Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀pà Èso Tí Kò Jọjú, àmọ́ Tó Wúlò fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Nǹkan

Ẹ̀pà Èso Tí Kò Jọjú, àmọ́ Tó Wúlò fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Nǹkan

Ẹ̀pà Èso Tí Kò Jọjú, àmọ́ Tó Wúlò fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Nǹkan

Ṣé o fẹ́ràn ẹ̀pà? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn náà ló fẹ́ràn rẹ̀ bíi tìrẹ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lórí ilẹ̀ ayé ló ń gbádùn ẹ̀pà. Àwọn orílẹ̀-èdè méjì tó ní olùgbé tó pọ̀ jù lọ lágbàáyé—ìyẹn Ṣáínà àti Íńdíà—ló ń gbin ohun tó lé ní ìdajì gbogbo ẹ̀pà tí wọ́n ń gbìn lágbàáyé.

Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà máa ń kórè ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù kílò ẹ̀pà lọ́dọọdún, àwọn ni wọ́n sì ń gbin ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá mẹ́wàá gbogbo ẹ̀pà tó wà lágbàáyé. Àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tí wọ́n tún máa ń ṣọ̀gbìn ẹ̀pà gan-an ni Ajẹntínà, Brazil, Gúúsù Áfíríkà, Màláwì, Nàìjíríà, Senegal, àti Sudan. Báwo ni ẹ̀pà ṣe di ohun tó gbayì nílé-lóko bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ àwọn ipò kan wà tó jẹ́ pé yóò bọ́gbọ́n mu láti yẹra fún jíjẹ ẹ̀pà?

Ẹ̀pà Ti Wà Tipẹ́

Àwọn kan sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ilẹ̀ Gúúsù Amẹ́ríkà ni ẹ̀pà ti ṣẹ̀ wá. Ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ ọnà àtayébáyé tó ń fi hàn pé àwọn èèyàn fẹ́ràn ẹ̀pà ni orù kan tí wọ́n ṣàwárí ní orílẹ̀-èdè Peru, èyí tí wọ́n ti ń lò ṣáájú kí Christopher Columbus tó ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè náà. Bí èèpo ẹ̀pà ṣe máa ń rí lójú gẹ́lẹ́ ni orù náà ṣe rí, wọ́n sì tún fi àwòrán ẹ̀pà ṣe ọ̀ṣọ́ sí i lára. Àwọn olùṣàwárí ọmọ ilẹ̀ Sípéènì, tí wọ́n kọ́kọ́ rí ẹ̀pà ní ilẹ̀ Gúúsù Amẹ́ríkà, ṣàkíyèsí pé ó jẹ́ oúnjẹ aṣaralóore tó dára gan-an fún ìrìn-àjò wọn. Nítorí náà, wọ́n mú ẹ̀pà díẹ̀ dání nígbà tí wọ́n ń padà sí ilẹ̀ Yúróòpù. Àwọn ará Yúróòpù tún lo ẹ̀pà ní oríṣiríṣi ọ̀nà mìíràn, kódà wọ́n lò ó láti fi rọ́pò èso kọfí.

Nígbà tó yá, àwọn Potogí mú ẹ̀pà wá sí ilẹ̀ Áfíríkà. Níbẹ̀, kò pẹ́ táwọn èèyàn fi mọ̀ pé oúnjẹ tó wúlò gan-an ni ẹ̀pà jẹ́, àti pé ó lè hù ní ilẹ̀ tí kò lọ́ràá rárá níbi tí àwọn irúgbìn mìíràn ò ti lè hù. Àní, ńṣe ni ẹ̀pà tiẹ̀ tún máa ń pèsè èròjà nitrogen tí ilẹ̀ tó ti ṣá nílò gan-an. Bí àkókò ti ń lọ, wọ́n mú ẹ̀pà láti ilẹ̀ Áfíríkà lọ sí Àríwá Amẹ́ríkà nígbà òwò ẹrú.

Láàárín ẹ̀wádún tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1530, àwọn Potogí mú ẹ̀pà lọ sí ilẹ̀ Íńdíà àti Macao, àwọn ọmọ ilẹ̀ Sípéènì sì mú un lọ sí orílẹ̀-èdè Philippines. Láti àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ni àwọn oníṣòwò ti mú ẹ̀pà lọ sí ilẹ̀ Ṣáínà. Àwọn ará ibẹ̀ rí i pé èso náà yóò ṣèrànwọ́ láti kojú ìyàn tó ń mú hánhán ní orílẹ̀-èdè náà.

Àwọn onímọ̀ nípa ewéko ní ọ̀rúndún tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1700 ṣèwádìí lórí ẹ̀pà, wọ́n sì parí èrò sí pé yóò dára gan-an fún bíbọ́ ẹlẹ́dẹ̀. Nígbà tó fi máa di ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1800, àwọn àgbẹ̀ ti ń gbin ẹ̀pà fún títà ní àgbègbè South Carolina ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nígbà Ogun Abẹ́lé Ilẹ̀ Amẹ́ríkà, èyí tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1861, ẹ̀pà ni oúnjẹ tí wọ́n ń fún àwọn ọmọ ogun ìhà méjèèjì tó dojú kọ ara wọn.

Àmọ́ ṣá o, nígbà yẹn, oúnjẹ àwọn akúṣẹ̀ẹ́ ni ọ̀pọ̀ èèyàn ka ẹ̀pà sí. Èrò tó wà lọ́kàn ọ̀pọ̀ èèyàn yìí wà lára ohun tó mú kí àwọn àgbẹ̀ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ayé ọjọ́un kọ̀ láti ṣọ̀gbìn ẹ̀pà fún jíjẹ. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ṣáájú kí àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ àgbẹ̀ tó dé ní nǹkan bí ọdún 1900, wàhálà tó wà nídìí ẹ̀pà gbígbìn kì í ṣe kékeré, torí pé ó ń béèrè ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ àti owó tabua.

Àmọ́ nígbà tó fi máa di ọdún 1903, George Washington Carver, ará Amẹ́ríkà kan tó jẹ́ aṣáájú onímọ̀ sáyẹ́ǹsì nínú iṣẹ́ àgbẹ̀, ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣèwádìí lórí onírúurú nǹkan tí wọ́n lè mú jáde látinú ẹ̀pà. Bí àkókò ti ń lọ, àwọn ohun tó mú jáde nínú rẹ̀ tí wọ́n lè fi ẹ̀pà ṣe lé ní ọ̀ọ́dúnrún, lára ìwọ̀nyí sì ni ohun mímu, èròjà ìṣaralóge, aró, egbòogi, ọṣẹ ìfọṣọ, oògùn apakòkòrò, àti yíǹkì táwọn tẹ̀wétẹ̀wé ń lò. Carver tún máa ń rọ àwọn àgbẹ̀ àdúgbò pé kò yẹ kó jẹ́ pé òwú nìkan ni wọ́n á máa gbìn, torí pé òwú máa ń mú kí ilẹ̀ ṣá, àmọ́ kí wọ́n máa gbin ẹ̀pà náà pẹ̀lú. Nígbà yẹn, kòkòrò kan tó ń jẹ́ boll weevil máa ń ba òwú tí wọ́n bá gbìn jẹ́, èyí ló mú kí ọ̀pọ̀ àgbẹ̀ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Carver fún wọn. Kí wá ni àbájáde èyí? Ọ̀gbìn ẹ̀pà wá búrẹ́kẹ́ gan-an débi pé ó di ọ̀kan lára àwọn irúgbìn pàtàkì tó ń mówó wọlé ní ìhà gúúsù orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Béèyàn bá ṣèbẹ̀wò sí ìlú Dothan, ní ìpínlẹ̀ Alabama, yóò rí ọwọ̀n kan tí wọ́n ṣe láti fi ṣe ìrántí ọ̀gbẹ́ni Carver. Kódà, ní ìlú Enterprise, tó wà ní ìpínlẹ̀ Alabama, àwọn náà ṣe ọwọ̀n kan láti fi ṣe ìrántí kòkòrò boll weevil, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọṣẹ́ tí kòkòrò náà ń ṣe fún òwú tí wọ́n gbìn ló sún àwọn àgbẹ̀ láti máa gbin ẹ̀pà.

Gbígbin Ẹ̀pà

Irúgbìn onípódi ni ẹ̀pà, ìyẹn ni pé èèyàn ní láti pa èèpo rẹ̀ kó tó lè jẹ ẹ́. Nígbà tí ẹ̀pà bá ń hù, yóò bẹ̀rẹ̀ sí yọ òdòdó.

Nígbà tí òdòdó náà bá rẹ̀ sílẹ̀, ẹ̀ka tín-ín-rín tí ó gbé òdòdó náà sókè yóò tẹ orí ba lọ sí ilẹ̀, yóò sì wọ inú erùpẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀. Orí ẹ̀ka tín-ín-rín tí ó wọ ilẹ̀ lọ náà á wá bẹ̀rẹ̀ sí í tóbi nínú ilẹ̀ títí ó máa fi di pódi ẹ̀pà. Igi ẹ̀pà kan lè ní tó ogójì pódi ẹ̀pà.

Ẹ̀pà máa ń hù dáadáa ní àgbègbè ilẹ̀ olóoru, tí oòrùn ti máa ń ràn, tí òjò kì í sì í rọ̀ lárọ̀jù. Nǹkan bí oṣù mẹ́ta sí mẹ́rin lẹ́yìn tí a ti gbin ẹ̀pà ni a lè kórè rẹ̀, ó sinmi lórí oríṣi ẹ̀pà tó jẹ́ àti bí ipò ojú ọjọ́ bá ṣe rí. Láti kórè ẹ̀pà, àwọn tó ń ṣọ̀gbìn rẹ̀ yóò hú u jáde tigbòǹgbò-tigbòǹgbò, wọn yóò sì jẹ́ kó gbẹ dáadáa kí wọ́n tó tọ́jú rẹ̀ kó má bàa bà jẹ́. Lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbin ẹ̀pà máa ń lo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tó wà fún iṣẹ́ àgbẹ̀, èyí tó máa ń wú ẹ̀pà nílẹ̀, tí yóò sì yọ àwọn èso rẹ̀ lọ́wọ́ kan náà.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ohun Tí Wọ́n Lè Lo Ẹ̀pà Fún

Ẹ̀pà ní ọ̀pọ̀ èròjà aṣaralóore nínú. Ó ní ọ̀pọ̀ ṣákítí nínú tó dára fún ara, bẹ́ẹ̀ ló tún ní oríṣi èròjà fítámì mẹ́tàlá àti èròjà mineral mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n nínú, ọ̀pọ̀ lára àwọn èròjà wọ̀nyí ni kò sì sí nínú àwọn oúnjẹ táwọn èèyàn ń jẹ lóde òní. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopædia Britannica sọ pé: “Bí a bá gbé ìwọ̀n ẹ̀pà kan kalẹ̀ tá a sì tún gbé ẹ̀dọ̀ màlúù ìwọ̀n kan náà kalẹ̀, tá a wá fi wọn wéra, ẹ̀pà ní ọ̀pọ̀ èròjà protein, mineral àti vitamin nínú ju ẹ̀dọ̀ màlúù lọ.” Àmọ́, kí ẹ̀yin tí ẹ ò fẹ́ sanra jù tàbí tí ẹ fẹ́ rí pẹ́lẹ́ńgẹ́ ṣọ́ra o! Ẹ̀pà tún ní “ọ̀rá tó pọ̀ gan-an nínú” ó sì ní “ọ̀pọ̀ èròjà afúnnilókun tó ń jẹ́ calorie ju ṣúgà lọ.”

Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ń lo ẹ̀pà ní oríṣiríṣi ọ̀nà nínú oúnjẹ wọn. Òórùn rẹ̀ kò sì ṣòroó mọ̀ nínú oúnjẹ èyíkéyìí tí wọ́n bá fi sè. Anya von Bremzen, òǹṣèwé lórí oúnjẹ sísè, kọ̀wé pé: “Ẹ̀pà máa ń ta sánsán gan-an ni, òórùn rẹ̀ kò sì láṣìmọ̀ rárá débi pé bákan náà ni gbogbo oúnjẹ tí wọ́n bá fi ẹ̀pà sè ṣe máa ń ta sánsán. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹni tó bá tọ́ oúnjẹ tí wọ́n fi ẹ̀pà sè nílẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wò á rí i pé ìtọ́wò wọn jọra, ì bá à jẹ́ ọbẹ̀ ẹ̀pà ilẹ̀ Indonesia, ọbẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, ọbẹ̀ ilẹ̀ Ṣáínà, ọbẹ̀ ilẹ̀ Peru tàbí ẹ̀pà lílọ̀ tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa fi ń jẹ búrẹ́dì.”

Jákèjádò ayé làwọn èèyàn tún mọ̀ pé ẹ̀pà dára gan-an fún ìpápánu. Bí àpẹẹrẹ, ní orílẹ̀-èdè Íńdíà, wọ́n máa ń lú ẹ̀pà mọ́ àwọn oúnjẹ oníhóró mìíràn, irú bíi gbúgbúrú, wọ́n sì máa ń tà á ní òpópónà. Ó yẹ fún àfiyèsí pé, ẹ̀pà lílọ̀, tí wọ́n máa ń fi sórí búrẹ́dì láwọn orílẹ̀-èdè kan, ni ìwé The Great American Peanut sọ pé “dókítà kan ló ṣàwárí rẹ̀ ní ìlú St. Louis [ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà] ní nǹkan bí ọdún 1890 gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ tó dára fún ìlera àwọn arúgbó.”

Àmọ́ o, ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n tún ń lo ẹ̀pà fún yàtọ̀ sí pé kéèyàn jẹ ẹ́ ní tààràtà. Káàkiri ilẹ̀ Éṣíà, wọ́n máa ń lo òróró ẹ̀pà fún oúnjẹ sísè. Wọ́n tún lè fi òróró ẹ̀pà dín nǹkan, òórùn rẹ̀ kì í sì í bo ohun téèyàn fi dín náà mọ́lẹ̀.

Ní orílẹ̀-èdè Brazil, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti yọ òróró inú ẹ̀pà, wọ́n máa ń fi ṣákítí rẹ̀ tó ṣẹ́ kù bọ́ àwọn ẹran ọ̀sìn. Bákan náà, àwọn ohun tí wọ́n ń fi ẹ̀pà ṣe wọ́pọ̀ nínú àwọn ohun èlò tá à ń lò lójoojúmọ́.—Wo ìsọfúnni tó wà lókè.

Ẹ Ṣọ́ra—Ẹ̀yin Tí Ẹ̀pà Kò Bá Lára Mu!

Ó ṣeé ṣe láti tọ́jú ẹ̀pà fún àkókò gígùn láìsí pé a gbé e sínú fìríìjì. Àmọ́ ṣá o, èèyàn gbọ́dọ̀ ṣọ́ra. Ẹ̀pà tó bá ti ń hu olú máa ń ní èròjà aflatoxin nínú, èyí tó lè fa àrùn jẹjẹrẹ. Láfikún sí i, ẹ̀pà kò bá àwọn èèyàn kan lára mu. Ìwé ìròyìn Prevention sọ pé, bí ẹ̀pà kò bá bá ẹnì kan lára mu ó “lè mú kí onítọ̀hún máa ní ọ̀fìnkìn tàbí kí ara máa yún un, kódà ó lè yọrí sí gìrì tó lè ṣekú pani.” Ìwádìí lóríṣiríṣi ti fi hàn pé ńṣe ni àwọn ọmọdé tó ń ní àwọn ìṣòro tó ń fi hàn pé ẹ̀pà kò bá wọn lára mu túbọ̀ ń pọ̀ sí i.

Ìwé ìròyìn Prevention tún ṣàlàyé pé, bí bàbá àti ìyá ọmọ kan bá ní ikọ́ ẹ̀gbẹ, ìṣòro imú dídí tàbí ifo, ó ṣeé ṣe pé kí ẹ̀pà máà bá ọmọ tí wọ́n bá bí lára mu.

Ẹ̀pà tún lè ṣàì bá àwọn ọmọ kan lára mu bí àwọn ohun kan kò bá bá àwọn ìyá wọn lára mu tàbí bí mílíìkì ò bá bá irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ lára mu ní ọdún àkọ́kọ́ tí wọ́n bí wọn. Dókítà Hugh Sampson, ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìtọ́jú àrùn àwọn ọmọdé ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìṣègùn ti Yunifásítì Johns Hopkins, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, sọ pé: “Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kí àwọn òbí má ṣe fún àwọn ọmọ wọn ní ẹ̀pà lílọ̀ rárá ní ọdún mẹ́ta àkọ́kọ́ tí wọ́n bí wọn.”

Yálà o fẹ́ràn ẹ̀pà tàbí o kò fẹ́ràn rẹ̀, ó ṣeé ṣe kí àgbéyẹ̀wò tá a ṣe lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó wúlò fún jẹ́ kó o túbọ̀ mọrírì èso tí kò jọjú, àmọ́ tó gbajúmọ̀ yìí.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Àwọn Ohun Èlò Ojoojúmọ́ Tí Ẹ̀pà Wà Lára Ohun Tí Wọ́n Fi Ṣe Wọ́n

• Pátákó tí wọ́n fi ń bo ògiri

• Igi ìyáná nínú ilé

• Ohun tí wọ́n fi ń nu ìdọ̀tí ẹran ọ̀sìn

• Bébà

• Ọṣẹ ìfọṣọ

• Aporó

• Ohun èlò amú-irin-dán-gbinrin

• Èròjà olómi tó ń ṣí ìdọ̀tí

• Yíǹkì

• Gíríìsì ẹ̀rọ

• Èròjà ìfárùngbọ̀n

• Ìpara tí wọ́n fi ń pajú

• Ọṣẹ

• Ohun èlò tí wọ́n ń tẹ́ sílẹ̀

• Rọ́bà

• Èròjà ìṣaralóge

• Ọ̀dà

• Ohun abúgbàù

• Ọṣẹ ìfọrun

• Egbòogi

[Credit Line]

Ibi tí a ti mú ìsọfúnni yìí: The Great American Peanut

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Ewé

Ẹ̀ka tín-ín-rín tó gbé ewé òdòdó náà sókè

Ilẹ̀ |

Ìtàkùn Ẹ̀pà

[Credit Line]

Ìwé ìròyìn The Peanut Farmer

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Ọwọ̀n tí wọ́n ṣe ní ìrántí George Washington Carver

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Amẹ́ríkà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Áfíríkà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Éṣíà

[Credit Line]

FAO photo/R. Faidutti

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Díẹ̀ lára onírúurú ìpápánu tí wọ́n lè fi ẹ̀pà ṣe

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Ẹ̀pà lílọ̀ jẹ́ oúnjẹ tó gbajúmọ̀ láwọn orílẹ̀-èdè kan