Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí ni Ìfẹ́ Ọrọ̀ Àlùmọ́ọ́nì?

Kí ni Ìfẹ́ Ọrọ̀ Àlùmọ́ọ́nì?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Kí ni Ìfẹ́ Ọrọ̀ Àlùmọ́ọ́nì?

A DÁ èèyàn lọ́nà tí wọ́n á fi nífẹ̀ẹ́ sí nǹkan tẹ̀mí, tí wọ́n á sì tún fẹ́ láti jọ́sìn Ọlọ́run. Síbẹ̀, látinú àwọn nǹkan tá a lè fojú rí la ti dá èèyàn, ó sì nílò àwọn nǹkan ti ara, bẹ́ẹ̀ la sì tún dá a lọ́nà tó máa fi lè gbádùn àwọn nǹkan wọ̀nyí. Àwọn Kristẹni kan ní ọ̀pọ̀ ohun ìní tara. Ṣé èyí wá jẹ́ ẹ̀rí pé olùfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ni wọ́n àti pé wọn kì í ṣe ẹni tẹ̀mí? Lódìkejì ẹ̀wẹ̀, ṣé àwọn tó jẹ́ akúṣẹ̀ẹ́ kò lè jẹ́ olùfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, àti pé ṣé nǹkan tẹ̀mí máa ń jẹ wọ́n lọ́kàn ju àwọn tó lọ́rọ̀ lọ?

Ó dájú pé, wàá gbà pé nínífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ju kí èèyàn ní ọrọ̀ rẹpẹtẹ tàbí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìní lọ. Gbé àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí yẹ̀ wò, nípa ohun tí nínífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì jẹ́ ní ti gidi àti bá a ṣe lè yẹra fún àwọn àkóbá tó ń ṣe fún ipò tẹ̀mí.

Wọ́n Ní Ọrọ̀ àti Ọlá

Ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan ní ọrọ̀ àti ọlá. Bí àpẹẹrẹ, Ábúráhámù “ní ọ̀pọ̀ wọ̀ǹtìwọnti ọ̀wọ́ ẹran àti fàdákà àti wúrà.” (Jẹ́nẹ́sísì 13:2) Bíbélì pe Jóòbù ni “ẹni tí ó pọ̀ jù lọ nínú gbogbo àwọn Ará Ìlà-Oòrùn” nítorí pé ó ní ohun ọ̀sìn rẹpẹtẹ, ó sì tún ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìránṣẹ́. (Jóòbù 1:3) Àwọn ọba Ísírẹ́lì, irú bíi Dáfídì àti Sólómọ́nì ní ọrọ̀ jaburata.—1 Kíróníkà 29:1-5; 2 Kíróníkà 1:11, 12; Oníwàásù 2:4-9.

Àwọn Kristẹni tí wọ́n lọ́rọ̀ wà nínú ìjọ Kristẹni ti ọ̀rúndún kìíní. (1 Tímótì 6:17) Bíbélì pe Lìdíà ní “ẹni tí ń ta ohun aláwọ̀ àlùkò, ará ìlú ńlá Tíátírà, ẹni tí ó jẹ́ olùjọsìn Ọlọ́run.” (Ìṣe 16:14) Aró aláwọ̀ àlùkò àtàwọn aṣọ tí wọ́n bá fi pa láró máa ń wọ́n gan-an, àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn tàbí àwọn ọlọ́rọ̀ ló sì sábà máa ń lò ó. Nípa bẹ́ẹ̀, Lìdíà fúnra rẹ̀ lè ti jẹ́ ẹni tó lọ́rọ̀ dé àyè kan.

Ní ìdàkejì, àwọn olóòótọ́ olùjọ́sìn Jèhófà kan wà tí wọ́n kúṣẹ̀ẹ́ gan-an lákòókò tí à ń kọ Bíbélì. Ìjábá, jàǹbá àti ikú sọ àwọn ìdílé kan di òtòṣì. (Oníwàásù 9:11, 12) Kò mà ní rọrùn rárá o, fún àwọn tó jẹ́ aláìní láti máa rí àwọn mìíràn kí wọ́n máa gbádùn ọrọ̀ tàbí àwọn nǹkan tara! Síbẹ̀, yóò jẹ́ ohun tó lòdì fún wọn láti wá máa ṣèdájọ́ àwọn ọlọ́rọ̀ pé wọ́n jẹ́ olùfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì tàbí kí wọ́n parí èrò sí pé àwọn akúṣẹ̀ẹ́ ló ń sin Ọlọ́run ní kíkún jù. Kí nìdí? Gbé olórí ohun tó ń fa ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì yẹ̀ wò.

Ìfẹ́ Owó

Ìwé atúmọ̀ èdè kan túmọ̀ ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì sí “ríronú ṣáá nípa nǹkan tara tàbí jíjẹ́ kó gbani lọ́kàn dípò wíwá ìmọ̀ tàbí àwọn nǹkan tẹ̀mí.” Nípa bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ní í ṣe gan-an pẹ̀lú ohun tó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn wa, àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ sí wa àtàwọn ohun tá à ń lépa ní ìgbésí ayé wa. Àwọn àpẹẹrẹ Bíbélì méjì tó wà nísàlẹ̀ yìí fi èyí hàn kedere.

Jèhófà bá Bárúkù wí gidigidi, ẹni tó jẹ́ akọ̀wé wòlíì Jeremáyà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó mú kí Bárúkù jẹ́ akúṣẹ̀ẹ́ ni, bí ipò àwọn nǹkan ṣe rí ní ìlú Jerúsálẹ́mù àti bó ṣe jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ tímọ́tímọ́ fún Jeremáyà, ẹni táwọn èèyàn kò gba tiẹ̀. Síbẹ̀ náà, Jèhófà sọ fún un pé: “Ní tìrẹ, ìwọ ń wá àwọn ohun ńláńlá fún ara rẹ. Má ṣe wá wọn mọ́.” Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí í gba Bárúkù lọ́kàn, tó ń ronú ṣáá nípa ọrọ̀ tàbí ohun táwọn ẹlòmíràn ní. Jèhófà rán Bárúkù létí pé Òun á dáàbò bò ó lọ́wọ́ ìparun tó ń bọ̀ lórí Jerúsálẹ́mù àmọ́ Òun kò ní dáàbò bo àwọn nǹkan ìní rẹ̀.—Jeremáyà 45:4, 5.

Jésù sọ àpèjúwe kan nípa ọkùnrin kan tí òun náà di ẹni tí nǹkan tara gbà lọ́kàn. Ọkùnrin yìí jẹ́ kí ọrọ̀ rẹ̀ gbà á lọ́kàn dípò tí ì bá fi lo àwọn ohun tó ní láti fi mú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Ọlọ́run gbòòrò sí i. Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà sọ pé: “Ṣe ni èmi yóò ya àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ mi lulẹ̀, èmi yóò sì kọ́ àwọn tí ó tóbi, . . . èmi yóò [sì] sọ fún ọkàn mi pé: ‘Ọkàn, ìwọ ní ọ̀pọ̀ ohun rere tí a tò jọ pa mọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún; fara balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, máa jẹ, máa mu, máa gbádùn.’” Jésù wá sọ pé: “Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fún un pé, ‘Aláìlọ́gbọ́n-nínú, òru òní ni wọn yóò fi dandan béèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ. Ta ni yóò wá ni àwọn ohun tí ìwọ tò jọ pa mọ́?’ Bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń rí fún ẹni tí ó bá ń to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”—Lúùkù 12:16-21.

Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú àkọsílẹ̀ méjì yìí? Wọ́n ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé kì í ṣe bí ohun ìní tí ẹnì kan ní ṣe pọ̀ tó ló mú kó jẹ́ olùfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ kíka àwọn nǹkan tara sí ohun ṣíṣe pàtàkì jù lọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé. Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí, a ti mú àwọn kan ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.” (1 Tímótì 6:9, 10) Ohun tó ń fa ìṣòro ni pípinnu láti di ọlọ́rọ̀ àti nínífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan tara.

Ó Yẹ Ká Yẹ Ara Wa Wò

Yálà wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ tàbí tálákà, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí wọ́n má bàa di ẹni tó kó sí ọ̀fìn ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì. Agbára ọrọ̀ máa ń tanni jẹ ó sì lè fún nǹkan tẹ̀mí pa. (Mátíù 13:22) Ìfẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí í lépa àwọn nǹkan tara dípò àwọn nǹkan tẹ̀mí lè máa gbilẹ̀ nínú wa ká tó mọ̀, èyí yóò sì mú àwọn àbájáde tí ń bani nínú jẹ́ wá.—Òwe 28:20; Oníwàásù 5:10.

Nípa bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí àwọn Kristẹni ṣàyẹ̀wò ara wọn láti mọ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ sí wọn ní ìgbésí ayé àti ohun tí wọ́n ń lépa. Yálà nǹkan tara díẹ̀ lèèyàn ní tàbí púpọ̀, àwọn tí nǹkan tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn máa ń sapá láti fi ọ̀rọ̀ ìṣítí Pọ́ọ̀lù sọ́kàn pé kí wọ́n má ṣe gbé ìrètí wọn lé “ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run, ẹni tí ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa.”—1 Tímótì 6:17-19.