Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ọmọ Ogun Tó Ń Yan Lọ!

Àwọn Ọmọ Ogun Tó Ń Yan Lọ!

Àwọn Ọmọ Ogun Tó Ń Yan Lọ!

“Abúlé kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́lé sí lọ́wọ́ là ń gbé ní orílẹ̀-èdè Belize, igbó púpọ̀ sì yí àrọko náà ká. Lówùúrọ̀ ọjọ́ kan, ní nǹkan bí agogo mẹ́sàn-án, ńṣe làwọn ọmọ ogun kan ya bo ilé wa. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìjàlọ bẹ̀rẹ̀ sí gba abẹ́ ilẹ̀kùn àti gbogbo inú ihò tí wọ́n rí wọlé, tí wọ́n ń wá ohun tí wọ́n máa jẹ. Kò sí ohunkóhun tá a lè ṣe ju pé ká fi ilé wa sílẹ̀ fún nǹkan bíi wákàtí kan sí méjì tí àwọn ìjàlọ náà fi kún inú ilé bámúbámú. Nígbà tá a fi máa wọlé padà, wọ́n ti jẹ gbogbo kòkòrò tó wà nínú ilé wa tán pátápátá, àwọn ìjàlọ náà sì ti wábi gbà.”

ÌṢẸ̀LẸ̀ YÌÍ KÌ Í ṢE ohun àjèjì sí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbé nílẹ̀ olóoru, irú bí orílẹ̀-èdè Belize, kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ bí wọn nínú. Ó jẹ́ ọ̀nà kan láti palẹ̀ àwọn kòkòrò ayọnilẹ́nu bí aáyán àtàwọn eku mọ́ kúrò nínú ilé. Láfikún sí i, pàǹtírí kankan kì í ṣẹ́ kù sílẹ̀.

Lọ́nà tó gbàfiyèsí, ńṣe làwọn ìjàlọ tá à ń sọ níbí yìí máa ń ṣe bí ológun nínú gbogbo ìgbòkègbodò wọn. a Dípò kí wọ́n kọ́ ibùgbé tí wọ́n á máa gbé títí lọ, ńṣe làwọn ọmọ ogun tó máa ń ṣí kiri wọ̀nyí, tí iye wọn lè tó ọ̀kẹ́ méje ààbọ̀ [150,000] nígbà míì, máa ń ṣe ibùgbé onígbà kúkúrú. Ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe èyí ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjàlọ wọ̀nyí á fi ẹsẹ̀ kọ́ ara wọn lẹ́sẹ̀ láti ṣe ògiri yíká yèyé ìjàlọ tí ń pamọ àtàwọn ọmọ ìjàlọ tíntìntín tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí. Látinú ibùgbé onígbà kúkúrú tí wọ́n ṣe yìí ni wọ́n á ti rán àwọn ìjàlọ tó jẹ́ ọmọ ogun jáde láti lọ wá oúnjẹ, ìyẹn oúnjẹ bíi kòkòrò tàbí àwọn ìṣẹ̀dá kéékèèké bí aláǹgbá, ńṣe làwọn ológun wọ̀nyí á sì tò tẹ̀lé ara wọn ní ìlà gígùn. Àwọn ìjàlọ tó jẹ́ aṣáájú nínú ẹgbẹ́ ológun náà tún máa ń ṣe ohun kan láti fi mú kòkòrò tí wọ́n á pa jẹ, ìyẹn ni pé wọ́n máa ń ya sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀tún àti sẹ́gbẹ̀ẹ́ òsì kúrò nínú ìlà gbọọrọ náà. Èyí máa ń wáyé nígbà tó bá di pé kò sí kòkòrò kankan tí wọ́n ń tọpasẹ̀ rẹ̀, lákòókò yìí, àwọn ìjàlọ tó jẹ́ aṣáájú á tẹsẹ̀ dúró, wọ́n á sì mú kí gbogbo ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ náà dúró sójú kan. Ńṣe làwọn ìjàlọ tó wà lọ́wọ́ ẹ̀yìn á rọ́ gììrì síwájú, tí àwọn ìjàlọ tó wà lọ́wọ́ iwájú á sì máa ṣù jọ sí ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ìlà náà, èyí á sì mú kí àwọn ọmọ ogun náà máa ya sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀tún àti sẹ́gbẹ̀ẹ́ òsì.

Ọjọ́ mẹ́rìndínlógójì làwọn kòkòrò wọ̀nyí fi máa ń ṣe gbogbo ìgbòkègbodò wọn. Wọ́n á fi ọjọ́ mẹ́rìndínlógún yan lọ, wọ́n á sì sinmi fún ogún ọjọ́, láàárín àkókò yìí sì tún ni yèyé ìjàlọ tí ń pamọ máa ń yé ẹyin rẹ̀. Lẹ́yìn èyí, ebi á mú kí àwùjọ àwọn kòkòrò náà tún yan lọ lẹ́ẹ̀kan sí i, ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ wọn sì lè fẹ̀ tó mítà mẹ́wàá. Àwọn nǹkan bí aláǹtakùn, àkekèé, yímíyímí, àkèré àti aláǹgbá tó ń sá fún wọn á wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀tún àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ òsì, bẹ́ẹ̀ làwọn ẹyẹ á máa tẹ̀ lé wọn, àmọ́ kì í ṣe láti jẹ àwọn ìjàlọ wọ̀nyí bí kò ṣe torí àtijẹ àwọn kòkòrò tó ń sá fún wọn.

Nínú Bíbélì, Òwe 30:24, 25 sọ pé àwọn ìjàlọ “ní ọgbọ́n àdámọ́ni,” nítorí náà, wọ́n jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun àgbàyanu ìṣẹ̀dá.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àpilẹ̀kọ yìí ń sọ̀rọ̀ nípa irú ìjàlọ kan tó ń jẹ́ Eciton, èyí tó wà ní Àárín Gbùngbùn àti Gúúsù Amẹ́ríkà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Ìjàlọ

[Credit Line]

© Frederick D. Atwood

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Ṣíṣe afárá nípa fífi ẹsẹ̀ kọ́ ara wọn lẹ́sẹ̀

[Credit Line]

Tim Brown/www.infiniteworld.org