“Jèhófà Ni Olùtùnú Mi”
“Jèhófà Ni Olùtùnú Mi”
GBÓLÓHÙN tó wà lókè yìí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ atọ́nà tí Ọba Charles Kẹsàn-án ti ilẹ̀ Sweden yàn láàyò nígbà ìṣàkóso rẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ atọ́nà náà ṣe kà lédè Látìn ni pé: “Iehovah solatium meum.” Ọba yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọba bíi mélòó kan nínú ìran tó jọba nílẹ̀ Sweden, láti ọdún 1560 sí ọdún 1697, tí wọ́n pe àfiyèsí sí orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù tàbí lédè Látìn lára ẹyọwó, lára àmì ẹ̀yẹ tàbí nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń lò bí atọ́nà wọn. Charles Kẹsàn-án tún dá ẹgbẹ́ kan sílẹ̀ tó ń jẹ́ Ẹgbẹ́ Olùjọsìn ti Jèhófà. Lọ́jọ́ tí ọba Charles ń gbadé lọ́dún 1607, ó lo gbẹ̀dẹ̀ ọrùn kan tí wọ́n ń pè ní ṣéènì Jèhófà.
Kí lohun tó sún àwọn ọba wọ̀nyí láti ṣe ohun tí wọ́n ṣe yìí? Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ gbà gbọ́ pé ìsìn Àwọn Ọmọlẹ́yìn Calvin tó wà nílẹ̀ Yúróòpù nígbà náà, pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ tí wọ́n ní fún Bíbélì, ló mú wọn ṣe bẹ́ẹ̀. Níwọ̀n bí wọ́n ti jẹ́ ọba tó kàwé gan-an lákòókò tí ojú ṣẹ̀ṣẹ̀ ń là bọ̀, ó hàn gbangba pé wọ́n mọ orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, lédè Látìn dáadáa. Ó dájú pé àwọn kan lára wọn mọ̀ pé orúkọ náà fara hàn ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìgbà nínú Bíbélì èdè Hébérù ti ìpilẹ̀ṣẹ̀.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkọsílẹ̀ ló fi hàn gbangba-gbàǹgbà pé ní apá ibi púpọ̀ nílẹ̀ Yúróòpù ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún àti ìkẹtàdínlógún, orúkọ náà Jèhófà sábà máa ń fara hàn nínú ẹyọwó àti nínú àmì ẹ̀yẹ, bákan náà ló máa ń fara hàn lára àwọn ilé tí ìjọba kọ́ fún ìlò àwọn aráàlú àti lára ṣọ́ọ̀ṣì. Ó ṣe kedere pé, ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà yẹn ló tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ tí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún un, ìyẹn ni àkọsílẹ̀ Ẹ́kísódù 3:15 tó kà pé: “Jèhófà . . . ni orúkọ mi fún àkókò tí ó lọ kánrin.”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
ṢÉÈNÌ TÓ NÍ ÀMÌ ÌDÁNIMỌ̀ TI ẸGBẸ́ OLÙJỌSÌN TI JÈHÓFÀ, 1606, èyí tí wọ́n fi góòlù, ohun ọ̀ṣọ́ tó ń dán gbinrin àtàwọn òkúta iyebíye ṣe
ỌBA ERIK KẸRÌNLÁ 1560-68
ỌBA CHARLES KẸSÀN-ÁN 1599-1611 (arákùnrin Erik Kẹrìnlá)
ỌBA GUSTAVUS KEJÌ ADOLPH 1611-32 (ọmọkùnrin Charles Kẹsàn-án)
ỌBABÌNRIN CHRISTINA 1644-54 (ọmọbìnrin Gustavus Kejì Adolph)
[Àwọn Credit Line]
Ṣéènì: Livrustkammaren, Stockholm Sverige; ẹyọwó: Kungl. Myntkabinettet, Sveriges Ekonomiska Museum