Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ìlànà Rere Ń jó Àjórẹ̀yìn

Àwọn Ìlànà Rere Ń jó Àjórẹ̀yìn

Àwọn Ìlànà Rere Ń jó Àjórẹ̀yìn

ARA ẹ̀bùn títóbi jù lọ tí àwọn òbí lè fún àwọn ọmọ wọn ni ojúlówó ìfẹ́ àtàwọn ìlànà tí àwọn fúnra wọn ń tẹ̀ lé, tí kì í ṣe èyí tí wọ́n kàn ń fẹnu lásán sọ.

Láìsí àwọn ìlànà bíbójúmu, òfúùtùfẹ́ẹ̀tẹ̀ ni ìgbésí ayé á wulẹ̀ jẹ́. Àwọn ìlànà rere máa ń jẹ́ káyé ẹni nítumọ̀. Wọ́n máa ń jẹ́ kéèyàn mọ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé. Wọ́n ń jẹ́ kéèyàn mọ irú ìwà tó yẹ kí ọmọlúwàbí máa hù àtàwọn tí kò yẹ.

Síbẹ̀ náà, ńṣe làwọn ìlànà tó ti wà látọjọ́ pípẹ́ ń yára yí padà. Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ronald Inglehart sọ pé “ńṣe ni àṣà ìbálòpọ̀ táwọn èèyàn ń gùn lé báyìí túbọ̀ ń fún wọn lómìnira láti tẹ́ ìfẹ́ ìbálòpọ̀ wọn lọ́rùn bó ṣe wù wọ́n àti láti máa ṣe ohunkóhun tó bá ṣáà ti wà lọ́kàn wọn.” Nínú ìwádìí kan tí Àjọ Aṣèwádìí tó ń jẹ́ Gallup ṣe ní orílẹ̀-èdè mẹ́rìndínlógún lọ́dún 1997, wọ́n béèrè lọ́wọ́ àwọn èèyàn ibẹ̀ pé kí ni èrò wọn nípa bí àwọn èèyàn ṣe ń bímọ láìṣègbéyàwó. Àbájáde ìwádìí náà ni pé: “Ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ àwọn èèyàn ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ní apá Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù ló fara mọ́ irú ìgbésí ayé tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dóde yìí, nígbà táwọn tó fara mọ́ ọn ní orílẹ̀-èdè Singapore àti Íńdíà kò tó ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú ọgọ́rùn-ún.”

Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé òmìnira láti ní ìbálòpọ̀ bó ṣe wuni yìí dára gan-an ni. Àmọ́ ṣá o, ìwé pẹlẹbẹ kan tó ń jẹ́ The Rise of Government and the Decline of Morality, èyí tí ọ̀gbẹ́ni James A. Dorn kọ sọ pé, “bí àwọn ọmọ tí wọ́n ń bí láìṣègbéyàwó ṣe pọ̀ rẹ́kẹrẹ̀kẹ” àti “bí àwọn ìdílé ṣe ń tú ká” jẹ́ “ẹ̀rí tó ń fi hàn gbangba pé ìwà ìbàjẹ́ ti gbilẹ̀ sí i láwùjọ.”

Àwọn Ìlànà Rere Mìíràn Náà Ń Jó Àjórẹ̀yìn

Àwọn ìlànà rere mìíràn táwọn èèyàn ti ń tẹ̀ lé tipẹ́tipẹ́ náà ti ń di nǹkan ìgbàgbé báyìí. Ètò kan tí wọ́n pè ní Wíwádìí Bí Àwọn Èèyàn Ṣe Ń Hùwà Rere Sí Lágbàáyé, èyí tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Inglehart jẹ́ aṣáájú fún ròyìn pé, ńṣe ni àṣà “àìbọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ túbọ̀ ń peléke sí i” láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà lágbàáyé.

Ìlànà rere mìíràn tó ti wà látayébáyé ni kíkáràmáásìkí iṣẹ́. Àmọ́, ẹ̀rí fi hàn pé ìlànà yìí náà ń wó lulẹ̀. Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Àjọ Tó Ń Rí Sí Ìdàgbàsókè Àwọn Òwò Aládàáni fọ̀rọ̀ wá àwọn agbanisíṣẹ́ tó lé ní ìlàjì mílíọ̀nù lẹ́nu wò. “Ìdá mọ́kànlélọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ọ̀hún ló sọ pé kò rọrùn láti rí àwọn èèyàn láti ṣe àwọn iṣẹ́ tó wà nílẹ̀, ìdá mọ́kànlélógún nínú ọgọ́rùn-ún sì sọ pé iṣẹ́ táwọn tí wọ́n ń gbà síṣẹ́ ń ṣe kò kúnjú ìwọ̀n rárá.” Agbanisíṣẹ́ kan sọ pé: “Ńṣe ló túbọ̀ ń ṣòro láti rí àwọn òṣìṣẹ́ tó ń wá síbi iṣẹ́ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ lọ́sẹ̀, tí wọ́n ń tètè dé, tí wọn ò sì mutí yó.”

Ètò ọrọ̀ ajé tí kò lọ déédéé lè jẹ́ ohun tó ń fa àìṣe déédéé lẹ́nu iṣẹ́ yìí. Bí èrè táwọn iléeṣẹ́ ń jẹ ṣe ń dín kù, bẹ́ẹ̀ làwọn agbanisíṣẹ́ ń dá àwọn òṣìṣẹ́ dúró tàbí kí wọ́n máà fún wọn láwọn àǹfààní kan tó tọ́ sí wọn. Ìwé ìròyìn kan tó ń jẹ́ Ethics & Behavior sọ pé: “Àwọn òṣìṣẹ́ tí wọn ò fòótọ́ inú bá lò yìí á wá bẹ̀rẹ̀ sí hu àwọn ìwà tí kò bójú mu sáwọn tó gbà wọ́n síṣẹ́. Wọn ò ní fi tọkàntara ṣiṣẹ́ mọ́ nítorí pé ó lè dọ̀la kí wọ́n sọ fún wọn pé kò síṣẹ́ mọ́.”

Ohun mìíràn tó tún fi hàn gbangba pé ayé ti bà jẹ́ ni àìmọ̀wàáhù àti àìkì í bọ̀wọ̀ fúnni tó ń peléke sí i. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn òṣìṣẹ́ tó sọ pé ìwà àìlọ́wọ̀ táwọn èèyàn máa ń hù nínú ọ́fíìsì kì í jẹ́ káwọn láyọ̀.” Nígbà tí wọ́n sì fọ̀rọ̀ wá àwọn oníṣòwò kàǹkàkàǹkà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lẹ́nu wò, “ìdá ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó fèsì ló sọ pé àìbọ̀wọ̀ fúnni nínú ìṣòwò ti lọ sókè sí i.” Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àjọ kan tó ń ṣojú fún ilé iṣẹ́ ìròyìn CNN sọ, “Àìkìí bọ̀wọ̀ fún àwọn oníbàárà ti wá wọ́pọ̀ débi pé, nǹkan bí ìlàjì àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò nínú ìwádìí kan ló sọ pé àwọ́n ti bínú jáde nínú ilé ìtajà kan láìra ohunkóhun nínú ọdún tó kọjá látàrí èyí. Ìdajì sọ pé àwọ́n sábà máa ń rí i táwọn èèyàn á máa pariwo sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù alágbèéká tàbí kí wọ́n máa lò ó lọ́nà tó ń múnú bíni. Awakọ̀ mẹ́fà nínú mẹ́wàá sì sọ pé gbogbo ìgbà làwọ́n máa ń rí i táwọn èèyàn máa ń wakọ̀ lọ́nà tí kò bójú mu rárá tàbí lọ́nà àìbìkítà.”

Báwo Ni Ìwàláàyè Èèyàn Ṣe Ṣeyebíye Tó?

Ìgbà mìíràn wà táwọn èèyàn á sọ pé àwọ́n ní “àwọn ìlànà dáradára” kan tí àwọ́n ń tẹ̀ lé, àmọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu lásán lèyí sábà máa ń jẹ́, wọn kì í fi ṣèwà hù. Bí àpẹẹrẹ, Àjọ Tó Ń Rí sí Híhu Ìwà Ọmọlúwàbí Lágbàáyé fọ̀rọ̀ wá àwọn èèyàn kan tí wọ́n ṣojú fún ogójì orílẹ̀-èdè lẹ́nu wò. Ìdá ogójì nínú ọgọ́rùn-ún wọn ló mú “bíbọ̀wọ̀ fún ìwàláàyè” gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ìlànà rere márùn-ún tó ṣe “pàtàkì jù lọ.” a

Àmọ́, kí là ń rí nínú ìwà àwọn èèyàn? Kò sí tàbí ṣùgbọ́n pé àwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ lágbàáyé ní àwọn ohun tí wọ́n lè fi mú púpọ̀ nínú ìyà tó ń jẹ aráyé kúrò. Àmọ́, ìwé kan tí Carol Bellamy, tó jẹ́ olùdarí àgbà fún Àjọ Tí Ń Bójú Tó Àkànlò Owó Tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ṣètò fún Àwọn Ọmọdé kọ sọ lọ́dún 1998 pé, àìjẹunrekánú “ló ń fa ikú ohun tó ju ìlàjì lọ lọ́dọọdún nínú nǹkan bíi mílíọ̀nù méjìlá àwọn ọmọ tí kò tíì pé ọdún márùn-ún tí wọ́n ń kú láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Àwọn èèyàn ò tíì kú tó bẹ́ẹ̀ rí látìgbà tí àrùn Black Death ti pa àwọn èèyàn lọ rẹ́kẹrẹ̀kẹ ní ilẹ̀ Yúróòpù ní ọ̀rúndún kẹrìnlá.” Irú àwọn ìròyìn báwọ̀nyí máa ń dáyà já ẹnikẹ́ni tó bá mọyì ìwàláàyè ẹ̀dá èèyàn. Bellamy fi kún un pé: “Síbẹ̀, ìṣòro àìjẹunrekánú tó kárí ayé yìí kò jẹ́ nǹkan kan lójú àwọn tó lè wá nǹkan ṣe sí i, láìka bí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe túbọ̀ ń fẹ̀rí hàn sí i nípa àwọn ewu tó wà nínú ìṣòro náà. Bí èrè àwọn iléeṣẹ́ ńláńlá ṣe máa túbọ̀ lọ sókè sí i lọ́jà àgbáyé ni wọ́n ń fojoojúmọ́ ayé gbọ́ dípò tí wọn ì bá fi ṣú já ìparun ńláǹlà tí ìṣòro àìjẹunrekánú lè fà tàbí àwọn àǹfààní pàtàkì tó wà bákan náà nínú jíjẹ oúnjẹ aṣaralóore.”

Ojú ṣákálá táwọn èèyàn fi ń wo ìwàláàyè ẹ̀dá èèyàn ti fara hàn lágbo ìmọ̀ ìṣègùn náà. Lóhun tí kò tíì pẹ́ rárá sígbà tá a wà yìí, ìyẹn níbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1970, bí wọ́n bá bí ọmọ kan lọ́mọ oṣù mẹ́fà, kò dájú pé ọmọ náà á yè. Àmọ́ lọ́jọ́ òní, ohun tó tó ìdá ogójì nínú ọgọ́rùn-ún irú àwọn ọmọ tóṣù wọn ò pé bẹ́ẹ̀ ló ṣeé ṣe kí wọ́n yè é. Ẹ ò rí i pé ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé, pẹ̀lú ìtẹ̀síwájú yìí, oyún tí wọ́n fojú bù pé àwọn èèyàn ń ṣẹ́ dà nù jákèjádò ayé lọ́dọọdún tó ogójì mílíọ̀nù sí ọgọ́ta mílíọ̀nù! Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn oyún tí wọ́n ń ṣẹ́ wọ̀nyí ló sì jẹ́ pé ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan péré ló kù kí wọ́n tó àwọn ọmọ tóṣù wọn ò pé táwọn dókítà ń ṣiṣẹ́ àṣelàágùn láti gbà là! Ǹjẹ́ èyí kò fi hàn pé ńṣe ni ìlànà ìwà rere túbọ̀ ń jó àjórẹ̀yìn sí i lọ́nà kíkàmàmà?

Aráyé Nílò Ìtọ́sọ́nà Láti Mọ Ohun Tó Tọ́

Nígbà tí Àjọ Aṣèwádìí tó ń jẹ́ Gallup béèrè ìbéèrè náà, “Kí ni kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì rárá nígbèésí ayé?” lọ́wọ́ àwọn èèyàn, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló sọ pé “ṣíṣe gbogbo ohun tí ìsìn mi bá sọ” wà lára ohun méjì tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. Abájọ tó jẹ́ pé ńṣe ni iye àwọn tó ń lọ sí sọ́ọ̀ṣì ń fi ojoojúmọ́ dín kù. Ọ̀jọ̀gbọ́n Inglehart sọ pé, aásìkí táwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn ayé ń gbádùn ti “mú kí ọkàn wọn balẹ̀ lọ́nà tí kò tíì sírú ẹ̀ rí” àti pé “èyí ti mú kí àwọn èèyàn má fi bẹ́ẹ̀ rí ìwúlò ìfọ̀kànbalẹ̀ tí ìsìn ti máa ń pèsè látọjọ́ pípẹ́.”

Báwọn èèyàn ò ṣe fi bẹ́ẹ̀ ní ìgbọ́kànlé nínú ìsìn mọ́ náà ni wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ní ìgbọ́kànlé nínú Bíbélì mọ́. Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe káàkiri àgbáyé, wọ́n béèrè lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò pé ta ni wọ́n máa ń gbára lé tàbí kí ni wọ́n máa ń gbára lé nígbà tó bá di ọ̀ràn mímọ irú ìwà tó tọ́ láti hù. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn ló sọ pé àtinú ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sáwọn rí làwọ́n ti máa ń kẹ́kọ̀ọ́. Àbọ̀ ìwádìí náà ni pé: “Ipò kejì lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún ni wọ́n fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí nínú àwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì nígbèésí ayé.”

Abájọ tó fi jẹ́ pé ńṣe làwọn ìlànà tó ń yí padà ń jẹ́ kí ayé bà jẹ́ sí i! Àìsí ìtọ́sọ́nà fún ìwà rere, pa pọ̀ pẹ̀lú ìlépa ọrọ̀ lójú méjèèjì àti ìwà tèmi-nìkan-ṣáá, ti jẹ́ kí ojúkòkòrò àti àìbìkítà fún ìmọ̀lára àwọn ẹlòmíràn gbòde kan. Àwọn ohun pàtàkì wo la ti gbé sọ nù látàrí àwọn ìyípadà wọ̀nyí?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní ohun tó lé ní àádọ́ta ọdún sẹ́yìn, àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tẹ́wọ́ gba Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lágbàáyé. Ẹ̀ka Àkọ́kọ́ nínú Ìpolongo náà sọ pé: “Gbogbo èèyàn la bí lómìnira, tí wọ́n sì dọ́gba ní ti iyì àti ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn.”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]

Ìpínyà ìdílé, àìkáràmáásìkí iṣẹ́, àti ìwà ewèlè ló ń fi ìlànà rere tí ń jó rẹ̀yìn hàn lónìí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Àìlóǹkà àwọn ọmọ, tó jẹ́ pé ọ̀sẹ̀ díẹ̀ péré ló kù kí wọ́n tó ọmọ tí oṣù rẹ̀ kò pé yìí, làwọn èèyàn ń ṣẹ́ dà nù lọ́dọọdún