Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Ṣèbẹ̀wò Sí Oko Ọ̀gẹ̀dẹ̀

Mo Ṣèbẹ̀wò Sí Oko Ọ̀gẹ̀dẹ̀

Mo Ṣèbẹ̀wò Sí Oko Ọ̀gẹ̀dẹ̀

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ GÚÚSÙ ÁFÍRÍKÀ

MO MÀ fẹ́ràn ọ̀gẹ̀dẹ̀ o. Mo gbà pé ọ̀pọ̀ èèyàn náà ló fẹ́ràn rẹ̀. Kì í ṣe pé ọ̀gẹ̀dẹ̀ dùn nìkan ni, àmọ́ ó tún ní ọ̀pọ̀ èròjà aṣaralóore bíi fítámì àti mineral nínú, ó sì máa ń fọ ìdọ̀tí inú kúrò. Ṣé wàá fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa èso aṣaralóore yìí? Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àgbẹ̀ kan àti aya rẹ̀ fi ọ̀nà àgbàyanu tí ọ̀gẹ̀dẹ̀ máa ń gbà hù fúnra rẹ̀ hàn mí.

Tony àti Marie (tí àwòrán wọn wà lókè) ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀ ní Ẹkùn Ìpínlẹ̀ Limpopo ní orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà, ní àgbègbè kan tó ń jẹ́ Levubu. Onírúurú irè oko ni wọ́n ń gbìn sórí ilẹ̀ wọn tó jẹ́ hẹ́kítà márùnléláàádọ́ta. Ṣùgbọ́n ọ̀gẹ̀dẹ̀ ni olórí ohun tí wọ́n ń gbìn. Tony yóò fẹ́ láti túbọ̀ sọ ọ̀pọ̀ nǹkan fún wa nípa èso tí tọmọdé tàgbà fẹ́ràn yìí.

Bí Ọ̀gẹ̀dẹ̀ Ṣe Ń Hù àti Ipa Tí Ipò Ojú Ọjọ́ Ń Kó

Tony ṣàlàyé pé: “Ilẹ̀ tó dára jù fún gbígbin ọ̀gẹ̀dẹ̀ ni ilẹ̀ tó bá ní amọ̀ tó pọ̀, kì í ṣe ilẹ̀ oníyanrìn tàbí ilẹ̀ olókùúta. Yẹ̀pẹ̀ náà gbọ́dọ̀ pọ̀ kó sì lọ́ràá dáadáa. Ọ̀gẹ̀dẹ̀ máa ń so dáadáa láwọn àgbègbè tí ojú ọjọ́ kò bá tutù nini. Ká sòótọ́, ilẹ̀ olóoru gan-an ni wọ́n fẹ́ràn jù. Àgbègbè Levubu máa ń gbóná gan-an, ooru sì máa ń mú púpọ̀ níbẹ̀.” Nígbà tí mo béèrè lọ́wọ́ Tony bóyá ọ̀gẹ̀dẹ̀ nílò òjò, ó dáhùn pé: “Ọ̀gẹ̀dẹ̀ ń fẹ́ kí òjò máa rọ̀ déédéé tàbí kéèyàn máa bomi rin ín lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.”

Ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ fara jọ igi, àmọ́ kì í ṣe igi rárá, torí pé ewé ló wé jọ sí i lára. Ìdìpọ̀ ewé ni, kì í ṣe igi tó ń ní ẹ̀ka. Látinú gbòǹgbò rẹ̀ tí wọ́n ń pè ní rhizome ni ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ ti ń jáde. Àtinú gbòǹgbò yìí ni ìtàkùn rẹ̀ ti máa ń ta lọ sísàlẹ̀, bákan náà ló jẹ́ pé látinú gbòǹgbò yìí kan náà ni ewé ọ̀gẹ̀dẹ̀ ti ń yọ sókè, tí òdòdó ńlá aláwọ̀ àlùkò kan yóò sì hù nínú rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Àwọn ọ̀mùnù tún máa ń hù látinú gbòǹgbò yìí láti di ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ tuntun.

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ máa ń hù ní ìpele mẹ́ta pàtàkì, èyí táwọn àgbẹ̀ ní àgbègbè Levubu máa ń pè ní “ìyá ìyá, ọmọ, àti ọmọ ọmọ.” (Wo àwòrán.) Èyí tí wọ́n ń pè ní “ìyá ìyá” á so lọ́dún yìí, “ọmọ” á so lọ́dún tó ń bọ̀, èyí tó jẹ́ “ọmọ ọmọ” á sì so lọ́dún tó máa tẹ̀ lé e. “Àwọn ọmọ ọmọ,” ìyẹn àwọn tó hù jáde kẹ́yìn, máa ń tò yíká àwọn “ìyá.” Nígbà tí àwọn “ọmọ ìkókó” wọ̀nyí bá ti ga dé eékún, àwọn àgbẹ̀ á gé gbogbo wọn dà nù, àyàfi àwọn tó bá yọrí jù nínú wọn ni wọ́n á fi sílẹ̀.

Òdòdó aláwọ̀ àlùkò náà, èyí tó máa wá di pádi ọ̀gẹ̀dẹ̀ tó bá yá, máa ń gba àárín ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ náà hù sókè, látinú gbòǹgbò tó wà nínú ilẹ̀. Níkẹyìn, òdòdó yìí á gba àárín àwọn ewé ńlá méjì tó wà lókè jáde, á sì ṣẹ́rí wálẹ̀. Bí àwọn ìtànná òdòdó náà bá ti ń rẹ̀ dà nù, apópó ọ̀gẹ̀dẹ̀ mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tí kò ì gbó, tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ pádi ọ̀gẹ̀dẹ̀ á bẹ̀rẹ̀ sí fara hàn—ṣùgbọ́n lójú ẹni tí kò bá mọ̀ nípa ọ̀gbìn ọ̀gẹ̀dẹ̀, ńṣe ló máa dà bíi pé ọ̀gẹ̀dẹ̀ náà ń dàgbà ní ìdoríkodò! Apópó ọ̀gẹ̀dẹ̀ kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbó bọ̀ lè ní tó ogún ẹyọ ọ̀gẹ̀dẹ̀ tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, iga ni wọ́n sì máa ń pe ẹyọ ọ̀gẹ̀dẹ̀ kọ̀ọ̀kan.

Ìgbà Ìkórè

Bí òdòdó aláwọ̀ àlùkò náà bá ti yọ, kíkórè ọ̀gẹ̀dẹ̀ lè má ju oṣù mẹ́ta tàbí mẹ́fà sí ìgbà náà lọ. Dúdú ni wọ́n máa ń bẹ́ ẹ, ṣùgbọ́n á jẹ́ lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ọ̀gẹ̀dẹ̀ náà bá ti yọ dáadáa, tí wọ́n ti tóbi gbàǹgbà gbàǹgbà. Pádi ọ̀gẹ̀dẹ̀ kan tó tóbi tó láti tà lọ́jà lè wọ̀n tó kílò márùndínlógójì. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti bẹ́ wọn, wọ́n á da ọ̀rá bo àwọn ọ̀gẹ̀dẹ̀ náà lórí kí nǹkan má bàa ha wọ́n lára nígbà tí wọ́n bá ń fi ọkọ̀ gbé wọn lọ sí ibí tí wọ́n ń kó wọn sí kí wọ́n tó pọ́n. Níbẹ̀, wọ́n á gé apópó àwọn ọ̀gẹ̀dẹ̀ yìí sí kéékèèké, ìyẹn ni pé apópó kọ̀ọ̀kan á ní ẹyọ ọ̀gẹ̀dẹ̀ mẹ́ta sí mẹ́fà lára, lẹ́yìn náà ni wọ́n á fún oògùn apakòkòrò sí wọn lára.

Ní orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà, wọ́n máa ń kó àwọn ọ̀gẹ̀dẹ̀ náà sínú àwọn páálí tí wọ́n ti fi àtè lẹ̀ tí wọ́n sì dáhò tóó-tòò-tó sí lára nítorí atẹ́gùn, wọ́n á wá gbé wọn lọ sí iyàrá kan tí wọ́n ti máa pọ́n. Nínú iyàrá náà, wọ́n máa ń lo gáàsì kan tó ń jẹ́ ethylene láti fi mú kí àwọn ọ̀gẹ̀dẹ̀ náà pọ́n. a Wọ́n á fi àwọn páálí ọ̀gẹ̀dẹ̀ náà sílẹ̀ nínú iyàrá tí kò tutù jù tàbí gbóná jù yìí fún ọjọ́ kan tàbí méjì, lẹ́yìn náà ni wọ́n á fi ránṣẹ́ sí àwọn tó fẹ́ rà wọ́n.

Tony sọ pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ pé: “Mi ò mọ̀ bóyá mò ń ṣojúsàájú ni, àmọ́ mo gbà gbọ́ pé ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbègbè Levubu dùn ju ti ibòmíràn lọ, bóyá nítorí ilẹ̀ wa ni. Àmọ́, ó dunni pé, torí pé a jìnnà gan-an sí ìlú ńlá èyíkéyìí tí wọ́n ti ń fi ọjà ránṣẹ́ sílẹ̀ òkèèrè, orílẹ̀-èdè yìí nìkan la ti ń gbádùn wọn.”

Ó Dára fún Ìlera Rẹ

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ ní èròjà aṣaralóore kan tó ń jẹ́ potassium nínú. Nínú àpilẹ̀kọ kan tí ìwé ìròyìn Health kọ lórí ọ̀gẹ̀dẹ̀, ó ní: “Ọ̀pọ̀ ìwádìí ló ti fi hàn pé èròjà yìí lè mú kí egungun rẹ lágbára, kò sì ní jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ ríru àti àrùn ẹ̀gbà tètè ṣe ọ.” Ìwé ìròyìn náà fi kún un pé: “Ọ̀gẹ̀dẹ̀ ní èròjà agbóguntàrùn kan nínú, èyí tó máa ń dènà àwọn kòkòrò tó lè sọ ọmọ ìkókó di aláàbọ̀ ara, ìyẹn ni vitamin B tó ṣe kókó fún àwọn aláboyún àtàwọn obìnrin tí wọ́n wà ní ọjọ́ orí ọmọ bíbí.” Ọ̀gẹ̀dẹ̀ tún ní àwọn èròjà mineral pàtàkì mìíràn nínú, irú bíi magnesium, èyí tó máa ń jẹ́ kí egungun ní èròjà calcium táá sì jẹ́ kó lágbára.

Àwọn èròjà amino acid méjìdínlógún ló para pọ̀ di èròjà protein tó wà nínú ọ̀gẹ̀dẹ̀, títí kan gbogbo àwọn èròjà ṣíṣekókó tí ara rẹ kò lè mú jáde tó bó ṣe yẹ tàbí tí kò tiẹ̀ lè mú jáde rárá. Èròjà carbohydrate tó tó ìdá méjìlélógún nínú ọgọ́rùn-ún ló wà nínú ọ̀gẹ̀dẹ̀, ìwọ̀nyí sì ń fára lókun torí pé ọ̀gẹ̀dẹ̀ máa ń tètè dà. Inú Marie dùn láti fi kún un pé: “Ọ̀gẹ̀dẹ̀ tún máa ń pèsè àwọn èròjà aṣaralóore bíi vitamin A, vitamin B, àti vitamin C. Bákan náà, wọ́n tún máa ń so inú ró, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìwọ̀nba díẹ̀ ti tó láti jẹ.” Nígbà náà, o ò ṣe wá ọ̀gẹ̀dẹ̀ kan jẹ—wàá rí i pé ó dára fún ọ, ó sì dùn gan-an!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bí ọ̀gẹ̀dẹ̀ bá fúnra rẹ̀ pọ́n, ó máa ń mú gáàsì ethylene yìí kan náà jáde, èyí tá á jẹ́ kó túbọ̀ máa pọ́n lọ. Nípa báyìí, ọ̀nà mìíràn láti mú kí ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú pọ́n ni láti fi àwọn díẹ̀ tó ti pọ́n sáàárín àwọn tí kò tíì pọ́n.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Ewé ọ̀gẹ̀dẹ̀

Òdòdó/ọ̀gẹ̀dẹ̀

Ìdìpọ̀ ewé tó para pọ̀ di ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀

Ibi tí ilẹ̀ dé

Ìdí ewé

Gbòǹgbò

[Credit Line]

Àwòrán: A mú un látinú àwòrán tó wà nínú ìwé The Complete Encyclopedia of Illustration/J. G. Heck

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Ìyá ìyá

Ọmọ

Ọmọ ọmọ

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Òdòdó ńlá aláwọ̀ àlùkò yìí ló máa di pádi ọ̀gẹ̀dẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn

[Credit Line]

Ẹni tó ya àwòrán yìí ni Kazuo Yamasaki

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ìgbà ìkórè (lápá òsì); àwọn ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ wọ̀nyí máa pọnmọ tó bá yá (òkè)