Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jíjẹ́ Kí Àwọn Ọmọdé Gbádùn Ìgbà Èwe Wọn

Jíjẹ́ Kí Àwọn Ọmọdé Gbádùn Ìgbà Èwe Wọn

Jíjẹ́ Kí Àwọn Ọmọdé Gbádùn Ìgbà Èwe Wọn

BÍ ÀWỌN òbí bá ṣe ojúṣe wọn bó ṣe yẹ, àwọn ọmọ wọn á gbádùn ìgbà èwe wọn gidigidi. Àmọ́ àwọn nǹkan wo ló yẹ kí àwọn òbí ṣe láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dáadáa? Ó ṣeé ṣe kó o ti gbọ́ àwọn ìmọ̀ràn kan lórí ọ̀ràn yìí. Máa lo ọ̀pọ̀ àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ. Máa tẹ́tí gbọ́ ohun tí wọ́n bá ní í sọ. Fún wọn ní ìtọ́sọ́nà tó yè kooro. Máa fi ọ̀ràn wọn rora rẹ wò, máa bá wọn yọ̀ bí wọ́n bá ń yọ̀, bí ohun kan bá sì ń dùn wọ́n jẹ́ kó dun ìwọ náà. Jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́ fún wọn, láìsí pé ò ń pa ojúṣe rẹ gẹ́gẹ́ bí òbí tì. Lóòótọ́ o, irú àwọn ìlànà tá a máa ń gbọ́ léraléra bẹ́ẹ̀ yóò ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́. Àmọ́ ohun kan tún wà tó ṣe pàtàkì ju àwọn wọ̀nyí lọ tó gbọ́dọ̀ ṣáájú.

Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn òbí yíká ayé ti rí i pé fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò lohun tó lè jẹ́ kéèyàn tọ́mọ dáadáa. Kí nìdí? Nítorí pé Jèhófà, Ọlọ́run ọlọgbọ́n tó pèsè Bíbélì, náà ló dá ètò ìdílé sílẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; 2:18-24; Éfésù 3:15) Nítorí náà, kò sí àní-àní pé Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó mí sí ni ohun èlò tó dára jù lọ láti lò gẹ́gẹ́ bí ìtọ́sọ́nà lórí ọmọ títọ́. Àmọ́, báwo ni ìwé tọ́jọ́ rẹ̀ ti pẹ́ gan-an bíi Bíbélì ṣe lè là wá lóye lórí àṣà òde òní ti ṣíṣàì jẹ́ kí àwọn ọmọdé fara balẹ̀ gbádùn ìgbà èwe wọn? Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ kan tá a lè fi sílò.

“Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ìṣísẹ̀ Àwọn Ọmọ”

Jákọ́bù, ọmọ Ísákì, jẹ́ bàbá àwọn ọmọ tó lé ní méjìlá. Bíbélì ṣàkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tó sọ nígbà ìrìn àjò kan tí ìdílé rẹ̀ rìn, ó sọ pé: “Àwọn ọmọ jẹ́ ẹlẹgẹ́ . . . Kí olúwa mi [Ísọ̀, ẹ̀gbọ́n Jákọ́bù] jọ̀wọ́ kọjá, kí ó sì máa nìṣó níwájú ìránṣẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi fúnra mi máa bá ìrìn àjò náà bọ̀ lọ́nà tí ó rọ̀ mí lọ́rùn . . . ní ìbámu pẹ̀lú ìṣísẹ̀ àwọn ọmọ.”—Jẹ́nẹ́sísì 33:13, 14.

Jákọ́bù mọ̀ pé àwọn ọmọ òun kò lágbára bí àwọn àgbàlagbà. Wọ́n jẹ́ “ẹlẹgẹ́” ní ti pé, wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lókun nínú tó àgbàlagbà, wọn ò sì lè dá bójú tó ara wọn. Dípò kí Jákọ́bù fipá mú àwọn ọmọ rẹ̀ láti máa rìn ní kóyákóyá bí òun ṣe ń rìn, ńṣe ló rọra tẹsẹ̀ dúró dè wọ́n kí ìrìn rẹ̀ lè bá tiwọn mu. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó fara wé ọgbọ́n tí Ọlọ́run máa ń fi hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn. Baba wa ọ̀run mọ ibi tí agbára wa mọ. Kì í béèrè ohun tí agbára wa ò bá gbé lọ́wọ́ wa.—Sáàmù 103:13, 14.

Kódà àwọn ẹranko kan máa ń fi irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ hàn, nítorí pé Ọlọ́run ti dá wọn pẹ̀lú “ọgbọ́n àdámọ́ni.” (Òwe 30:24) Bí àpẹẹrẹ, àwọn onímọ̀ nípa ìṣẹ̀dá ti ṣàkíyèsí pé gbogbo àwọn erin tó wà nínú agbo kan máa ń mú kí ìrìn wọn bá ti erin kékeré tó bá wà láàárín wọn mu, wọ́n á máa tẹsẹ̀ dúró títí dìgbà tí erin kékeré náà á fi bá wọn.

Ọ̀pọ̀ èèyàn nínú àwùjọ òde òní kò tẹ̀ lé ọgbọ́n Ọlọ́run. Àmọ́ kò pọn dandan kó o máa ṣe bíi tiwọn. Máa fi sọ́kàn pé “ẹlẹgẹ́” ni ọmọ rẹ, ìyẹn ni pé kò tíì lágbára láti tẹ́rí gba ẹrù iṣẹ́ àwọn àgbàlagbà. Bí àpẹẹrẹ, ká ní o jẹ́ òbí anìkàntọ́mọ tó o sì ní àwọn ìṣòro títa kókó kan, o lè máa ronú pé ó yẹ kó o fọ̀ràn lọ ọmọ rẹ, àmọ́ má ṣe fọ̀ràn lọ̀ ọ́ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, wá àgbàlagbà kan tó dàgbà dénú tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro náà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ—pàápàá ẹni tó máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ bí wàá ṣe fi ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì sílò.—Òwe 17:17.

Bákan náà, má ṣe mú ìgbà èwe ọmọ rẹ nira fún un, kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ̀ wá kún fọ́fọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbòkègbodò láìsí ìsinmi rárá, kí ọwọ́ rẹ̀ sì dí débi pé kò tiẹ̀ ní lè gbádùn ìgbà èwe rẹ̀ mọ́ rárá. Ṣètò àwọn ohun tí ọmọ rẹ yóò máa ṣe lọ́nà tó bá ọjọ́ orí àti ipò rẹ̀ mu, kì í ṣe pé kó o kàn máa fara wé àṣà ọmọ títọ́ tó gbòde kan lónìí. Bíbélì fún wa ní ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n yìí pé: “Má ṣe jẹ́ kí ayé tó yí ẹ ká mú ẹ bá bátànì rẹ̀ mu.”—Róòmù 12:2, Phillips.

“Ohun Gbogbo Ni Ìgbà Tí A Yàn Kalẹ̀ Wà Fún”

Ìlànà ọlọgbọ́n mìíràn tó wà nínú Bíbélì ni pé: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, àní ìgbà fún gbogbo àlámọ̀rí lábẹ́ ọ̀run.” Lóòótọ́, àsìkò iṣẹ́ wà. Iṣẹ́ púpọ̀ ló sì wà fún àwọn ọmọdé láti ṣe—irú bí iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́, iṣẹ́ ilé, àti àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí. Bó ti wù kó rí, àyọkà Bíbélì kan náà sọ pé “ìgbà rírẹ́rìn-ín” àti “ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri” náà tún wà.—Oníwàásù 3:1, 4.

Ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí àwọn ọmọdé máa ṣeré, kí wọ́n máa rẹ́rìn-ín, kí wọ́n sì máa lo okun ìgbà èwe wọn láti yọ̀ ṣìnkìn láìsí àníyàn tó máa kó wọn lọ́kàn sókè pọ̀ ju ọjọ́ orí wọn lọ. Bó bá jẹ́ pé ojoojúmọ́ ayé ni ọwọ́ wọn máa ń dí, tó jẹ́ pé wọ́n á lọ sí ilé ẹ̀kọ́, wọ́n á tún mú àwọn iṣẹ́ mìíràn ṣe tí wọ́n bá dé, bákan náà ni wọ́n á tún bójú tó àwọn iṣẹ́ bàǹtàbanta mìíràn, a jẹ́ pé wọn ò ní ráyè ṣeré rárá nìyẹn. Èyí sì lè mú kí wọ́n di ẹni tí òbí ń dá lágara, kódà wọ́n lè ní àárẹ̀ ọkàn pàápàá.—Kólósè 3:21.

Ṣàgbéyẹ̀wò bó o tún ṣe lè fi ìlànà Bíbélì yìí kan náà sílò láwọn ọ̀nà mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ohun gbogbo ni àkókò wà fún, ǹjẹ́ ìyẹn kò fi hàn pé ìgbà èwe jẹ́ àkókò láti fi ṣe bí èwe? Ó ṣeé ṣe kó o dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ àwọn ọmọ rẹ lè máà fìgbà gbogbo gbà pẹ̀lú rẹ. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọmọdékùnrin àti ọmọdébìnrin máa ń fẹ́ láti ṣe àwọn ohun tí wọ́n rí i tí àwọn àgbàlagbà ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọdébìnrin lè fẹ́ máa wọṣọ kí wọ́n sì máa múra bí ẹni pé wọ́n ti dàgbà. Bí wọ́n bá tètè bàlágà, èyí lè jẹ́ kó máa wù wọ́n gan-an láti ṣe bí àgbàlagbà.

Àwọn òbí tó jẹ́ ọlọgbọ́n máa ń rí ewu tó wà nínú irú ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀. Àwọn ìpolówó ọjà àtàwọn eré ìnàjú kan nínú ayé oníwà pálapàla yìí máa ń fi hàn pé àwọn ọmọdé lóye ìbálòpọ̀ dáadáa, pé kò sí ohun téèyàn lè fi bò fún wọn níbẹ̀. Ńṣe ni èròjà ìṣaralóge, àwọn ohun ọ̀ṣọ́, àtàwọn aṣọ tí kò bójú mu túbọ̀ ń wọ́pọ̀ sí i láàárín àwọn èwe. Àmọ́, ṣé ó yẹ ká gba àwọn ọmọdé láyè láti máa ṣe ohun táwọn èèyànkéèyàn á fi rí wọn lò fún ìbálòpọ̀? Bí àwọn òbí bá ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti wọṣọ lọ́nà tó bá ọjọ́ orí wọn mu, ńṣe ni wọ́n ń fi ìlànà Bíbélì mìíràn sílò, ìyẹn ni pé: “Afọgbọ́nhùwà tí ó ti rí ìyọnu àjálù ti fi ara rẹ̀ pa mọ́.”—Òwe 27:12.

Àpẹẹrẹ mìíràn rèé: Jíjẹ́ kí eré ìdárayá di ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ lójú ọmọ kan lè mú kí ìgbésí ayé irú ọmọ bẹ́ẹ̀ dojú rú, tó jẹ́ pé kò ní sí àkókò fún un mọ́ láti fi ṣètò fún gbogbo àlámọ̀rí rẹ̀. Bíbélì gbà wá níyànjú pé: “Ara títọ́ ṣàǹfààní fún ohun díẹ̀; ṣùgbọ́n fífọkànsin Ọlọ́run ṣàǹfààní fún ohun gbogbo, bí ó ti ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí àti ti èyí tí ń bọ.”—1 Tímótì 4:8.

Má ṣe jẹ́ kí àṣà ‘gbígbégbá orókè lọ́nàkọnà’ wọ àwọn ọmọ rẹ lára. Ọ̀pọ̀ òbí ló máa ń mú gbogbo ìgbádùn tó yẹ kí àwọn ọmọ rí nínú eré ìdárayá kúrò nípa títì wọn láti di ẹni tí yóò máa báni díje lójú méjèèjì, wọ́n á máa sọ fún wọn pé wọ́n gbọ́dọ̀ rọ́wọ́ mú lọ́nàkọnà. Nípa báyìí, èyí máa ń sún àwọn ọmọdé kan láti máa ṣe màgòmágó tàbí kí wọ́n tiẹ̀ ṣe àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n ń bá ṣeré léṣe kí wọ́n bàa lè rọ́wọ́ mú. Dájúdájú, gbígbégbá orókè kò ṣe pàtàkì tó irú àwọn àbájáde búburú bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀mí ìbánidíje ń mú wá!

Kíkọ́ Láti Ní Ìkóra-Ẹni-Níjàánu

Gbígbà pé ohun gbogbo ni àkókò wà fún ṣòro gan-an fún àwọn ọmọdé. Kò rọrùn fún wọn láti ní sùúrù tí ọwọ́ wọn ò bá tíì tẹ ohun kan tí wọ́n fẹ́. Ohun tó tún wá mú kí ọ̀rọ̀ yìí burú sí i ni pé, ńṣe ló dà bíi pé ọ̀pọ̀ èèyàn lóde òní ti pinnu pé ohunkóhun tí àwọn bá fẹ́ gbọ́dọ̀ tẹ̀ àwọn lọ́wọ́ lójú ẹsẹ̀. Àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn tó ń ṣonígbọ̀wọ́ eré ìnàjú sábà máa ń sọ fún àwọn èèyàn pé, “Ẹ rí i pé ẹ ra ohunkóhun tẹ́ ẹ bá fẹ́ rà, kẹ́ ẹ sì rí i pé ẹ rà á lójú ẹsẹ̀!”

Má ṣe jẹ́ kí irú àwọn ìkéde bẹ́ẹ̀ sún ọ láti máa kẹ́ àwọn ọmọ rẹ lákẹ̀ẹ́bàjẹ́. Ìwé náà, The Child and the Machine sọ pé: “Mímọ̀ pé ó máa ń gba àkókò àti iṣẹ́ gidi kí ọwọ́ tó tẹ ohun téèyàn ń wá jẹ́ àmì pàtàkì kan tó ń fi hàn pé ẹnì kan jẹ́ onílàákàyè ẹ̀dá. Ìkóra-ẹni-níjàánu àti ìrẹ́pọ̀ láàárín àwùjọ ló lè yanjú ìṣòro ìwà ipá tó ń peléke sí i, èyí táwọn ọmọdé ń hù ní ilé ẹ̀kọ́ àti nígbà tí wọn ò bá sí ní ilé ẹ̀kọ́.” Ìlànà Bíbélì kan tó lè ràn wá lọ́wọ́ sọ pé: “Bí ènìyàn bá ń kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ní àkẹ́jù láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, ní ìkẹyìn ìgbésí ayé rẹ̀, yóò di aláìmọ ọpẹ́ dá pàápàá.” (Òwe 29:21) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa bíbójútó àwọn ìránṣẹ́ tí kò tíì dàgbà púpọ̀ ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń dìídì sọ, ọ̀pọ̀ òbí ti rí i pé ìlànà yìí ṣàǹfààní gan-an fún àwọn ọmọ wọn.

Lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan táwọn ọmọdé nílò, ó ṣe pàtàkì gidigidi pé kí wọ́n ní ohun tí Bíbélì pè ní “ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Ìbáwí onífẹ̀ẹ́ máa ń ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti ní àwọn ànímọ́ bí ìkóra-ẹni-níjàánu àti sùúrù. Àwọn ànímọ́ wọ̀nyí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn.

Gbogbo Ohun Tó Ń Ṣèdíwọ́ fún Ìgbà Èwe Alárinrin Yóò Wá Sópin Láìpẹ́

Àmọ́ o lè máa wò ó pé, ‘Ǹjẹ́ bí ayé ṣe rí yìí ni Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ àti ọlọgbọ́n, ẹni tó mí sí àwọn ìlànà ṣíṣàǹfààní wọ̀nyí ṣe dìídì pète pé kí ayé wa rí? Ǹjẹ́ ó pète pé kí àwọn ọmọdé máa dàgbà nínú ayé eléwu tí kì í bìkítà fúnni rárá yìí?’ Lọ fọkàn balẹ̀ pé, Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀, Kristi Jésù, nífẹ̀ẹ́ ìran èèyàn gan-an, títí kan gbogbo ọmọdé láìka ọjọ́ orí wọn sí. Láìpẹ́, wọn yóò mú gbogbo ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé.—Sáàmù 37:10, 11.

Ṣé wàá fẹ́ láti mọ bí àkókò alálàáfíà àti aláyọ̀ yẹn ṣe máa rí? Fojú inú wo ìran yìí ná, èyí tí Bíbélì ṣàpèjúwe lọ́nà tó fani mọ́ra: “Ìkookò yóò . . . máa gbé ní ti tòótọ́ fún ìgbà díẹ̀ pẹ̀lú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, àmọ̀tẹ́kùn pàápàá yóò sì dùbúlẹ̀ ti ọmọ ewúrẹ́, àti ọmọ màlúù àti ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ àti ẹran tí a bọ́ dáadáa, gbogbo wọn pa pọ̀; àní ọmọdékùnrin kékeré ni yóò sì máa dà wọ́n.” (Aísáyà 11:6) Nínú ayé yìí tó jẹ́ pé àwọn èèyàn máa ń sábà hùwà àìláàánú sí àwọn ọmọdé nípa ṣíṣàì jẹ́ kí wọ́n fara balẹ̀ gbádùn ìgbà èwe wọn tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ jẹ́ kí wọ́n gbádùn rẹ̀ rárá, ẹ wo bó ṣe tuni nínú tó láti mọ̀ pé Ọlọ́run ṣèlérí irú ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ bẹ́ẹ̀ fún ìran èèyàn lórí ilẹ̀ ayé! Láìsí àní-àní, Ẹlẹ́dàá kò pète pé kí àwọn ọmọdé máà gbádùn ìgbà èwe wọn tàbí pé kí wọ́n má fara balẹ̀ gbádùn rẹ̀—kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fẹ́ kí ìgbà ọmọdé wọn máa dùn yùngbà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Dípò tí wàá máa fi àwọn ìṣòro tó o ní dẹ́rù pa ọmọ rẹ, fọ̀ràn lọ àgbàlagbà mìíràn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]

Eré ṣíṣe ṣe pàtàkì fún àwọn ọmọdé