Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ipò Nǹkan Lè Dára Sí I?

Ǹjẹ́ Ipò Nǹkan Lè Dára Sí I?

Ǹjẹ́ Ipò Nǹkan Lè Dára Sí I?

LÓDE ÒNÍ, Àjọ Ìlera Àgbáyé àtàwọn àjọ mìíràn tí ìlera àwọn aráàlú ń jẹ lọ́kàn ti ń ṣe ọ̀kan-kò-jọ̀kan ètò láti mójú tó bí àwọn àrùn ṣe ń tàn kálẹ̀ àti láti ṣèkáwọ́ wọn. Onírúurú àjọ ló ń pèsè ọ̀pọ̀ ìsọfúnni fún àǹfààní àwọn èèyàn, wọ́n sì ń ṣonígbọ̀wọ́ àwọn ìwádìí lóríṣiríṣi láti lè kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àwọn egbòogi tuntun àtàwọn ọ̀nà tuntun tí a lè gbà kápá ìṣòro àwọn àrùn tí kòkòrò ń gbé kiri, èyí tó túbọ̀ ń gbilẹ̀ sí i. Àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àtàwọn àwùjọ lódindi tún lè ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan láti kọ́ ara wọn lẹ́kọ̀ọ́ àti láti dáàbò bo ara wọn. Síbẹ̀, dídáàbò bo ara ẹni kì í ṣe ohun kan náà pẹ̀lú kíkápá àrùn kárí ayé.

Ọ̀pọ̀ àwọn ògbógi gbà gbọ́ pé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti àjọṣepọ̀ gbogbo àgbáyé ṣe kókó kí akitiyan láti ṣèkáwọ́ àrùn tó lè kẹ́sẹ járí. Nínú ìwé The Coming Plague—Newly Emerging Diseases in a World out of Balance, èyí tí akọ̀ròyìn Laurie Garrett, ẹni tó ti gba ẹ̀bùn ẹ̀yẹ Pulitzer Prize kọ, ó sọ pe: “Bí àjọṣe tó wà láàárín àwọn èèyàn àti láàárín àwọn orílẹ̀-èdè kárí ayé ṣe ń yára tẹ̀ síwájú ń béèrè pé kí àwọn ẹ̀dá èèyàn níbi gbogbo tí wọ́n bá wà lórí ilẹ̀-ayé má kàn wo àdúgbò wọn, àgbègbè wọn, tàbí orílẹ̀-èdè wọn gẹ́gẹ́ bí ibi tí àyíká wọ́n mọ. Àwọn kòkòrò àrùn, àtàwọn kòkòrò tó ń gbé wọn kiri, kò mọ èyíkéyìí lára àwọn ààlà ìpínlẹ̀ tí àwọn ẹ̀dá èèyàn ṣe.” Bí àrùn bá bẹ́ sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè kan, kì í ṣe àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ nìkan lèyí máa dá àníyàn sílẹ̀ fún, àmọ́ gbogbo ayé lápapọ̀.

Àwọn ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè kan àtàwọn èèyàn kan máa ń wà lójúfò láti kíyè sí ohunkóhun tó bá jẹ mọ́ àrùn—títí kan àwọn ètò tó wà fún kíkápá àrùn pàápàá—èyí tó ń wá láti orílẹ̀-èdè mìíràn yàtọ̀ sí tiwọn. Láfikún sí i, bí àwọn ìjọba kì í ṣeé ronú nípa ọjọ́ iwájú àti bí àwọn oníṣòwò ṣe ń fi ìwọra ṣòwò sábà máa ń ṣèdíwọ́ fún akitiyan táwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé ń pawọ́ pọ̀ ṣe. Nínú ogun tí ẹ̀dá èèyàn ń bá àrùn jà yìí, ǹjẹ́ àwọn kòkòrò àrùn ò ní ṣẹ́gun wa báyìí? Òǹṣèwé Eugene Linden, tó gbà pé àwọn kòkòrò máa ṣẹ́gun, sọ pé: “Àkókò tó kù fún wa láti kojú ìṣòro yìí ti kúrú gan-an.”

Ìdí Tí A Fi Ní Ìrètí

Ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ kò lè dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn àrùn tó ń pọ̀ sí i. Ká sòótọ́, ọ̀kan ṣoṣo péré ni ìṣòro àwọn àrùn tí kòkòrò ń gbé kiri wulẹ̀ jẹ́ lára ọ̀pọ̀ ohun tó jẹ́ ewu fún ìlera ẹ̀dá èèyàn. Àmọ́, ìdí wà láti ní ìrètí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí lóye ìbáṣepọ̀ dídíjú tó wà láàárín àwọn ohun alààyè, wọ́n gbà pé ilẹ̀ ayé lágbára láti tún ara rẹ̀ ṣe. Ẹlẹ́dàá ti ṣe àgbáálá ayé wa lọ́nà tó máa fi lè tún àwọn ìṣẹ̀dá tó ti bà jẹ́ ṣe. Bí àpẹẹrẹ, àwọn igi igbó tún máa ń hù padà níbi tí a bá ti gé wọn lulẹ̀, àjọṣe tó wà láàárín àwọn ohun alààyè tí kò ṣeé fojú rí, àwọn kòkòrò, àtàwọn ẹranko sì máa ń gún régé sí i bí àkókò ti ń lọ.

Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, ọ̀nà dídíjú tí a gbà ṣètò àwọn ìṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé fi hàn pé Ẹlẹ́dàá kan wà, ìyẹn Ọlọ́run, ẹni tó jẹ́ pé láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ló ti ṣe àwọn ètò tí nǹkan yóò fi máa lọ geerege lórí ilẹ̀ ayé. Ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fúnra wọn gbà pé ọlọ́gbọ́n gíga kan ní láti wà tó ṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé. Láìsí àní-àní, àwọn tó jẹ́ aláròjinlẹ̀ kò lè sẹ́ pé Ọlọ́run wà. Bíbélì sọ pé Ẹlẹ́dàá náà, Jèhófà Ọlọ́run, jẹ́ alágbára ńlá gbogbo àti onífẹ̀ẹ́. Ó wù ú gidigidi pé ká láyọ̀.

Bíbélì tún ṣàlàyé pé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́, ìran èèyàn ti jogún àìpé, àìsàn àti ikú. Ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí pé a ti kégbèé ayérayé lé wa lórí, pé a óò máa jìyà títí ayé ni? Rárá o! Ète Ọlọ́run ni láti sọ ilẹ̀ ayé di Párádísè, níbi tí àwọn ẹ̀dá èèyàn á ti máa gbé ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀dá mìíràn, àti ńlá àti kékeré. Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ayé kan máa wà, níbi tí kò ti ní sí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí, yálà àwọn ẹranko tó tóbi fàkìàfakia tàbí àwọn kòkòrò tíntìntín, tí yóò jẹ́ ewu fún àwọn èèyàn.—Aísáyà 11:6-9.

Láìsí àní-àní, àwọn èèyàn yóò kópa nínú iṣẹ́ bíbójútó àwọn ipò dáradára wọ̀nyẹn—ìyẹn nípa mímú kí àjọṣe tó wà láàárín ẹ̀dá èèyàn àti àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀dá tó wà láyìíká wọn dán mọ́rán. Ọlọ́run pàṣẹ fún ẹ̀dá èèyàn láti máa “bójú tó” ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 2:15) Nínú Párádísè tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, àwọn èèyàn yóò ṣe iṣẹ́ yìí ní àṣeyege nípa ṣíṣègbọràn sí àwọn ìtọ́sọ́nà Ẹlẹ́dàá fúnra rẹ̀. Nítorí náà, a lè máa fojú sọ́nà fún ọjọ́ náà nígbà tí “olùgbé kankan [kì] yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:24.