Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Dé Tí Wọ́n Tún Fi Ń Padà Wá?

Kí Ló Dé Tí Wọ́n Tún Fi Ń Padà Wá?

Kí Ló Dé Tí Wọ́n Tún Fi Ń Padà Wá?

NÍ NǸKAN bí ogójì ọdún sẹ́yìn, àwọn èèyàn rò pé àwọn àrùn tó wọ́pọ̀ gan-an, èyí tí kòkòrò ń tàn kálẹ̀, irú bí ibà pọ́njú àti ibà wórawóra, ni a ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mú kúrò tán ní ibi púpọ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Àmọ́, ohun kan táwọn èèyàn ò retí ṣẹlẹ̀—àwọn àrùn tí kòkòrò ń gbé kiri tún bẹ̀rẹ̀ sí padà wá.

Kí nìdí? Ohun kan tó fa èyí ni pé, àwọn kan lára àwọn kòkòrò náà àtàwọn àrùn tí wọ́n ń gbé kiri ti lágbára débi pé àwọn oògùn apakòkòrò àtàwọn oògùn tí wọ́n fi ń kápá wọn kò ràn wọ́n mọ́. Kì í ṣe àlòjù àwọn oògùn apakòkòrò nìkan lohun tí kì í jẹ́ kí oògùn ran àwọn kòkòrò yìí, àmọ́ àìkíílo oògùn bó ṣe yẹ tún dá kún ìṣòro yìí. Ìwé Mosquito sọ pé: “Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ agboolé àwọn akúṣẹ̀ẹ́, àwọn èèyàn á ra oògùn, wọ́n á kàn lo ìwọ̀nba tó máa jẹ́ kí ohun tó ń ṣe wọ́n fúyẹ́, lẹ́yìn náà, wọ́n á kó ìyókù sí ibì kan títí dìgbà tí àìsàn á tún ṣe wọ́n.” Níwọ̀n bí irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ kò ti péye, àwọn kòkòrò àrùn tó lágbára gan-an lè wà nínú ara aláìsàn náà, wọ́n á sì bí sí i lọ́pọ̀lọpọ̀ débi pé oògùn ò ní lè kápá wọn mọ́.

Ìyípadà Nínú Ipò Ojú Ọjọ́

Kókó pàtàkì kan tó fa bí àwọn kòkòrò tó ń tan àrùn kálẹ̀ ṣe padà wá ni ìyípadà tó ń ṣẹlẹ̀—ìyẹn ìyípadà nínú àwọn ohun tí Ẹlẹ́dàá dá àti ìyípadà tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ ẹ̀dá èèyàn. Àpẹẹrẹ kan ni ipò ojú ọjọ́ tó ti yí padà jákèjádò ayé. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan sọ pé bí ayé ṣe ń móoru sí i yóò mú kí àwọn kòkòrò tó ń gbé àrùn kiri pọ̀ sí i láwọn àgbègbè tó jẹ́ olótùútù nísinsìnyí. Àwọn ẹ̀rí wà láti fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí èyí ti máa ṣẹlẹ̀. Dókítà Paul R. Epstein tó ń ṣiṣẹ́ ní Center for Health and the Global Environment, èyí tó wà ní Ilé Ẹ̀kọ́ṣẹ́ Ìṣègùn ti Harvard, sọ pé: “Lóde òní, ìròyìn lóríṣiríṣi ń fi hàn pé àwọn kòkòrò àtàwọn àrùn tí wọ́n ń gbé kiri (irú bí ibà malaria àti ibà dengue) ti ń gbilẹ̀ gan-an ní àwọn àgbègbè olókè ní ilẹ̀ Áfíríkà, ilẹ̀ Éṣíà, àti ní Látìn Amẹ́ríkà.” Ní Costa Rica, ibà dengue ti kọjá àwọn àgbègbè tó jẹ́ olókè, ìyẹn àwọn òkè ńlá tó jẹ́ pé títí di ẹnu àìpẹ́ yìí, àwọn ló sé àrùn náà mọ́ àgbègbè Etíkun Pacific, ní báyìí ó ti gba gbogbo orílẹ̀-èdè náà kan.

Àmọ́ ojú ọjọ́ tó ń móoru tún lè fa àwọn ìṣòro mìíràn. Láwọn àgbègbè kan, ó máa ń sọ àwọn odò ńlá di ọ̀gọ̀dọ̀, nígbà tó jẹ́ pé láwọn ibòmíràn, ó máa ń fa òjò àti omíyalé tó máa ń ṣokùnfà àwọn adágún omi tí kò ṣàn. Nínú àwọn ọ̀ràn méjèèjì yìí, omi tí kò kúrò lójú kan yìí gan-an nibi táwọn ẹ̀fọn máa ń wá láti fi ṣe ilé tí wọ́n á máa pa mọ sí. Ojú ọjọ́ tó móoru gan-an tún máa ń mú kí àwọn ẹ̀fọn tètè pa mọ, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n pọ̀ sí i, ó sì tún máa ń mú kí àkókò tí ẹ̀fọn máa ń wà gùn sí i. Àwọn ẹ̀fọn máa ń ní agbára kún agbára láwọn ìgbà tí ojú ọjọ́ bá ń móoru. Àní, ojú ọjọ́ tó móoru máa ń jẹ́ kí àwọn kòkòrò àrùn tó wà nínú àwọn ẹ̀fọn pọ̀ sí i. Èyí ló fà á tó fi jẹ́ pé, wọ́n lè kó àrùn ranni bí wọ́n bá géni jẹ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Síbẹ̀, àwọn nǹkan mìíràn ṣì wà tó ń fa àníyàn.

Bí Àwọn Kòkòrò Ṣe Máa Ń Tan Àrùn Kálẹ̀

Ìyípadà tó ń ṣẹlẹ̀ nínú àwùjọ ẹ̀dá èèyàn tún lè dá kún àwọn àrùn táwọn kòkòrò ń gbé kiri. Láti mọ bí èyí ṣe lè ṣẹlẹ̀, a ní láti fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ipa tí àwọn kòkòrò ń kó. Nínú ọ̀pọ̀ àìsàn, ó lè jẹ́ pé kòkòrò wulẹ̀ jẹ́ agbódegbà kan lásán ni lára ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń tan àìsàn kálẹ̀. Ẹranko kan tàbí ẹyẹ kan lè máa gbé àrùn kan kiri nígbà tó bá ń gbé kòkòrò tó ní in lára kiri tàbí nígbà tó bá ń gbé kòkòrò àrùn kiri nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Bí kòkòrò àrùn náà kò bá pa ẹranko náà, ó lè fi ara ẹranko náà ṣelé tí á sì máa tàn án káàkiri.

Gbé àpẹẹrẹ àrùn Lyme yẹ̀ wò. Wọ́n ṣàkíyèsí àrùn yìí lọ́dún 1975 wọ́n sì sọ ọ lórúkọ ìlú Lyme, tó wà ní ìpínlẹ̀ Connecticut, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, níbi tí wọ́n ti kọ́kọ́ rí i. Ó lè jẹ́ pé àwọn eku tàbí ẹran ọ̀sìn tó bá àwọn ọkọ̀ ojú omi wá láti ilẹ̀ Yúróòpù ló gbé kòkòrò bakitéríà tó ń fa àrùn Lyme wá sí Àríwá Amẹ́ríkà ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn. Lẹ́yìn tí eégbọn tó kéré bíńtín kan tó ń jẹ́ Ixodes bá ti fa ẹ̀jẹ̀ ẹranko alárùn kan mu, inú eégbọn náà ni kòkòrò àrùn náà á wà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Bí eégbọn náà bá wá bu ẹranko mìíràn tàbí èèyàn kan jẹ lẹ́yìn náà, ó lè tàtaré kòkòrò bakitéríà náà sínú ìṣàn ẹ̀jẹ̀ ẹni náà.

Ìhà àríwá ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni àrùn Lyme ti gbilẹ̀ jù, ó sì ti pẹ́ tó ti ń jà ràn-ìn níbẹ̀. Oríṣi òkété kan báyìí ló sábà máa ń gbé kòkòrò bakitéríà tó ń fa àrùn Lyme kiri níbẹ̀. Òkété náà tún máa ń gbé eégbọn kiri lára rẹ̀, pàápàá àwọn eégbọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà. Àwọn eégbọn tó ti dàgbà ní tiwọn máa ń fi ara ẹtu ṣelé, níbi tí wọ́n á ti máa jẹun tí wọ́n á sì máa gùn. Gbàrà tí wọ́n bá ti mu ẹ̀jẹ̀ yó, eégbọn tó jẹ́ abo náà á bọ́ sílẹ̀ láti yé ẹyin, láìpẹ́ àwọn ọmọ tó pa náà á dàgbà, wọ́n á sì máa bá irú ìgbésí ayé náà lọ.

Ipò Nǹkan Yí Padà

Àwọn kòkòrò àrùn ti ń bá àwọn ẹranko àtàwọn kòkòrò gbé pọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún láìsí pé wọ́n ń fi àrùn ṣe ẹ̀dá èèyàn. Àmọ́ ìyípadà nínú ipò nǹkan lè mú kí àrùn kan di àjàkálẹ̀ àrùn, kó di ohun tí yóò máa kọ lu ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lágbègbè kan. Kí ni ìyípadà tó wáyé nínú ọ̀ràn àrùn Lyme?

Láyé àtijọ́, pípa tí àwọn ẹranko apẹranjẹ ń pa àwọn ẹtu jẹ mú kí àjọṣe àárín àwọn ẹtu àti eégbọn dín kù gidigidi. Nígbà tí àwọn ará Yúróòpù ayé ọjọ́un tó wá tẹ ìlú dó nílẹ̀ Amẹ́ríkà gé àwọn igi igbó lulẹ̀ torí iṣẹ́ àgbẹ̀, àwọn ẹtu tó wà nínú igbó dín kù gidigidi, bẹ́ẹ̀ làwọn ẹranko apẹranjẹ náà wábi gbà. Àmọ́ ní agbedeméjì ẹ̀wádún tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1800, ọ̀pọ̀ àwọn àgbẹ̀ tó wà ní ìlà oòrùn Amẹ́ríkà fi oko wọn sílẹ̀ láti lọ dáko ní ìwọ̀ oòrùn, èyí sì mú kí igi tún bẹ̀rẹ̀ sí hù nínú igbó náà. Làwọn ẹtu bá tún bẹ̀rẹ̀ sí padà, àmọ́ àwọn ẹranko tó ń pa wọ́n jẹ kò padà. Nípa bẹ́ẹ̀, ńṣe ni iye àwọn ẹtu inú igbó bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i lọ́nà kíkàmàmà, bẹ́ẹ̀ làwọn eégbọn náà bá tún ya dé.

Ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn náà, kòkòrò bakitéríà tó ń fa àrùn Lyme fara hàn, ó sì ti ń gbé ara àwọn ìgalà fún ọ̀pọ̀ ọdún kó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá di nǹkan eléwu fún ẹ̀dá èèyàn. Àmọ́, nígbà táwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí kọ́lé sí àwọn àgbègbè tó wà létí igbó náà, èyí mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọdé àti àgbàlagbà máa sún mọ́ ibi tí àwọn eégbọn ń gbé. Làwọn eégbọn náà bá bẹ̀rẹ̀ sí ràn mọ́ àwọn èèyàn lára, ẹni tó bá sì ti ràn mọ́ máa kó àrùn Lyme ni.

Ipa Tí Àrùn Ń Kó Nínú Ayé Tí Kò Fara Rọ Yìí

Ìsọfúnni tá a jíròrò yìí wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí àrùn ń gbà bẹ̀rẹ̀ tó sì ń tàn kálẹ̀, ó sì tún jẹ́ àpẹẹrẹ ọ̀nà kan tí àwọn ẹ̀dá èèyàn ń gbà mú kí àrùn padà wá. Nínú ìwé náà, The Future in Plain Sight, èyí tí Eugene Linden tó jẹ́ onímọ̀ nípa àyíká kọ, ó sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àwọn ẹ̀dá èèyàn ló ń fọwọ́ ara wọn fa àwọn àrùn bíburú jáì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń jẹ yọ lóde òní.” Àwọn àpẹẹrẹ mìíràn nìwọ̀nyí: Bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ṣe túbọ̀ ń rìnrìn-àjò tí àwọn ọ̀nà tí wọ́n ń gbà rìnrìn-àjò sì túbọ̀ ń yára kánkán sí i lè tan kòkòrò àrùn kálẹ̀, kí àwọn ohun abẹ̀mí tó ń gbé wọn kiri náà sì di èyí tó wà káàkiri àgbáyé. Bí àwọn èèyàn ṣe ń ba ibi tí àwọn ìṣẹ̀dá ńlá àti kéékèèké ń gbé jẹ́ ń ṣàkóbá fún àwọn ohun alààyè tó wà níbẹ̀ ní ọ̀kan-ò-jọ̀kan. Ọ̀gbẹ́ni Linden sọ pé: “Ìbàyíkájẹ́ máa ń ṣèpalára fún afẹ́fẹ́ àti omi, èyí sì máa ń mú kí agbára ìdènà àrùn àwọn ẹranko àtàwọn ẹ̀dá èèyàn di aláìlágbára.” Ó fi ọ̀rọ̀ Dókítà Epstein kún un pé: “Ká gé e kúrú, bí àwọn èèyàn ṣe ń ṣèdíwọ́ fún ibùgbé àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn ti mú kó ṣòro gan-an fún àgbáyé láti ṣèkáwọ́ àrùn, ó sì ń mú kí àyè túbọ̀ gba àwọn kòkòrò àrùn.”

Rúkèrúdò òṣèlú máa ń yọrí sí ogun, èyí tó lè ṣàkóbá fún ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn, tó sì lè ṣàkóbá fún àwọn ohun amáyédẹrùn bí ètò ìlera àti ìpínkiri oúnjẹ. Láfikún sí i, ìwé Biobulletin tí Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé–Nípa-Ìtàn-Sí ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà tẹ̀ jáde, ṣàlàyé pé: “Àwọn olùwá-ibi-ìsádi, tí kò rí oúnjẹ aṣaralóore jẹ, tí wọn kò sì lókun nínú, ni wọ́n sábà máa ń fi sínú àwọn àgọ́ tó jẹ́ pé, bí èrò inú wọn ṣe kún àkúnfàya, tí kò sì sí ìmọ́tótó níbẹ̀ máa ń jẹ́ kó rọrùn fún oríṣiríṣi àrùn láti kọ lù wọ́n.”

Àìríná àìrílò máa ń jẹ́ káwọn èèyàn ṣí kiri, yálà láàárín orílẹ̀-èdè wọn tàbí láti kọjá sí orílẹ̀-èdè mìíràn, àwọn ibi térò pọ̀ sí gan-an ni wọ́n sì máa ń lọ jù. Ìwé Biobulletin sọ pé: “Àwọn kòkòrò àrùn fẹ́ràn ibi tí èrò bá pọ̀ sí gidigidi.” Bí iye àwọn èèyàn tó ń gbé nínú ìlú kan bá ṣe ń pọ̀ sí i ni “àwọn ohun ṣíṣekókó tó lè mú kí ìlera àwọn aráàlú gbé pẹ́ẹ́lí sí i, irú bí ẹ̀kọ́ tó ṣe kókó, oúnjẹ aṣaralóore, àti ètò abẹ́rẹ́ àjẹsára kò ní lè kárí gbogbo wọn.” Àpọ̀jù èrò tún máa ń mú kí ìpèsè omi, àti ètò pípalẹ̀ ìdọ̀tí àti ẹ̀gbin mọ́ ṣòro gan-an, èyí á sì mú kí ṣíṣe ìmọ́tótó àyíká àti ṣíṣe ìtọ́jú ara ẹni nira gan-an, nígbà tó jẹ́ pé lọ́wọ́ kan náà, á jẹ́ kó rọrùn fún àwọn kòkòrò àtàwọn ohun abẹ̀mí mìíràn tó ń gbé àrùn kiri láti máa gbèrú sí i. Síbẹ̀, ojútùú wà sí ìṣòro yìí o, gẹ́gẹ́ bí a óò ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]

“Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àwọn ẹ̀dá èèyàn ló ń fọwọ́ ara wọn fa àwọn àrùn bíburú jáì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń jẹ yọ lóde òní”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Kòkòrò Àrùn West Nile Ti Gbòde Kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà

Ọdún 1937 ni wọ́n kọ́kọ́ mọ kòkòrò àrùn tó ń jẹ́ West Nile, ní orílẹ̀-èdè Uganda, ẹ̀fọn ló sì sábà ń kó o ran àwọn èèyàn. Lẹ́yìn èyí ni wọ́n tún ṣàkíyèsí rẹ̀ ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé, ilẹ̀ Éṣíà, àgbègbè Oceania, àti ilẹ̀ Yúróòpù. Ìgbà tó di ọdún 1999 ni wọ́n tó ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ nípa kòkòrò àrùn yìí ní ìhà Ìwọ̀ Oòrùn Ilẹ̀ ayé. Àmọ́, látìgbà náà wá, àwọn èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ni àrùn náà ti kọ lù ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó sì ti pa àwọn èèyàn tó lé ní igba.

Ọ̀pọ̀ àwọn tó ní kòkòrò àrùn yìí lára ni kì í mọ̀ pé àwọn ti ní in, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àìlera kan tó fara jọ otútù lè máa jẹ yọ. Àmọ́, ìwọ̀nba kéréje lára àwọn èèyàn yìí ló máa ń ní àìsàn líle koko, irú bíi kí ọpọlọ wúlé àti kí àrùn lọ́rùnlọ́rùn kọ luni. Títí di àkókò yìí, kò tíì sí abẹ́rẹ́ àjẹsára kankan tàbí ìtọ́jú pàtó kan tó wà fún kòkòrò àrùn West Nile. Ibùdó Tó Ń Ṣèkáwọ́ Àrùn Tó sì Ń Dènà Rẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ṣèkìlọ̀ pé àwọn èèyàn lè ní kòkòrò àrùn West Nile lára nígbà tí wọ́n bá ń ṣe iṣẹ́ abẹ pípààrọ̀ ẹ̀yà ara, irú bíi kíndìnrín tàbí ẹ̀dọ̀fóró, ó sì tún lè ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n bá gba ẹ̀jẹ̀ ẹnì kan tó ní kòkòrò àrùn náà sára. Ilé iṣẹ́ ìròyìn Reuters ròyìn lọ́dún 2002 pé: “Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, kò tíì sí ọ̀nà kankan láti gbà ṣàyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ láti mọ̀ bóyá ó ní kòkòrò àrùn West Nile nínú.”

[Credit Line]

CDC/James D. Gathany

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]

Báwo Lo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Rẹ? Àwọn Àbá Tó Lè Ṣe Ọ́ Láǹfààní

Kárí ayé làwọn akọ̀ròyìn Jí! béèrè lọ́wọ́ àwọn tó ń gbé àwọn àgbègbè tí kòkòrò ti ń tan àrùn kálẹ̀ nípa àwọn àbá tí wọ́n ní nípa béèyàn ṣe lè ní ìlera tó jí pépé. Ó ṣeé ṣe kí ìmọ̀ràn tí wọ́n mú wá ṣèrànwọ́ ní àgbègbè rẹ.

Ìmọ́tótó Ni Ohun Àkọ́kọ́ Láti Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Àìsàn

Jẹ́ kí ilé rẹ mọ́ tónítóní

“Máa fi nǹkan bo àwọn ohun tó ò ń kó oúnjẹ sí. Fi nǹkan bo oúnjẹ tó o ti sè títí dìgbà tí wàá jẹ ẹ́. Nu oúnjẹ tó bá dà sílẹ̀ kúrò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Má ṣe fi àwo tó o fi jẹun sílẹ̀ láìfọ̀ di ọjọ́ kejì tàbí kó o sọ àjẹkù oúnjẹ síta títí di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì tó o máa lọ dà á nù. Dé e mọ́ inú nǹkan tàbí kó o bò ó mọ́lẹ̀, nítorí àwọn kòkòrò àtàwọn èkúté tó máa ń jáde lóru láti wá ohun tí wọ́n máa jẹ. Bákan náà, fífi sìmẹ́ǹtì fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ rẹ́ orí ilẹ̀ alámọ̀ á jẹ́ kó rọrùn láti mú kí ilé wà ní mímọ́ tónítóní, á sì lé àwọn kòkòrò sá.”—Áfíríkà.

“Gbé èso tàbí ohunkóhun tó lè fa àwọn kòkòrò wọlé jìnnà sí itòsí ilé. Má ṣe gba àwọn ẹran ọ̀sìn láàyè nínú ilé, irú bí ewúrẹ́, ẹlẹ́dẹ̀ tàbí adìyẹ. Máa fi nǹkan bo ṣáláńgá tó wà níta gbangba. Tètè fi iyẹ̀pẹ̀ bo ìgbẹ́ ẹran ọ̀sìn tàbí kó o bu eérú lé e lórí kí eṣinṣin má bàa bò ó. Kódà bí àwọn aládùúgbò rẹ kì í bá ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, o lè lé àwọn kòkòrò jìnnà kúrò láyìíká ilé rẹ díẹ̀, kó o sì tún fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wọn.”—Gúúsù Amẹ́ríkà.

[Àwòrán]

Fífi oúnjẹ tàbí pàǹtírí sílẹ̀ láìbò dà bíi kíké sí àwọn kòkòrò láti wá bá ọ jẹun

Máa ṣe ìmọ́tótó

“Ọṣẹ kò wọ́n rárá, torí náà máa fọ ọwọ́ àti aṣọ rẹ déédéé, pàápàá lẹ́yìn tó o bá ti fara kan àwọn ẹlòmíràn tàbí àwọn ẹranko. Má ṣe máa fọwọ́ kan òkú ẹranko. Má ṣe máa fọwọ́ sí ẹnu, imú àti ojú rẹ. Máa fọ àwọn aṣọ rẹ déédéé, kódà bó bá dà bíi pé wọ́n ṣì mọ́. Àmọ́ o, níwọ̀n bí àwọn lọ́fíńdà kan ti máa ń fa kòkòrò wọlé, má ṣe máa lo àwọn ọṣẹ àtàwọn èròjà ìtọ́jú ara tó ní òórùn.”—Áfíríkà.

Àwọn Ohun Tó O Lè Ṣe Láti Dènà Àrùn

Kó àwọn ohun tí ẹ̀fọn lè pa ọmọ sí kúrò nílẹ̀

Fi nǹkan bo ìkòkò omi tàbí àwọn ohun mìíràn tí omi wà nínú rẹ̀. Palẹ̀ ohunkóhun tó lè gba omi dúró mọ́ kúrò nílẹ̀. Má ṣe jẹ́ kí omi dá rogún sínú àwọn ìkòkò tí a gbin òdòdó sí. Ẹ̀fọn lè pa ọmọ sínú ohunkóhun tó bá ti lè gba omi dúró fún ọjọ́ mẹ́rin, ó kéré tán.—Gúúsù Ìlà Oòrùn Éṣíà.

Má ṣe máa ṣí ara sílẹ̀ fún kòkòrò

Má ṣe máa wà níbi tí àwọn kòkòrò máa ń pọ̀ sí tàbí ibi tí wọ́n sábà máa ń wà. Oòrùn máa ń tètè wọ̀ ní ilẹ̀ olóoru, nípa bẹ́ẹ̀ ọwọ́ alẹ́ làwọn èèyàn máa ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ilé, nígbà tí àwọn kòkòrò máa ń wà káàkiri. Jíjókòó tàbí sísùn sí ìta gbangba nígbà tí àwọn àrùn tí kòkòrò ń gbé kiri máa ń wọ́pọ̀ á jẹ́ kí wọ́n tètè ràn ọ́.—Áfíríkà.

[Àwòrán]

Sísùn sí ìta gbangba níbi tí àwọn ẹ̀fọn ti ń gbá yìn-ìn dà bíi kíké sí àwọn ẹ̀fọn láti wá mu ẹ̀jẹ̀ rẹ

Máa wọ àwọn aṣọ tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣí ara sílẹ̀, pàápàá nígbà tó o bá wà nínú igbó. Máa fi àwọn èròjà tó ń lé kòkòrò sá sára aṣọ rẹ, kó o sì máa fi wọ́n para, àmọ́ máa rí i pé ò ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tó bá irú èròjà bẹ́ẹ̀ wá. Ṣàyẹ̀wò bóyá eégbọn wà lára rẹ tàbí lára àwọn ọmọ rẹ lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti rin kiri nínú igbó. Máa ṣètọ́jú àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ dáadáa torí àìsàn, má sì jẹ́ kí wọ́n ní kòkòrò lára.—Àríwá Amẹ́ríkà.

Má ṣe máa fi bẹ́ẹ̀ fara kan àwọn ẹran ọ̀sìn, torí pé àwọn kòkòrò ara wọn lè kó àrùn ran àwọn ẹ̀dá èèyàn.—Àárín Gbùngbùn Éṣíà.

Ṣètò fún gbogbo ìdílé láti máa lo nẹ́ẹ̀tì tó ń dáàbò boni lọ́wọ́ ẹ̀fọn—pàápàá èyí tí oògùn apakòkòrò wà lára rẹ̀. Fi nẹ́ẹ̀tì sójú fèrèsé ilé rẹ, kó o sì rí i pé o dí ibi tó bá luhò lára rẹ̀. Fi nǹkan dí àwọn ibi tí kòkòrò lè gbà wọlé lára òrùlé àti lára ògiri. Ṣíṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí láti dènà àrùn lè náni lówó díẹ̀, àmọ́ owó tó o máa pàdánù á jù bẹ́ẹ̀ lọ bó o bá gbé ọmọ rẹ lọ sí ilé ìwòsàn tàbí bó bá jẹ́ pé baálé ilé tó ń gbọ́ bùkátà ni àìsàn ò jẹ́ kó lọ síbi iṣẹ́.—Áfíríkà.

[Àwòrán]

Kò yẹ kí àwọn kòkòrò jẹ́ ọ̀rẹ́ wa. Gbá wọn dà nù!

Palẹ̀ gbogbo ibi tí àwọn kòkòrò lè rí fara pa mọ́ sí kúrò nínú ilé rẹ. Fi nǹkan rẹ́ ògiri àti òrùlé, kó o sì dí àwọn ibi tó sán lára ògiri. Fi aṣọ bo abẹ́ òrùlé oníkoríko nítorí kòkòrò. Má ṣe jẹ́ kí àwọn nǹkan wà lára ògiri jángan-jàngan, irú bíi bébà, fọ́tò àtàwọn aṣọ tá a fi kọ́ sára ògiri, torí pé àwọn kòkòrò lè fara pa mọ́ síbẹ̀.—Gúúsù Amẹ́ríkà.

Àwọn kan máa ń rò pé kòkòrò àti èkúté ilé jẹ́ ọ̀rẹ́ èèyàn. Kò rí bẹ́ẹ̀ o! Má ṣe jẹ́ kí wọ́n wọnú ilé rẹ. Máa lo àwọn èròjà tó ń lé kòkòrò sá àti oògùn apakòkòrò—àmọ́ máa rí i pé ò ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà tó bá irú oògùn bẹ́ẹ̀ wá. Máa lo àwọn ohun èlò tó ń pa eṣinṣin. Ronú nípa ohun tó o lè ṣe fúnra rẹ: Obìnrin kan rán aṣọ dọọrọ kan, ó bu iyẹ̀pẹ̀ sínú rẹ̀, ó wá fi sábẹ́ ilẹ̀kùn kí àwọn kòkòrò má bàa ráyè wọlé.—Áfíríkà.

[Àwòrán]

Àwọn nẹ́ẹ̀tì tó ń dáàbò boni lọ́wọ́ ẹ̀fọn, èyí tí oògùn apakòkòrò ti wà lára wọn, kò wọ́n tó oògùn àti owó ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn

Àwọn ọ̀nà tó o lè gbà dènà àìsàn

Láti dènà àìsàn, máa jẹ oúnjẹ aṣaralóore, máa sinmi dáadáa, kó o sì máa ṣe eré ìmárale. Má ṣe máa ṣàníyàn jù.—Áfíríkà.

Ẹ̀yin Arìnrìn-Àjò: Ṣáájú kó o tó rìnrìn àjò, gbìyànjú láti mọ àwọn ìsọfúnni tó bágbà mu nípa àwọn àrùn tó wà níbi tó ò ń lọ. O lè rí àwọn ìsọfúnni wọ̀nyí lọ́dọ̀ àwọn àjọ tó ń bójú tó ìlera àwọn aráàlú àti ní ibùdó ìsọfúnni lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó jẹ́ ti ìjọba. Kó o tó rìnrìn-àjò, gba àwọn ìtọ́jú yíyẹ láti lè dènà àwọn ewu tó lè yọjú ní àgbègbè tó o fẹ́ lọ ṣèbẹ̀wò sí.

Bí Ara Rẹ Kò Bá Le

Tètè lọ gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn

Ọ̀pọ̀ àrùn máa ń rọrùn láti wò bí aláìsàn bá tètè lọ fún àyẹ̀wò lọ́dọ̀ dókítà.

Ṣọ́ra, kí wọ́n má fi ohun tó ń ṣe ọ́ pe nǹkan mìíràn

Lọ fún àyẹ̀wò lọ́dọ̀ àwọn dókítà tó mọ̀ nípa àwọn àrùn tí kòkòrò ń kó ranni tí wọ́n sì mọ̀ nípa àwọn àrùn ilẹ̀ olóoru, ìyẹn bó o bá ṣèbẹ̀wò síbẹ̀. Sọ gbogbo àwọn àmì tó ò ń rí fún dókítà rẹ àti gbogbo àwọn ibi tó o ti rìnrìn àjò lọ, kódà nígbà pípẹ́ sẹ́yìn pàápàá. Ìgbà tó bá pọn dandan nìkan ni kó o máa lo oògùn agbógunti kòkòrò àrùn, kó o sì rí i pé o lo gbogbo oògùn náà tán.

[Àwòrán]

Àwọn àrùn tí kòkòrò ń gbé kiri lè fara jọ àwọn àìsàn mìíràn. Ṣe àlàyé yékéyéké fún dókítà rẹ nípa àwọn ibi tó o ti rìnrìn àjò lọ

[Credit Line]

Àwòrán àgbáyé: Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Ǹjẹ́ Àwọn Kòkòrò Lè Kó Àrùn Éèdì Ran Èèyàn?

Lẹ́yìn ohun tó ti lé lọ́dún mẹ́wàá tí àwọn onímọ̀ nípa kòkòrò àtàwọn onímọ̀ nípa ìṣègùn ti ń ṣèwádìí lóríṣiríṣi, wọn kò tíì rí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé ẹ̀fọn tàbí àwọn kòkòrò mìíràn ń kó àrùn éèdì ran èèyàn.

Bí àpẹẹrẹ, nínú ọ̀ràn ti ẹ̀fọn, ẹnu rẹ̀ kò dà bí abẹ́rẹ́ tí àwọn nọ́ọ̀sì ń lò, èyí tó jẹ́ pé ọ̀nà kan ṣoṣo tí wọ́n ń gbà fi fa ẹ̀jẹ̀ sínú ike abẹ́rẹ́ náà ni wọ́n ń gbà fi fà á sára èèyàn. Dípò ìyẹn, apá kan ẹnu ẹ̀fọn ló máa ń fi fa ẹ̀jẹ̀, ó sì máa ń lo apá kejì láti fi pọ itọ́ ẹnu rẹ̀ síni lára. Ọ̀gbẹ́ni Thomas Damasso, ògbóǹtagí kan lórí kòkòrò àrùn tó ń fa àrùn éèdì, tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Àwùjọ Tó Ń Rí sí Ìlera Àwọn Aráàlú ní ìlú Mongu, lórílẹ̀-èdè Zambia, sọ pé lẹ́yìn tí ẹ̀fọn bá ti fa ẹ̀jẹ̀ mu, ẹ̀yà ara rẹ̀ tó ń mú kí oúnjẹ dà yóò fọ́ àwọn èròjà inú ẹ̀jẹ̀ náà sí wẹ́wẹ́, yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ pa fáírọ́ọ̀sì náà run. Kòkòrò àrùn éèdì kì í sí nínú ìgbẹ́ àwọn kòkòrò. Àti pé, láìdàbí kòkòrò àrùn tó ń fa ibà, kòkòrò àrùn éèdì kì í dé inú ẹṣẹ́ tí itọ́ ẹ̀fọn ti ń wá.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ kòkòrò àrùn kéékèèké tó lè kéèràn ranni ní láti wọ ara ẹnì kan kó tó lè ní kòkòrò tó ń fa àrùn éèdì. Bí ẹ̀fọn bá ń fa ẹ̀jẹ̀ ẹnì kan mu tó sì wá ṣàdédé fò lọ sọ́dọ̀ ẹlòmíràn, láìka bí ẹ̀jẹ̀ ẹnu rẹ̀ ṣe lè pọ̀ tó, kò ní tó ohun tó lè kéèràn ran ẹni náà. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn ògbógi sọ, kódà pípa ẹ̀fọn tó ti mu ẹ̀jẹ̀ tó ní kòkòrò àrùn éèdì mọ́ ojú egbò kò lè mú kí onítọ̀hún ní àkóràn àrùn éèdì.

[Credit Line]

CDC/James D. Gathany

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Eégbọn tó máa ń wà lára ẹtu (àwòrán rẹ̀ ni a mú tóbi lápá ọ̀tún) máa ń kó àrùn Lyme ran àwọn ẹ̀dá èèyàn

Apá òsì sí apá ọ̀tún: Abo tó ti dàgbà, akọ tó ti dàgbà, àti ọmọ tín-ń-tín tí wọ́n bí

[Credit Line]

Àwòrán àwọn eégbọn: CDC

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]

Omíyalé, àìsí ìmọ́tótó àti bí àwọn èèyàn ṣe ń ṣí kiri ń dá kún bí àwọn àrùn tí kòkòrò ń gbé kiri ṣe ń pọ̀ sí i

[Credit Line]

FOTO UNACIONES (látọ̀dọ̀ U.S. Army)