Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí A Ṣe Pa Òùngbẹ Tẹ̀mí Tó Ń Gbẹ Mí

Bí A Ṣe Pa Òùngbẹ Tẹ̀mí Tó Ń Gbẹ Mí

Bí A Ṣe Pa Òùngbẹ Tẹ̀mí Tó Ń Gbẹ Mí

GẸ́GẸ́ BÍ LUCIA MOUSSANETT ṢE SỌ Ọ́

ÀGBÈGBÈ Valle d’Aosta wà ní àárín gbùngbùn àwọn òkè ńlá tó wà ní ìkangun ìhà àríwá ilẹ̀ Ítálì, nítòsí àwọn òkè ńlá Swiss Alps, ó sì sún mọ́ òkè Mont Blanc lílókìkí tó wà nílẹ̀ Faransé. Ibẹ̀ ni wọ́n bí mi sí lọ́dún 1941, ní àrọko kékeré kan tó ń jẹ́ Challant St. Anselme.

Èmi ni mo dàgbà jù nínú àwa ọmọ márùn-ún; ọkùnrin làwọn àbúrò mi mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Òṣìṣẹ́ aláápọn ni màmá wa, ó sì jẹ́ ọmọ ìjọ Kátólíìkì tí kì í fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré rárá. Inú ìdílé onísìn ni bàbá mi náà ti wá. Méjì lára àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ló jẹ́ obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé. Àwọn òbí mi fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan du ara wọn nítorí mi, lára ìwọ̀nyí sì ni pé wọ́n jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́. Kò sí iléèwé kankan ní àrọko kékeré tá à ń gbé, nítorí náà nígbà tí mo di ọmọ ọdún mọ́kànlá, àwọn òbí mi ṣètò pé kí n lọ sí iléèwé kan tó ní ibùgbé fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́, èyí tí àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ń bójú tó.

Níbẹ̀, mo kọ́ èdè Látìn àti èdè Faransé, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka ẹ̀kọ́ mìíràn. Nígbà tí mo wá di ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, mo bẹ̀rẹ̀ sí ronú jinlẹ̀-jinlẹ̀ nípa bí mo ṣe lè sin Ọlọ́run. Mo ronú pé lílọ sí ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ni ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà sin Ọlọ́run. Àmọ́ o, àwọn òbí mi kò fara mọ́ èrò mi yìí rárá, torí pé Màmá nìkan ni ẹrù iṣẹ́ bíbójútó àwọn arákùnrin mi máa já lé léjìká. Ìrètí àwọn òbí mi ni pé ẹ̀kọ́ mi á jẹ́ kí n rí iṣẹ́ tó dára, yóò sì jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti pèsè owó fún gbígbọ́ bùkátà ìdílé wa.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí àwọn òbí mi ṣe gba ọ̀rọ̀ náà bà mí nínú jẹ́, mo fẹ́ láti rí ète gidi nígbèésí ayé, mo sì ronú pé ìfẹ́ Ọlọ́run ló yẹ kó gba ipò àkọ́kọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, lọ́dún 1961, mo di ọ̀kan lára àwọn onísìn tó ń gbé ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé kan tó jẹ́ ti àwọn ẹlẹ́sìn Roman Kátólíìkì.

Ìgbésí Ayé Mi Gẹ́gẹ́ Bí Obìnrin Ajẹ́jẹ̀ẹ́ Ìnìkàngbé

Ní àwọn oṣù àkọ́kọ́ níbẹ̀, mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn òfin àti ìlànà ṣọ́ọ̀ṣì náà, mo sì ṣiṣẹ́ láyìíká ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà. Ní August 1961, mo bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ṣẹ́ mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ aṣọ tí àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé máa ń wọ̀. Bákan náà, mo sọ ìpinnu mi jáde láti sọ ara mi lórúkọ tuntun kan, ìyẹn ni Ines, tó jẹ́ orúkọ ìyá mi. Nígbà tí wọ́n fọwọ́ sí i, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pè mí ní Arábìnrin Ines.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àyíká ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà ni ọ̀pọ̀ lára àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀dé tó ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti máa ń ṣiṣẹ́, ìwọ̀nba ìwé tí mo kà mú kí n tóótun láti máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ àwọn ọmọ iléèwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Ní ọdún méjì lẹ́yìn náà, ní August 1963, mo jẹ́ ẹ̀jẹ́, mo sì di obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé nínú ẹgbẹ́ olùjọsìn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Àwọn Arábìnrin ti San Giuseppe, ní àgbègbè Aosta, nílẹ̀ Ítálì. Lẹ́yìn náà, àwọn alábòójútó ilé àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà tún ṣètò pé kí n lọ gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ nípa rírán mi lọ sí Yunifásítì ti Maria Santissima Assunta tó wà ní ìlú Róòmù.

Nígbà tí mo padà sí Aosta lọ́dún 1967 lẹ́yìn tí mo parí ẹ̀kọ́ mi ní ìlú Róòmù, mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga kan. Lọ́dún 1976, wọ́n fi mí ṣe ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì ń kọ́ àwọn ọmọléèwé lẹ́kọ̀ọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ náà, mo sì wá di ọmọ ẹgbẹ́ Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Ẹ̀kọ́ ní àgbègbè Valle d’Aosta.

Ohun tó wà lọ́kàn mi gan-an ni ríran àwọn aláìní lọ́wọ́. Mo máa ń fi ọ̀ràn wọn ro ara mi wò. Nítorí náà, mo dá onírúurú ètò ìfẹ́dàáfẹ́re sílẹ̀, lára ìwọ̀nyí ni ọ̀kan tó wà fún ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn tí àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí ń bá fínra àmọ́ tí wọn kò ní ìdílé. Mo tún dá ètò kan sílẹ̀ láti máa kọ́ àwọn ọmọ àwọn àjèjì tó ṣí wọ̀lú lẹ́kọ̀ọ́. Láfikún sí i, mo máa ń bá àwọn aláìní wá iṣẹ́ àti ilé, mo sì máa ń ṣètò owó láti fi tọ́jú àwọn aláìsàn tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Mo gbìyànjú láti máa gbé ayé mi níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà ìsìn tí ṣọ́ọ̀ṣì náà fi lélẹ̀.

Ní àkókò náà, mo tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ ìsìn Kátólíìkì, títí kan àwọn ẹ̀kọ́ bíi Mẹ́talọ́kan, àìleèkú ọkàn, àti ojú ìwòye àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì nípa ọjọ́ ọ̀la ayérayé ẹ̀dá èèyàn. Lákòókò yẹn, ẹ̀kọ́ ìsìn Kátólíìkì tún fàyè gba àwọn ọmọ ìjọ láti ní ojú ìwòye ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nípa ọ̀ràn ẹ̀sìn, irú bí àmúlùmálà ìgbàgbọ́, èyí tó túmọ̀ sí pé èèyàn lè fara mọ́ àwọn ìsìn mìíràn ó sì lè máa bá wọn ṣe pọ̀.

Àwọn Ọ̀ràn Tó Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Dà Mí Lọ́kàn Rú

Síbẹ̀, àwọn ohun kan nínú ìlànà Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ń dà mí lọ́kàn rú. Bí àpẹẹrẹ, ṣáájú ìbatisí àti ìgbọ́wọ́léni-lórí, ó yẹ kí àwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn ti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí túmọ̀ sí. Àmọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn òbí wọ̀nyí àtàwọn ọmọ wọn ni kì í wá sí kíláàsì ìsìn, àwọn mìíràn kò sì sapá rárá láti kẹ́kọ̀ọ́. Síwájú sí i, ńṣe làwọn tí a kò bá tẹ́wọ́ gbà fún ìbatisí àti ìgbọ́wọ́léni-lórí ní ṣọ́ọ̀ṣì àgbègbè wọn á kàn wulẹ̀ lọ sí ti àgbègbè mìíràn láti lọ ṣe ìbatisí tàbí ìgbọ́wọ́léni-lórí níbẹ̀. Lójú tèmi, ìgbàgbọ́ oréfèé tí kò tọkàn ẹni wá àti ìwà àgàbàgebè ni ìyẹn jẹ́.

Nígbà míì, màá rò ó títí, màá sì béèrè lọ́wọ́ àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ẹlẹgbẹ́ mi pé, “Ṣé kì í ṣe Ìhìn Rere ló yẹ ká máa wàásù ni dípò tí a ó fi máa fi tọkàntara lọ́wọ́ sí onírúurú àwọn ìgbòkègbodò mìíràn?” Àwọn ẹlẹgbẹ́ mi yòókù á dá mi lóhùn pé: “Ṣíṣe iṣẹ́ rere la fi ń wàásù.”

Láfikún sí i, ó ṣòro fún mi láti gbà gbọ́ pé mo ní láti máa lọ sọ́dọ̀ àlùfáà láti lọ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi. Mo ronú pé ó yẹ kí n lè bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nípa irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ tó jẹ́ tara mi. Síwájú sí i, híhá àdúrà sórí àti sísọ ọ́ ní àsọtúnsọ jẹ́ ohun kan tó ṣòro fún mi láti tẹ́wọ́ gbà. Ó tún ṣòro fún mi láti gbà gbọ́ pé póòpù jẹ́ aláìlẹ́ṣẹ̀. Bí àkókò ti ń lọ, mo parí èrò sí pé màá máa ṣe ohun tí mo rò pé ó tọ́ lórí irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, màá sì máa ṣe ojúṣe mi lọ nínú ẹ̀sìn náà.

Ìfẹ́ Láti Ní Ìmọ̀ Bíbélì

Mo ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Bíbélì, mo sì máa ń yán hànhàn láti mọ̀ nípa rẹ̀. Nígbàkigbà tí mo bá fẹ́ ṣe ìpinnu kan tàbí tí mo rí i pé ó yẹ kí n wá ìtìlẹyìn Ọlọ́run, mo máa ń ka Bíbélì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rí ní ilé àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà, mo máa ń kà á fúnra mi. Àkọsílẹ̀ Aísáyà 43:10-12, níbi tí Jèhófà Ọlọ́run ti sọ pé, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” máa ń wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin. Àmọ́, ní gbogbo ìgbà yẹn, mi ò lóye gbólóhùn yẹn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

Nígbà tí mo wà ní yunifásítì ní ìlú Róòmù lágbedeméjì ẹ̀wádún tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1960, mo ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́dún mẹ́rin kan nípa ẹ̀kọ́ ìsìn, èyí tí Ibùjókòó Ìjọba Póòpù ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀. Àmọ́, Bíbélì kò sí lára àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a lò níbẹ̀. Lẹ́yìn tí mo padà sí Aosta, mo lọ sí onírúurú àpéjọ tó wà fún ìṣọ̀kan àwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni kárí ayé, kódà mo pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé tí àgbájọpọ̀ ẹ̀sìn àtàwọn ìsìn tí kì í ṣe Kátólíìkì ṣètò. Èyí jẹ́ kí n túbọ̀ máa yán hànhàn láti túbọ̀ mọ àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú Bíbélì. Àìfohùnṣọ̀kan pọ̀ láàárín àwọn ẹgbẹ́ tí wọ́n sọ pé àwọ́n ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Mímọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì

Lọ́dún 1982, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá síbi tí mo ti ń ṣiṣẹ́ ìfẹ́dàáfẹ́re, ó sì gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nípa Bíbélì pẹ̀lú mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ mi dí gan-an, èrò nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wú mi lórí. Nítorí náà mo sọ pé, “Jọ̀wọ́, wá bá mi ní ilé ẹ̀kọ́, ká lè sọ̀rọ̀ nígbà tí ọwọ́ mi bá dilẹ̀.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé obìnrin náà wá wò mí, kò sí ‘àkókò tí ọwọ́ mi ń dilẹ̀’ lẹ́nu iṣẹ́ mi. Kò pẹ́ sígbà náà ni mo gbọ́ pé ìyá mi ti ní àrùn jẹjẹrẹ, nítorí náà mo tọrọ àyè níbi iṣẹ́ láti lọ ràn án lọ́wọ́. Lẹ́yìn ikú rẹ̀ ní April 1983, mo padà sẹ́nu iṣẹ́ mi, àmọ́ nígbà yẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí ti wá mi títí wọn kò sì mọ ibi tí mo wà. Àmọ́, kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni Ẹlẹ́rìí mìíràn, ẹni tó tó ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, wá sọ́dọ̀ mi láti bá mi sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Mo ti ń ka ìwé Ìṣípayá nínú Bíbélì fúnra mi nígbà yẹn. Nítorí náà, mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Àwọn wo ni àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí Bíbélì mẹ́nu kàn nínú Ìṣípayá orí kẹrìnlá?”

Wọ́n ti fi kọ́ mi pé gbogbo èèyàn rere ló máa lọ sọ́run, nípa bẹ́ẹ̀ mi ò gbà pé ó bọ́gbọ́n mu rárá pé a óò ya àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì lára àwọn wọ̀nyí sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn yòókù ní ọ̀run. Mo ṣe kàyéfì pé, ‘Ta ni àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì yìí? Kí ni wọ́n máa ṣe?’ Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí kàn ń jà gùdù lọ́kàn mi ṣáá ni. Ẹlẹ́rìí náà kò yéé wá mi wá, àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé, mo lè máà sí nílé, nípa bẹ́ẹ̀ kò ṣeé ṣe fún un láti rí mi.

Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Ẹlẹ́rìí náà mú àdírẹ́sì mi fún Marco, ọ̀kan lára àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ rẹ̀. Níkẹyìn, ní February 1985, ó rí mi. Ìwọ̀nba ìṣẹ́jú díẹ̀ péré la fi sọ̀rọ̀ nítorí pé ọwọ́ mi dí, àmọ́ a ṣe àdéhùn láti tún ríra sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn èyí, òun àti aya rẹ̀, Lina, máa ń bẹ̀ mí wò déédéé, láti ràn mí lọ́wọ́ kí n lè lóye Bíbélì. Kò pẹ́ sígbà yìí ni mo rí i kedere pé àwọn lájorí ẹ̀kọ́ ìsìn Kátólíìkì, irú bíi Mẹ́talọ́kan, àìleèkú ọkàn, àti ọ̀run àpáàdì kò bá Bíbélì mu rárá àti rárá.

Ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí

Nígbà tí mo lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn, ó hàn gbangba pé ohun tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí ti Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì. Gbogbo èèyàn ló ń kọrin, kì í ṣe àwọn ẹgbẹ́ akọrin nìkan. Lẹ́yìn èyí, wọ́n á tún kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé náà. Mo tún bẹ̀rẹ̀ sí rí i pé “àwọn arákùnrin” àti “àwọn arábìnrin” ló para pọ̀ di ètò àjọ náà lápapọ̀. Gbogbo wọ́n ló bìkítà nípa ara wọn gan-an. Àwọn nǹkan wọ̀nyí wú mi lórí gidigidi.

Láàárín àkókò yẹn, aṣọ tí àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé máa ń wọ̀ ni mo máa ń wọ̀ lọ sípàdé. Ìyàlẹ́nu gbáà ló máa ń jẹ́ fún àwọn kan láti rí obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Inú mi máa ń dùn gan-an láti rí i pé ìdílé ńlá kan tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ ló yí mi ká. Bákan náà, bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí rí i pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ìlànà tí mo ti ń tẹ̀ lé nígbèésí ayé mi ni kò bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì kò sọ níbì kankan pé kí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa wọ aṣọ àkànṣe kan. Bí onírúurú ipò oyè ṣe wà nínú ṣọ́ọ̀ṣì, àti gbogbo afẹfẹyẹ̀yẹ̀ ìsìn, yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa àwọn alàgbà onírẹ̀lẹ̀ tí yóò máa ṣàbójútó nínú ìjọ.

Ńṣe ló dà bíi pé orí ẹrọ̀fọ̀ ni mo dúró sí, tí kò sí ilẹ̀ líle lábẹ́ ẹsẹ̀ mi. Ó ṣòro fún mi láti gbà gbọ́ pé mo ti wà nínú ìṣìnà fún ọdún mẹ́rìnlélógún gbáko. Síbẹ̀, mo rí i kedere pé òtítọ́ ni ohun tí mò ń kọ́ látinú Bíbélì báyìí. Ẹ̀rú bà mí nígbà tí mo rò ó pé lẹ́ni ọdún mẹ́rìnlélógójì, mo ní láti ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésí ayé mìíràn. Àmọ́, báwo ni mo ṣe lè máa rìn bí ẹni tí wọ́n fi nǹkan bò lójú nísinsìnyí tí mo ti rí ohun tí Bíbélì fi kọ́ni ní ti tòótọ́?

Ìpinnu Pàtàkì

Mo mọ̀ pé fífi ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà sílẹ̀ yóò túmọ̀ sí pé mi ò ní ní ohun ìní tàbí owó kankan. Àmọ́, mo rántí ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ nípa àwọn olódodo pé, ‘a kì yóò fi wọ́n sílẹ̀ láé tàbí kí ọmọ wọn máa tọrọ oúnjẹ kiri.’ (Sáàmù 37:25) Mo mọ̀ pé màá pàdánù nípa tara, àmọ́ mo gbọ́kàn lé Ọlọ́run, mo sì parí èrò sí pé, ‘Kí ló yẹ kó máa bà mí lẹ́rù?’

Àwọn tó jẹ́ ara ìdílé mi rò pé mo ya wèrè ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn kó ìdààmú bá mi, mo rántí ọ̀rọ̀ Jésù pé: ‘Àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ bàbá tàbí ìyá wọn jù mí lọ, kò yẹ fún mi.’ (Mátíù 10:37) Lọ́wọ́ kan náà, bí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe ń yọ̀ mọ́ mi fún mi níṣìírí ó sì fún mi lókun. Bí mo bá ń rìn lọ lójú pópó nínú aṣọ ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé mi, wọ́n máa ń rí i pé àwọ́n wá kí mi. Èyí jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ ẹgbẹ́ àwọn ará yìí, kí n sì túbọ̀ di ara ìdílé wọn.

Níkẹyìn, mo lọ bá Ìyá Ìjọ, ẹni tó jẹ́ alábòójútó ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà, mo sì ṣàlàyé fún un nípa ìdí tí mo ṣe fẹ́ fi ibẹ̀ sílẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo gbìyànjú láti fi hàn án nínú Bíbélì ìdí tí mo fi ṣèpinnu yìí, ó kọ̀ jálẹ̀ láti tẹ́tí sílẹ̀, ó sì ń sọ pé: “Bí mo bá fẹ́ lóye ohunkóhun nínú Bíbélì, mo lè sọ fún ògbógi kan tó mọ̀ nípa Bíbélì!”

Ìyàlẹ́nu gbáà ni ìpinnu mi jẹ́ fún Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì. Wọ́n fẹ̀sùn kàn mí pé oníṣekúṣe ni mí, àti pé mo ní àrùn ọpọlọ. Àmọ́, àwọn tó mọ̀ mí mọ̀ pé ẹ̀sùn èké lásán ni wọ́n ń fi kàn mí. Onírúurú ọ̀nà làwọn èèyàn tí mò ń bá ṣiṣẹ́ gbà hùwà sí mi. Àwọn kan wò ó pé ìgboyà tí mo ní ni mo fi lè ṣe irú ohun bẹ́ẹ̀. Ó dun àwọn mìíràn gan-an, torí pé wọ́n ń rò pé mo ti ṣìnà. Ńṣe làwọn kan tiẹ̀ ń káàánú mi.

Ní July 4, 1985, mo fi Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì sílẹ̀. Níwọ̀n bí àwọn Ẹlẹ́rìí ti mọ ohun tójú àwọn tó bá gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń rí, ìbẹ̀rù pé wọ́n lè lọ ṣe mí ní jàǹbá sì mú kí wọ́n fi mí pa mọ́ fún nǹkan bí oṣù kan. Wọ́n á wá gbé mi lọ sí ìpàdé, wọ́n á sì tún gbé mi padà lọ sí ibi tí mò ń gbé. Mi ò yọjú síta rárá títí dìgbà tí gbogbo nǹkan rọlẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Nígbà tó wá di August 1, 1985, mo bẹ̀rẹ̀ sí kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Nígbà tí mo lọ sí Àpéjọ Àgbègbè ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní apá ìparí oṣù August yẹn, ó di mímọ̀ fún àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn pé mo ti fi ṣọ́ọ̀ṣì náà sílẹ̀, wọ́n sì gbé ọ̀rọ̀ mi jáde nínú ìwé ìròyìn. Nígbà tí mo ṣe batisí lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ní December 14, 1985, iléeṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n àti iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn àdúgbò ronú pé ohun tí mo ṣe kò bójú mu rárá àti rárá, nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n tún gbé ìròyìn náà síta lẹ́ẹ̀kan sí i, láti rí i dájú pé gbogbo èèyàn gbọ́ nípa ohun tí mo ṣe.

Nígbà tí mo fi ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà sílẹ̀, mi ò ní ohunkóhun rárá. Mi ò níṣẹ́, mi ò nílé, mi ò sì lówó ìfẹ̀yìntì. Nítorí náà, fún nǹkan bí ọdún kan, iṣẹ́ tí mò ń ṣe ni bíbójútó obìnrin kan tó jẹ́ alárùn ẹ̀gbà. Ní July 1986, mo di aṣáájú ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń pe àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Mo ṣí lọ sí àgbègbè kan tí ìjọ kékeré kan tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ wà. Níbẹ̀, mò ń kọ́ àwọn èèyàn ní èdè àjèjì nílé wọn, mo sì tún ń ṣe àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ mìíràn, nípa bẹ́ẹ̀, mò ń lo àwọn ẹ̀kọ́ tí mo ti kọ́ nígbà tí mo wà níléèwé. Èyí jẹ́ kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìgbòkègbodò mi ṣeé yí padà bí mo ṣe fẹ́.

Sísìn ní Ilẹ̀ Òkèèrè

Ní báyìí tí mo ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì, ó wù mí láti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ nípa rẹ̀ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Níwọ̀n bí mo ti ń sọ èdè Faransé, mo ronú nípa lílọ sìn ní orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Áfíríkà kan tí wọ́n ti ń sọ èdè Faransé. Àmọ́, lọ́dún 1992, ìjọba fàṣẹ sí iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lábẹ́ òfin lórílẹ̀-èdè Albania tó wà nítòsí. Ní ìparí ọdún náà, a yan àwùjọ kéréje àwọn aṣáájú ọ̀nà kan láti ilẹ̀ Ítálì síbẹ̀. Lára àwọn aṣáájú ọ̀nà wọ̀nyí ni Mario àti Cristina Fazio, tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya kan látinú ìjọ mi. Wọ́n ké sí mi láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn, wọ́n sì rọ̀ mí láti ronú nípa sísìn ní ilẹ̀ Albania. Nítorí náà, lẹ́yìn tí mo ti ro ọ̀rọ̀ náà síwá-sẹ́yìn, tí mo sì ti fi sínú àdúrà, lẹ́ni ọdún méjìléláàádọ́ta, mo tún fi ipò nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ burú jù sílẹ̀, mo sì ṣí lọ sí àyíká tó ṣàjèjì sí mi pátápátá.

Ìyẹn jẹ́ ní March 1993. Nígbà tí mo débẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo rí i pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè náà kò jìnnà púpọ̀ sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ mi, ilẹ̀ àjèjì pátápátá ni mo wà. Ẹsẹ̀ làwọn èèyàn máa ń fi rìn lọ gbogbo ibi tí wọ́n bá ń lọ, èdè ilẹ̀ Albania ni wọ́n sì ń sọ, èdè tí kò yé mi páàpáà. Ìyípadà kíkàmàmà ń ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè náà lásìkò yẹn, torí pé ńṣe ni wọ́n ń fi ètò òṣèlú kan rọ́pò òmíràn. Síbẹ̀, òùngbẹ òtítọ́ Bíbélì ń gbẹ àwọn èèyàn, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ láti kàwé àti láti kẹ́kọ̀ọ́. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń tẹ̀ síwájú lọ́nà yíyára kánkán, èyí sì máa ń múnú mi dùn, torí pé ó ń jẹ́ kí n lè mú ara mi bá àyíká tuntun yìí mu.

Nígbà tí mo dé ìlú Tiranë, tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè náà, lọ́dún 1993, ìjọ kan ṣoṣo ló wà ní orílẹ̀-èdè Albania, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀, tí wọ́n wà káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè náà, sì fi díẹ̀ lé ní ọgọ́rùn-ún ni. Lóṣù yẹn, ní àpéjọ àkànṣe tá a kọ́kọ́ ṣe ní ìlú Tiranë, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta èèyàn àti márùnlélọ́gọ́rin [585] ló pésẹ̀, àwọn méjìlélógójì ló ṣì ṣèrìbọmi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò lóye ohunkóhun, bí mo ṣe ń gbọ́ bí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe ń kọrin tí mo sì ń rí bí wọ́n ṣe tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ wú mi lórí gidigidi. Ní oṣù April, a ṣe Ìṣe Ìrántí ikú Jésù Kristi, ẹ̀ẹ́dégbèje èèyàn ó lé méjìdínlógún [1,318] ló sì pésẹ̀! Látìgbà náà lọ, ńṣe ni ìgbòkègbodò Kristẹni ń gbèrú lọ́nà kíkàmàmà ní orílẹ̀-èdè Albania.

Nígbà kan, mo máa ń wo gbogbo ìlú Tiranë láti òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì alájà mẹ́rin tí mò ń gbé, màá sì máa ronú pé, ‘Ìgbà wo ló máa ṣeé ṣe fún wa ná láti dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn èèyàn wọ̀nyí?’ Jèhófà Ọlọ́run bójú tó ìyẹn. Nísinsìnyí, ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́tàlélógún ló wà ní Tiranë. Ní gbogbo orílẹ̀-èdè náà, ìjọ méjìdínláàádọ́rin àtàwọn àwùjọ tó jẹ́ méjìlélógún ló wà, àpapọ̀ iye àwọn Ẹlẹ́rìí sì jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlá ó lé mẹ́rìndínláàádọ́ta [2,846]. Láàárín ọdún díẹ̀ péré ni ìtẹ̀síwájú kíkàmàmà yìí wáyé! Àwọn èèyàn tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlá ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti márùndínlọ́gọ́rùn-ún [12,795] ló sì pésẹ̀ sí Ìṣe Ìrántí lọ́dún 2002!

Ní ọdún mẹ́wàá yìí tí mo ti lò ní orílẹ̀-èdè Albania, mo láyọ̀ gidigidi pé mo láǹfààní láti ṣèrànwọ́ fún ogójì èèyàn, ó kéré tán, láti tẹ̀ síwájú dórí ṣíṣe ìrìbọmi. Àwọn kan lára wọn ń sìn báyìí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àti nínú àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún mìíràn. Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, wọ́n máa ń yan àwùjọ àwọn aṣáájú ọ̀nà mẹ́fà láti ilẹ̀ Ítálì láti ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù ní Albania. Wọ́n máa ń ṣètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ olóṣù mẹ́ta fún àwùjọ kọ̀ọ̀kan láti kọ́ èdè, mo sì gba ìwé ìkésíni láti kọ́ àwọn kíláàsì mẹ́rin tó kẹ́kọ̀ọ́ gbẹ̀yìn.

Nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ mi kọ́kọ́ gbọ́ nípa ìpinnu mi láti fi ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀, wọ́n gbógun tì mí gidi gan-an. Àmọ́ o, lẹ́yìn gbogbo àwọn ọdún wọ̀nyí, ìṣarasíhùwà wọn kò fi bẹ́ẹ̀ le koko mọ́, níwọ̀n bí wọ́n ti rí i pé kò sóhun tó ṣe mi, ọkàn mi sì balẹ̀. Ó dùn mọ́ mi nínú pé, ìdílé mi, títí kan ẹ̀gbọ́n bàbá mi obìnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún, ẹni tó ṣì jẹ́ obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé síbẹ̀, tún ń ṣètìlẹyìn fún mi gidigidi pẹ̀lú.

Látìgbà tí mo ti wá mọ Jèhófà, ó ti bójú tó mi nínú onírúurú ipò! Ó darí ẹsẹ̀ mi sínú ètò àjọ rẹ̀. Bí mo bá wẹ̀yìn wò, mo máa ń rántí bí mo ṣe máa ń hára gàgà láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tálákà àtàwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́, àti bó ṣe máa ń wù mí láti lo ara mi tokuntokun nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tí mo fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, torí pé ó ti rí i dájú pé a pa òùngbẹ tẹ̀mí tó ń gbẹ mí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Ìdílé kan nílẹ̀ Albania tí mo bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn mọ́kànlá ti ṣèrìbọmi

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn obìnrin wọ̀nyí tí mo bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílẹ̀ Albania wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún nísinsìnyí