Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ìṣòro Tó Rọ̀ Mọ́ Títọ́jú Àrùn Àtọ̀gbẹ

Àwọn Ìṣòro Tó Rọ̀ Mọ́ Títọ́jú Àrùn Àtọ̀gbẹ

Àwọn Ìṣòro Tó Rọ̀ Mọ́ Títọ́jú Àrùn Àtọ̀gbẹ

“Kò sí kékeré àrùn àtọ̀gbẹ. Àrùn tó léwu ni.”—Anne Daly, Òṣìṣẹ́ Àjọ Tó Ń Mójú Tó Àrùn Àtọ̀gbẹ Nílẹ̀ Amẹ́ríkà.

“ÀYẸ̀WÒ ẹ̀jẹ̀ rẹ fi hàn pé àìsàn kékeré kọ́ ló ń ṣe ọ́. O nílò ìtọ́jú ní kíákíá.” Ọ̀rọ̀ tí dókítà sọ yìí da jìnnìjìnnì bo Deborah. Ó sọ pé: “Lálẹ́ ọjọ́ náà, mi ò yéé ronú ṣáá pé ó ní láti jẹ́ pé àṣìṣe wà nínú àyẹ̀wò náà. Kò jẹ́ jẹ́ òótọ́ pé mò ń ṣàìsàn.”

Gẹ́gẹ́ bó ti máa ń rí lára ọ̀pọ̀ èèyàn, Deborah ronú pé kò sóhun tó ṣe òun, nípa bẹ́ẹ̀ kò ṣe nǹkan kan sí àwọn àmì tó ń rí. Ó ronú pé oògùn kan tí òun ń lò ló jẹ́ kí òùngbẹ máa gbẹ òun ṣáá. Ó ka ìtọ̀ tó ń tọ̀ nígbà gbogbo sí àbájáde omi tí òún ń mu jù. Ti rírẹ̀ tó sì máa ń rẹ̀ ẹ́ ńkọ́? Ó gbà pé kò sí abiyamọ kan tó tún ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tí kì í rẹ̀.

Àmọ́ àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ tó ṣe ló wá fi hàn pé àrùn àtọ̀gbẹ ló ń yọ ọ́ lẹ́nu. Ó ṣòro fún Deborah láti gba nǹkan tí àyẹ̀wò yìí gbé jáde gbọ́. Ó sọ pé: “Mi ò sọ fún ẹnì kankan nípa àìsàn náà. Tó bá wá di òru, táwọn aráalé ti sùn, màá ranjú kalẹ̀ nínú òkùnkùn, màá sì máa sunkún.” Bíi ti Deborah, nígbà táwọn kan bá gbọ́ pé àwọ́n ti ní àrùn ìtọ̀ ṣúgà, ọkàn wọn á kọ́kọ́ dàrú, ìrònú á dorí wọn kodò, inú tiẹ̀ lè máa bí wọn pàápàá. Karen sọ pé: “Ó níye ìgbà tí mo sunkún, tí màá máa ronú pé kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀.”

Bọ́rọ̀ ṣe máa ń rí lára nìyí tí nǹkan téèyàn ò retí bá ṣàdédé ṣẹlẹ̀. Àmọ́, pẹ̀lú ìtìlẹyìn látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn, àwọn tó ní àrùn àtọ̀gbẹ lè múra wọn bá ipò wọn mu. Karen sọ pé: “Nọ́ọ̀sì tó ń tọ́jú mi ràn mí lọ́wọ́ láti gbà pé ó ti dé ó ti dé ná. Ó fi mí lọ́kàn balẹ̀ pé kò burú rárá láti sunkún. Ẹkún yìí jẹ́ kára tù mí ó sì ràn mí lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba ipò mi.”

Ìdí Tí Kì Í Fi Í Ṣe Àìsàn Yẹpẹrẹ

Wọ́n ti ní “àìsàn tó máa ń ṣàkóbá fún ètò ìgbẹ́mìíró inú ara” ni àrùn àtọ̀gbẹ, èyí kì í sì í ṣe irọ́. Nígbà tí ara kò bá lè mú èròjà gúlúkóòsì jáde, ọ̀pọ̀ lára àwọn ètò pàtàkì tó ń lọ nínú ara lè dáwọ́ iṣẹ́ dúró, nígbà mìíràn èyí lè yọrí sí àwọn nǹkan tó máa ṣekú pani. Dókítà Harvey Katzeff sọ pé: “Kì í ṣe àrùn àtọ̀gbẹ fúnra rẹ̀ ló ń pa àwọn èèyàn, àwọn àìsàn tó máa ń tìdí rẹ̀ yọ ló ń pa wọ́n. A mọ bí a ṣe lè dènà àwọn àìsàn wọ̀nyí kí wọ́n má ṣẹlẹ̀, àmọ́ bí wọ́n bá ti ṣẹlẹ̀ pẹ́nrẹ́n, kì í rọrùn fún wa rárá láti wò [wọ́n] sàn.” a

Ǹjẹ́ ìrètí wà fún àwọn tó ní àrùn àtọ̀gbẹ? Bẹ́ẹ̀ ni, ìrètí wà—bí wọ́n bá mọ bí àrùn náà ti burú tó tí wọn ò sì fi ìtọ́jú rẹ̀ jáfara. b

Oúnjẹ Tó Dára àti Eré Ìmárale

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ṣeé ṣe láti dènà àrùn àtọ̀gbẹ Oríṣi Kìíní, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń wádìí láti mọ bí ohun téèyàn jogún ṣe ń fa àrùn yìí, wọ́n sì ń gbìyànjú láti ṣàwárí àwọn ọ̀nà tí àrùn náà kò fi ní máa ṣàkóbá fún agbára ìdènà àrùn ara. (Wo àpótí náà, “Iṣẹ́ Tí Èròjà Gúlúkóòsì Ń Ṣe Nínú Ara,” ní ojú ìwé 8.) Ìwé kan tó ń jẹ́ Diabetes—Caring for Your Emotions as Well as Your Health sọ pé: “Ní ti àrùn àtọ̀gbẹ Oríṣi Kejì, eléyìí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣòro láti tọ́jú. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n ti jogún àrùn yìí ni kì í hàn lára wọn rárá kìkì nítorí pé wọ́n ń jẹ àwọn oúnjẹ tó ń ṣara wọn lóore wọ́n sì ń ṣe eré ìmárale déédéé, nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ní ìlera tó jí pépé wọn ò sì sanra jù.” c

Nígbà tí ìwé ìròyìn ìṣègùn náà, Journal of the American Medical Association, ń tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì eré ìmárale, ó sọ̀rọ̀ nípa àbájáde ìwádìí gbígbòòrò kan tí wọ́n ṣe nípa àwọn obìnrin. Ìwádìí náà fi hàn pé “eré ìmárale téèyàn ṣe fún àkókò díẹ̀ máa ń jẹ́ kí ara túbọ̀ mú èròjà insulin púpọ̀ jáde, èyí sì ń jẹ́ kí [àwọn ohun tíntìntín inú ẹ̀jẹ̀ (sẹ́ẹ̀lì)] lè túbọ̀ ṣàmúlò gúlúkóòsì kí wọ́n sì tún fi pa mọ́ fún ohun tó lé ní wàkátí mẹ́rìnlélógún.” Nípa bẹ́ẹ̀, ìròyìn náà kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, “ìrìn rírìn àti ṣíṣe àwọn ohun tó ń béèrè pé kéèyàn lo okun ara lè dín ewu níní àrùn àtọ̀gbẹ Oríṣi Kejì kù jọjọ láàárín àwọn obìnrin.” Àwọn olùṣèwádìí náà dámọ̀ràn ṣíṣe eré ìmárale tí kò gba agbára fún ọgbọ̀n iṣẹ́jú lójoojúmọ́, tàbí ṣíṣe eré ìmárale lọ́jọ́ tó pọ̀ jù lọ nínú ọ̀sẹ̀. Èyí lè jẹ́ àwọn eré ìmárale tí kò gba agbára bí ìrìn rírìn. Ìwé náà, American Diabetes Association Complete Guide to Diabetes sọ pé ìrìn rírìn “ló fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ eré ìmárale tó dára jù lọ, tí kò léwu nínú rárá, tí kò sì náni ní nǹkan kan.”

Àmọ́ ṣá o, bí àwọn tó ní àrùn àtọ̀gbẹ yóò bá ṣe eré ìmárale, àwọn dókítà ní láti mójú tó wọn dáadáa. Ìdí ni pé, àrùn àtọ̀gbẹ lè ba ètò ìṣànkiri ẹ̀jẹ̀ àtàwọn iṣan ara jẹ́, èyí sì lè ṣèpalára fún bí ẹ̀jẹ̀ ṣe ń ṣàn nínú ara àti béèyàn ṣe ń mọ nǹkan lára sí. Nípa bẹ́ẹ̀, nǹkan lè rọra gé ẹni tó lárùn àtọ̀gbẹ lẹ́sẹ̀ kó má sì mọ̀, kí kòkòrò àrùn wọ ojú ọgbẹ́ náà, kó sì di egbò ńlá—èyí jẹ́ ìṣòro ńlá tó lè yọrí sí gígé ẹsẹ̀ náà bí onítọ̀hún kò bá tètè mójú tó o. d

Síbẹ̀, ṣíṣe eré ìmárale déédéé lè ṣèrànwọ́ láti kápá àrùn àtọ̀gbẹ. Ìwé ADA Complete Guide sọ pé: “Bí àwọn olùṣèwádìí ṣe túbọ̀ ń wádìí láti mọ àwọn àǹfààní tó wà nínú ṣíṣe eré ìmárale déédéé, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n túbọ̀ ń ṣàwárí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní ló wà nínú rẹ̀.”

Ìtọ́jú Nípasẹ̀ Gbígba Abẹ́rẹ́ Insulin

Láfikún sí jíjẹ oúnjẹ aṣaralóore àti ṣíṣe eré ìmárale déédéé, ọ̀pọ̀ àwọn tó ní àrùn àtọ̀gbẹ tún ní láti máa ṣàyẹ̀wò ìwọ̀n gúlúkóòsì inú ẹ̀jẹ̀ wọn lójoojúmọ́ kí wọ́n sì tún máa gba abẹ́rẹ́ insulin sára níye ìgbà lóòjọ́. Ó ti ṣeé ṣe fún àwọn kan tó ní àrùn àtọ̀gbẹ Oríṣi Kejì láti dáwọ́ lílo oògùn insulin dúró, ó kéré tán fúngbà díẹ̀. Èyí jẹ́ nítorí ìlera wọn tó gbé pẹ́ẹ́lí sí i látàrí jíjẹ àwọn oúnjẹ tó bá ipò wọn mu àti ṣíṣe eré ìmárale déédéé. e Karen, ẹni tó ní àrùn àtọ̀gbẹ Oríṣi Kìíní, ti rí i pé ṣíṣe eré ìmárale ń jẹ́ kí oògùn insulin tí òun ń gún sára túbọ̀ ṣiṣẹ́ dáadáa. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ti ṣeé ṣe fún un láti dín oògùn insulin tí ara rẹ̀ nílò lójúmọ́ kù sí ìdá ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún.

Àmọ́ bó bá di dandan fún ẹnì kan tó ní àrùn àtọ̀gbẹ láti máa gba abẹ́rẹ́ insulin láìdáwọ́dúró, kò sídìí tó fi yẹ kó bọkàn jẹ́. Mary Ann, nọ́ọ̀sì tó níwèé ẹ̀rí ìjọba, tó ń tọ́jú ọ̀pọ̀ àwọn tó ní àrùn àtọ̀gbẹ, sọ pé: “Bó bá di dandan kó o máa gba abẹ́rẹ́ insulin nìṣó, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ayé rẹ ti doríkodò. Irú àrùn àtọ̀gbẹ yòówù kó o ní, bó o bá ṣàkóso ìwọ̀n ṣúgà inú ẹ̀jẹ̀ rẹ dáadáa, wàá dín ewu níní àwọn àìsàn mìíràn tí àrùn àtọ̀gbẹ lè fà lọ́jọ́ iwájú kù.” Àní, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí fi hàn pé àwọn èèyàn tó ní àrùn àtọ̀gbẹ Oríṣi Kìíní àmọ́ tí wọ́n ń ṣàkóso ìwọ̀n ṣúgà inú ẹ̀jẹ̀ wọn dáadáa “kò fi bẹ́ẹ̀ ní ìṣoro ojú, ìṣòro kíndìnrín, àti ìṣòro iṣan ara tí àrùn àtọ̀gbẹ máa ń fà.” Bí àpẹẹrẹ, ìdá mẹ́rìndínlọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ni ewu níní àrùn tó lè mú kí ojú wọn fọ́ fi dín kù! Àwọn tó ní àrùn àtọ̀gbẹ Oríṣi Kejì tí wọ́n sì ń kápá ìwọ̀n ṣúgà inú ẹ̀jẹ̀ wọn dáadáa náà máa ń jẹ irú àǹfààní kan náà.

Láti mú kí gbígba oògùn insulin sára túbọ̀ rọrùn kó má sì fi bẹ́ẹ̀ nira, àwọn tó ní àrùn àtọ̀gbẹ sábà máa ń lo àwọn ike abẹ́rẹ́ tó rí bíi gègé ìkọ̀wé, èyí tó máa ń ní abẹ́rẹ́ tó tín-ínrín gan-an tí kì í fi bẹ́ẹ̀ dunni. Mary Ann sọ pé: “Èyí téèyàn bá kọ́kọ́ gún ló sábà máa ń dunni jù, lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn aláìsàn ló máa ń sọ pé àwọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ má mọ̀ pé àwọn gún nǹkan kan sára.” Irú àwọn abẹ́rẹ́ mìíràn tí wọ́n tún máa ń lò ni èyí tó máa ń fúnra rẹ̀ gun ara rẹ̀ sínú awọ ara tí kò sì ní í dunni rárá. Òmíràn tún ni abẹ́rẹ́ tó máa ń gún oògùn insulin sínú ara ní wàrà-ǹ-ṣe-ṣà, àti èyí tí wọ́n ń pè ní infuser, tó máa ń ní rọ́bà kan tó lè wà nínú ara fún ọjọ́ méjì tàbí mẹ́ta tí yóò sì máa tú oògùn insulin sínú ara díẹ̀díẹ̀. Ọ̀kan tún wà tó ń jẹ́ insulin pump, tó fi díẹ̀ ju kòròfo ìṣáná lọ, èyí tó ti wọ́pọ̀ gan-an lẹ́nu ọdún àìpẹ́ yìí. Ẹ̀rọ kóńkóló tí èèyàn lè ṣètò ọ̀nà tí yóò máa gbà ṣiṣẹ́ yìí máa ń rọra tú èròjà insulin sínú ara ní ìwọ̀n díẹ̀díẹ̀ nípasẹ̀ rọ́bà kan, níbàámu pẹ̀lú ohun tí ara nílò lójúmọ́, láìsí pé ó pọ̀ jù tàbí kéré jù, bẹ́ẹ̀ ló sì tún rọrùn láti lò.

Máa Bá A Nìṣó Láti Mọ̀ Sí I Nípa Àrùn Yìí

Ju gbogbo rẹ̀ lọ, kò sí oògùn ajẹ́bíidán kankan fún àrùn àtọ̀gbẹ. Bó bá di ọ̀ràn irú ìtọ́jú tẹ́nì kan máa yàn, kálukú gbọ́dọ̀ gbé àwọn kókó kan yẹ̀ wò láti lè ṣe ìpinnu. Mary Ann sọ pé: “Bó o bá tiẹ̀ wà lábẹ́ àbójútó àwọn dókítà, ọwọ́ rẹ gan-an ṣì ni ìpinnu wà nípa ọ̀nà tó o fẹ́ kí wọ́n gbé ìtọ́jú rẹ gbà.” Kódà, ohun tí ìwé àtìgbàdégbà náà, Diabetes Care sọ ni pé: “Gbígba ìtọ́jú lọ́dọ̀ dókítà láìsí pé ìwọ fúnra rẹ ń bá a nìṣó láti ní òye bó o ṣe lè bójú tó àrùn yìí la lè pè ní ìtọ́jú tí kò kúnjú ìwọ̀n tí kò sì bá ìlànà mu.”

Bí àwọn tó ní àrùn àtọ̀gbẹ bá ṣe túbọ̀ ń mọ̀ sí i nípa àìsàn wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n á ṣe lè túbọ̀ mójú tó ìlera wọn sí i tí wọ́n á sì lè mú kí ẹ̀mí wọn túbọ̀ gùn kí ìlera wọn sì túbọ̀ jí pépé. Àmọ́ ṣá o, láti lè ní ìmọ̀ nípa ohun kan tó máa ṣeni láǹfààní, ó gba sùúrù. Ìwé náà, Diabetes—Caring for Your Emotions as Well as Your Health ṣàlàyé pé: “Bó o bá gbìyànjú láti mọ gbogbo ohun tó so mọ́ àrùn náà lẹ́ẹ̀kan, ó ṣeé ṣe kó o máà rí ojútùú rẹ̀ kó o má sì lè lo àwọn ìsọfúnni tó o rí náà lọ́nà tó máa ṣe ọ́ láǹfààní. Yàtọ̀ síyẹn, o ò lè rí ọ̀pọ̀ ìsọfúnni tó wúlò púpọ̀ tí wàá nílò nínú àwọn ìwé ńlá tàbí ìwé pélébé. Ohun tó o ní láti mọ̀ dáadáa ni . . . bí ìwọ̀n ṣúgà inú ẹ̀jẹ̀ rẹ ṣe ń lọ sókè tàbí lọ sódò níbàámu pẹ̀lú onírúurú ìgbòkègbodò tó ò ń ṣe. Yóò gba àkókò kó o tó lè lóye èyí, ó sì jẹ́ nípa dídán oríṣiríṣi ìsọfúnni tó ò ń rí wò.”

Bí àpẹẹrẹ, nípa fífara balẹ̀ ṣàkíyèsí ara rẹ dáadaa, wàá mọ bí ara rẹ ṣe máa ń rí nígbà tó o bá ní ìdààmú, èyí tó lè mú kí ìwọ̀n ṣúgà inú ẹ̀jẹ̀ rẹ ṣàdéédé lọ sókè. Ken sọ pé: “Ó ti pé àádọ́ta ọdún tí mo ti ń bá àrùn àtọ̀gbẹ yí mo sì máa ń mọ àwọn ohun tó máa ń sọ fún mi!” “Títẹ́tí” sí ara rẹ̀ ti ṣe Ken láǹfààní gan-an, nítorí pé ó ṣì lè ṣiṣẹ́ bí ẹni tí ara rẹ̀ le bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé lẹ́ni àádọ́rin ọdún!

Ìtìlẹyìn Ìdílé Ṣe Pàtàkì

Ohun tí a ò tún ní gbójú fò dá nínú ìtọ́jú àrùn àtọ̀gbẹ ni ìtìlẹ́yìn àwọn tó wà nínú ìdílé. Kódà, ìwé kan sọ pé “bí ìdílé kan bá ṣe wà tímọ́tímọ́ sí ló dà bíi pé ó jẹ́ ohun tó ṣe kókó jù lọ” nínú bíbójútó àrùn àtọ̀gbẹ àwọn ọmọdé àtàwọn tí kò tíì dàgbà púpọ̀.

Ó máa ń ṣàǹfààní tí àwọn tó wà nínú ìdílé bá mọ̀ nípa àrùn àtọ̀gbẹ, àní tí wọ́n tiẹ̀ ń wáyè lẹ́nì kọ̀ọ̀kan láti máa bá aláìsàn náà lọ sọ́dọ̀ dókítà. Lílóye àrùn náà yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣètìlẹ́yìn, kí wọ́n mọ àwọn àmì pàtàkì, kí wọ́n sì mọ ìgbésẹ̀ tí wọ́n ní láti gbé. Ted, ẹni tí ìyàwó rẹ̀ ti ní àrùn àtọ̀gbẹ látọmọ ọdún mẹ́rin sọ pé: “Mo lè sọ ìgbà tí ìwọ̀n ṣúgà inú ẹ̀jẹ̀ Barbara bá lọ sílẹ̀ gan-an. A lè jọ máa sọ̀rọ̀ lọ báyìí, àmọ́ ẹ̀ẹ̀kan náà ló máa dákẹ. Á máa làágùn kíkankíkan yóò sì máa bínú láìnídìí. Ara rẹ̀ kò sì ní gbé kánkán bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́.”

Bákan náà ló jẹ́ pé, nígbà tí Catherine, ìyàwó Ken, bá rí i tí ọkọ rẹ̀ kò túra ká mọ́, tó dì kuku, tó sì tún rí i tí ìṣesí rẹ̀ yí padà, yóò ju ìbéèrè kan sí i. Bí ìdáhùn Ken bá fi hàn pé ọ̀rọ̀ ti dojú rú, ìyẹn á jẹ́ kí Catherine mọ̀ pé àkókò ti tó láti ṣe ìpinnu èyíkéyìí láìṣẹ̀ṣẹ̀ dúró dé ọkọ rẹ̀, kó sì tètè wá ojútùú sí ìṣòro náà. Ken àti Barbara mọrírì rẹ̀ gan-an pé àwọ́n ní àwọn alábàáṣègbéyàwó tó lóye ipò àwọn dáadáa, tí àwọ́n nífẹ̀ẹ́ tí àwọ́n sì fọkàn tán gan-an. f

Àwọn tó jẹ́ ara ìdílé aláìsàn náà, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an ní láti sapá láti máa ṣètìlẹ́yìn, kí wọ́n jẹ́ aláàánú, kí wọ́n sì máa ní sùúrù. Àwọn ànímọ́ wọ̀nyí ló lè ran àwọn aláìsàn náà lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro tó dojú kọ wọ́n nígbèésí ayé àní, ó tiẹ̀ tún lè mú kí ìlera wọn gbé pẹ́ẹ́lí sí i pàápàá. Gbogbo ìgbà ni ọkọ Karen máa ń sọ fún un pé òun wà fún un lọ́jọ́kọ́jọ́, ìtura ńlá gbáà ni èyí sì máa ń mú bá Karen. Karen sọ pé: “Nigel máa ń sọ fún mi pé, ‘Dandan ni kí àwọn èèyàn jẹun kí wọ́n sì mu omi láti wà láàyè, bó ṣe jẹ́ pé ìwọ náà gbọ́dọ̀ jẹun kó o sì mu omi—kó o sì tún gba abẹ́rẹ́ insulin díẹ̀.’ Àwọn ọ̀rọ̀ onífẹ̀ẹ́ rẹ̀, síbẹ̀ tó ń jẹ́ kí n mọ ohun tí mo gbọ́dọ̀ ṣe, jẹ́ ohun tí mo nílò gẹ́lẹ́.”

Ó tún ṣe pàtàkì kí àwọn tó jẹ́ ara ìdílé aláìsàn náà àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mọ̀ pé bí ìwọ̀n ṣúgà inú ẹ̀jẹ̀ bá ṣe ń lọ sókè lọ sódò ni èyí máa ń nípa lórí ìmọ̀lára onítọ̀hún. Obìnrin kan sọ pé: “Nígbà tí mo bá bẹ̀rẹ̀ sí í ní ẹ̀dùn ọkàn nítorí ìwọ̀n ṣúgà inú ẹ̀jẹ̀ mi tí kò dúró sójú kan, ńṣe ni màá dákẹ́ rigidi, mi ò ní dá sí ẹnikẹ́ni mọ́, nǹkan kì í sìí pẹ́ bí mi nínú tí gbogbo rẹ̀ á sì sú mi. Lẹ́yìn èyí, ojú á wá bẹ̀rẹ̀ sí tì mí fún bí mo ṣe ń ṣe bí ọmọdé. Àmọ́ nígbà tí mo bá rántí pé àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ mọ ohun tó fà á, èyí máa ń ṣèrànwọ́, mo sì máa ń gbìyànjú láti ṣàkóso rẹ̀.”

Ó ṣeé ṣe láti kápá àrùn àtọ̀gbẹ dáadáa, pàápàá bí ẹni tí àrùn náà ń ṣe bá rí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn tó jẹ́ ara ìdílé rẹ̀. Àwọn ìlànà Bíbélì tún lè ṣèrànwọ́ pẹ̀lú. Lọ́nà wo?

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Lára àwọn àìsàn tí àrùn àtọ̀gbẹ máa ń fà ni àrùn ọkàn, àrùn ẹ̀gbà, kí kíndìnrín má ṣiṣẹ́ dáadáa, kí ẹ̀jẹ̀ má fi bẹ́ẹ̀ ṣàn lọ sí apá tàbí ẹsẹ̀, àti kí àwọn iṣan ara bà jẹ́. Bí ẹ̀jẹ̀ kò bá ṣàn dáadáa dé ẹsẹ̀, èyí lè fa egbò, bí ìṣòro náà bá sì lágbára, gígé ni wọ́n máa gé ẹsẹ̀ náà. Àrùn àtọgbẹ yìí kan náà ló tún sábà máa ń fọ́ àwọn àgbàlagbà lójú.

b Jí! kò sọ pé irú ìtọ́jú báyìí ló dára láti gbà o. Kí àwọn tó bá fura pé àwọ́n ní àrùn àtọ̀gbẹ lọ rí dókítà tó mọ̀ nípa dídènà rẹ̀ àti títọ́jú rẹ̀.

c Ó dà bíi pé sísanra sí ikùn léwu ju sísanra sí ìdí lọ.

d Inú ewu ńlá làwọn tó ní àrùn àtọ̀gbẹ tó sì tún ń mu sìgá fi ara wọn sí, nítorí pé sìgá mímu máa ń ba ọkàn àti ètò ìṣànkiri ẹ̀jẹ̀ jẹ́ nínú ara, ó sì tún máa ń sọ àwọn òpójẹ̀ di tín-ínrín. Ìwé kan sọ pé, ìdá márùndínlọ́gọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n ń gé ẹsẹ̀ wọn nítorí àrùn àtọ̀gbẹ ló jẹ́ àwọn amusìgá.

e Àwọn oògùn tí wọ́n ń gba ẹnu lò ti ran díẹ̀ lára àwọn èèyàn wọ̀nyí lọ́wọ́. Lára àwọn oògùn náà ni àwọn tó ń jẹ́ kí ẹ̀ya ara tó ń jẹ́ pancreas túbọ̀ mú èròjà insulin jáde, àwọn mìíràn tí kì í jẹ́ kí èròjà ṣúgà pọ̀ jù nínú ẹ̀jẹ̀, àtàwọn tó ń jẹ́ kí ohun tíntìntín inú ẹ̀jẹ̀ túbọ̀ gba èròjà insulin dáadáa. (Wọn kì í sábà fún àwọn tó ní àrùn àtọgbẹ Oríṣi Kìíní ni oògùn tí wọ́n máa gba ẹnu lò.) Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, oògùn insulin kò ṣeé gba ẹnu lò, nítorí pé dídà oúnjẹ kì í jẹ́ kó lágbára mọ́ nígbà tó bá fi máa dé inú ìṣàn ẹ̀jẹ̀. Àti oògùn insulin tí wọ́n ń fà sára o àtàwọn oògùn tí wọ́n ń gba ẹnu lò o, kò sí ọ̀kankan tó ní kí àwọn tó ní àrùn àtọ̀gbẹ dáwọ́ ṣíṣe eré ìmárale àti jíjẹ oúnjẹ tó ń ṣara lóore dúró.

f Àwọn lọ́gàálọ́gàá nídìí iṣẹ́ ìṣègùn dá a lámọ̀ràn pé kí àwọn èèyàn tó bá ní àìsàn àtọ̀gbẹ máa mú káàdì tó ń fi hàn pé wọ́n ní àrùn náà rìn nígbà gbogbo, kí wọ́n sì máa wọ ohun ọ̀ṣọ́ tó ń fi hàn pé àìsàn náà wà lára wọn. Bí ìṣòro pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀, àwọn nǹkan ìdánimọ̀ wọ̀nyí lè dá ẹ̀mí wọn sí. Bí àpẹẹrẹ, bí ìwọ̀n ṣúgà inú ẹ̀jẹ̀ wọn bá lọ sílẹ̀ tí èyí sì mú kí ìṣesí wọn yí padà, àwọn èèyàn lè fi àṣìṣe rò pé àìsàn mìíràn ló ń ṣe wọ́n tàbí kí wọ́n tiẹ̀ rò pé ńṣe ni wọ́n mutí yó.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ǹjẹ́ Àrùn Àtọ̀gbẹ Máa Ń Ṣe Àwọn Ọmọdé Náà?

Dókítà Arthur Rubenstein, ògbóǹkangí nínú ìmọ̀ nípa ẹṣẹ́ tí ń tú àwọn èròjà inú ara sínú ẹ̀jẹ̀, tó sì tún jẹ́ olùkọ́ àgbà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ìṣègùn Mount Sinai ní ìlú New York sọ pé, àrùn àtọ̀gbẹ “ti ń di àrùn àwọn èwe báyìí o.” Ńṣe ni ó túbọ̀ ń ṣe àwọn tí ọjọ́ orí túbọ̀ kéré. Nígbà tí Dókítà Robin S. Goland, ògbóǹkangí onímọ̀ nípa àrùn àtọ̀gbẹ ń sọ̀rọ̀ nípa àrùn àtọ̀gbẹ Oríṣi Kejì, ó sọ pé: “Lọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn, ohun tá a fi ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn ni pé àrùn yìí kì í ṣe àwọn èèyàn tí kò tíì pé ọmọ ogójì ọdún. Àmọ́ báyìí, a ti ń rí i tí àwọn ọmọ tí kò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́wàá ń ní in.”

Kí ló mú kí àrùn àtọ̀gbẹ túbọ̀ wọ́pọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́? Nígbà míì, wọ́n máa ń jogún rẹ̀. Àmọ́ sísanra jù àti àyíká tí wọ́n ń gbé tún máa ń fà á. Iye àwọn ọmọdé tí wọ́n sanra jọ̀kọ̀tọ̀ ti di ìlọ́po méjì láàárín ogún ọdún sígbà tá a wà yìí. Kí ló fa èyí? Dókítà William Dietz, tó ń ṣiṣẹ́ ní Ibùdó Tó Ń Ṣèkáwọ́ Àrùn Tó sì Ń Dènà Rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Láti ogún ọdún sẹ́yìn ni ọ̀pọ̀ ìyípadà ti dé bá ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà jẹun àtàwọn ìgbòkègbodò wọn. Lára àwọn ìyípadà yìí ni pé, ọ̀pọ̀ èèyàn ló túbọ̀ ń jẹun nílé àrójẹ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ; àwọn èèyàn kì í sábà jẹ oúnjẹ àárọ̀ mọ́; mímu àwọn ọtí ẹlẹ́rìndòdò àti jíjẹ àwọn oúnjẹ àyáragbọ́ ti wọ́pọ̀ sí i; àwọn ọmọdé kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣe [eré ìdárayá] mọ́ ní iléèwé; wọ́n sì ti yọ àkókò ìsinmi ráńpẹ́ lẹ́nu ìkẹ́kọ̀ọ́ kúrò nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́.”

Àrùn àtọ̀gbẹ kì í lọ pátápátá téèyàn bá ti ní in. Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọ̀dọ́langba kan tóun náà ní àrùn yìí. Ohun tó sọ kò ju pé: “Yẹra fún àwọn pàrùpárù oúnjẹ, sì máa rí i pé ìlera rẹ wà ní ipò tó dára.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwés 8, 9]

Iṣẹ́ Tí Gúlúkóòsì Ń Ṣe Nínú Ara

Gúlúkóòsì ni orísun agbára ẹgbàágbèje ohun tíntìntín inú ẹ̀jẹ̀ (sẹ́ẹ̀lì). Àmọ́ kó tó lè dé inú àwọn ohun tíntìntín inú ẹ̀jẹ̀ náà, ó nílò “kọ́kọ́rọ́” kan, ìyẹn ni èròjà insulin, kẹ́míkà kan tí ẹṣẹ́ tó ń jẹ́ pancreas máa ń mú jáde. Ní ti àwọn tó ní àrùn àtọ̀gbẹ Oríṣi Kìíní, ara wọn kì í mú èròjà insulin jáde rárá. Ní ti àwọn tó ní àrùn àtọ̀gbẹ Oríṣi Kejì, ìyẹn èyí tó máa ń ṣe àwọn àgbàlagbà, ara wọn máa ń mú èròjà insulin jáde àmọ́ kì í pọ̀ tó. g Síwájú sí i, àwọn ohun tíntìntín inú ẹ̀jẹ̀ wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ gba èròjà insulin—ìyẹn ni pé èròjà insulin kì í dénú àwọn ohun tíntìntín náà. Ohun kan náà ló máa ń jẹ́ àbájáde oríṣi àrùn àtọ̀gbẹ méjèèjì yìí: ìyẹn ni pé àwọn ohun tíntìntín inú ẹ̀jẹ̀ kò ní rí gúlúkóòsì tí wọ́n nílò, lẹ́sẹ̀ kan náà, èròjà yìí á ti pọ̀ jù nínú ẹ̀jẹ̀.

Ní ti àrùn àtọ̀gbẹ Oríṣi Kìíní, èyí tó ń yọjú lọ́mọdé, ńṣe ni agbára ìdènà àrùn ara ẹni náà á máa gbógun ti àwọn ohun tíntìntín kan nínú ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n ń pè ní beta cells, tó máa ń mú èròjà insulin jáde nínú ẹṣẹ́ pancreas. Nípa bẹ́ẹ̀, àrùn àtọ̀gbẹ Oríṣi Kìíní jẹ́ èyí tó máa ń gbógun ti agbára ìdènà àrùn ara. Nígbà mìíràn, wọ́n máa ń pè é ní àrùn àtọ̀gbẹ tí agbára ìdènà àrùn máa ń gbà láàyè. Lára àwọn nǹkan tó lè mú kí agbára ìdènà àrùn ara máa ṣiṣẹ́ gbòdì ni àkóràn, àwọn kẹ́míkà onímájèlé àti oríṣi àwọn oògùn kan. Ohun tí ẹnì kan jogún tún lè wà lára rẹ̀, nítorí pé àrùn àtọ̀gbẹ Oríṣi Kìíní wọ́pọ̀ gan-an nínú àwọn ìdílé kan, àárín àwọn aláwọ̀ funfun lèyí sì wọ́pọ̀ sí jù lọ.

Ní ti àrùn àtọ̀gbẹ Oríṣi Kejì, wọ́n sábà máa ń jogún rẹ̀, àmọ́ àárín àwọn tí àwọ̀ wọn kò fi bẹ́ẹ̀ funfun tán lèyí wọ́pọ̀ sí jù. Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Ọsirélíà àtàwọn Àmẹ́ríńdíà wà lára àwọn tó máa ń ní in jù lọ. Àwọn ẹ̀yà Àmẹ́ríńdíà yìí ló sì máa ń ní àrùn àtọ̀gbẹ Oríṣi Kejì jù lọ lágbàáyé. Àwọn olùṣèwádìí ti ń wádìí láti mọ bí apilẹ̀ àbùdá ẹnì kan ṣe tan mọ́ sísanra jọ̀kọ̀tọ̀, àti bó ṣe dà bíi pé àpọ̀jù ọ̀rá máa ń mú kí ara àwọn kan kọ èròjà insulin nítorí apilẹ̀ àbùdá wọn. h Àrùn àtọ̀gbẹ Oríṣi Kejì yàtọ̀ sí Oríṣi Kìíní, nítorí pé àwọn tó bá ti lé lọ́mọ ogójì ọdún ló sábà máa ń ní in.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

g Nǹkan bí ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó ní àrùn àtọ̀gbẹ ló jẹ́ pé Oríṣi Kejì ni wọ́n ní. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn èèyàn mọ oríṣi àrùn àtọgbẹ yìí sí “àtọ̀gbẹ tí àwọn tó ní in kò nílò èròjà insulin” tàbí “àtọ̀gbẹ tó ń yọjú nígbà téèyàn bá di àgbàlagbà.” Àmọ́ àwọn gbólóhùn yìí kò gbé ìtumọ̀ rẹ̀ dáadáa, nítorí pé ohun tó tó ìdá ogójì nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó ní àrùn àtọ̀gbẹ Oríṣi Kejì yìí ló nílò èròjà insulin. Síwájú sí i, àwọn ọ̀dọ́ tí iye wọn túbọ̀ ń pọ̀ sí i, tí àwọn mìíràn lára wọn kò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá rárá, ni àyẹ̀wò ń fi hàn pé wọ́n ti ní àrùn àtọ̀gbẹ Oríṣi Kejì.

h Ní gbogbo gbòò, wọ́n sábà máa ń sọ pé ẹnì kan sanra jù bí ẹni náà bá fi ìdá ogún nínú ọgọ́rùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ wọ̀n kọjá ohun tó yẹ kí ara rẹ̀ wọ̀n.

[Àwòrán]

Èròjà gúlúkóòsì

[Credit Line]

Nípasẹ̀ Ìyọ̀ǹda: Pacific Northwest National Laboratory

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]

Iṣẹ́ Tí Ẹṣẹ́ Pancreas Ń Ṣe Nínú Ara

Ẹṣẹ́ pancreas kò tóbi ju ẹyọ ọ̀gẹ̀dẹ̀ kan lọ, inú ikùn ló sì máa ń wà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé The Unofficial Guide to Living With Diabetes ti sọ, “ẹṣẹ́ pancreas tí kò bá níṣòro máa ń ṣiṣẹ́ lọ geerege láìdáwọ́dúró láti rí i pé ara ní ìwọ̀n ṣúgà tó yẹ. Ó máa ń ṣe èyí nípa títú kìkì ìwọ̀n èròjà insulin tí ara nílò sínú ẹ̀jẹ̀, bí ìwọ̀n gúlúkóòsì inú ara ti ń lọ sókè tàbí lọ sílẹ̀ látàárọ̀ ṣúlẹ̀.” Àwọn ohun tíntìntín inú ẹ̀jẹ̀ tá à ń pè ní beta cells tó wà nínú ẹṣẹ́ pancreas ló máa ń mú èròjà insulin jáde.

Nígbà tí àwọn beta cells yìí kò bá mú èròjà insulin tó tó jáde mọ́, gúlúkóòsì á bẹ̀rẹ̀ sí gbára jọ nínú ẹ̀jẹ̀. Òdìkejì èyí ni kí èròjà gúlúkóòsì ṣaláìtó nínú ẹ̀jẹ̀. Ńṣe ni ẹ̀dọ̀ àti ẹṣẹ́ pancreas jọ máa ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀. Ẹ̀dọ̀ máa ń ṣèrànwọ́ láti bójú tó ìwọ̀n ṣúgà tó wà nínú ẹ̀jẹ̀ nípa fífi àpọ̀jù gúlúkóòsì pa mọ́. Nígbà tí ẹṣẹ́ pancreas bá sì gbún ẹ̀dọ̀ ní kẹ́ṣẹ́, ẹ̀dọ̀ á yí gúlúkóòsì tó ti fi pa mọ́ padà fún ìlò ara.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Iṣẹ́ Tí Ṣúgà Ń Ṣe Nínú Ara

Ọ̀rọ̀ kan tí kì í ṣòótọ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń sọ ni pé àjẹjù ṣúgà ló máa ń fa àrùn àtọ̀gbẹ. Àmọ́, àwọn oníṣègùn ti fi ẹ̀rí hàn pé, láìka bí ṣúgà tẹ́nì kan ń jẹ ṣe pọ̀ tó, sísanra lohun tó máa ń dá kún níní àrùn àtọ̀gbẹ láàárín àwọn èèyàn tó bá wà nínú àbùdá wọn. Síbẹ̀, jíjẹ ṣúgà lájẹjù kò dára fún ìlera, níwọ̀n bí kì í ti í fi bẹ́ẹ̀ ṣe ara lóore, ó sì tún lè mú kéèyàn sanra.

Ohun mìíràn tí kì í tún ṣe òótọ́ ni pé, àwọn tó ní àrùn àtọ̀gbẹ máa ń fẹ́ láti jẹ ṣúgà gan-an. Àmọ́, ká sòótọ́, kò sí ìyàtọ̀ nínú bí àwọn àti ọ̀pọ̀ èèyàn mìíràn ṣe máa ń nífẹ̀ẹ́ sí nǹkan tó dùn. Téèyàn ò bá ṣàkóso àrùn náà, ó lè jẹ́ kí ebi máa pa onítọ̀hún àmọ́ kò túmọ̀ sí pé ṣúgà ni yóò máa wu ẹni náà láti jẹ. Àwọn tó ní àrùn àtọ̀gbẹ lè jẹ nǹkan tó dùn, àmọ́ wọ́n gbọ́dọ̀ máa fi èyí sọ́kàn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ jẹ àwọn oúnjẹ mìíràn, kí ìwọ̀n ṣúgà inú ẹ̀jẹ̀ wọn máà bàa pọ̀ jù.

Àwọn ìwádìí tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí fi hàn pé jíjẹ àwọn oúnjẹ tí èròjà fructose pọ̀ nínú wọn, ìyẹn ṣúgà tó ń wá látinú èso àti ẹ̀fọ́, lè ṣèdíwọ́ fún bí ara ṣe ń mú èròjà insulin jáde, kódà ó lè mú kí àwọn ẹranko ní àrùn àtọ̀gbẹ pàápàá, láìka bí wọ́n ṣe sanra tó sí.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Ọ̀nà Tó Rọrùn Láti Ṣàlàyé Àrùn Àtọ̀gbẹ

ẸṢẸ́ PANCREAS

↓ ↓ ↓

Ẹni Tí Ara Rẹ̀ Le Ẹni Tó Ní Àrùn Ẹni Tó Ní Àrùn

Àtọ̀gbẹ Oríṣi Kìíní Àtọ̀gbẹ Oríṣi Kejì

Lẹ́yìn téèyàn bá Agbára ìdènà àrùn ara Lọ́pọ̀ ìgbà jù lọ,

jẹun tán, ẹṣẹ́ onítọ̀hún máa ń gbógun èròjà insulin tí ẹṣẹ́

pancreas á bẹ̀rẹ̀ sí ti àwọn ohun tíntìntín pancreas yóò máa mú

ṣiṣẹ́ lórí èròjà inú ẹ̀jẹ̀ tó ń jẹ́ beta jáde lára onítọ̀hún

gúlúkóòsì tó ti cells tó ń mú èròjà kò ní tó nǹkan

pọ̀ sí i nínú ẹ̀jẹ̀, insulin jáde nínú ẹṣẹ́

nípa mímú ìwọ̀n pancreas. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹṣẹ́

èròjà insulin pancreas kò ní mú èròjà

tó yẹ jáde insulin jáde

↓ ↓ ↓

Èròjà insulin á lẹ̀ Láìsí ìrànlọ́wọ́ insulin, Bí àwọn ohun tó ń

mọ́ ojú àwọn ohun gúlúkóòsì kò lè dénú jẹ́ kí èròjà insulin

tíntìntín inú ẹ̀jẹ̀ àwọn ohun tíntìntín ráyè wọnú àwọn ohun

(sẹ́ẹ̀lì). Èyí ni yóò inú ẹ̀jẹ̀ tíntìntín inú ẹ̀jẹ̀ kò

wá mú kó ṣeé ṣe fún bá ṣiṣẹ́ dáadáa, kò ní

gúlúkóòsì láti ráyè ṣeé ṣe fún àwọn ohun

wọnú àwọn ohun tíntìntín náà láti

tíntìntín náà gba gúlúkóòsì sínú

látinú ẹ̀jẹ̀

↓ ↓ ↓

Àwọn ohun tíntìntín Gúlúkóòsì á bẹ̀rẹ̀ sí gbára jọ

inú ẹ̀jẹ̀ yóò gba gúlúkóòsì nínú ìṣàn ẹ̀jẹ̀, èyí yóò sì dabarú

sínú, wọn yóò sì ṣàmúlò rẹ̀. àwọn ètò pàtàkì nínú ara,

Nípa bẹ́ẹ̀, gúlúkóòsì inú yóò sì tún ba àwọn òpójẹ̀ jẹ́

ìṣàn ẹ̀jẹ̀ á padà sí ìwọ̀n tó yẹ

[Àwòrán]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Sẹ́ẹ̀lì

Ohun tó ń mú kí insulin lè wọnú sẹ́ẹ̀lì

Ibi tí insulin ń gbà wọnú sẹ́ẹ̀lì

Insulin

Àárín sẹ́ẹ̀lì

Gúlúkóòsì

[Àwòrán]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÌṢÀN Ẹ̀JẸ̀

Sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa

Gúlúkóòsì

[Credit Line]

Àwòrán Ọkùnrin: The Complete Encyclopedia of Illustration/J. G. Heck

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Jíjẹ oúnjẹ tó dára ṣe pàtàkì fún àwọn tó ní àrùn àtọ̀gbẹ

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwọn tó ní àrùn àtọ̀gbẹ lè ṣe àwọn ìgbòkègbodò táwọn ẹlòmíràn ń ṣe