Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdáhùn wọn sì wà ní ojú ìwé 28. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)

1. Nígbà tí Sámúsìnì “ń wá àyè lòdì sí àwọn Filísínì,” ta ló yàn láti fi ṣe aya? (Onídàájọ́ 14:1-4)

2. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe ṣàlàyé, béèyàn bá jẹ́ ẹrú fún Ọlọ́run, kí ni kò tún lè jẹ́ ẹrú fún lẹ́sẹ̀ kan náà? (Lúùkù 16:13)

3. Baba ńlá Mèsáyà wo ló wá di ọkọ Rúùtù? (Rúùtù 4:13)

4. Ọ̀nà wo ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa èdè Hébérù yàn láti máa gbà pe orúkọ Ọlọ́run?

5. Nítorí ìwàkiwà Jésíbẹ́lì tó burú jáì, kí ni Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀? (1 Àwọn Ọba 21:23)

6. Fún ìdí wo ni Ábúráhámù fi ra hòrò Mákípẹ́là lọ́wọ́ “àwọn ọmọ Hétì”? (Jẹ́nẹ́sísì 23:19, 20)

7. Gbólóhùn wo, èyí tó túmọ̀ sí kíkó aṣọ mọ́ra ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, la lò nínú Ìwé Mímọ́ láti dúró fún gbígbára dì láti ronú jinlẹ̀jinlẹ̀ tàbí gbígbára dì fún ìgbòkègbodò tẹ̀mí? (Jóòbù 38:3)

8. Ọmọkùnrin wo ni Ádámù àti Éfà bí nígbà tí Ádámù jẹ́ ẹni àádóje ọdún? (Jẹ́nẹ́sísì 5:3)

9. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ta ni àwọn ọ̀tá fi ṣẹ́gun Ísírẹ́lì ní ìlú Áì? (Jóṣúà 7:20)

10. Orúkọ wo ni wọ́n ń pe adé tí wọ́n ń lò ní ìjímìjí? (2 Àwọn Ọba 11:12)

11. Níwọ̀n bí Màríà kò ti lágbára láti fi àgbò rúbọ lẹ́yìn tó bí Jésù, kí ni Òfin gbà á láyè láti lò dípò àgbò? (Lúùkù 2:24)

12. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe máa ń tọ́ka sí ara rẹ̀ nínú ọ̀pọ̀ àwọn lẹ́tà onímìísí tó kọ? (Éfésù 1:1)

13. Nígbà tí Senakéríbù Ọba Ásíríà ń gbìyànjú láti mú kí àwọn Júù juwọ́ sílẹ̀, kí ló mú kí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn rẹ̀ túbọ̀ kó Hesekáyà nírìíra gan-an? (Aísáyà 36:14, 15, 18-20)

14. Ibo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà nígbà tó gbọ́ ìpè náà: “Rékọjá wá sí Makedóníà, kí o sì ràn wá lọ́wọ́”? (Ìṣe 16:8, 9)

15. Kí nìdí tí Hánáánì aríran fi bá Ásà ọba Júdà tó jẹ́ ọba rere wí, lẹ́yìn tó ti fi ìṣòtítọ́ ṣàkóso fún ọ̀pọ̀ ọdún? (2 Kíróníkà 16:7)

16. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ, báwo ló ṣe yẹ kéèyàn fi ìṣòtítọ́ fara dà á pẹ́ tó? (Máàkù 13:13)

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè

1. Obìnrin Filísínì kan láti ìlú Tímúnà

2. Ọrọ̀

3. Bóásì

4. Yáwè

5. “Àwọn ajá ni yóò jẹ Jésíbẹ́lì”

6. Láti lò ó fún ibi ìsìnkú Sárà, aya rẹ̀

7. “Di abẹ́nú rẹ lámùrè”

8. Sẹ́ẹ̀tì

9. Ákáánì

10. Dáyádémà

11. “Oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì”

12. Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Kristi Jésù

13. Nítorí pé Senakéríbù fọ́nnu pé Jèhófà kò ní lè dá wọn nídè, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè tí òún ti ṣẹ́gun wọn kò ṣe lè dá wọn nídè

14. Ní Tíróásì, èbúté kan ní Éṣíà Kékeré

15. Nítorí pé ní àkókò yẹn, fún ìdí tí a kò mọ̀, Ọba Ásà lọ lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú ọba Síríà dípò kó gbára lé Jèhófà

16. Títí “dé òpin”