Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Oorun—Ṣé Fáwọn Olóòrayè ni Àbí Ohun Àìgbọ́dọ̀máṣe?

Oorun—Ṣé Fáwọn Olóòrayè ni Àbí Ohun Àìgbọ́dọ̀máṣe?

Oorun—Ṣé Fáwọn Olóòrayè ni Àbí Ohun Àìgbọ́dọ̀máṣe?

LÓJÚ ÀWỌN ÈÈYÀN KAN, fífi àkókò ṣòfò ni oorun sísùn jẹ́. Ó tẹ́ wọn lọ́rùn kí ọwọ́ wọn máa dí lójoojúmọ́ lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àti àwọn àjọṣe àárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, kó wá jẹ́ pé ìgbà tó bá ti rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu nìkan ni wọ́n máa tóó sùn. Àmọ́ o, ní tàwọn ẹlòmíràn, tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ òru ni wọn kì í rí oorun sùn tí wọ́n á kàn máa yí kiri lórí ibùsùn títí di àfẹ̀mọ́jú tí oorun á ṣẹ̀ṣẹ̀ wá gbé wọn lọ, kò sí ohun tí wọn ò lè ṣe láti lè máa sun oorun àsùngbádùn.

Kí ló fà á táwọn kan kì í fi í rí oorun sùn, nígbà tó sì jẹ́ pé àwọn kan kì í tiẹ̀ fẹ́ẹ́ sùn rárá? Ǹjẹ́ ó yẹ ká wo oorun bi ohun tó wà fáwọn olóòrayè àbí bí ohun àìgbọ́dọ̀máṣe? Láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, ó yẹ ká lóye ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ara wa nígbà tá a bá ń sùn.

Ó Ṣòro Láti Ṣàlàyé Bí Oorun Ṣe Ń Múni Lọ

Ohun náà gan-an tó ń mú kí oorun gbéni lọ kò tíì yé ọmọ ẹ̀dá. Àmọ́ o, àwọn olùṣèwádìí sọ pé oorun jẹ́ ohun kan tó díjú láti ṣàlàyé, wọ́n ní ọpọlọ ló ń darí rẹ̀, àti pé aago kan nínú ara wa náà tún ń ṣàkóso rẹ̀.

Bá a bá ṣe ń dàgbà sí i ni oorun sísùn wa máa ń yí padà. Ọmọ tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí máa ń sùn ṣẹ́-ṣẹ̀ẹ̀-ṣẹ́ ní ọ̀pọ̀ ìgbà lóòjọ́, èyí tí àpapọ̀ rẹ̀ máa ń jẹ́ nǹkan bíi wákàtí méjìdínlógún. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn ògbógi nípa oorun sọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé oorun tí àwọn àgbàlagbà kan nílò lójúmọ́ ọjọ́ kan lè máà ju wákàtí mẹ́ta péré lọ, àwọn mìíràn nílò oorun tó tó wákàtí mẹ́wàá.

Àwọn ìwádìí ẹnu àìpẹ́ yìí ti fi hàn pé, àwọn ìyàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ nínú bí aago inú ara wa ṣe ń ṣiṣẹ́ tún lè jẹ́ ká mọ ìdí tí àwọn ọ̀dọ́langba kan fi máa ń lọ́ra láti dìde lórí ibùsùn nígbà tí ilẹ̀ bá mọ́. Ó dà bíi pé aago inú ara máa ń sún síwájú nígbà ìbàlágà, èyí sì máa ń mú kí àwọn ọ̀dọ́langba máa pẹ́ kí wọ́n tó sùn, kí wọ́n sì máa pẹ́ jí. Àṣà kí wọ́n má pẹ́ kí wọ́n tó sùn yìí wọ́pọ̀ gan-an láàárín àwọn ọ̀dọ́langba, ó sì sábà máa ń pòórá nígbà tí wọ́n bá fi máa pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún.

Àwọn èròjà kan nínú ara wa ló ń darí aago inú ara, àwọn ògbógi sì ti ṣàwárí púpọ̀ lára wọn. Ọ̀kan lára wọn ni èròjà melatonin, èyí tí wọ́n sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ló ń mú kí oorun máa kun èèyàn. Ọpọlọ ló ń pèsè èròjà yìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan sì gbà pé òun ni kì í jẹ́ kí ara èèyàn gbé kánkán mọ́ ṣáájú kéèyàn tó sùn. Nígbà tí ọpọlọ bá ń mú èròjà yìí jáde, ara ẹni á silé, ẹ̀jẹ̀ tó ń ṣàn lọ sí ọpọlọ á máa dín kù, àwọn iṣan ara wa á sì bẹ̀rẹ̀ sí í dẹ̀ díẹ̀díẹ̀, títí wọ́n á fi di aláìlágbára mọ́. Kí lohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e nígbà téèyàn bá ti ń sùn?

‘Ohun Tó Ń Ṣe Ara Ẹ̀dá Lóore Jù Lọ’

Ní nǹkan bíi wákàtí méjì lẹ́yìn tá a bá ti sùn, ẹyinjú wa méjèèjì á bẹ̀rẹ̀ síí yí sọ́tùn-ún sósì. Ìwádìí tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe lórí ọ̀ràn yìí ló mú kí wọ́n pín oorun sí ọ̀nà pàtàkì méjì. Ọ̀kan ni oorun àsùnwọra tó máa ń mú kí ẹyinjú yí lọ yí bọ̀ léraléra, èkejì sì ni oorun àsùnwọra tí ẹyinjú ẹni kì í yí lọ yí bọ̀. A tún lè pín oorun tí ẹyinjú ẹni kì í yí lọ yí bọ̀ sí ìpele mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, èyí tí ìpele kọ̀ọ̀kan máa ń mú kí oorun túbọ̀ wọra sí i béèyàn ṣe ń sùn nìṣó. Nígbà téèyàn bá ń sun oorun àsùnwọra lóru, oorun tí ẹyinjú ń yí lọ yí bọ̀ máa ń wáyé ní àìmọye ìgbà, tí oorun tí ẹyinjú ẹni kì í yí lọ yí bọ̀ sì máa ń là á.

Ìgbà téèyàn bá ń sùn tí ẹyinjú sì ń yí lọ yí bọ̀ lèèyàn sábà máa ń lálàá. Gbogbo iṣan ara á sinmi, ara ẹni á sì balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ lásìkò yìí, èyí ló máa ń jẹ́ kí ara tuni nígbà téèyàn bá jí. Láfikún sí i, àwọn olùṣèwádìí kan gbà gbọ́ pé àsìkò yìí ni àwọn ohun tuntun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ máa ń ráyè jókòó dáadáa sínú ọpọlọ, tí yóò sì wà lára àwọn ohun téèyàn á máa rántí fún ìgbà pípẹ́.

Nígbà tá a bá sùn wọra (ìyẹn ìpele kẹta àti ìkẹrin oorun tí ẹyinjú ẹni kì í yí lọ yí bọ̀), ìwọ̀n ìfúnpá wa àti ìlùkìkì ọkàn wa á lọ sílẹ̀ gan-an, èyí á mú kí ètò ìṣànkiri ẹ̀jẹ̀ ara wa sinmi, kò sì ní jẹ́ ká ní àwọn àrùn tó jẹ mọ́ ọkàn àti òpójẹ̀. Láfikún sí i, àsìkò oorun tí ẹyinjú ẹni kì í yí lọ yí bọ̀ yìí ni ara máa ń mú èròjà kan tó ń jẹ́ kéèyàn dàgbà sókè jáde lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ, kódà, lóru, ara àwọn ọ̀dọ́langba kan lè pèsè èròjà yìí lọ́nà tó fi ìgbà àádọ́ta pọ̀ ju ti ọ̀sán lọ.

Ó dà bíi pé oorun tún máa ń nípa lórí oúnjẹ jíjẹ. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣàwárí pé, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ òpìtàn Shakespeare, lóòótọ́ àti lódodo ni oorun jẹ́ “ohun tó ń ṣe ara ẹ̀dá lóore jù lọ.” Ńṣe ni ọpọlọ wa máa ń ka àìsí oorun sí àìjẹun. Nígbà tá a bá ń sùn, ara wa máa ń mú èròjà kan jáde tó ń jẹ́ leptin, èyí tó máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé a ti yó. Bá a bá pẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ tá ò sùn, ara wa ò ní fi bẹ́ẹ̀ pèsè èròjà yìí, a ó sì máa nímọ̀lára pé a nílò èròjà carbohydrate sí i. Nípa bẹ́ẹ̀, àìkìísùn lè yọrí sí jíjẹ àwọn oúnjẹ tó ní èròjà carbohydrate púpọ̀ sí i, èyí sì lè yọrí sí sísanra jọ̀kọ̀tọ̀.—Wo àpótí náà, “Oorun Ọ̀sán,” tó wà lójú ìwé 14.

Ó Ṣe Kókó fún Ìlera

Ṣùgbọ́n kò tán síbẹ̀ o. Oorun máa ń jẹ́ kó rọrùn fún ara wa láti palẹ̀ àwọn ohun tín-tìn-tín kan mọ́ kúrò nínú ara, èyí tó máa ń mú kí àwọn sẹ́ẹ̀lì ara di arúgbó, tó sì tún lè fa àrùn jẹjẹrẹ pàápàá. Nínú ìwádìí kan tí Yunifásítì Chicago ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n ṣètò pé kí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mọ́kànlá tí ìlera wọn jí pépé sun oorun wákàtí mẹ́rin péré fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn àkókò náà, ńṣe làwọn sẹ́ẹ̀lì ara wọn ń ṣiṣẹ́ bíi ti ọmọ ọgọ́ta ọdún, àti pé, èròjà insulin inú ẹ̀jẹ̀ wọn ti lọ sílẹ̀ gan-an bíi ti ẹni tó ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà! Àìkìísùn tún máa ń ṣèdíwọ́ fún ìmújáde sẹ́ẹ̀lì funfun inú ẹ̀jẹ̀ àti èròjà kan tó ń jẹ́ cortisol, èyí tó lè jẹ́ kí ẹnì kan máa tètè ní àkóràn àtàwọn àrùn tó jẹ mọ́ ìṣànkiri ẹ̀jẹ̀.

Láìsí àní-àní, oorun ṣe kókó fún ìlera àti ọpọlọ tó jí pépé. Lójú ìwòye olùṣèwádìí kan tó ń jẹ́ William Dement, tó jẹ́ olùdásílẹ̀ ibùdó àkọ́kọ́ fún ṣíṣe ìwádìí nípa oorun ní Yunifásítì Stanford, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó ní: “Ó jọ pé oorun ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ fún dídíwọ̀n bá a ṣe máa pẹ́ tó láyé.” Deborah Suchecki, tó jẹ́ olùṣèwádìí ní ibùdó ìṣèwádìí kan nípa oorun ní ìlú São Paulo, lórílẹ̀-èdè Brazil sọ pé: “Ká ní àwọn èèyàn mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ara ẹni tí kì í báá sùn ni, wọn ì bá máa ronú dáadáa kí wọ́n tó máa sọ pé fífi àkókò ṣòfò ni oorun jẹ́ tàbí pé àwọn ọ̀lẹ ni oorun wà fún.”—Wo àpótí tó wà lókè.

Àmọ́, ǹjẹ́ gbogbo oorun ló ń mára jí pépé? Kí nìdí tí àwọn kan fi máa ń sùn ní gbogbo òru síbẹ̀ tí wọ́n á jí tí ara wọn á ṣì wúwo? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ díẹ̀ lára àwọn ìṣòro oorun pàtàkì, yóò sì ṣàlàyé bó o ṣe lè máa sun oorun àsùngbádùn.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

ÀWỌN ÀBÁJÁDE ÀÌRÓORUNSÙN

ÀWỌN ÀBÁJÁDE TÓ LÈ WÀ FÚN ÌGBÀ DÍẸ̀

◼ Títòògbé

◼ Kí ìṣarasíhùwà ẹni máa ṣàdédé yí padà

◼ Àìlè tètè rántí nǹkan

◼ Àìlè fọkàn yàwòrán àwọn ohun tó o fẹ́ ṣe, kó o ṣètò wọn lẹ́sẹẹsẹ, kó o sì ṣe wọ́n láṣeyọrí

◼ Àìlèpọkànpọ̀

ÀWỌN ÀBÁJÁDE TÓ LÈ WÀ FÚN ÀKÓKÒ PÍPẸ́

◼ Sísanra jọ̀kọ̀tọ̀

◼ Dídarúgbó láìtọ́jọ́

◼ Kó máa rẹ èèyàn ṣáá

◼ Kí àrùn tètè máa ranni, irú bí àtọ̀gbẹ, àwọn àrùn tó jẹ mọ́ ọkàn àti òpójẹ̀, àtàwọn àrùn tó jẹ mọ́ ikùn àti ìfun

◼ Gbígbàgbé nǹkan ju bó ṣe yẹ lọ

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]

OORUN Ọ̀SÁN

Ǹjẹ́ ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọ rí pé, lẹ́yìn tó o jẹun ọ̀sán tán, ńṣe lo bẹ̀rẹ̀ sí tòògbé ṣáá, tó ò sì lè ṣe ohunkóhun sí i? Èyí kò fi dandan túmọ̀ sí pé o ní ìṣòro àìróorunsùn. Ohun tó ń jẹ́ kí oorun kunni lọ́wọ́ ọ̀sán ni pé ara máa ń silé lásìkò yẹn. Bákan náà, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí èròjà protein kan tí ọpọlọ ń mú jáde. Orúkọ rẹ̀ ni hypocretin, tàbí eroxin, òun ló sì máa ń mú ká wà lójúfò. Kí ni ìsopọ̀ tó wà láàárín èròjà yìí àti oúnjẹ tá à ń jẹ?

Nígbà tá a bá ń jẹun, ara wa máa ń mú èròjà kan tó ń jẹ́ leptin jáde, èyí tó máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé a ti yó. Àmọ́, èròjà leptin yìí máa ń ṣèdíwọ́ fún ìmújáde èròjà hypocretin. Èyí túmọ̀ sí pé, bí èròjà leptin bá ṣe pọ̀ tó nínú ọpọlọ ni èròjà hypocretin tó wà nínú ara ṣe máa kéré sí, bẹ́ẹ̀ sì ni oorun á ṣe máa kunni tó. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn èèyàn máa ń ṣíwọ́ iṣẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ ọ̀sán láti fi oorun díẹ̀ rẹjú.

[Graph tó wà ní ojú ìwé 13]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÌPELE OORUN

Àwòrán tó lè tètè yéni

Ìpele Oorun

Ìgbà téèyàn wà lójúfò

Oorun tí ẹyinjú ẹni ti ń yí lọ yí bọ̀

Oorun tí ẹyinjú ẹni kì í yí lọ yí bọ̀

Oorun téèyàn ò sùn wọra 1

2

3

Oorun téèyàn sùn wọra 4

1 2 3 4 5 6 7 8

Iye Wákàtí Téèyàn Fi Sùn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]

Oorun tó tó ṣe kókó fún ìlera àti ọpọlọ tó jí pépé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ìgbà téèyàn ń sùn ni ara máa ń mú èròjà kan tó ń jẹ́ kéèyàn dàgbà sókè jáde lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ