Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Mo Ní Láti Mọ̀ Sí I”

“Mo Ní Láti Mọ̀ Sí I”

“Mo Ní Láti Mọ̀ Sí I”

LLỌ́DÚN 2001, obìnrin kan kọ̀wé pé: “Lánàá, mo gba ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?, èyí tí mo kọ̀wé béèrè fún.” Ó ṣàlàyé pé òun ti kọ́kọ́ rí ibi méjì tí wọ́n ti polówó ìwé náà. Ó sọ pé: “Ńṣe ni mò ń retí lójú méjèèjì pé kí ìwé náà dé nítorí pé lẹ́yìn tí mo ka àwọn ìpolówó náà, mo mọ̀ pé mo ní láti mọ̀ sí i. Kété tí mo gba ìwé pẹlẹbẹ náà ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í kà á. Gbogbo ohun tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ yín náà ló bọ́gbọ́n mu, inú Bíbélì ló sì ti wá.”

Ó wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Mo mọ̀ pé mo gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fi ohun tí mo kà náà sílò ní kíákíá.”

A gbà gbọ́ pé ìwọ náà á jàǹfààní bó o bá ka ìwé olójú ewé 32 náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? Yàtọ̀ sí ẹ̀kọ́ fífanimọ́ra kan nínú rẹ̀ tó sọ pé “Ta Ni Jesu Kristi?,” wàá tún rí àwọn mìíràn. Àwọn bíi “Ta Ni Ọlọrun?,” “Kí ni Ète Ọlọrun fún Ilẹ̀ Ayé?,” àti “Kí Ni Ìjọba Ọlọrun?” Bó o bá fẹ́ láti gba ẹ̀dà kan, jọ̀wọ́ kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ìwé 5 ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.