Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ọmọ Tí Kò Gbádùn Ìgbà Èwe Wọn

Àwọn Ọmọ Tí Kò Gbádùn Ìgbà Èwe Wọn

Àwọn Ọmọ Tí Kò Gbádùn Ìgbà Èwe Wọn

“Gbígbádùn ìgbà èwe ni olórí ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdé.”—“The Hurried Child.”

LÁÌSÍ àní-àní, wàá gbà pé ó yẹ kí gbogbo ọmọdé gbádùn ìgbà èwe wọn, láìsí àníyàn tí yóò máa kó wọn lọ́kàn sókè. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ ọmọdé, lọ́kùnrin àti lóbìnrin ni ìgbà ọmọdé wọn kò lárinrin. Ìwọ ronú nípa ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọdé, bóyá ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù pàápàá, tí gbogbo ìrètí wọn ọjọ́ iwájú kò dájú mọ́ nítorí pé ogun ń jà lórílẹ̀-èdè wọn. Tún fojú inú wo gbogbo àwọn ọmọdé tí àwọn ẹni ibi kan ti bà láyé jẹ́ nípa lílò wọ́n bí ẹrú tàbí fífi ìyà jẹ wọ́n.

Ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ lára wa láti ronú nípa bó ṣe máa ń rí lára ọmọdé kan tó bá di dandan fún un láti lọ máa gbé níta torí pé ó gbà pé ibẹ̀ láàbò ju inú ilé lọ. Ní àkókò ẹlẹgẹ́ yìí, tó yẹ kí àwọn òbí máa fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ọmọ kí wọ́n sì máa dáàbò bò wọ́n, ni àwọn ọmọ ọ̀hún wá ń di ọmọ asùnta, tí wọ́n sì ní láti mọ bí wọ́n á ṣe máa dáàbò bò ara wọn lọ́wọ́ àwọn òǹrorò èèyàn tó fẹ́ fi wọ́n ṣèfà jẹ. Tá a bá wò ó síbí wò ó sọ́hùn-ún, a óò rí i pé àkókò oníyánpọnyánrin tí à ń gbé yìí ti ṣàkóbá fún ìgbà ọmọdé.

“Ká Ní Mo Lè Padà Sígbà Ọmọdé Mi Ni”

Carmen tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlélógún kò gbádùn ìgbà ọmọdé rẹ̀ rárá. a Àwọn òbí wọn ló fipá mú òun àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin láti di ọmọ asùnta nítorí pé ńṣe ni bàbá wọn máa ń lù wọ́n, ìyá wọn kò sì bìkítà fún wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbígbé ìgbésí ayé ọmọ asùnta léwu, ó ṣeé ṣe fún àwọn ọmọbìnrin méjèèjì náà láti yẹra fún àwọn ìṣòro tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó ń sá fi ilé sílẹ̀ máa ń kó sí.

Síbẹ̀, Carmen ṣì máa ń kábàámọ̀ fún bí kò ṣe gbádùn ìgbà ọmọdé rẹ̀, torí pé kò tiẹ̀ lè rántí pé òun ṣe ọmọdé rí. Ó kédàárò pé: “Àtìgbà tí mo ti wà ní kékeré títí mo fi di ọmọ ọdún méjìlélógún ni mo ti ń fàyà rán ìṣòro tí àwọn àgbàlagbà ń ní. Nísinsìnyí, mo ti wà nílé ọkọ mo sì ti bímọ kan, àmọ́ ó ṣì máa ń wù mí láti ṣe àwọn ohun táwọn ọmọbìnrin kéékèèké máa ń ṣe, irú bíi fífi bèbí ṣeré. Mo fẹ́ kí àwọn òbí mi nífẹ̀ẹ́ mi kí wọ́n sì máa gbé mi mọ́ra. Ká ní mo lè padà sígbà ọmọdé mi ni.”

Àìlóǹkà àwọn ọmọdé ló ń jìyà bíi ti Carmen àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Wọ́n ti di ọmọ asùnta, nípa bẹ́ẹ̀ kò ṣeé ṣe fún wọn láti gbádùn ìgbà èwe wọn. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ wọ̀nyí ló máa ń hùwà ọ̀daràn láti lè rówó fi gbọ́ bùkátà ara wọn. Àwọn ìròyìn àti ìwádìí lóríṣiríṣi fi hàn pé àwọn ọmọ tí ọjọ́ orí wọn ò tó nǹkan ti ń hùwà ipá báyìí. Ohun mìíràn tó tún mú kí ìṣòro náà peléke sí i ni pé, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdébìnrin ló ń di ìyá ọmọ nígbà tí wọn kò tíì pé ọmọ ogún ọdún—ní àkókò tó jẹ́ pé àwọn fúnra wọn ṣì jẹ́ ọmọdé tó yẹ kí òbí ṣì máa bójú tó.

Ìṣòro Táwọn Èèyàn Ò Kíyè sí Láwùjọ

Kò yani lẹ́nu pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọdé ló jẹ́ pé ilé alágbàtọ́ ni wọ́n máa ń bá ara wọn nígbẹ̀yìn. Ọ̀rọ̀ olóòtú tó jáde nínú ìwé ìròyìn Weekend Australian sọ pé: “Àṣà fífi ọmọ sọ́dọ̀ alágbàtọ́ ti ń gbèrú, àmọ́ a ò kíyè sí i. A ò fi bẹ́ẹ̀ mójú tó ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí ìdílé wọn ti dà rú.” Ìwé ìròyìn náà tún fi kún un pé: “Àwọn ọmọ kan tí wọ́n wà lọ́dọ̀ alágbàtọ́ lè wà níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀ oṣù, tàbí fún ọ̀pọ̀ ọdún pàápàá, kí àwọn òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re tí wọ́n yàn láti bójú tó wọn má sì bẹ̀ wọ́n wò rárá, nígbà tó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n máa ń mú àwọn ọmọ mìíràn látọ̀dọ̀ alágbàtọ́ kan lọ sọ́dọ̀ alágbàtọ́ mìíràn, tí wọn kò sì ní rí ibùgbé gidi kan.”

Nínú ìròyìn kan, a gbọ́ pé wọ́n fi ọmọ ọdún mẹ́tàlá kan sí ilé alágbàtọ́ mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láàárín ọdún mẹ́ta péré—kódà kì í sùn ju oorun ọjọ́ kan lọ láwọn ibòmíràn. Ọmọbìnrin náà wá ń rántí báyìí, nípa bó ṣe máa ń dùn ún gan-an nítorí bí wọ́n ṣe ń pa á tì, tí kò sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọdé tó wà nílé alágbàtọ́ bíi tiẹ̀ ló jẹ́ pé wọn kò gbádùn ìgbà ọmọdé wọn.

Abájọ nígbà náà, tí àwọn ọ̀mọ̀ràn òde òní fi ń sọ pé àìlóǹkà ọmọdé ni kò gbádùn ìgbà èwe wọn, èyí sì ń kó ìbànújẹ́ bá wọn. Bó o bá jẹ́ òbí, o lè wo àwọn ìròyìn tí kò múnú ẹni dùn wọ̀nyí kó o sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé ó jẹ́ kó o lè gbọ́ bùkátà àwọn ọmọ rẹ, àti pé ó ṣeé ṣe fún ọ láti pèsè ibùgbé fún wọn. Àmọ́ ìṣòro mìíràn ṣì tún wà o. Láyé òde òní, kì í kúkú ṣe gbogbo ìgbà náà ló jẹ́ pé àwọn ọmọdé ò gbádùn ìgbà èwe wọn rárá. Nígbà míì, ńṣe làwọn òbí máa ń gbé ọ̀pọ̀ nǹkan kà wọ́n láyà, tí wọn ò ní jẹ́ kí wọ́n fara balẹ̀ gbádùn ìgbà èwe wọn. Báwo lèyí ṣe ń ṣẹlẹ̀, àwọn àbájáde wo ló sì máa ń tìdí ẹ̀ yọ?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ padà.