Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Ìṣòro Jíjẹ́ Ọmọ Àgbàtọ́?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Ìṣòro Jíjẹ́ Ọmọ Àgbàtọ́?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Ìṣòro Jíjẹ́ Ọmọ Àgbàtọ́?

“Mi ò mọ nǹkan kan rárá nípa àwọn òbí tó bí mi lọ́mọ, ìyẹn sì máa ń múnú bí mi gidigidi.” —Barbara, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún.

“Mi ò tiẹ̀ mọ nǹkan kan páàpáà nípa ibi tí wọ́n bí mi sí gan-an tàbí àwọn òbí tó bí mi lọ́mọ. Nígbà míì, mo máa ń ronú nípa rẹ̀ láàárín òru.” —Matt, ọmọ ọdún mẹ́sàn-án.

“Nígbà tí mo bá ń bá àwọn alágbàtọ́ mi ṣe awuyewuye, mo máa ń ronú pé ó ṣeé ṣe kí àwọn òbí mi gan-gan lóye mi jù wọ́n lọ. Mo mọ̀ pé kò yẹ kí n máa ní irú èrò tí kò tọ́ bẹ́ẹ̀ lọ́kàn, àmọ́ mi ò sọ ọ́ létí wọn rí.” —Quintana, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún.

LÁÌSÍ àní-àní, jíjẹ́ ọmọ àgbàtọ́ ní àwọn ìṣòro tiẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ ni irú àwọn èrò bí irú èyí tá a mẹ́nu kàn lókè yìí máa ń wà lọ́kàn wọn. Ọ̀pọ̀ lára wọn máa ń wò ó pé bóyá káwọn ṣèwádìí láti mọ àwọn òbí àwọn gan-gan tàbí kí wọ́n máa ronú pé bóyá ayé àwọn ì bá dùn ju bó ṣe rí yìí lọ ká ní ọ̀dọ̀ wọn ni àwọ́n ń gbé. Ṣùgbọ́n, kì í ṣe ìwọ̀nyí nìkan làwọn ìṣòro tí wọ́n ń kojú.

Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú lórí kókó yìí, a jíròrò díẹ̀ lára àwọn èrò tí kò tọ́ tí àwọn ọ̀dọ́ kan tí wọ́n gbà tọ́ máa ń ní nípa ara wọn. a Gbígbógun ti irú àwọn èrò tí ń múni rẹ̀wẹ̀sì bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì tó o bá fẹ́ láti gbádùn ayé rẹ gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí wọ́n gbà tọ́. Àmọ́, kí ni díẹ̀ lára àwọn ìṣòro mìíràn tó lè jẹ yọ, kí sì làwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì tó o lè gbé láti kojú wọn?

Ṣé Òbí Ni Wọ́n Jẹ́ fún Mi Lóòótọ́?

Ọmọkùnrin ọlọ́dún mẹ́tàlá kan tó ń jẹ́ Jake sọ pé òun máa ń ronú ṣáá nípa ìyá tó bí òun lọ́mọ. Èyí ni kò jẹ́ kí àjọṣe òun àtàwọn alágbàtọ́ rẹ̀ gún régé. Ó sọ pé: “Nígbàkigbà tí orí mi bá ń gbóná, ohun tí mo máa ń sọ ni pé, ‘Ìwọ kọ́ ni ìyá mi kẹ̀—o ò kàn lè máa fi ìyà jẹ mí bẹ́ẹ̀ yẹn!’”

Bí ìwọ náà ṣe rí ọ̀rọ̀ yìí sí, ìbéèrè pàtàkì kan wà tí Jake ní láti wá ìdáhùn sí, ìyẹn ni pé: Ta ló yẹ kó kà sí ìyá rẹ̀? Bó bá jẹ́ pé wọ́n gbà ọ́ tọ́ ni, irú ìbéèrè yìí lè máa jà gùdù lọ́kàn rẹ, pàápàá bó o bá ń ronú pé ó ṣeé ṣe kí àwọn òbí rẹ gan-gan bójú tó ọ dáadáa ju bí àwọn alágbàtọ́ rẹ ṣe ń ṣe lọ. Àmọ́, ṣé bíbímọ sáyé nìkan ló ń fi hàn pé èèyàn jẹ́ òbí?

Ìyá tó jẹ́ alágbàtọ́ Jake kò rò bẹ́ẹ̀ o. Jake sọ pé: “Ìyá tó tọ́ mi máa ń sọ pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni o, èmi gan-an ni ìyá rẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀tọ̀ lẹni tó bí ẹ, èmi ni ìyá rẹ báyìí.’” Nígbà tí tọkọtaya kan bá gba ọmọ kan sọ́dọ̀ wọn láti máa bójú tó o, láti máa gbọ́ bùkátà lórí rẹ̀, àti láti máa tọ́ ọ, ní tòótọ́ wọ́n ti di òbí fún ọmọ náà nìyẹn. (1 Tímótì 5:8) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí ìjọba orílẹ̀-èdè tó ò ń gbé kà wọ́n sí náà nìyẹn. Àmọ́, ǹjẹ́ Ọlọ́run kà wọ́n sí òbí rẹ gan-gan?

Gbé ọ̀ràn ọmọ kan tó gbé ọ̀dọ̀ alágbàtọ́ yẹ̀ wò, ìyẹn Jésù Kristi. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èyí ni ọ̀ràn gbígba ọmọ tọ́ tó lókìkí jù lọ nínú ìtàn. Jésù kì í ṣe ọmọ bíbí Jósẹ́fù tó jẹ́ káfíńtà, síbẹ̀ Jósẹ́fù gbà láti máa tọ́ Jésù gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ gan-gan. (Mátíù 1:24, 25) Bí Jésù ṣe ń dàgbà, ǹjẹ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ̀tẹ̀ sí ọlá àṣẹ Jósẹ́fù? Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù mọ̀ pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí òun ṣègbọràn sí bàbá tó gba òun ṣọmọ. Jésù mọ̀ nípa òfin kan tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dáadáa. Òfin wo nìyẹn?

Bọlá fún Baba Rẹ àti Ìyá Rẹ

Ìwé Mímọ́ sọ fún àwọn èwe pé: “Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.” (Diutarónómì 5:16) Bíbélì sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà, ‘bíbọlá fúnni’ láti tọ́ka sí bíbọ̀wọ̀ fúnni, bíbuyì fúnni, àti gbígba ti ẹni rò. O lè máa fi irú ọlá bẹ́ẹ̀ hàn sí àwọn alágbàtọ́ rẹ nípa jíjẹ́ onínúure sí wọn, bíbọ̀wọ̀ fún ipò wọn gẹ́gẹ́ bí òbí, wíwà ní ìfohùnṣọ̀kan pẹ̀lú wọn, àti wíwà ní ìmúratán láti ṣe ohunkóhun tí wọ́n bá ní kó o ṣe, níwọ̀n ìgbà tí ohun náà bá ti tọ̀nà.

Àmọ́, kí ló yẹ kó o ṣe láwọn ìgbà tó bá dà bíi pé àwọn alágbàtọ́ rẹ kò ṣe ohun tó o rò pé ó tọ̀nà? Kò sí àní-àní pé ìyẹn á máa ṣẹlẹ̀. Gbogbo òbí ló jẹ́ aláìpé, ì báà jẹ́ alágbàtọ́ tàbí òbí tó bí ọ lọ́mọ. Wíwo àwọn àléébù wọn lè mú kó nira gan-an fún ọ láti ṣègbọràn sí wọn. Abájọ tó fi jẹ́ pé nírú àwọn ìgbà bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o máa ronú pé ọmọ tí wọ́n gbà tọ́ kúkú ni ọ́, torí náà bóyá kò yẹ kó o ṣègbọràn sí wọn nítorí ìyẹn. Àmọ́, ǹjẹ́ ó yẹ kí ìyẹn dín ọ̀wọ̀ tó o ní fún wọn kù?

Ríronú nípa àpẹẹrẹ Jésù lè ràn ọ́ lọ́wọ́ lórí èyí. Rántí pé, ẹni pípé ni. (Hébérù 4:15; 1 Pétérù 2:22) Àmọ́ bàbá tó gbà á ṣọmọ kì í ṣe ẹni pípé; bẹ́ẹ̀ ni ìyá tó bí i náà kì í ṣe ẹni pípé. Nígbà náà, ó dájú pé àwọn ìgbà kan á wà tí Jésù á máa rí i pé àwọn òbí òun ṣe àṣìṣe. Ǹjẹ́ ó ṣọ̀tẹ̀ sí bí Jósẹ́fù ṣe ń lo ipò orí rẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀dá aláìpé ni tàbí bí Màríà ṣe ń ṣe àṣìṣe nínú bó ṣe ń ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyá? Rárá o. Bíbélì sọ fún wa pé bí Jésù ṣe ń dàgbà, ó “ń bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ sábẹ́” àwọn òbí rẹ̀.—Lúùkù 2:51.

Ó dára ná, nígbà tí ìwọ àtàwọn alágbàtọ́ rẹ kò bá jọ fohùn ṣọ̀kan lórí ohun kan, ó lè dá ọ lójú hán-ún hán-ún pé wọn kò tọ̀nà. Àmọ́, o ní láti gbà pé aláìpé ni ìwọ náà. Nítorí náà, ó dájú pé láwọn ìgbà míì ìwọ náà lè má tọ̀nà. Èyí ó wù kó jẹ́, ṣé ohun tó dára jù kọ́ ni pé kó o tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù? (1 Pétérù 2:21) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣègbọràn. Ṣùgbọ́n, ìdí tó túbọ̀ ṣe pàtàkì wà tó fi yẹ kó o ṣègbọràn sí àwọn òbí rẹ.

Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín nínú ohun gbogbo, nítorí èyí dára gidigidi nínú Olúwa.” (Kólósè 3:20) Dájúdájú, ṣíṣègbọràn yóò mú inú Baba rẹ ọ̀run dùn. (Òwe 27:11) Ó sì fẹ́ kó o kọ́ ìgbọràn nítorí pé ó fẹ́ kí ìwọ náà jẹ́ aláyọ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ àwọn èwe láti máa ṣègbọràn, ó sì tún fi kún un pé, “kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí ìwọ sì lè wà fún àkókò gígùn lórí ilẹ̀ ayé.”—Éfésù 6:3.

Mímú Kí Àjọṣe Ìwọ Àtàwọn Alágbàtọ́ Rẹ Túbọ̀ Dán Mọ́rán

Láti mú kí àjọṣe ìwọ àtàwọn alágbàtọ́ rẹ dán mọ́rán, àwọn ohun mìíràn wà tó o ní láti ṣe yàtọ̀ sí bíbọlá fún wọn àti ṣíṣègbọràn sí wọn. Ó dájú pé, wàá fẹ́ kí ilé yín tòrò, kí ìfẹ́ sì jọba níbẹ̀. Ojúṣe àwọn alágbàtọ́ rẹ ni láti mú kí ilé yín jẹ́ irú ibi àlàáfíà bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ìwọ náà lè kó ipa pàtàkì nínú ọ̀rọ̀ yìí. Lọ́nà wo?

Lákọ̀ọ́kọ́, wá ọ̀nà láti dojúlùmọ̀ àwọn alágbàtọ́ rẹ dáadáa. Béèrè lọ́wọ́ wọn nípa ìgbésí ayé wọn àtẹ̀yìnwá, ìrírí tí wọ́n ti ní nígbèésí ayé, àtàwọn ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí. Máa fọ̀ràn lọ̀ wọ́n bí ohun kan bá jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn fún ọ, kó o wá àsìkò tí ara tù wọ́n, tí ara wọn sì balẹ̀ láti tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ. (Òwe 20:5) Èkejì, wá ọ̀nà tó o fi lè mú kí ètò ìdílé máa lọ geerege, irú bíi ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ilé tó bá yẹ láìsí pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń sọ fún ọ.

Àmọ́, ọ̀ràn ti àwọn òbí rẹ gan-gan ńkọ́? Ká ní o pinnu láti wá wọn rí, tàbí ká ní wọ́n pinnu láti wá ọ rí, ǹjẹ́ ó yẹ kí èyí ba àjọṣe tó o ti ní pẹ̀lú àwọn alágbàtọ́ rẹ jẹ́? Láyé ìgbà kan, àwọn àjọ tó ń bójú tó ọmọdé kì í sábà fún àwọn òbí ní ìsọfúnni nípa ibi tí wọ́n ti lè rí ọmọ wọn tàbí kí wọ́n fún ọmọ ní ìsọfúnni nípa ibi tí àwọn òbí rẹ̀ wà. Àmọ́, lóde òní, àwọn ìlànà tó wà láwọn orílẹ̀-èdè kan kò fi bẹ́ẹ̀ rin kinkin lórí ọ̀ràn yìí mọ́, ó sì ti ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí wọ́n gbà tọ́ láti rí àwọn òbí wọn tí wọn ò dá mọ̀ rárá. Ṣùgbọ́n, ó ṣeé ṣe kí àwọn ìlànà orílẹ̀-èdè rẹ lórí ọ̀ràn gbígba ọmọ tọ́ yàtọ̀ sí èyí.

Bó ti wù kó rí, ìwọ fúnra rẹ lo máa pinnu, bóyá kó o wá àwọn òbí rẹ gan-gan rí tàbí kó o máà wá wọn rí, ìpinnu yìí sì lè má rọrùn láti ṣe. Èrò oríṣiríṣi ló máa ń wá sọ́kàn àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n gbà tọ́ lórí ọ̀ràn yìí. Àwọn kan máa ń yán hànhàn láti wá àwọn òbí wọn rí; àwọn mìíràn sì ti pinnu pé àwọn ò ní wá wọn. Àmọ́ ṣá o, jẹ́ kó dá ọ lójú pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tí wọ́n gbà tọ́ ló ti rí àwọn òbí wọn, láìsí pé àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú àwọn alágbàtọ́ wọn bà jẹ́.

Gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn alágbàtọ́ rẹ tàbí lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ tó dàgbà dénú nínú ìjọ Kristẹni. (Òwe 15:22) Gbé ìpinnu rẹ yẹ̀ wò dáadáa, kó o sì ro ọ̀rọ̀ náà sọ́tùn-ún sósì kó o tó gbé ìgbésẹ̀ èyíkéyìí. Òwe 14:15 sọ pé, “afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”

Bó o bá pinnu láti wá àwọn òbí rẹ gan-gan rí, sapá láti mú un dá àwọn alágbàtọ́ rẹ lójú pé o ṣì nífẹ̀ẹ́ wọn àti pé ọ̀wọ̀ tó o ní fún wọn kò ní dáwọ́ dúró. Lọ́nà yẹn, bó o ṣe ń mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn òbí rẹ tó fi ọ́ sọ́dọ̀ alágbàtọ́ nígbà pípẹ́ sẹ́yìn, àjọṣe tó wà láàárín ìwọ àtàwọn alágbàtọ́ tó tọ́ ọ dàgbà tó sì bójú tó ọ kò ní bà jẹ́.

Mú Kí Àjọṣe Ìwọ àti Baba Rẹ Ọ̀run Túbọ̀ Dán Mọ́rán

Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n gbà tọ́ ló máa ń bẹ̀rù pé àwọn òbí tó gbà wọ́n tọ́ lè pa wọ́n tì. Wọ́n máa ń ṣàníyàn pé àwọn alágbàtọ́ wọn lè fi àwọn sílẹ̀ bí àwọn òbí wọn gan-gan ṣe fi wọ́n sílẹ̀. Láìsí àní-àní, irú àwọn ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ lè máa wá sí ọ lọ́kàn. Síbẹ̀, rántí ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n yìí: “Kò sí ìbẹ̀rù nínú ìfẹ́, ṣùgbọ́n ìfẹ́ pípé a máa ju ìbẹ̀rù sóde.” (1 Jòhánù 4:18) Má ṣe jẹ́ kí ìbẹ̀rùbojo pé àwọn alágbàtọ́ rẹ lè fi ọ́ sílẹ̀ gbà ọ́ lọ́kàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, mú kí ìfẹ́ tó o ní sí àwọn ẹlòmíràn pọ̀ sí i, títí kan gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé náà. Àmọ́ ṣá o, lékè gbogbo rẹ̀, mú kí ìfẹ́ tó o ní fún Baba rẹ ọ̀run, Jèhófà Ọlọ́run, pọ̀ sí i. Atóófaratì ni, tí kò lè fi àwọn ọmọ rẹ̀ olóòótọ́ sílẹ̀ láé. Ó sì lágbára láti mú ìbẹ̀rù rẹ kúrò.—Fílípì 4:6, 7.

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Catrina, tí wọ́n gbà tọ́ nígbà tó wà lọ́mọdé, sọ pé kíka Bíbélì ti ran òun lọ́wọ́ gan-an láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run, ó sì ti jẹ́ kí ìgbésí ayé òun dùn kó sì nítumọ̀. Ó sọ pé níní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà “ṣe pàtàkì gidigidi nítorí pé Baba wa ọ̀run mọ bí ọ̀ràn ṣe rí lára wa.” Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí Catrina yàn láàyò ni Sáàmù 27:10, tó sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Wá ọ̀nà láti dojúlùmọ̀ àwọn alágbàtọ́ rẹ dáadáa