Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ìwà Ìkà Bíburú Jáì Kí Ló Dé Tí Wọ́n Túbọ̀ Ń Peléke Sí I?

Àwọn Ìwà Ìkà Bíburú Jáì Kí Ló Dé Tí Wọ́n Túbọ̀ Ń Peléke Sí I?

Àwọn Ìwà Ìkà Bíburú Jáì Kí Ló Dé Tí Wọ́n Túbọ̀ Ń Peléke Sí I?

Lówùúrọ̀ ọjọ́ kan, Frank àti Gabriella aya rẹ̀ rọra ń gbafẹ́ lọ létíkun kan ní ìpínlẹ̀ Oregon, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n sì ń wo bí oòrùn ṣe ń yọ bọ̀. Ara ò fu wọ́n rárá pé nǹkan kan fẹ́ ṣẹlẹ̀ sí wọn. Ìṣẹ́jú díẹ̀ lẹ́yìn èyí ni ẹnì kan sún mọ́ wọn tó sì yìnbọn lù wọ́n lágbárí, báwọn méjèèjì ṣe kú nìyẹn. Ṣé ẹni náà gbẹ̀san nǹkan kan tí wọ́n fi ṣe é ni? Àbí ó ń jowú wọn ni? Rárá o. Ẹni tó yìnbọn fún wọn náà kò mọ̀ wọ́n rí rárá o, èrò kan tó ti wà lọ́kàn rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ló gbé jáde—ìyẹn ni pé ó fẹ́ mọ bó ṣe máa ń rí láti pààyàn.

“Ní Sunday, ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù April ọdún 1996, Martin Bryant di ẹni táwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé kò ní gbàgbé bọ̀rọ̀, lẹ́yìn tó ṣe ohun kan tó kà sí bàbàrà nígbèésí ayé rẹ̀. Gbogbo ẹni tó ń bá pàdé lọ́nà ló ń yìnbọn fún bó ti ń rìn kiri ìlú Port Arthur, ní erékùṣù Tasmania, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ohun kan tó kà sí nǹkan amóríyá tó sì fún un ní ìmọ̀lára pé ó jẹ́ alágbára.” (Ìwé A Study of Our Decline, látọwọ́ Philip Atkinson) Èèyàn márùndínlógójì ló rán lọ sí sàréè!

Bàbá kan tó jẹ́ ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́ta tó sì ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè Kánádà ń gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀ lọ láàárọ̀ kùtù bó ṣe máa ń ṣe. Bó ti ń lọ, dírẹ́bà kan gbá a látẹ̀yìn, ó sì fi í sílẹ̀ pé bó bá lè kú kó kú. Nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin mítà ni mọ́tò náà fi wọ́ kẹ̀kẹ́ rẹ̀ tuuru lójú ọ̀nà náà. Ńṣe làwọn èèyàn tiẹ̀ kọ́kọ́ rò pé àwọn awakọ̀ tó máa ń gbá èèyàn tí wọ́n sì máa ń sá lọ ni. Ìwádìí síwájú sí i ló wá fi hàn pé ńṣe lẹni tó gbá bàbá náà lọ jí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà gbé tó sì ń wà á níwàkuwà kiri fún ìgbádùn. Kò sí tàbí ṣùgbọ́n pé “nǹkan amóríyá” ni gbígbá tó gbá bàbá oníkẹ̀kẹ́ náà jẹ́ fún un.

Ṣé Ìwà Ọ̀daràn Oríṣi Mìíràn Ló Tún Dóde Yìí Ni?

Ó pẹ́ tí ìwà ọ̀daràn ti wà, àmọ́ irú àwọn tá a mẹ́nu kàn lókè yìí ti ń mú káwọn èèyàn máa béèrè pé: “Kí ló dé? Báwo lẹnì kan ṣe lè ronú àtiṣe irú nǹkan báyìí?” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìwà ọ̀daràn wíwọ́pọ̀, irú bí olè jíjà tàbí èrú ṣíṣe lè má fi bẹ́ẹ̀ jọ àwọn èèyàn lójú mọ́, oríṣi àwọn ìwà ọ̀daràn mìíràn tó ń gbàfiyèsí àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ti ń peléke sí i báyìí, èyí tó ń mú káwọn èèyàn máa sọ lọ́kàn wọn pé, ‘Èyí ò bójú mu rárá! Ibo layé yìí tiẹ̀ ń lọ ná?’

Irú àwọn ìwà ọ̀daràn tá à ń sọ yìí tún yàtọ̀ o. Wọ́n máa ń kó jìnnìjìnnì báni, wọ́n sì máa ń rorò gan-an. Bíi ti àwọn àpẹẹrẹ tá a mẹ́nu kàn lókè, àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀, tí kì í ṣe pé wọ́n mọ àwọn ọ̀daràn náà rí níbikíbi, ni wọ́n sábà máa ń ṣe é sí. Yàtọ̀ síyẹn, lọ́pọ̀ ìgbà, ó tún máa ń dà bíi pé kò sí ìdí tó ní láárí kan pàtó tó ń mú wọn hu àwọn ìwà ìkà wọ̀nyí. Tá a bá wá ní ká máa kà wọ́n, wọn ò lópin.

Ní oṣù April ọdún 1999, ní ìpínlẹ̀ Colorado, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjì pa akẹ́kọ̀ọ́ méjìlá àti olùkọ́ kan nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀jò ìbọn nínú ọgbà ilé ìwé, àwọn náà sì para wọn lẹ́yìn náà. Ọkùnrin kan kú ní ìpínlẹ̀ California lọ́dún 1982 lẹ́yìn tó lo oògùn kan tó rà lórí àtẹ, èyí tí ẹnì kan ti fi májèlé kan tó ń jẹ́ strychnine sínú rẹ̀. Lọ́dún 1993, àwọn ọmọkùnrin méjì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá tan ọmọ ọlọ́dún méjì kan tó ń jẹ́ James Bulger kúrò nínú ibi ìtajà kan ní ìlú Bootle, ní àgbègbè Merseyside, nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, nígbà tí ìyá rẹ̀ wà nínú ìsọ̀ alápatà kan. Wọ́n mú un lọ sí ojú ọ̀nà ọkọ̀ ojú irin kan, wọ́n sì fi kóńdó lù ú pa.

A lè pe àwọn ìwà ọ̀daràn kan ní ìpániláyà, bí irú èyí tó wáyé ní ọ̀nà abẹ́lẹ̀ kan ní ìlú Tokyo lọ́dún 1995. Jìnnìjìnnì bo àwọn èèyàn ilẹ̀ Japan nígbà táwọn kan tó wà nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn lọ tú afẹ́fẹ́ olóró dà sí ọ̀nà abẹ́lẹ̀ kan ní ìlú Tokyo. Èèyàn méjìlá ló kú tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn sì ṣèṣe. Ọ̀pọ̀ èèyàn ò ní gbàgbé àjálù tó bá Ibùdó Ìṣòwò Àgbáyé ní ìlú New York, àti àjálù tó bá orílé-iṣẹ́ tó ń rí sọ́ràn ààbò, ìyẹn Pentangon, nítòsí Washington, D.C., lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, èyí tó gbẹ̀mí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta èèyàn. Bákan náà ni bọ́ǹbù tó bú lọ́dún tó kọjá ní ìlú Bali, ní orílẹ̀-èdè Indonesia, èyí tó gbẹ̀mí ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó igba èèyàn.

Ó hàn gbangba pé irú àwọn ìwà ìkà bíburú jáì báwọ̀nyí ti wá wọ́pọ̀ gan-an. Jákèjádò ayé nìṣòro yìí ti ń ṣẹlẹ̀, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló sì kàn. Kò yọ olówó sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni tálákà pàápàá ò mórí bọ́.

Nígbà míì, ńṣe ló máa ń dà bíi pé àwọn apààyàn yìí ń bára wọn díje, tí wọ́n á fẹ́ mọ ẹni tó lè hùwà ìkà tó burú jáì jù. Síwájú sí i, ńṣe làwọn ìwà ọ̀daràn tó jẹ́ pé ìkórìíra ló fà á náà túbọ̀ ń wọ́pọ̀ sí i. Ìpa-ìkà ni àwọn ọ̀daràn náà sì máa ń pa àwọn èèyàn tí “ẹ̀ṣẹ̀” wọn ò ju pé àwọ̀ wọn, ìsìn wọn, tàbí ẹ̀yà wọn yàtọ̀ lọ—bí irú ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1994, nígbà tí wọ́n pa nǹkan bí ogójì ọ̀kẹ́ [800,000] àwọn ẹ̀yà Tutsi nípakúpa ní orílẹ̀-èdè Rwanda.

Gbogbo èyí ló mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ronú pé: ‘Kí ló tiẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ gan-an? Ṣé bí nǹkan ṣe rí nígbà kan rèé ni? Kí ló lè mú káwọn èèyàn máa hu irú àwọn ìwà ìkà bíburú jáì báyìí? Ìrètí wo ló wà pé irú àwọn ìwà ọ̀daràn báyìí máa kásẹ̀ nílẹ̀ pátápátá tàbí pé wọ́n máa dín kù?’ Àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí àtàwọn mìíràn.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

Ẹnikẹ́ni táwọn tó ń hu ìwà ìkà bíburú jáì yìí bá rí ni wọ́n máa ń hù ú sí láìsí ìdí tó ní láárí kan tó mú wọn ṣe bẹ́ẹ̀