Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àtọ̀gbẹ—“Àrùn Tó Ń Yọ́ Kẹ́lẹ́ Ṣọṣẹ́”

Àtọ̀gbẹ—“Àrùn Tó Ń Yọ́ Kẹ́lẹ́ Ṣọṣẹ́”

Àtọ̀gbẹ—“Àrùn Tó Ń Yọ́ Kẹ́lẹ́ Ṣọṣẹ́”

NÍGBÀ tí Ken wà lọ́mọ ọdún mọ́kànlélógún, ńṣe ni òùngbẹ á kàn máa gbẹ ẹ́ ṣáá, láìlè ṣàlàyé ohun tó fà á. Ó tún máa ń tọ̀ léraléra—nígbà tó tiẹ̀ yá, ó di kó máa tọ̀ ní gbogbo ogún ìṣẹ́jú. Kò pẹ́ kò jìnnà, ẹsẹ̀ Ken bẹ̀rẹ̀ sí wúwo nílẹ̀. Ó máa ń rẹ̀ ẹ́ tẹnutẹnu, ojú rẹ̀ á sì máa ṣe bàìbàì.

Ìgbà tí òjòjò kan kọ lu Ken ló tó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Àbẹ̀wò tó ṣe sọ́dọ̀ dókítà fi hàn pé kì í ṣe òjòjò lásán ló ń ṣe é—àmọ́ ó ti ní àrùn àtọ̀gbẹ Oríṣi Kìíní, èyí tí í ṣe àrùn àtọ̀gbẹ ọmọdé. Ìṣòro yìí kì í jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ara láti ṣàmúlò àwọn èròjà aṣaralóore kan, pàápàá jù lọ ṣúgà inú ẹ̀jẹ̀ tó ń jẹ́ gúlúkóòsì. Oṣù kan àtààbọ̀ ni Ken lò ní ọsibítù kí ìwọ̀n ṣúgà inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tó padà sí bó ṣe yẹ.

Ìyẹn ti lé ní àádọ́ta ọdún báyìí, ọ̀nà tí wọ́n ń gbà tọ́jú àrùn yìí sì ti dára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ fíìfíì. Àmọ́ ṣá o, àrùn àtọ̀gbẹ yìí kò fi Ken lọ́rùn sílẹ̀ o, kì í sì í ṣe òun nìkan ló ní ìṣòro náà. Jákèjádò ayé, ó lé ní ogóje [140] mílíọ̀nù èèyàn tí wọ́n fojú bù pé wọ́n ní àrùn yìí, gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé sì ti sọ, iye yìí lè di ìlọ́po méjì tó bá fi máa di ọdún 2025. Abájọ tí ọkàn àwọn ògbógi kò fi balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń rí àrùn yìí tó túbọ̀ ń gbilẹ̀ sí i. Èyí ló mú kí Dókítà Robin S. Goland, ọ̀kan lára àwọn olùdarí ilé ìwòsàn kan tó wà fún ìtọ́jú àrùn àtọ̀gbẹ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Pẹ̀lú iye àwọn èèyàn tá a ti bẹ̀rẹ̀ sí í rí tí wọ́n ń ní àrùn yìí báyìí, ó ṣeé ṣe kó di àjàkálẹ̀ àrùn.”

Gbé àwọn ìròyìn ṣókí yìí láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé yẹ̀ wò.

ỌSIRÉLÍÀ: Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Tó Ń Mójú Tó Àrùn Àtọ̀gbẹ Lágbàáyé Ẹ̀ka Ti Ilẹ̀ Ọsirélíà ṣe sọ, “àrùn àtọ̀gbẹ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àrùn tó ṣòro láti wò sàn ní ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí.”

ÍŃDÍÀ: Ó kéré tán, ọgbọ̀n mílíọ̀nù èèyàn ló ní àrùn àtọ̀gbẹ níbẹ̀. Dókítà kan sọ pé: “Ní nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn, ekukáká la fi rí àwọn tí kò tíì pé ọmọ ogójì ọdún tí wọ́n ní àrùn yìí. Lónìí, ìdajì àwọn tó ní àìsàn yìí ni kò tíì pé ogójì ọdún.”

SINGAPORE: Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn olùgbé ibẹ̀ tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọgbọ̀n ọdún sí ọdún mọ́kàndínláàádọ́rin tí wọ́n ní àrùn àtọ̀gbẹ. Ọ̀pọ̀ ọmọdé ni àyẹ̀wò ti fi hàn pé wọ́n ní in, kódà àwọn kan nínú wọn kò tiẹ̀ tíì pé ọmọ ọdún mẹ́wàá rárá.

ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ: Nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún èèyàn ni àrùn àtọ̀gbẹ ń bá jà níbẹ̀, àyẹ̀wò sì ń fi hàn pé àwọn èèyàn tó tó ogójì ọ̀kẹ́ [800,000] ló tún ń ní in lọ́dọọdún. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló ní àrùn yìí lára àmọ́ tí wọn kò tíì mọ̀.

Ohun tó túbọ̀ mú kí àrùn àtọ̀gbẹ ṣòro láti tọ́jú ni pé, ó lè ti wà lára ẹnì kan fún ìgbà pípẹ́ kí àyẹ̀wò tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá fi hàn. Ìwé ìròyìn Asiaweek sọ pé: “Nítorí pé àwọn àmì tó máa ń kọ́kọ́ yọjú kì í fi bẹ́ẹ̀ lágbára, àrùn àtọ̀gbẹ lè wà lára ẹnì kan kí onítọ̀hún má sì mọ̀.” Èyí ló mú kí wọ́n pe àrùn àtọ̀gbẹ ní àrùn tó ń yọ́ kẹ́lẹ́ ṣọṣẹ́.

Nítorí bí àìsàn yìí ṣe túbọ̀ ń wọ́pọ̀ sí i, tó sì jẹ́ àrùn tó burú jáì, àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò:

● Kí ló ń fa àrùn àtọ̀gbẹ?

● Báwo làwọn tó ní àrùn náà ṣe lè kojú rẹ̀?

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń Pè É Ní Àrùn Àtọ̀gbẹ Tàbí Àrùn Ìtọ̀ Ṣúgà

Ọ̀rọ̀ náà “àtọ̀gbẹ” tàbí “ìtọ̀ ṣúgà” wá látinú ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì kan tó túmọ̀ sí “láti tú jáde,” ó sì wá látinú ọ̀rọ̀ Látìn kan tó túmọ̀ sí “dùn bí oyin.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí bá àìsàn yìí mu gẹ́lẹ́, nítorí pé omi kì í dúró lára ẹni tó bá ní àrùn àtọ̀gbẹ, ńṣe ló máa ń dà bíi pé bó ṣe ń gba ẹnu rẹ̀ wọlé ló ń lọ sínú àpò ìtọ̀ tí ẹni náà sì ń tọ̀ ọ́ jáde kíákíá. Síwájú sí i, ìtọ̀ ẹni náà á máa dùn nítorí pé ó ní èròjà ṣúgà nínú. Kódà, kó tó di pé wọ́n jágbọ́n àwọn ọ̀nà tó gbéṣẹ́ gan-an láti mọ̀ bóyá ẹnì kan ní àrùn yìí lára, ohun tí wọ́n máa ń ṣe ni pé, wọ́n á lọ da ìtọ̀ ẹni náà sí tòsí ibi tí àwọn èèrà wà. Bí àwọn èèrà bá bò ó, èyí fi hàn pé ṣúgà wà nínú ìtọ̀ náà nìyẹn.