Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Bíbélì Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ fún Àwọn Tó Ní Àrùn Àtọ̀gbẹ

Bí Bíbélì Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ fún Àwọn Tó Ní Àrùn Àtọ̀gbẹ

Bí Bíbélì Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ fún Àwọn Tó Ní Àrùn Àtọ̀gbẹ

ÌKÓRA-ẸNI-NÍJÀÁNU àti níní èrò rere lọ́kàn ṣe pàtàkì gan-an fún ìlera àti àlàáfíà àwọn tó ní àrùn àtọ̀gbẹ. Àmọ́ kí wọ́n tó lè ní àwọn ànímọ́ wọ̀nyí, wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ tí kò dáwọ́ dúró. Nítorí náà, kò yẹ kí àwọn tó wà nínú ìdílé aláìsàn náà àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa rọ̀ ọ́ láti jẹ àwọn pàrùpárù oúnjẹ, bóyá kí wọ́n máa sọ fún un pé, ‘Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo yìí kò lè ṣe ẹ́ ní nǹkan kan.’ Harry, ẹni tó ní àrùn ọkàn àti àrùn àtọ̀gbẹ Oríṣi Kejì, sọ pé: “Ìyàwó mi ń ṣètìlẹyìn fún mi gan-an ni. Kì í jẹ́ kí àwọn oúnjẹ tí kò yẹ kí n jẹ wà nínú ilé. Àmọ́ àwọn kan kò mọ ìyẹn, wọn ò sì mọ bó ṣe máa ń nira tó nígbà míì láti mójú kúrò lára irú àwọn oúnjẹ bẹ́ẹ̀.”

Bí ìwọ àti ẹni tó ní àrùn àtọ̀gbẹ bá jọ ń gbé tàbí tẹ́ ẹ jọ ń wà pa pọ̀, fi àwọn ìlànà dáradára méjì tó wá látinú Bíbélì yìí sọ́kàn: “Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì,” àti “Ìfẹ́ . . . kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.”—1 Kọ́ríńtì 10:24; 13:4, 5.

Gbogbo ẹni tí ìlera rẹ̀ bá jẹ lógún, yálà onítọ̀hún ní àrùn àtọ̀gbẹ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ló gbọ́dọ̀ máa lo ìkóra-ẹni-níjàánu nínú oúnjẹ jíjẹ. Bíbélì pèsè ìrànwọ́ lórí kókó yìí, nítorí ó jẹ́ ká rí i pé ó ṣe pàtàkì fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láti ní ìkóra-ẹni-níjàánu. Ǹjẹ́ o ti pinnu láti ní ànímọ́ yìí nínú ìgbésí ayé rẹ? (Gálátíà 5:22, 23) Àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú Bíbélì tún lè ṣèrànwọ́, irú bí àpẹẹrẹ Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ẹnì kan tí àrùn àtọ̀gbẹ ń yọ lẹ́nu sọ pé: “[Pọ́ọ̀lù] ní ẹ̀gún kan nínú ara rẹ̀ èyí tí kò fi í sílẹ̀, síbẹ̀ ó fi ìṣòtítọ́ sin Ọlọ́run, ó sì sìn ín ní kíkún. Èmi náà lè ṣe bẹ́ẹ̀!”

Bẹ́ẹ̀ ni, Pọ́ọ̀lù fara mọ́ ipò tí ò ṣeé yí padà ó sì ṣàṣeyọrí gan-an nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì rẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 12:7-9) Ọmọ ọdún méjìdínlógún ni Dustin, afọ́jú ni nígbà tí wọ́n bí i, àtọmọ ọdún méjìlá ló sì ti ní àrùn àtọ̀gbẹ. Ó kọ̀wé pé: “Mo mọ̀ pé kò sí ẹnì kankan láyé yìí tí gbogbo nǹkan dára fún látòkèdélẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe fẹ́. Mò ń wọ̀nà de àkókò náà nínú ayé tuntun Ọlọ́run, nígbà tí àrùn àtọ̀gbẹ kò ní ṣe mí mọ́. Lójú mi, ìṣòro tó máa wà fún ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ ló jẹ́. Ó lè máà jẹ́ àìlera tó ń tètè lọ bí òtútù, àmọ́ bópẹ́ bóyá, yóò lọ.”

Ohun tí Dustin ní lọ́kàn tó fi sọ gbólóhùn yẹn ni ìrètí tó ní, èyí tá a gbé ka Bíbélì, nípa ìlera pípé tí yóò wà nínú Párádísè ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Ìṣípayá 21:3, 4) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèlérí pé, lábẹ́ ìṣàkóso àtọ̀runwá náà, “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24; Mátíù 6:9, 10) Ṣé wàá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìlérí tá a gbé ka Bíbélì yìí? Kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ, tàbí kó o kọ̀wé sí àwọn tó ṣe ìwé ìròyìn yìí nípa lílo àdírẹ́sì tó bá yẹ lára àwọn tá a tò sí ojú ìwé 5.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Ìkóra-ẹni-níjàánu àti níní èrò rere lọ́kàn ṣe pàtàkì