Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kò Retí Pé Òun Á Ṣàṣeyọrí Tó Tóyẹn

Kò Retí Pé Òun Á Ṣàṣeyọrí Tó Tóyẹn

Kò Retí Pé Òun Á Ṣàṣeyọrí Tó Tóyẹn

REBEKKA tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ní orílẹ̀-èdè Jámánì sọ pé: “Mo mọ̀ pé olùkọ́ tó ń kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ nípa ìtàn kò nífẹ̀ẹ́ sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà rárá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ ìdí rẹ̀.” Nítorí náà, nígbà tí olùkọ́ náà béèrè bóyá ẹnikẹ́ni á fẹ́ láti wá sọ̀rọ̀ lórí kókó kan níwájú kíláàsì, Rebekka kò fẹ́ jáde. Síbẹ̀, ó fi ìgboyà béèrè lọ́wọ́ olùkọ́ náà bóyá ó lè fún òun láyè láti sọ̀rọ̀ lórí inúnibíni tí wọ́n ṣe sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lákòókò ìjọba Násì nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Inú olùkọ́ náà dùn sí èyí.

Àwọn ọmọ kíláàsì náà gbádùn àsọyé Rebekka gan-an, wọ́n sì gba àwọn ìwé ìròyìn àti ìwé kékeré tí àpapọ̀ wọn jẹ́ mẹ́rìnlélógójì tí wọ́n dá lórí kókó ọ̀rọ̀ tó sọ. Lẹ́yìn náà, Rebekka kó àwọn ohun tó fi ṣe ìwádìí náà fún olùkọ́ rẹ̀, títí kan àwọn ìwé àtàwọn fídíò tí kì í ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló kọ wọ́n tàbí ló mú wọn jáde. Ọ̀kan lára àwọn fídíò náà ṣàfihàn inúnibíni tí wọ́n ṣe sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ìlà Oòrùn Jámánì nígbà Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀. Olùkọ́ náà nífẹ̀ẹ́ sí èyí gan-an, níwọ̀n bí kò ti mọ̀ nípa kókó yìí.

Lẹ́yìn èyí ni Rebekka ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mọ ìdí tí olùkọ́ rẹ̀ kò fi nífẹ̀ẹ́ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Olùkọ́ náà ṣàlàyé pé òun àti ẹnì kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà jọ lọ síléèwé nígbà kan. Ó ní ọ̀dọ́kùnrin náà kì í sọ̀rọ̀ nípa ìsìn rẹ̀ tàbí kó sọ nǹkan kan láti fi hàn pé Ẹlẹ́rìí lòun. Èyí ló mú kí olùkọ́ náà ronú pé abàmì èèyàn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò sì fẹ́ ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú wọn. Àmọ́ àsọyé tí Rebekka sọ ti yí èrò rẹ̀ padà. Rebekka sọ pé: “Àárín èmi àti olùkọ́ yìí ti wá gún régé. Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ kí àwa ọ̀dọ́ túbọ̀ máa sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ wa fún àwọn ẹlòmíràn.”

Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò parí síbẹ̀ o. Olùkọ́ náà sọ fún àwọn olùkọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù nípa àsọyé alárinrin tí Rebekka sọ. Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, olùkọ́ tó ń kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ nípa ìlànà ìwà híhù ní kí Rebekka wá sọ àsọyé mìíràn, àmọ́ kò ní jẹ́ níwájú àwọn ọmọ kíláàsì nìkan bí kò ṣe lákòókò ayẹyẹ pàtàkì kan—ìyẹn nígbà ìrántí ọdọọdún tí ilé ẹ̀kọ́ náà máa ń ṣe fún dídá tí wọ́n dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n sílẹ̀ nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìlú Auschwitz lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì parí. Nǹkan bí òjìdínnírínwó [360] akẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùkọ́ tó ń lọ sí bíi mẹ́wàá ló wà níkàlẹ̀. Ní òpin àsọyé náà, àwọn tó pésẹ̀ gba àádọ́ta ìwé kékeré, àwọn alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ náà sì béèrè fún àádọ́jọ ẹ̀dà sí i láti pín in lẹ́yìn náà.

Rebekka ò retí pé òun á ṣàṣeyọrí tó tóyẹn. Kì í ṣe àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ nìkan ló jẹ́rìí kúnnákúnná fún nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀, àmọ́ ó tún jẹ́rìí fún ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ lódindi. Bákan náà, ó ṣeé ṣe fún olùkọ́ rẹ̀ láti borí iyèméjì tó ti ní tẹ́lẹ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ìjọba Násì bẹ́ Heinrich Fundis lórí. Wọ́n tún pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àwọn aláṣẹ sọ fún ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé àwọ́n á da wọn sílẹ̀ bí wọ́n bá buwọ́ lu àkọsílẹ̀ yìí, èyí tó ń fi hàn pé wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí mọ́

[Credit Line]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda United States Holocaust Memorial Museum

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Wọ́n já àwọn ọmọdé gbà kúrò lọ́wọ́ àwọn òbí wọn, irú bíi Berthold Mewes

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Fídíò yìí sọ nípa bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe fi ìgboyà hàn lákòókò ìjọba Násì ní orílẹ̀-èdè Jámánì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Wọ́n rán àmì onígun mẹ́ta aláwọ̀ àlùkò mọ́ aṣọ ẹ̀wọ̀n àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti fi dá wọn mọ̀