Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gbádùn Òpin Ọ̀sẹ̀ O!

Gbádùn Òpin Ọ̀sẹ̀ O!

Gbádùn Òpin Ọ̀sẹ̀ O!

Ó FẸ́RẸ̀Ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló máa ń wọ̀nà fún òpin ọ̀sẹ̀, nígbà tó bá sì dé òun làwọn èèyàn sábà máa ń gbádùn jù lọ nínú ọ̀sẹ̀. Àwọn kan máa ń fi rìnrìn àjò, àwọn kan máa ń fi ṣe eré ìdárayá, àwọn kan máa ń lò ó fún ìjọsìn, nígbà tí àwọn mìíràn máa ń lò ó láti fi sùn.

Ní apá Ìwọ̀ Oòrùn ayé, òpin ọ̀sẹ̀ máa ń bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Friday ó sì máa ń wọ ọjọ́ Sunday. Ṣùgbọ́n, ibo ni àṣà òpin ọ̀sẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀? Bó bá sì jẹ́ pé ibi tí àwọn èèyàn ti sábà máa ń fi ọjọ́ márùn-ún láàárín ọ̀sẹ̀ ṣiṣẹ́ lò ń gbé, àwọn ọ̀nà dáradára wo lo lè gbà lo òpin ọ̀sẹ̀ rẹ?

Ọjọ́ Ìsinmi Nígbà Àtijọ́ Ló Di Òpin Ọ̀sẹ̀ Lóde Òní

Òfin Sábáàtì tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ ọdún sẹ́yìn sọ pé: “Ọjọ́ mẹ́fà ni kí a fi ṣe iṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni sábáàtì ìsinmi pátápátá. Ohun mímọ́ ni lójú Jèhófà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ ní ọjọ́ sábáàtì ni a ó fi ikú pa dájúdájú.” (Ẹ́kísódù 31:15) Sábáàtì náà tún fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ òbí láǹfààní láti bójú tó ipò tẹ̀mí àwọn ìdílé wọn.

Sábáàtì àwọn Júù máa ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí oòrùn bá wọ̀ lọ́jọ́ Friday, ó sì máa ń parí nígbà tí oòrùn bá wọ̀ lọ́jọ́ Sátidé. Àmọ́ o, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà The World Book Encyclopedia sọ, àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ “sọ ọjọ́ Sunday di ọjọ́ àkànṣe ìjọsìn, nítorí pé wọ́n gbà gbọ́ pé ọjọ́ yẹn ni Jésù jíǹde. Nígbà tó fi máa di apá ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀wádún tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 300 Lẹ́yìn Ikú Olúwa Wa, ṣọ́ọ̀ṣì àti ìjọba ti fàṣẹ sí i gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìsinmi tó bófin mu ní Yúróòpù.”

Lọ́nà tó gbàfiyèsí, kò ì tíì pẹ́ púpọ̀ tí wọ́n mú kí àkókò ìsinmi ju ọjọ́ kan ṣoṣo lọ. Èyí bẹ̀rẹ̀ nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní ẹ̀wádún tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1870, níbi tó jẹ́ pé ọ̀sán Sátidé ni iṣẹ́ ọ̀sẹ̀ kan máa ń wá sópin. Ọ̀sán Sátidé tí wọn kì í ṣiṣẹ́ yìí ló wá pa pọ̀ mọ́ Sunday láti di òpin ọ̀sẹ̀. Gbogbo ìdílé lápapọ̀ á kọ́kọ́ jọ jẹun pọ̀ lọ́sàn-án Sátidé, lẹ́yìn náà, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Atlantic Monthly ṣe sọ, “ohun tó sábà máa ń tẹ̀ lé [oúnjẹ yìí] ni ìwẹ̀ ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ níbi ìlúwẹ̀ẹ́ gbogbo gbòò ti àdúgbò.”

Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n tiẹ̀ túbọ̀ fi kún òpin ọ̀sẹ̀, ó wá kúkú di ọjọ́ ìsinmi ọlọ́jọ́ méjì. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn kan ṣe sọ, lọ́dún 1908, iléeṣẹ́ kan ní àgbègbè New England ló kọ́kọ́ ṣètò pé káwọn èèyàn máa fi ọjọ́ márùn-ún péré láàárín ọ̀sẹ̀ ṣiṣẹ́. Àwọn òṣìṣẹ́ tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Júù àtàwọn “Kristẹni” tẹ́wọ́ gba ètò yìí, níwọ̀n bí ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan ti ní ọjọ́ ìsinmi tirẹ̀—ọjọ́ Sátidé fún àwọn ẹlẹ́sìn Júù àti ọjọ́ Sunday fún àwọn “Kristẹni.” Kò pẹ́ rárá tí àṣà kéèyàn máa fi ọjọ́ márùn-ún péré láàárín ọ̀sẹ̀ ṣiṣẹ́ fi yára tàn kálẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Henry Ford tó ní iléeṣẹ́ kan tó ń ṣe ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ gbé àṣà yìí lárugẹ, níwọ̀n bó ti fojú inú wò ó pé bí àwọn ìdílé ṣe ń gbafẹ́ jáde lópin ọ̀sẹ̀ yóò mú kí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ túbọ̀ tà sí i.

Ǹjẹ́ O Ti Wéwèé Láti Ṣe Ohun Kan ní Òpin Ọ̀sẹ̀?

Lónìí, òpin ọ̀sẹ̀ ọlọ́jọ́ méjì ti di ohun tí gbogbo èèyàn tẹ́wọ́ gbà ní apá Ìwọ̀ Oòrùn ayé. Bó bá jẹ́ pé àgbègbè yẹn lò ń gbé, ó ṣeé ṣe kí àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ máa béèrè lọ́wọ́ rẹ bí ọ̀sẹ̀ bá ti ń parí lọ pé, “Kí lo wéwèé láti ṣe ní òpin ọ̀sẹ̀ yìí?” Ìbéèrè yẹn á mú kó o ronú nípa onírúurú nǹkan gbígbádùnmọ́ni tó o lè ṣe.

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀gá rẹ ló ń darí gbogbo àkókò rẹ níbi iṣẹ́ jálẹ̀ ọ̀sẹ̀, òpin ọ̀sẹ̀ lè fún ọ láǹfààní láti lo àkókò rẹ bó ṣe wù ọ́. Ó lè fún ọ láyè láti gbádùn àkókò ìsinmi ráńpẹ́ kúrò lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ tó ò ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Òpin ọ̀sẹ̀ tún lè fún ọ láyè láti sinmi dáadáa tàbí láti lo àkókò pẹ̀lú àwọn aráalé rẹ. Tàbí kẹ̀, kó fún ọ láyè láti lọ́wọ́ nínú ohun táwọn èèyàn sábà máa ń ṣe ní òpin ọ̀sẹ̀—ìyẹn ni lílọ sí àwọn ibi ìtajà láti lọ fún ojú lóúnjẹ. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Brigitte, ẹni tó ń gbé ní ilẹ̀ Jámánì, sọ pé: “Lílọ láti ṣọ́ọ̀bù kan sí òmíràn máa ń gbádùn mọ́ mi gan-an ni.”

Ìwádìí fi hàn pé ọ̀pọ̀ èèyàn fẹ́ràn láti máa lo àkókò ọwọ́-dilẹ̀ wọn láti ṣe eré ìnàjú. Ní ti àwọn tó ti pinnu láti máa lo òpin ọ̀sẹ̀ wọn nílé, ọ̀kan-kò-jọ̀kan ohun àṣenajú ló wà fún wọn láti ṣe. Wọ́n lè ṣe àwọn nǹkan bíi, ṣíṣètọ́jú ọgbà láyìíká ilé, ṣíṣàkójọ sítáǹpù, fífi ohun èlò ìkọrin ṣeré tàbí fífetísílẹ̀ sí orin, wíwo fídíò, síse oúnjẹ, kíkọ lẹ́tà, kíkàwé, rírán aṣọ, híhun nǹkan, ṣíṣe eré ìdárayá, àti kíkun àwòrán, láti mẹ́nu kan díẹ̀. Àwọn kan fẹ́ràn ṣíṣe àwọn ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n bá àwọn ọmọ wọn àti ọkọ tàbí aya wọn ṣeré pọ̀, irú bíi títa ayò tàbí títa lúdò. a

Ǹjẹ́ Bíbélì dẹ́bi fún lílo àkókò ẹni fún irú àwọn ohun tó jọ pé kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì bẹ́ẹ̀? Rárá o. Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.” (Oníwàásù 4:6) Béèyàn bá ṣe é ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, eré ṣíṣe, ìsinmi àti eré ìnàjú ń kópa pàtàkì nínú ìgbésí ayé àwọn Kristẹni.

Ṣíṣe Àṣerégèé

Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àpọ̀jù nǹkan tó dára pàápàá burú, torí pé kò ní ṣeni láǹfààní, ó sì lè pani lára. Bí àpẹẹrẹ, ṣíṣe eré ìmárale láwọn àǹfààní tiẹ̀. (1 Tímótì 4:8) Àmọ́, ńṣe làwọn kan tó máa ń ṣeré ìdárayá lópin ọ̀sẹ̀ máa ń ṣe é pẹ̀lú ìtara òdì. Níwọ̀n bí wọ́n ti pinnu láti borí lọ́nàkọnà, wọ́n máa ń lo ọ̀nà oríṣiríṣi láti lè mọ eré ìdárayá tí wọ́n fẹ́ràn lámọ̀dunjú. Wọ́n máa ń ná owó gọbọi fún gbígba ìdálẹ́kọ̀ọ́ àti ríra àwọn ohun èlò eré ìdárayá tó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀, wọ́n sì máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò láti fi mọ̀ ọ́n dunjú.

Àwọn ewu mìíràn tún wà tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ìlera, èyí tó lè jẹ yọ bí ẹnì kan bá ń lo ara rẹ̀ kọjá bó ṣe yẹ fún eré ìdárayá atánnilókun tí kì í ṣe tẹ́lẹ̀. Ìwé ìròyìn kan sọ nípa àwọn tí ọjọ́ orí wọn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta ọdún, tí “wọ́n máa ń fi gbogbo agbára wọn lọ́wọ́ nínú eré ìdárayá ní òpin ọ̀sẹ̀.” Àwọn tó jẹ́ pé, pẹ̀lú ìpinnu wọn láti tún ní okun ìgbà èwe wọn padà, ńṣe ni wọ́n máa ń fara pa, tí wọ́n á fi apá tàbí ẹsẹ̀ rọ́, tí wọ́n á sì ní ọgbẹ́ lára. Àwọn mìíràn máa ń ṣe àwọn eré ìdárayá àṣejù tó lè ṣekú pa wọ́n tàbí kó mú kí wọ́n fara pa yánnayànna. b Ìmọ̀ràn Bíbélì pé ká jẹ́ “oníwọ̀ntúnwọ̀nsì” bá a mu gan-an nígbà náà. (Títù 2:2) Ńṣe ló yẹ kí eré ìmárale tuni lára, kì í ṣe pé kó tánni lókun tàbí kó ṣeni ní jàǹbá.

Nítorí èyí, àwọn kan yàn láti máa ṣe àwọn eré ìmárale tí kò fi bẹ́ẹ̀ le jù. Bí àpẹẹrẹ, rírin ìrìn kánmọ́kánmọ́ wọ́pọ̀ gan-an lórílẹ̀-èdè Jámánì. Kódà, eré ìnàjú kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn fẹ́ràn nílẹ̀ Yúróòpù ni ohun tí wọ́n ń pè ní ìrìn tó ń peni níjà. Béèyàn bá ń ṣe eré ìmárale yìí, kì í ṣe pé á máa bá àwọn ẹlòmíràn díje, àmọ́ yóò máa wo aago láti mọ ibi tí òún lè rìn dé láàárín àkókò kúkúrú. Ohun tí èyí wà fún ni pé, èèyàn á fojú bu ibì kan pàtó ní ìgbèríko kan láti rìn ín já. Láìsí àní-àní, ọ̀nà gbígbádùnmọ́ni kan lèyí jẹ́ láti ṣeré ìmárale kéèyàn sì tún máa gbádùn wíwo àwọn òdòdó aláràbarà tó wà láyìíká lákòókò kan náà! Bákan náà, ó jẹ́ ohun kan tí gbogbo ìdílé lápapọ̀ lè jọ gbádùn pa pọ̀.

Òpin Ọ̀sẹ̀ Tó Kún fún Ìgbòkègbodò Púpọ̀

Nígbà míì, àwọn èèyàn máa ń wéwèé láti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ní òpin ọ̀sẹ̀, débi pé ìwọ̀nba díẹ̀ ni wọ́n á lè gbádùn nínú rẹ̀ tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ gbádùn èyíkéyìí nínú rẹ̀. Nígbà tí ọ̀sẹ̀ tuntun bá wá bẹ̀rẹ̀, dípò tí ara wọn ì bá fi yá gágá, ńṣe ló máa rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu. Ìwé ìròyìn Focus ti ilẹ̀ Jámánì gbé ìròyìn kan jáde nípa ìwádìí kan, èyí tó fi hàn pé ìdá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló sọ pé àwọn eré ìnàjú tí àwọ́n ń ṣe ti máa ń tánni lókun jù.

Ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Ìsinmi ló ń jẹ́ kí ara ẹni lè bọ̀ sípò láti ṣiṣẹ́.” Jésù Kristi náà mọ̀ pé ara wa ń fẹ́ ìsinmi àti ìtura. Máàkù 6:31 ròyìn pé Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “‘Ẹ máa bọ̀, ẹ̀yin fúnra yín, ní ẹ̀yin nìkan sí ibi tí ó dá, kí ẹ sì sinmi díẹ̀.’ Nítorí ọ̀pọ̀ ni àwọn tí ń wá tí wọ́n sì ń lọ, wọn kò sì ní àkókò kankan tí ọwọ́ dilẹ̀, àní láti jẹ oúnjẹ.” Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíṣe eré ìmárale, lílọ sọ́jà, àti irú àwọn ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀ dára láyè tiwọn, ṣíṣètò àkókò fún kíka ìwé amáratuni, sísinmi tàbí sísùn lè mára tù ọ́ gan-an ni. Àmọ́ ṣá o, ohun kan tún wà tó lè mú kó o túbọ̀ gbádùn òpin ọ̀sẹ̀ rẹ.

Bíbójútó Ipò Tẹ̀mí

Nígbà tí Jésù ń ṣe Ìwàásù Lórí Òkè, ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Ọ̀kan lára àwọn ète tí a fi ṣètò Sábáàtì ọjọ́ ìsinmi ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ni láti fún àwọn èèyàn láyè láti bójú tó ipò tẹ̀mí wọn. Ǹjẹ́ a lè lo òpin ọ̀sẹ̀ fún irú ohun kan náà lónìí? Ronú nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìjọ wọn máa ń ṣe àwọn ìpàdé Kristẹni wọn yálà lọ́jọ́ Sátidé tàbí lọ́jọ́ Sunday. Wọ́n tún máa ń lo òpin ọ̀sẹ̀ fún àwọn ìpàdé wọn títóbi, irú bí àpéjọ àkànṣe, àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ àgbègbè. Ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń lò lára àkókò wọn ní òpin ọ̀sẹ̀ fún lílọ láti ilé dé ilé, láti jíròrò Bíbélì pẹ̀lú àwọn aládùúgbò wọn.

Lóòótọ́, gẹ́gẹ́ bíi ti gbogbo àwọn èèyàn mìíràn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ní iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, ilé àti ìdílé wọn láti bójú tó. Nípa bẹ́ẹ̀, nígbàkigbà tó bá ti ṣeé ṣe, wọ́n tún máa ń wéwèé àwọn ìgbòkègbodò fàájì fún ara wọn àti fún àwọn ìdílé wọn. Àmọ́, àwọn nǹkan tẹ̀mí ni wọ́n máa ń fi sí ipò àkọ́kọ́. Ǹjẹ́ fífi àwọn nǹkan tẹ̀mí sí ipò àkọ́kọ́ ń fa ìnira fún wọn? Gbé ìrírí àwọn tá a mẹ́nu kàn nísàlẹ̀ wọ̀nyí yẹ̀ wò.

Ṣáájú kí àwọn tọkọtaya kan nílẹ̀ Jámánì tí orúkọ wọn ń jẹ́ Jürgen àti Doris tó di Ẹlẹ́rìí, ibi ìṣeré ìmárale kan ní àgbègbè wọn ni wọ́n ti máa ń gbádùn òpin ọ̀sẹ̀ wọn. Melle àti Helena sì máa ń fi àkókò wọn ṣèbẹ̀wò sí àwọn ibi tí wọ́n ti ń ṣàfihàn iṣẹ́ ọnà. Helmut ní tirẹ̀ máa ń lo òpin ọ̀sẹ̀ láti fi gbádùn àwọn ìṣẹ̀dá tó wà láyìíká. Nígbà tí Silvia máa ń lo òpin ọ̀sẹ̀ rẹ̀ ní ilé ijó dísíkò. Àmọ́ o, látìgbà tí àwọn ẹni wọ̀nyí ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyípadà kíkàmàmà ti dé bá bí wọ́n ṣe ń lo àkókò ọwọ́-dilẹ̀ wọn.

Jürgen àti Doris ṣàlàyé pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn eré ìnàjú wa máa ń mú ìyípadà bá ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́, àmọ́ a ò lè sọ pé èyí ń mú kí ìgbésí ayé wa sunwọ̀n sí i. Ní báyìí, bí a ṣe ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì ń mú kí ìgbésí ayé wọn túbọ̀ nítumọ̀ sí i, àmọ́ kì í ṣe tiwọn nìkan àti tiwa náà pẹ̀lú.” Báwo lọ̀ràn ti rí fún Melle àti Helena? Wọ́n sọ pé: “Bíbélì pèsè àwọn ìtọ́ni nípa béèyàn ṣe lè gbé ayé lọ́nà tó dára jù lọ, sísọ nípa èyí fún àwọn ẹlòmíràn sì máa ń fún wa láyọ̀ gidigidi.” Kí ló mú kí Helmut túbọ̀ máa gbádùn ayé rẹ̀ gan-an báyìí? Ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé ohun tí mò ń ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ṣe pàtàkì lójú Jèhófà.” Silvia sì sọ pé: “Iṣẹ́ ìwàásù ń béèrè fún lílọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn àti bíbá wọn jíròrò lọ́nà tó lárinrin, mo sì máa ń gbádùn méjèèjì.”

O ò ṣe bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n bá tún ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ? Bó o bá bá ọ̀kan lára wọn jíròrò ṣókí, èyí lè jẹ́ ìgbésẹ̀ rẹ àkọ́kọ́ láti mọ bí ìgbésí ayé rẹ ṣe lè nítumọ̀ sí i, kì í ṣe ní òpin ọ̀sẹ̀ nìkan àmọ́ ní gbogbo ọjọ́ tó wà láàárín ọ̀sẹ̀!

Láìka irú eré ìnàjú tó o lè fẹ́ràn àtimáa ṣe sí, jẹ́ kí òpin ọ̀sẹ̀ rẹ jẹ́ èyí tí ń gbéni ró tó sì gbádùn mọ́ni. Bó bá jẹ́ pé àgbègbè tí wọ́n ti ń sọ èdè Jámánì lò ń gbé, a kí ọ pé “schönes Wochenende.” Bó bá jẹ́ pé èdè Spanish lò ń sọ, ìkíni wa ni pé, “¡Buen fin de semana!.” Bó o bá jẹ́ ará ilẹ̀ Ukraine, a kí ọ pé, “Бажаю вам приємно провести вихідні.” Ibikíbi tó o bá ń gbé, ohunkóhun tó o bá ń ṣe, gbádùn òpin ọ̀sẹ̀ o!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ìsọfúnni lórí àwọn ewu tó lè jẹ yọ nínú ṣíṣe àwọn eré ìdárayá orí ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́, wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Ó Ha Yẹ Kí N Máa Ṣe Àwọn Eré Àṣedárayá Orí Kọ̀m̀pútà Tàbí Fídíò Bí?” nínú ìtẹ̀jáde Jí! ti August 22, 1996.

b Wo àpilẹ̀kọ náà, ‘“Eré Ìdárayá Àṣejù”—Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí O Fara Rẹ Wewu?’ nínú ìtẹ̀jáde Jí! ti October 8, 2000.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]

Òpin ọ̀sẹ̀ tó lè gbádùn mọ́ni ni èyí téèyàn lò fún ìsinmi, eré ìtura àti ìgbòkègbodò tẹ̀mí lọ́nà tó máa ṣeni láǹfààní