Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Fara Dà Á Nígbà Tí Àjálù Bá Wáyé?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Fara Dà Á Nígbà Tí Àjálù Bá Wáyé?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Fara Dà Á Nígbà Tí Àjálù Bá Wáyé?

“Kí nìdí tí àwọn apániláyà fi ní láti pa màmá mi?”—Kevin. a

“[Ṣáájú September 11], mo fẹ́ràn kí n máa gba ọ̀nà abẹ́lẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, ńṣe ni mo máa ń ronú pé mo lè lọ kú síbẹ̀ táwọn oníṣẹ́ ibi bá lọ fi bọ́ǹbù fọ́ ọ.”—Peter.

ÀJÁLÙ tó wáyé ní September 11, 2001, nígbà tí àwọn apániláyà ba Ibùdó Ìṣòwò Tó Tóbi Jù Lọ Lágbàáyé jẹ́ ní ìlú New York City, ló ṣekú pa ìyá Kevin. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mọ̀lẹ́bí Peter kò kú bíi ti Kevin, àmọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà kó ìdààmú bá a gidigidi.

Ìròyìn kan sọ pé: “Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọdé tó ń gbé ní ìlú New York ni onírúurú ìṣòro ọpọlọ ń bá fínra, èyí tó jẹ yọ látàrí [ìṣẹ̀lẹ̀ láabi tó wáyé ní] September 11, bí àwọn ìṣòro wọ̀nyí sì ṣe máa bá ọ̀pọ̀ jù lọ wọn dàgbà nìyẹn.” Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé, bí àwọn àmì tó ń fi hàn pé èèyàn ní ìdààmú ọkàn “ṣe wọ́pọ̀ nínú àwọn ọmọdé tó fojú rí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ló ṣe wọ́pọ̀ nínú àwọn ọmọdé tó ń gbé níbi tó jìnnà gan-an sí ọ̀gangan ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.” b

Irú àwọn ìṣòro wọ̀nyí tún lè jẹ yọ látàrí àwọn àjálù mìíràn, irú bí àwọn èèyànkéèyàn ṣe máa ń so bọ́ǹbù mọ́ra tí wọ́n á sì fi gbẹ̀mí ara wọn àti tàwọn ẹlòmíràn ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, àti bí àwọn èèyàn kan ṣe máa ń ṣíná ìbọn bolẹ̀ láìbìkítà láwọn ibòmíràn. Nígbà tí ògbógi kan tó mọ̀ nípa àwọn àbájáde ìdààmú ọkàn ń sọ̀rọ̀ nípa irú ìbọn yíyìn láìbìkítà bẹ́ẹ̀, ó ní: “Kódà bó bá jẹ́ pé ẹgbẹ̀rún mẹ́ta kìlómítà síbi tí wọ́n ti ń yìnbọn [làwọn ọmọdé náà ń gbé], ó ṣì lè mú kí ìpayà [wọn] pọ̀ sí i.”

Kí ló fà á tí wọ́n fi ń ní ìpayà? Ìdí ni pé, nígbà táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bíburú jáì bá wáyé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan làwọn èwe máa ń rí tí wọ́n sì máa ń gbọ́ nínú ìròyìn. Wọ́n máa ń wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń dẹ́rù bani gidigidi ní àwòtúnwò, irú bí àwọn apániláyà ṣe fi bọ́ǹbù ba ibì kan jẹ́, ìṣẹ̀lẹ̀ ìbọn yíyìn ní ilé ẹ̀kọ́, àtàwọn ìjábá mìíràn lóríṣiríṣi, èyí á sì mú kó ṣòro fún ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ láti mọ́kàn kúrò lórí irú àwọn àjálù bẹ́ẹ̀. Abájọ tí ìwádìí kan tí Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ẹ̀kọ́ ní Ìlú New York City ṣètò rẹ̀ ṣe fi hàn pé: “Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tí Ibùdó Ìṣòwò Tó Tóbi Jù Lọ Lágbàáyé ti wó palẹ̀, ìdá mẹ́rìndínlọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọmọ iléèwé tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ ó lé igba àti mẹ́rìndínláàádọ́rin [8,266] ṣì máa ń ronú lemọ́lemọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà.”

À ń gbé ní àkókò kan tí Bíbélì pè ní “àkókò bíburú jáì.” (2 Tímótì 3:1-5, New International Version) Báwo wá lo ṣe lè fara dà á nígbà tí àjálù bíburú jáì bá wáyé? c

Ìdí Tí Àwọn Ohun Búburú Fi Ń Ṣẹlẹ̀

Ọ̀nà kan tó o lè gbà kojú ẹ̀dùn ọkàn tó lè dà bíi pé ó fẹ́ bò ọ́ mọ́lẹ̀ ni láti ru “agbára ìrònú [rẹ] ṣíṣe kedere” sókè. (2 Pétérù 3:1) Gbìyànjú láti ronú jinlẹ̀ lórí ipò tó o bá ara rẹ, kó o sì ronú nípa ohun tó jẹ́ ojú ìwòye Ọlọ́run nípa rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, o lè rán ara rẹ létí pé ọ̀pọ̀ àjálù tó ń wáyé wulẹ̀ jẹ́ àbájáde “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀.” (Oníwàásù 9:11) Jésù Kristi fún wa ní àpẹẹrẹ kan nípa èyí nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa ilé gogoro kan tó wó lulẹ̀ ní Sílóámù. Èèyàn méjìdínlógún ló kú nínú àjálù tó wáyé ní àgbègbè náà. Àmọ́, Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé kì í ṣe pé ńṣe ni Ọlọ́run fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ àwọn ẹni tó kàgbákò náà níyà. Ohun tó pa wọ́n kò wulẹ̀ ju pé wọ́n rìn sí àkókò tí ìṣẹ̀lẹ̀ aburú náà wáyé. (Lúùkù 13:1-5) Ṣíṣe àṣàrò lórí kókó yìí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fojú tó tọ́ wo àjálù.

Ríronú jinlẹ̀ tún lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yẹra fún dídi ẹni “tí ó kún fún ìhónú sí Jèhófà,” àti dídá a lẹ́bi fún ìṣẹ̀lẹ̀ apanilẹ́kún tó ṣẹlẹ̀. (Òwe 19:3) Jèhófà kọ́ ló ń mú ìnira bá wa, dípò èyí, òún jẹ́ “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” (2 Kọ́ríńtì 1:3) Nígbà tí àjálù bá wáyé, ńṣe ló yẹ ká sún mọ́ ọn—kì í ṣe pé ká fi ìbínú yẹra fún un. Ṣàṣàrò lórí ọ̀rọ̀ Bíbélì tó wà ní Jákọ́bù 1:13: “Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá wà lábẹ́ àdánwò, kí ó má ṣe sọ pé: ‘Ọlọ́run ni ó ń dán mi wò.’ Nítorí a kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” d

Ìṣẹ̀lẹ̀ bíburú jáì kan tó wáyé ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé tànmọ́lẹ̀ sórí kókó yìí. Bíbélì sọ fún wa pé ẹnì kan ṣoṣo tó yè nínú àjálù yẹn ròyìn pé: “Iná Ọlọ́run bọ́ láti ọ̀run, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jó láàárín àwọn àgùntàn àti àwọn ẹmẹ̀wà, ó sì jó wọn run.” (Jóòbù 1:16) Áà rẹ́rẹ́ rún! Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, ńṣe ni ọkùnrin tí jìnnìjìnnì ti bá yìí ń rò pé Ọlọ́run ló fà á. Àmọ́, kì í ṣe Ọlọ́run. Jóòbù 1:7-12 fi hàn pé ẹni tó fa iná náà kì í ṣe Ọlọ́run, bí kò ṣe Elénìní Ọlọ́run—Sátánì Èṣù!

Ìṣẹ̀lẹ̀ àrà ọ̀tọ̀ kan ni ìyẹn jẹ́: Jèhófà ló dìídì yọ̀ǹda fún Sátánì láti dán ìwà títọ́ Jóòbù wò. Nítorí náà, má ṣe ronú pé Sátánì ní tààràtà, ló ń fa àwọn àjálù bí ìjì líle àti omíyalé. e Síbẹ̀síbẹ̀, Bíbélì sọ pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Nípa bẹ́ẹ̀, ó lè lo àwọn ẹ̀dá èèyàn láti fa jàǹbá àti àjálù.

Àmọ́ o, kò yẹ ká sọ̀rètí nù. Tún gbé ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn yẹ̀ wò, èyí tá a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú Bíbélì nínú 1 Sámúẹ́lì 22:12-23. Níbẹ̀, a kà nípa bí wọ́n ṣe pa àwọn àlùfáà olóòótọ́ kan àtàwọn ìdílé wọn nípakúpa. Láìsí àní-àní, Sátánì kò ṣàì lọ́wọ́ nínú títi ọba búburú náà, Sọ́ọ̀lù láti hu ìwà ìkà bíburú jáì yìí. Bó ti wù kó rí, Dáfídì olùṣòtítọ́, ẹni tí òun náà di ọba lẹ́yìn ìgbà náà, kọ Sáàmù orí kejìléláàádọ́ta, níbi tó ti fi ìgbọ́kànlé rẹ̀ hàn pé Ọlọ́run yóò pa àwọn ẹni ibi tó ṣokùnfà àjálù náà run.—Sáàmù 52:5.

Bákan náà lónìí, jẹ́ kó dá ọ lójú pé Ọlọ́run kì yóò gba ìpànìyàn àti ìwà ipá tí Èṣù ń ṣokùnfà láyè láti máa bá a lọ títí láé. Àní, Bíbélì ṣèlérí pé láìpẹ́, Ọlọ́run yóò lo Ọmọ rẹ̀ láti “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú”! (1 Jòhánù 3:8) Bópẹ́ bóyá, gbogbo ìràlẹ̀rálẹ̀ ọṣẹ́ tí Sátánì ti ṣe á kásẹ̀ ńlẹ̀. Nípasẹ̀ àjíǹde, Ọlọ́run tún lè mú kí àwọn èèyàn tó ti kú nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bíburú jáì bí ìwà ipá tàbí ìpániláyà wàláàyè lẹ́ẹ̀kan sí i.—Ìṣe 24:15.

Àwọn Ohun Tó Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́ Láti Fara Dà Á

Ìrètí tá a gbé ka Bíbélì yìí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ kí ìbẹ̀rù má bàa kó jìnnìjìnnì bá ọ. Àmọ́, àwọn ohun mìíràn tó lè ṣèrànwọ́ wà tó o lè ṣe. Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí ìlànà Bíbélì tó wà ní Òwe 12:25. Sísọ bí ọ̀ràn ṣe rí lára rẹ fún àwọn ẹlòmíràn nìkan lohun tó lè jẹ́ kó o gbọ́ “ọ̀rọ̀ rere” tó jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣírí. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò tún ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ pé kì í ṣe ìwọ nìkan lò ń kojú ìṣòro náà. Nítorí náà, bó o bá ń ní ìdààmú ọkàn, gbìyànjú láti sọ ohun tó ń dùn ọ́ fún àwọn òbí rẹ tàbí fún ẹnì kan tó dàgbà dénú nínú ìjọ Kristẹni. f

Àmọ̀ràn mìíràn rèé o: Má ṣe máa wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ búburú tí wọ́n ń fi hàn lórí tẹlifíṣọ̀n ní àwòtúnwò. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò kàn máa jẹ́ kó túbọ̀ nira fún ọ láti mọ́kàn kúrò lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú náà ni.—Sáàmù 119:37.

Ṣé Kristẹni ni ọ́? Nígbà náà, má ṣe dẹwọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni rẹ. (Fílípì 3:16) Lára irú àwọn ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀ ni lílọ sí ìpàdé pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ àti sísọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa ìgbàgbọ́ rẹ. (Hébérù 10:23-25) Ìyẹn yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti má ṣe máa ronú ṣáá nípa àwọn èrò tí kò tọ́. Ńṣe ni dídá nìkan wà yóò túbọ̀ dá kún ìdààmú ọkàn rẹ, yóò sì ṣèpalára fún ọ nípa tẹ̀mí.—Òwe 18:1.

Bí a bá bára wa nínú ipò èyíkéyìí tí nǹkan ò ti fara rọ, bíbá ètò kíka Bíbélì lójoojúmọ́ lọ láìdáwọ́dúró lè ṣèrànwọ́ gidigidi fún wa. Ní àkókò tí àrùn jẹjẹrẹ ń bá ìyá ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Loraine fínra gidigidi, kíyè sí bó ṣe kojú ipò líle koko yìí. Ó sọ pé: “Mo rántí pé mo ka ìwé Jóòbù láìmọye ìgbà ní gbogbo ìgbà tí nǹkan ò fara rọ yẹn. Ìwé Sáàmù tún pèsè ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ìtùnú fún mi. Bí mo ṣe ń ka àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú látinú Ìwé Mímọ́, ńṣe ló ń dà bíi pé Jèhófà ń fọwọ́ gbá mi mọ́ra.” Arábìnrin rẹ̀ Mishael náà sọ pé: “Bí mi ò bá ka Bíbélì lọ́jọ́ kan, mo máa ń mọ̀ ọ́n lára. Kíá lọkàn mi á ti bẹ̀rẹ̀ sí í ro àwọn èrò tí kò tọ́. Kíka Bíbélì fún mi ní oúnjẹ amáralókun nípa tẹ̀mí tí mo nílò láti máa fara dà á lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan.”

Bó o bá lẹ́nì kan tó ti kú—pàápàá bí ẹni náà bá jẹ́ ara ìdílé rẹ—kíka ìwé pẹlẹbẹ náà, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú  g lè fún ọ ní ìtùnú gan-an. Wá àyè láti ka gbogbo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí, kó o sì ṣàṣàrò lórí wọn. Bákan náà, tún ṣàṣàrò lórí ìrètí àjíǹde. Loraine sọ pé: “Mo máa ń fọkàn yàwòrán pé ìyá mi jí dìde. Màá sì máa fojú inú wò ó pé, ó ń sọ fún mi pé: ‘Mo ti dé o. Ó yá, kí lo sè fún jíjẹ lálẹ́ òní?’ Ṣíṣe èyí máa ń múnú mi dùn.”

Gbígbára lé Jèhófà nínú àdúrà tún lè fún ọ ní okun tó o nílò láti fara da àwọn àjálù tó burú jáì. Loraine sọ pé: “Inú iyàrá ni mo wà nígbà tí ìyá mi dákẹ́. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo gbàdúrà sí Jèhófà láti fún mi lókun kí n lè fara dà á, kí n sì lè kojú ipò yìí. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ náà ni mo sì nímọ̀lára àlàáfíà Ọlọ́run.” Jẹ́ kí àdúrà tó ò ń gbà sí Jèhófà ṣe pàtó. Jẹ́ kó mọ bí ọ̀ràn ṣe rí lára rẹ gan-an. Onísáàmù rọ̀ wá pé: “Ẹ tú ọkàn-àyà yín jáde níwájú rẹ̀.”—Sáàmù 62:8.

Bí àkókò ṣe ń lọ, kò sí àní-àní pé ńṣe ni wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ láyé yóò máa pọ̀ sí i. (2 Tímótì 3:13) Síbẹ̀síbẹ̀, Bíbélì ṣèlérí pé: “Àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:9-11, 29) Rírọ̀ mọ́ ìrètí yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí ní fífara da àjálù tó bá wáyé.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

b Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn ògbógi nípa ìlera ọpọlọ sọ, lára irú àwọn àmì bẹ́ẹ̀ lè jẹ́, kí gbogbo nǹkan súni pátápátá, kéèyàn máa lálàá tó ń dẹ́rù bani, kéèyàn fẹ́ láti dá nìkan wà, kí ara ẹni máà gbé kánkán láti ṣe ohunkóhun, àti kí ẹ̀rí ọkàn máa dáni lẹ́bi tàbí kí inú máa bíni.

c Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àjálù kíkàmàmà ni àpilẹ̀kọ yìí ń sọ̀rọ̀ lé lórí ní tààràtà, a tún lè lo ìmọ̀ràn tá a pèsè láti kojú àwọn ìṣòro tó lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kọ̀ọ̀kan, irú bí ikú olólùfẹ́ ẹni.

d Fún ìjíròrò lórí ìdí tí Ọlọ́run fi fi àyè gba ìwà ibi, wo orí 7 ìwé náà, Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà, èyí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

e Wo “Ibere Lati ọwọ awọn Onkawe Wa” nínú Ile-Iṣọ Na ti June 1, 1975.

f Àmọ́, bó o bá ní ẹ̀dùn ọkàn tó kọjá ààlà, á dáa kó o lọ rí àwọn oníṣègùn.

g Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló tẹ̀ ẹ́ jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ó dára kó o dín wíwo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bíburú jáì tí wọ́n ń fi hàn lórí tẹlifíṣọ̀n kù