Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Òwe Ẹ̀yà Akan Òwe Tó Ń Gbé Àṣà Ìbílẹ̀ Lárugẹ

Àwọn Òwe Ẹ̀yà Akan Òwe Tó Ń Gbé Àṣà Ìbílẹ̀ Lárugẹ

Àwọn Òwe Ẹ̀yà Akan Òwe Tó Ń Gbé Àṣà Ìbílẹ̀ Lárugẹ

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ GÁNÀ

KÍ NI òwe? Ìwé atúmọ̀ èdè kan túmọ̀ òwe sí “gbólóhùn kúkúrú kan táwọn èèyàn sábà máa ń tọ́ka sí, bóyá láti fi fúnni nímọ̀ràn tàbí láti fi sọ ohun kan fúnni nípa ìgbésí ayé.” Àwọn ẹ̀yà Yorùbá tó wà lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà tiẹ̀ túmọ̀ òwe lọ́nà tó fani mọ́ra gan-an, wọ́n ní òwe ni “ẹṣin ọ̀rọ̀, bí ọ̀rọ̀ bá sọ nù òwe la fi ń wá a.”

Àwọn ẹ̀yà Akan tó wà ní orílẹ̀-èdè Gánà máa ń lo òwe kan dáadáa, èyí tó ń sọ bí òwe ṣe ṣe pàtàkì tó, wọ́n máa ń sọ pé: “Ààbọ̀ ọ̀rọ̀ là ń sọ fún ọmọlúwàbí, tó bá dénú rẹ̀ á di odindi.” Kókó inú òwe yìí ni pé kò dìgbà tá a bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ ní kíkún fún ọlọgbọ́n èèyàn kó tó mọ ohun tó yẹ kí òun ṣe. Òwe tó bá bá ọ̀rọ̀ mu máa ń mú kéèyàn ronú, ó máa ń jẹ́ kéèyàn lóye nǹkan, ó sì máa ń súnni láti ṣe ohun tó tọ́.

Nílẹ̀ Gánà, àwọn èèyàn máa ń lo òwe gan-an nígbà ayẹyẹ ìgbéyàwó àti nígbà ìsìnkú, bẹ́ẹ̀ ni òwe tún máa ń jẹ yọ nínú àwọn orin tó ń gbé ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn lárugẹ. Bákan náà, wọn ò lè ṣe kí wọ́n má lo òwe nígbà tí wọ́n bá ń yanjú ọ̀rọ̀ láàárín ara wọn. Agbẹnusọ tàbí aṣojú kan sábà máa ń lo ọ̀kan-kò-jọ̀kan òwe lọ́nà jíjáfáfá láti fi ṣàlàyé ọ̀rọ̀.

Ní àwùjọ àwọn ẹ̀yà Akan, lílo òwe lọ́nà jíjáfáfá jẹ́ àmì pé ẹnì kan jẹ́ amòye èèyàn. Ó yẹ fún àfiyèsí pé, nínú Bíbélì, Sólómọ́nì Ọba—ọkùnrin kan tí ó gbajúmọ̀ nítorí ọgbọ́n, ìmọ̀, àti òye tó ní nípa béèyàn ṣe ń bá ẹlòmíràn sọ̀rọ̀—ni àkọsílẹ̀ fi hàn pé ó mọ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta òwe. Ọlọ́run ló mí sí àwọn òwe inú Bíbélì, wọ́n sì ṣeé gbára lé, wọn kò dà bí àwọn òwe tí a gbé ka ìrírí àti òye ọmọ aráyé. Àmọ́, àwọn òwe ẹ̀dá èèyàn, láìka bí wọ́n ṣe lè mọ́gbọ́n dání tó, ni a kò gbọ́dọ̀ fi wé òwe Bíbélì. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn òwe Akan bíi mélòó kan.

Òwe Tó Ń Fi Èrò Wọn Nípa Ọlọ́run Hàn

Nílẹ̀ Gánà, òwe sábà máa ń fẹ̀rí hàn pé Ọlọ́run wà, èyí sì máa ń jẹ yọ nínú ọ̀pọ̀ òwe Akan. Àìgbọlọ́rungbọ́ kò sí nínú ìgbàgbọ́ àwọn ẹ̀yà Akan. Bí àpẹẹrẹ, òwe kan sọ pé: “A kì í fi Ọlọ́run han ọmọdé.” Ọ̀pọ̀ nǹkan ló fẹ̀rí hàn gbangba pé Ọlọ́run wà, kódà àwọn ọmọdé pàápàá mọ̀ pé ó wà. Wọ́n sábà máa ń lo òwe yìí nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa ohun kan tí kò ní ṣòro rárá fún ọmọdé kan láti mọ̀ láìṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ púpọ̀.

Òwe Akan mìíràn sọ pé: “Kò sí bó o ṣe lè sá tó, o ò lè sá mọ́ Ọlọ́run lọ́wọ́.” Nípa bẹ́ẹ̀, ẹni tó bá rò pé òún lè ṣe ohun kan tí Ọlọ́run ò ní rí òun wulẹ̀ ń tan ara rẹ̀ jẹ ni. Nígbà pípẹ́ sẹ́yìn, Bíbélì sọ kókó kan tó fara jọ èyí, nígbà tó sọ pé, ojú Ọlọ́run “ń bẹ ní ibi gbogbo, ó ń ṣọ́ àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.” (Òwe 15:3) Gbogbo wa la máa jíhìn fún Olódùmarè.

Òwe Tó Ń Fi Àṣà Tó Dára Láwùjọ Hàn

Gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn òwe tó jẹ́ ti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ mìíràn, àwọn òwe Akan jẹ́ ibi ìṣúra fún àwọn àṣà àti ìlànà ìwà híhù láwùjọ. Bí àpẹẹrẹ, òwe kan tó ń fi hàn kedere bí ọ̀rọ̀ ẹnu ṣe lágbára tó ni èyí tó sọ pé: “Kéèyàn fẹnu kọ burú ju kéèyàn fẹsẹ̀ kọ lọ.” Ahọ́n tí a kò bá ṣàkóso lè ṣe ọṣẹ́ ńláǹlà, kódà ó lè ṣekú pani pàápàá.—Òwe 18:21.

Àmọ́, bí a bá ṣàkóso ahọ́n wa, ahọ́n lè pẹ̀tù síjà, gẹ́gẹ́ bí àṣàyàn ọ̀rọ̀ yìí ṣe sọ, “Ahọ́n kì í wà nílé, kí eyín máa bá ara wọn jà.” Kókó inú òwe yìí ni pé, ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ lè yanjú ọ̀rọ̀ ní ìtùnbí-ìnùbí láàárín àwọn tó ń bára wọn jà, bóyá láàárín ọkùnrin kan àti ìyàwó rẹ̀. Kódà bí èyí kò bá ṣiṣẹ́ pàápàá, fífi ọgbọ́n lo ahọ́n nígbà tí wọ́n bá ń báni yanjú èdèkòyédè lè fòpin sí ìjà náà.

Òwe Tó Ń Kọ́ni Lọ́gbọ́n

Ìjẹ́pàtàkì níní òye àti làákàyè máa ń fara hàn kedere nínú ọ̀pọ̀ òwe tó ń kọ́ni lọ́gbọ́n. Ẹni tó bá ń fi ìwàǹwára ṣe nǹkan láìronú nípa ohun tó máa jẹ́ àbájáde àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ lè rí ọgbọ́n kọ́ látinú òwe tó sọ pé, “Ó yẹ kéèyàn kọ́kọ́ wá ibi tó máa sá gbà kó tó pe ṣèbé níjà.”

Òbí tó bá ń ṣàkíyèsí pé ọmọ òun ń hùwà kan tí kò bójú mu yóò fẹ́ láti kọ́gbọ́n lára òwe kan tó sọ pé, “Igi ganganran máà gún mi lójú, àtòkèrè la ti í lọ̀ ọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni o, a gbọ́dọ̀ tètè wá nǹkan ṣe sí ìwàkiwà tí ọmọ kan fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí hù kó tó di wàhálà ńlá síni lọ́rùn.

Òwe Tó Ń Sọ Nípa Àṣà Àtayébáyé Àtàwọn Àṣà Ìbílẹ̀

Nígbà míì, ó pọn dandan láti lóye àṣà ìbílẹ̀ kan dáadáa láti lè mọ ìtumọ̀ òwe rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ní àwùjọ àwọn ẹ̀yà Akan, ìwà àrífín ló jẹ́ láti máa lo ọwọ́ òsì níwájú àwọn ẹlòmíràn, pàápàá àwọn àgbàlagbà. Ìwà ọmọlúwàbí yìí ni òwe kan ṣàgbéyọ rẹ̀, ìyẹn òwe tó sọ pé, “Èèyàn kì í fi ọwọ́ òsì júwe ilé bàbá rẹ̀.” Ìtumọ̀ èyí ni pé, èèyàn gbọ́dọ̀ mọyì ohun ìní rẹ̀, títí kan orírun rẹ̀.

Òwe kan tó jẹ mọ́ àṣà oúnjẹ jíjẹ nínú ilé àwọn ẹ̀yà Akan sọ pé: “Ọmọ tó bá mọ ọwọ́ wẹ̀ á bá àgbà jẹun.” Lákòókò oúnjẹ, àwọn tó bá jẹ́ ọjọ́ orí kan náà ló máa ń bá ara wọn jẹun pọ̀. Àmọ́ o, ọmọ tó bá ṣe dáadáa, pàápàá tó jẹ́ onímọ̀ọ́tótó tó sì mọ̀wàá hù, ni bàbá rẹ̀ àtàwọn àgbàlagbà mìíràn lè fún láǹfààní àkànṣe láti bá wọn jẹun. Kókó inú òwe yìí ni pé, kì í ṣe ọjọ́ orí nìkan lohun tó ń jẹ́ káwọn èèyàn buyì fúnni àmọ́ béèyàn bá ṣe mọ̀wàá hù sí.

Ṣé ò ń ronú láti ṣègbéyàwó? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, gbé òwe Akan kan yẹ̀ wò, ìyẹn òwe tó sọ pé: “Ìgbéyàwó kì í ṣe ẹmu téèyàn lè tọ́ wò.” Àwọn tó ń ta ẹmu, ìyẹn ohun mímu kan tí wọ́n ń rí láti ara igi ọ̀pẹ, máa ń jẹ́ kí àwọn tó bá fẹ́ rà á kọ́kọ́ tọ́ ọ wò ná kí wọ́n tó sọ bí iye tí wọ́n máa rà ṣe máa pọ̀ tó tàbí bóyá wọ́n ò ní rà á mọ́. Àmọ́, ìgbéyàwó kì í ṣe ohun téèyàn lè tọ́ wò bẹ́ẹ̀. Òwe yìí ń fi hàn pé ìgbéyàwó jẹ́ ètò tó ní láti wà pẹ́ títí, àti pé ìgbéyàwó jẹ́-ká-dán-an-wò-ná kò bójú mu.

Fífẹ̀sọ̀ Ṣàkíyèsí Àwọn Nǹkan

Ọ̀pọ̀ òwe ń fi hàn pé àwọn baba ńlá àwọn ẹ̀yà Akan máa ń fara balẹ̀ kíyè sí àwọn èèyàn àtàwọn ẹranko. Bí àpẹẹrẹ, fífarabalẹ̀ kíyè sí àgbébọ̀ adìyẹ kan àtàwọn òròmọdìyẹ rẹ̀ ló mú kí wọ́n máa pòwe pé, “Òròmọdìyẹ tó bá dúró sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀ ló ń jẹ itan tata.” Kí ni ìtumọ̀ èyí? Béèyàn bá ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn, wọ́n á gbójú fò ó dá nígbà tí wọ́n bá ń pín ohun tó dáa.

Ẹnikẹ́ni tó bá ń wo àkèré tó ti kú kò ní ṣàì lóye ìtumọ̀ òwe tó sọ pé, “Ìgbà tí àkèré bá kú tán la máa ń mọ bó ṣe gùn tó.” Wọ́n sábà máa ń pa òwe yìí nígbà tí àwọn èèyàn ò bá mọyì ẹnì kan. Nígbà tí wọ́n bá hu irú ìwà yìí sẹ́nì kan, ó máa ń tu irú ẹni bẹ́ẹ̀ nínú láti mọ̀ pé tóun ò bá sí nítòsí lọ́jọ́ kan ó ṣeé ṣe kí èyí jẹ́ káwọn èèyàn rí i kedere pé òun wúlò.

Àwọn Òwe ní “Ìkékúrú”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àtẹnudẹ́nu ni àwọn òwe Akan, ìyẹn ni pé wọ́n ń gbà á láti ìran kan dé òmíràn, ọ̀pọ̀ ni wọ́n ń ṣàfihàn rẹ̀ nínú iṣẹ́ ọnà kí wọ́n má bàa pa run. Èèyàn lè rí irú àpẹẹrẹ àwọn òwe bẹ́ẹ̀ lára ère gbígbẹ́, ọ̀pá, ohun ìdíwọ̀n tí wọ́n fi góòlù ṣe, àti lára àwọn aṣọ ìbílẹ̀ àtàwọn aṣọ ìgbàlódé. Àwọn tó bá ṣèbẹ̀wò sí àwọn ibi tí wọ́n ń kó iṣẹ́ ọnà sí nílẹ̀ Gánà lè rí ère gbígbẹ́ kan tí wọ́n fi ń ṣàfihàn ọkùnrin kan tó ń gun igi nígbà tí ọkùnrin mìíràn ń ràn án lọ́wọ́. Ohun tí èyí ń fi hàn ni ọ̀rọ̀ òwe kan tó sọ pé, “Bó o bá ń gun igi tó dára, o lè rí ẹni tì ọ́ lẹ́yìn.” Kókó inú òwe yìí kò ṣòroó lóye—òun ni pé bó o bá dáwọ́ lé ohun tó gbayì, àwọn èèyàn lè ṣètìlẹyìn fún ọ.

Ètò ìsìnkú ní pàtàkì máa ń fún àwọn èèyàn láǹfààní láti ṣe ohun tí òǹkọ̀wé kan pè ní “fífi aṣọ pèdè.” Bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe jẹ́ àsìkò ọ̀fọ̀ máa ń mú káwọn èèyàn ronú jinlẹ̀ nípa ìgbésí ayé. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn iṣẹ́ ọnà tó máa ń wà lára àwọn aṣọ táwọn èèyàn ń wọ̀ nígbà ìsìnkú máa ń ṣàfihàn èrò wọn nípa àwọn nǹkan tó jẹ́ àdììtú nípa ìgbésí ayé. Bí àpẹẹrẹ, aṣọ tí wọ́n bá ya àkàbà tàbí àtẹ̀gùn sí lára lè ránni létí òwe kan tó sọ pé, “Kò sẹ́ni tí kò ní gun àkàbà ikú.” a Èyí jẹ́ ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ fún tọmọdétàgbà pé, kí wọ́n má ṣe máa gbé ara wọn ga, kí wọ́n má sì ṣe máa gbé ayé bíi pé ikú ò lè pa wọ́n.—Oníwàásù 7:2.

Ní àwùjọ àwọn ẹ̀yà Akan, àwọn aṣojú tàbí àwọn agbẹnusọ fún àwọn alákòóso ìbílẹ̀ máa ń mọ òwe lò dáradára, wọ́n sì tún máa ń mú ọ̀pá àṣẹ dání, èyí tí wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára láti fi ṣàfihàn àṣà dáradára kan táwọn èèyàn ń gbé lárugẹ. Bí àpẹẹrẹ, iṣẹ́ ọnà tó bá ṣàfihàn ẹyẹ tó fẹnu di orí ejò mú jẹ́ “ìkékúrú” fún òwe tó sọ pé, “Bó o bá ti di orí ejò mú, okùn lásán ni ìyókù gbogbo ara rẹ̀.” Kí ni òwe yìí ń fi hàn? A ní láti yanjú ọ̀ràn nípa mímú ohun tó jẹ́ ìṣòro ibẹ̀ kúrò.

Lílo Òwe Lọ́nà Yíyẹ

Gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn àkàwé mìíràn, ohun tá à ń sọ àti irú àwọn èèyàn tá à ń bá sọ̀rọ̀ ló máa pinnu ìgbà tí a lè lo òwe kan àti bí a ṣe lè lò ó. Àṣìpa òwe lè dín iyì ọ̀rọ̀ kan kù. Láfikún sí i, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé nínú àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ kan, ìlò òwe jẹ́ apá pàtàkì kan nínú bí àwọn èèyàn ṣe máa ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, ṣíṣi òwe lò lè mú kí àwọn èèyàn fi ojú tí kò dára wo irú ẹni bẹ́ẹ̀.

Ní orílẹ̀-èdè Gánà, àwọn àgbààgbà tó wà láwùjọ làwọn èèyàn máa ń kà sí ẹni tó ni òwe. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ kí wọ́n tó pòwe ni pé, “Àwọn àgbà máa ń sọ pé . . . ” Tó bá sì jẹ́ pé àwọn àgbààgbà tó lọ́jọ́ lórí gan-an lèèyàn ń bá sọ̀rọ̀, ohun tó yẹ kí ọmọlúwàbí èèyàn ṣe láti fi ọ̀wọ̀ hàn ni pé, ṣáájú kó tó pa òwe, kó kọ́kọ́ sọ gbólóhùn kan báyìí pé, “Ẹ̀yin àgbà ló máa ń sọ pé . . . ” Láti fi ọ̀wọ̀ hàn, ẹni tó ń sọ̀rọ̀, tó kéré lọ́jọ́ orí sí àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀, kò ní fẹ́ kí wọ́n máa rò pé òún ń kọ́ àwọn àgbàlagbà ní àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú òwe tí òún ń pa.

Àwọn Àkíyèsí Pàtàkì

Òwe lè ṣáájú ọ̀rọ̀ tàbí kó gbẹ̀yìn rẹ̀. Bákan náà, a lè fi ọgbọ́n wé e mọ́ ọ̀rọ̀ láàárín tó fi jẹ́ pé ẹni tó bá lè ronú jinlẹ̀ nìkan ló máa lè lóye ohun tá à ń sọ. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ẹnì kan tó jẹ́ ẹ̀yà Akan bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹlẹ́mìí àlàáfíà, ó lè sọ pé: “Bá a bá fi dá ti Lágbájá nìkan, kò ní sí ìró ìbọn kan ṣoṣo nínú abúlé yìí.” Èyí ń tọ́ka sí òwe tó sọ pé, “Bá a bá fi dá ti ìgbín àti ìjàpá nìkan, kò ní sí ìró ìbọn kankan nínú igbó.” Àwọn èèyàn ka àwọn ìṣẹ̀dá méjèèjì yìí sí ẹ̀dá jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, tí kì í yọni lẹ́nu, tí kò sì ń wáni níjà. Àwọn èèyàn tó bá ní àwọn ànímọ́ wọ̀nyí máa ń mú kí àlàáfíà wà níbi tí wọ́n bá wà.

Àmọ́ o, bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan tó jẹ́ ẹ̀yà Akan máa pa òwe tẹ̀léra-tẹ̀léra, ó lè fi ẹyọ kan ṣoṣo dá ọ lóhùn, kó sọ pé, “Èèyàn ò lè lálàá láìjẹ́ pé ó sùn.” Lédè mìíràn, èèyàn ò lè lo òwe láìjẹ́ pé èèyàn ń sọ ọ̀rọ̀ tó bá a mu lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ pé èèyàn ò lè lálàá láìjẹ́ pé ó sùn. Ọ̀rọ̀ téèyàn bá ń sọ ló máa pinnu irú òwe tó máa pa àti ìgbà tó máa pa á.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A lè rí iṣẹ́ ọnà yìí lára àwọn aṣọ tó jẹ́ àwọ̀ oríṣiríṣi tí àwọn èèyàn lè lò nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àwọn ayẹyẹ mìíràn, kì í ṣe lára àwọn aṣọ dúdú tí wọ́n sábà máa ń lò nígbà ìsìnkú nìkan.