Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìlànà Rere Tó Ń Jó Àjórẹ̀yìn Yìí Ipa Wo Ló Ń ní Lórí rẹ?

Ìlànà Rere Tó Ń Jó Àjórẹ̀yìn Yìí Ipa Wo Ló Ń ní Lórí rẹ?

Ìlànà Rere Tó Ń Jó Àjórẹ̀yìn Yìí Ipa Wo Ló Ń ní Lórí rẹ?

“KÍ NI ìṣòro títóbi jù lọ tó ń kojú orílẹ̀-èdè yìí?” Nígbà tí wọ́n béèrè ìbéèrè yìí lọ́wọ́ àwọn tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, èyí tó pọ̀ jù nínú wọn sọ pé bí ìdílé àti ìwà rere ṣe ń dìdàkudà ni ìṣòro tó tóbi jù tàbí kí ìwọ̀nyí wà lára àwọn ìṣòro náà. Àmọ́, kì í ṣe àwọn nìkan ní ìṣòro yìí kàn.

Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn ojoojúmọ́ kan ní ìlú Paris, tó ń jẹ́ International Herald Tribune sọ pé: “Ó hàn gbangba pé àwọn èèyàn, pàápàá àwọn ọ̀dọ́, ń yán hànhàn fún èròǹgbà kan tó máa lè so ayé pọ̀ ṣọ̀kan lọ́jọ́ iwájú. Wọ́n ń fẹ́ àwọn ìlànà kan tí gbogbo èèyàn á tẹ́wọ́ gbà láti kápá àwọn ohun tó ń fa ojúkòkòrò, ìmọtara-ẹni-nìkan àti àìsí ìfọwọ́sowọ́pọ̀, àwọn ìwà tó dà bíi pé ó ti ń gbilẹ̀ kárí ayé. . . . Àríyànjiyàn tó túbọ̀ ń peléke sí i yìí, nípa ìdí tó fi ṣe pàtàkì kí aráyé ní àwọn ìlànà ìwà híhù kan tí gbogbo èèyàn á máa tẹ̀ lé, fi hàn pé nǹkan ti wọ́.”

Ǹjẹ́ o rò pé àwọn ìjọba àtàwọn aṣáájú ayé, títí kan àwọn oníṣòwò kàǹkàkàǹkà lágbàáyé, ní àwọn ìlànà ìwà rere tá a nílò láti mú kí ọjọ́ ọ̀la wa dùn ju báyìí lọ, kí ààbò pọ̀ sí i, kí ọkàn wa sì túbọ̀ balẹ̀? Ǹjẹ́ bí ayé ṣe ń bà jẹ́ yìí ń kọ ìwọ náà lóminú?

Kókó kan tó lè máa kódààmú bá ọ gidigidi ni bó o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ. Ṣé ibi téèyàn ti lè fi ilẹ̀kùn ilé rẹ̀ sílẹ̀ láìfi kọ́kọ́rọ́ tì í lò ń gbé? Ṣé o lè rìn lójú pópó ládùúgbò rẹ lálẹ́ láìsí ìbẹ̀rù kankan? Ká tiẹ̀ ní àgbègbè tí kò sí ogun, wàhálà ẹlẹ́yàmẹ̀yà tàbí ìjà láàárín àwọn ẹgbẹ́ ọ̀daràn tó lè gbẹ̀mí ẹni lò ń gbé, síbẹ̀ o lè máa bẹ̀rù pé ẹnì kan lè ṣe ọ́ ní jàǹbá, pé àwọn kan lè wá kọ lù ọ́, tàbí kí àwọn kan fipá wọlé rẹ kí wọ́n sì jà ọ́ lólè. Ó dájú pé àwọn nǹkan wọ̀nyí á máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá ọ, wọ́n sì lè fayé sú ọ.

Kò tán síbẹ̀ o, ó ṣeé ṣe kó o má fi bẹ́ẹ̀ finú tán àwọn ẹlòmíràn mọ́ bíi tìgbà kan. Látinú ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí ọ, bóyá lẹ́nu iṣẹ́ tàbí nínú ìgbésí ayé rẹ, o lè ti rí i lọ́pọ̀ ìgbà pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé wọn ò kọ̀ láti ṣàkóbá fún ọ tàbí láti rẹ́ ọ jẹ bí wọ́n bá ṣáà ti máa rí àǹfààní kan níbẹ̀, kódà bí àǹfààní ọ̀hún ò tiẹ̀ pọ̀.

Àwọn Èèyàn Nílò Àpẹẹrẹ Rere Látọ̀dọ̀ Ìjọba

Látọjọ́ táláyé ti dáyé, gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé àwọn ìlànà tí ìjọba kan bá ń fi ṣèwà hù làwọn èèyàn irú àwùjọ bẹ́ẹ̀ náà á máa hù níwà. Calvin Coolidge, tó wá di ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nígbà tó yá, sọ nígbà kan pé: “Àwọn ẹ̀dá èèyàn máa ń sọ pé kálukú ló ní ẹ̀tọ́ tí Ẹlẹ́dàá ti dá mọ́ wọn, àmọ́ màá fẹ́ kí ẹnì kan wá ṣàlàyé fún mi ibi tí ẹ̀tọ́ kankan wà láyé yìí tàbí tí wọ́n ti mọ nǹkan tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé ìjọba ṣe àwọn òfin kan jáde tó jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa irú àwọn ẹ̀tọ́ bẹ́ẹ̀.”

Ju gbogbo rẹ̀ lọ, àwọn tó ń ṣàkóso, láìka ọ̀nàkọnà tí wọ́n gbà dé ipò náà sí, ló lè mú kí àwọn ẹ̀tọ́ aráàlú di èyí tá a bọ̀wọ̀ fún tàbí èyí tá a tẹ̀ lójú, irú bí òmìnira láti gbé ìròyìn jáde, òmìnira láti péjọ pọ̀, òmìnira ìsìn àti òmìnira láti sọ̀rọ̀ ní gbangba. Àwọn ẹ̀tọ́ mìíràn tún ni pé kí ìjọba má ṣe fàṣẹ ọba múni láìbófinmu tàbí kí wọ́n máa halẹ̀ mọ́ni, àti gbígbọ́ ẹjọ́ àwọn èèyàn láìṣe ojúsàájú.

Abraham Lincoln, tóun náà wá di ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nígbà tó yá, sọ nígbà kan pé: “Pàtàkì ohun tí ìjọba wà fún ni láti ṣe ohun tí àwùjọ èèyàn kan bá nílò fún wọn, èyí tó yẹ kí wọ́n ṣe fúnra wọn àmọ́ tí agbára wọn kò gbé e rárá tàbí tí wọn kò lè ṣe dáadáa fúnra wọn láìsí olùrànlọ́wọ́.” Nígbà tí ìjọba bá sapá láti gbé àwọn ohun ńláǹlà bẹ́ẹ̀ ṣe, àwọn èèyàn máa ń ní ìgbọ́kànlé nínú àwọn tó ń ṣàkóso.

Àmọ́ lónìí, ó dà bíi pé àríwísí táwọn èèyàn ń ṣe nípa wọn àti bí wọ́n ṣe ń fura sí wọn ti rọ́pò irú ìgbọ́kànlé àti ìfọkàntánni bẹ́ẹ̀. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé ìdá méjìdínláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló sọ pé ìwà táwọn tó jẹ́ lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba ń hù kàn máa ń sàn díẹ̀ ni tàbí kó tiẹ̀ burú pàápàá. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn ìwàkiwà táwọn aláṣẹ ìjọba máa ń hù, irú bíi gbígba rìbá àti kíkówójẹ, kò jẹ́ káwọn èèyàn fojú gidi wò wọ́n mọ́. Kò sí àní-àní pé, ohun tó fà á rèé tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi fọkàn tán àwọn alákòóso mọ́.

Àpẹẹrẹ Rere Sólómọ́nì Ọba

Àpẹẹrẹ ayé ọjọ́un kan á jẹ́ ká rí i bí ìlànà táwọn aláṣẹ ń tẹ̀ lé ṣe lè nípa lórí àwọn èèyàn tí wọ́n ń ṣàkóso lé lórí. Sólómọ́nì Ọba ṣàkóso lórí ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá láti ọdún 1037 sí 998 ṣáájú Sànmánì Tiwa. Ọ̀kan lára àwọn ọba tó ṣàkóso dáadáa ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì ni Dáfídì Ọba tó jẹ́ bàbá rẹ̀. Bíbélì sọ pé Dáfídì jẹ́ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti òdodo, àti ní pàtàkì jù lọ, ó jẹ́ ẹni tó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run tó sì ní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀. Dáfídì fi àwọn ìlànà wọ̀nyí kọ́ Sólómọ́nì.

Ọlọ́run Olódùmarè fara han Sólómọ́nì nínú àlá ó sì sọ fún un pé: “Béèrè! Kí ni kí n fún ọ?” (2 Kíróníkà 1:7) Dípò tí Sólómọ́nì ì bá fi béèrè ọrọ̀, tàbí ògo fúnra rẹ̀, tàbí pé kí òun rẹ́yìn àwọn tó bá gbógun ti òun nídìí ọ̀ràn ìṣèlú, ó fi àwọn ìlànà tó ṣeyebíye lójú rẹ̀ hàn nípa bíbẹ̀bẹ̀ fún ọkàn tó kún fún ọgbọ́n, òye, àtèyí tó máa lè ṣègbọràn, kó bàa lè ṣeé ṣe fún un láti jẹ́ ọba rere fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì.

Báwo ni ìṣàkóso Sólómọ́nì ṣe rí lára àwọn èèyàn náà? Ọlọ́run fi ọgbọ́n, ògo àti ọrọ̀ jíǹkí rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tó tẹ̀ lé àwọn ìlànà tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ fún orílẹ̀-èdè náà. Àwọn nǹkan táwọn awalẹ̀pìtàn hú jáde jẹ́rìí sí i pé aásìkí rẹpẹtẹ wà nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì. Ìwé kan tó ń jẹ́ The Archaeology of the Land of Israel sọ pé: “Ọrọ̀ tó ń ya wọ ààfin ọba náà láti gbogbo ọ̀nà, àti ọrọ̀ ajé tó ń búrẹ́kẹ́ . . . mú ìyípadà tó kàmàmà tó sì yára kánkán wá ní gbogbo apá ẹ̀ka ìjọba náà.”

Dájúdájú, ìṣàkóso rere Sólómọ́nì mú àlááfíà, ààbò, àti ayọ̀ wá fún àwọn tó ń ṣàkóso lé lórí. “Júdà àti Ísírẹ́lì . . . ń bá a lọ ní gbígbé ní ààbò, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà tirẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ tirẹ̀, láti Dánì dé Bíá-ṣébà, ní gbogbo ọjọ́ Sólómọ́nì.”—1 Àwọn Ọba 4:20, 25.

Àpẹẹrẹ Búburú Sólómọ́nì Ọba

Àmọ́, ó báni nínú jẹ́ pé, bíi ti ìlànà ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú láyé òde òní, àwọn ìlànà tí Sólómọ́nì ń tẹ̀ lé yí padà nígbà tó yá. Àkọsílẹ̀ Bíbélì sọ pé: “Ó . . . wá ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin aya, àwọn ọmọbìnrin ọba, àti ọ̀ọ́dúnrún wáhàrì; ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn aya rẹ̀ tẹ ọkàn-àyà rẹ̀. Ó sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí Sólómọ́nì ń darúgbó lọ pé àwọn aya rẹ̀ alára ti tẹ ọkàn-àyà rẹ̀ láti tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn; ọkàn-àyà rẹ̀ kò sì pé pérépéré pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkàn-àyà Dáfídì baba rẹ̀.”—1 Àwọn Ọba 11:3, 4.

Ipa wo ni àwọn ìlànà Sólómọ́nì Ọba tó yí padà yìí ní lórí àwọn èèyàn rẹ̀? Láìka ọgbọ́n àti òye ńláǹlà tí Sólómọ́nì ní sí, ó di alákòóso rírorò ní apá ìparí ìṣàkóso rẹ̀. Ìná àpà tí ìjọba rẹ̀ ń náwó mú kí ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè náà dẹnu kọlẹ̀ pátápátá. Àwọn òṣìṣẹ́ kò ní ìtẹ́lọ́rùn mọ́. Àwọn tó ń bá a du ìjọba kọjú ìjà sí i wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti gba ipò lọ́wọ́ rẹ̀. Ìṣọ̀kan tó ti wà ní orílẹ̀-èdè náà tẹ́lẹ̀ rí fẹ́rẹ̀ẹ́ pòórá pátápátá. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé òdìkejì ohun tí Sólómọ́nì fúnra rẹ̀ kọ sílẹ̀ ló wá ṣe, ìyẹn ni pé: “Nígbà tí olódodo bá di púpọ̀, àwọn ènìyàn a máa yọ̀; ṣùgbọ́n nígbà tí ẹni burúkú bá ń ṣàkóso, àwọn ènìyàn a máa mí ìmí ẹ̀dùn.”—Òwe 29:2.

Láìpẹ́ sígbà tí Sólómọ́nì kú, rúkèrúdò ìṣèlú àti àìfọkàntánni mú kí orílẹ̀-èdè náà pín sí méjì, ìnira, àìfohùnṣọ̀kan àtàwọn ìṣòro mìíràn lóríṣiríṣi sì gbalẹ̀ kan. Gbogbo nǹkan wá tojú sú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pátápátá. Ìjọba wọn ti yí àwọn ìlànà rere rẹ̀ padà, kò sì bìkítà mọ́ nípa ohun tó máa ṣe àwọn èèyàn náà láǹfààní jù lọ. Olórí àṣìṣe wọn ni pé, àwọn aṣáájú wọn kò ka Jèhófà àtàwọn òfin rẹ̀ sí mọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo orílẹ̀-èdè náà látòkèdélẹ̀ ló forí fá ìyà ọ̀hún.

Àìfọkàntánni Gbalé Ayé Kan

Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn alákòóso, àwọn ṣòwòṣòwò, àtàwọn tó gbé ẹ̀sìn karí ni kò fi bẹ́ẹ̀ ka títẹ̀lé àwọn ìlànà rere sí ohun pàtàkì mọ́. Èyí ti wá mú kí gbogbo nǹkan tojú sú àwọn èèyàn lápapọ̀. Bẹ́ẹ̀ làwọn ìṣòro tó ń kojú àwọn orílẹ̀-èdè túbọ̀ ń di èyí tí apá àwọn ìjọba àtàwọn aṣáájú mìíràn kò ká.

Bí àpẹẹrẹ, wọn ò lè fòpin sí ogun tàbí kí wọ́n dín iye tí àwọn èèyàn ń ná lórí àìsàn kù, èyí tó túbọ̀ ń ròkè sí i, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò lè wá ojútùú sí àbájáde burúkú tí ṣíṣe fàyàwọ́ oògùn olóró ń mú wá. Bákan náà ni ètò ẹ̀kọ́ ti dorí kodò. Àní, àwọn ìjọba kan tiẹ̀ ń ṣonígbọ̀wọ́ fún àwọn iléeṣẹ́ tó ń ṣètò tẹ́tẹ́ títa. Láfikún sí i, ọ̀pọ̀ àwọn lóókọlóókọ nídìí òwò àti ẹ̀sìn ti já àwọn èèyàn kulẹ̀ lọ́nà tó burú jáì nítorí ìwà pálapàla àti ìwà jẹgúdújẹrá wọn. Abájọ tí àìsí ìgbọ́kànlé nínú àwọn táwọn èèyàn ń wò pé ó yẹ kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ fi gbayé kan.

Ǹjẹ́ ìjọba kan tiẹ̀ wà tó lè rí sí i pé ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn tó ṣe kókó tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́, kí wọ́n sì fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ nínú mímú kí ìlànà ìwà rere fẹsẹ̀ múlẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni o, ó ṣeé ṣe. Àpilẹ̀kọ wa tó kẹ́yìn yóò ṣàlàyé bí èyí ṣe lè rí bẹ́ẹ̀.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]

‘Ó dà bíi pé ojúkòkòrò, ìmọtara-ẹni-nìkan, àti àìsí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ti ń gbilẹ̀ kárí ayé.’—ÌWÉ ÌRÒYÌN INTERNATIONAL HERALD TRIBUNE

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Nígbà tí Sólómọ́nì Ọba pa òfin Ọlọ́run mọ́, ó ṣeé ṣe fún un láti gbin àwọn ìlànà tó dára gan-an sọ́kàn àwọn tó ń ṣàkóso lé lórí