

e Jíjókòó láìṣe ohunkóhun lẹ́yìn oúnjẹ ọ̀sán 0 1 2 3

láìsí pé o mu ọtí líle

f Fífi ẹ̀yìn lélẹ̀ láti sinmi ní ọ̀sán 0 1 2 3

g Bíbá ẹnì kan fọ̀rọ̀ wérọ̀ lórí ìjókòó 0 1 2 3

h Wíwà nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, nígbà tí sún 0 1 2 3

kẹrẹ fà kẹrẹ dá ọkọ̀ dúró

Àròpọ̀ ․․․․․․․․․․․

Àbájáde

1-6: O kò ní láti ṣàníyàn

7-8: Ó sàn díẹ̀

9 ó lé: Rí i pé o wá ìrànwọ́ àwọn oníṣègùn

[Credit Line]

A gbé e ka Ìlànà Ìdíwọ̀n Oorun ti Epworth, tí Yunifásítì Stanford, ìlú California, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà yọ̀ǹda.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Àìkìísùn léwu

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ṣíṣe eré ìmárale, kíkàwé àti jíjẹ ìpápánu díẹ̀ lè mú kó o sun oorun àsùngbádùn