Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Jẹ́ Kí Wọ́n Mú Àwọn Níyè?

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Jẹ́ Kí Wọ́n Mú Àwọn Níyè?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Jẹ́ Kí Wọ́n Mú Àwọn Níyè?

“Kí a má ṣe rí láàárín rẹ ẹnikẹ́ni tí ń fi . . . èèdì di àwọn ẹlòmíràn.”—DIUTARÓNÓMÌ 18:10, 11.

Ó PẸ́ tí ọ̀rọ̀ ìmúniníyè ti jẹ́ kókó kan tó máa ń fa ọ̀pọ̀ awuyewuye àti iyàn jíjà. a Kódà kò rọrùn fáwọn tó mọ̀ dáadáa nípa rẹ̀ pàápàá láti ṣàlàyé rẹ̀. Ní gbogbo gbòò, ohun táwọn èèyàn mọ ìmúniníyè sí ni pé kéèyàn má mọ ohun tó ń ṣe mọ́ tàbí kéèyàn máa ṣèrànrán. Àmọ́ ṣá o, ohun tí ìmúniníyè lè ṣe fúnni ni ọ̀pọ̀ èèyàn fẹ́ láti mọ̀ kì í ṣe ohun tó jẹ́ gan-an.

Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ó ti wá ń di ohun tó wọ́pọ̀ pé kí àwọn oníṣègùn láwọn orílẹ̀-èdè kan máa dábàá ìmúniníyè bí ọ̀nà kan láti fi tọ́jú aláìsàn. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn Psychology Today sọ pé: “Ìmúniníyè lè wo ẹ̀fọ́rí sàn, ó lè dín ìrora ìbímọ kù, ó lè jẹ́ kéèyàn fi sìgá mímu sílẹ̀, ó ṣeé fi rọ́pò àwọn oògùn tí kì í jẹ́ kéèyàn mọ ìrora, ó sì lè jẹ́ kó ṣeé ṣe fún èèyàn láti kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa—gbogbo ìwọ̀nyí láìsí àbájáde búburú kankan.” Àmọ́ lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń wo ìmúniníyè pé bíbá ẹ̀mí lò àti iṣẹ́ òkùnkùn ló jẹ́.

Kí ni Bíbélì sọ lórí kókó yìí? Lóòótọ́, Bíbélì kì í ṣe ìwé tó dá lórí ìlera, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ̀rọ̀ lórí ìmúniníyè ní tààràtà. Àmọ́, àwọn ìlànà tá a lè rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ojú tí Ọlọ́run fi wo ọ̀ràn yìí.

Ǹjẹ́ Ìmúniníyè Ní Iṣẹ́ Òkùnkùn Nínú?

Ṣé ọ̀rọ̀ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ lohun táwọn èèyàn máa ń sọ pé ìmúniníyè ní iṣẹ́ òkùnkùn nínú? Lóòótọ́ o, àwọn nǹkan tí kò ṣẹlẹ̀ ní ti gidi àtàwọn nǹkan àràmàǹdà táwọn èèyàn ń rí nínú fíìmù tàbí tí wọ́n ń kà nínú ìwé lè máa mú wọn sọ bẹ́ẹ̀, àmọ́ ìdí tó dájú wà láti gbà pé ìmúniníyè ní bíbá ẹ̀mí lò nínú. Nígbà tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopedia of Occultism and Parapsychology ń sọ nípa ìmúniníyè, ó ṣàlàyé pé: “Kò sí béèyàn ṣe máa sọ nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìmúniníyè tí kò ní mẹ́nu kan iṣẹ́ òkùnkùn.” Báwọn ẹlẹ́sìn kan ṣe máa ń lọ nínú ìran, èyí tó ti jẹ́ apá kan iṣẹ́ oṣó àti iṣẹ́ òkùnkùn látọjọ́ pípẹ́, ni ọ̀pọ̀ èèyàn sábà máa ń wò bí oríṣi ìmúniníyè kan. Bákan náà, àwọn àlùfáà ní ilẹ̀ Íjíbítì àti ilẹ̀ Gíríìsì ayé ọjọ́un máa ń ra àwọn èèyàn níyè nígbà tí wọ́n bá ń gbìyànjú láti wò wọ́n sàn lórúkọ àwọn ọlọ́run èké wọn.

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ tá a fa ọ̀rọ̀ yọ nínú rẹ̀ lókè sọ pé: “Kódà lọ́jọ́ òní pàápàá, ‘Bíbá ẹ̀mí lò’ làwọn èèyàn ka ọ̀pọ̀ ìmúniníyè tó ń ṣẹlẹ̀ sí.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòro láti sọ bí onírúurú ìmúniníyè ṣe ní ìbẹ́mìílò nínú sí, kókó tó wà níbẹ̀ ni pé, gbogbo onírúurú ìbẹ́mìílò pátá ni Ọlọ́run dá lẹ́bi. (Diutarónómì 18:9-12; Ìṣípayá 21:8) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni kò ní láti dágunlá sí àwọn ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ ní kedere pé ó lòdì nípa ìmúniníyè.

Bó Ṣe Ń Nípa Lórí Ìhùwàsí Ẹni

Kí la lè sọ nípa ipa tí ìmúniníyè ń ní lórí ìrònú àti ìhùwàsí ẹni tí wọ́n ń darí? Ǹjẹ́ ewu kankan wà nínú èyí? Kókó kan tó ṣe pàtàkì ni pé, tí wọ́n bá ti mú ẹnì kan níyè, ẹni náà kò ní í lè fi bẹ́ẹ̀ ṣàkóso ìṣesí rẹ̀ mọ́. Ọ̀nà yìí làwọn tó máa ń múni níyè nínú eré orí ìtàgé máa ń lo, ìyẹn ni pé wọ́n á mú kí àwọn tó bá yọ̀ǹda ara wọn láti wá sórí pèpéle máa ṣe àwọn ohun tí àwọn yẹn kò jẹ́ dánú ara wọn ṣe, kódà wọ́n lè máa hùwà bíi pé wọ́n ti mutí yó.

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana sọ̀rọ̀ lórí ìmúniníyè ní gbangba yìí pé: “Ẹni tí wọ́n mú níyè náà lè dẹni tó ń ṣe ohun tí ẹni tó mú un níyè náà bá ń sọ fún un láìjanpata, ó sì lè máa ṣe àwọn ohun tí ara rẹ̀ sábà máa ń béèrè fún tìrọ̀rùntìrọ̀rùn. Ní gbogbo ìgbà tó bá wà ní ipò yìí, ó lè máa nímọ̀lára pé gbogbo nǹkan tó ń jẹ́ kí òun lè ṣàkóso ìwà àti ìṣesí òun ni wọ́n ti mú kúrò.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Collier’s Encyclopedia sọ pé: “Gbogbo ìrònú ẹni tí wọ́n mú níyè náà yóò pa pọ̀ sọ́nà kan, èyí á sì mú kó fiyè sílẹ̀ gidigidi sí gbogbo ohun tí ẹni tó mú un níyè náà bá ń wí fún un tí yóò sì máa ṣe nǹkan náà láìjiyàn.”

Ǹjẹ́ a lè sọ pé èyí kò léwu? Ǹjẹ́ yóò bọ́gbọ́n mu kí Kristẹni tòótọ́ kan jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn pa ìrònú òun dà nípa mímú òun níyè? Òdìkejì pátápátá lèyí yóò jẹ́ sí ọ̀rọ̀ ìṣílétí Pọ́ọ̀lù, èyí tó sọ pé: “Ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò yín. Ẹ sì jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.”—Róòmù 12:1, 2.

Ǹjẹ́ Kristẹni kan lè “di ẹ̀rí-ọkàn rere mú” bó bá jẹ́ kí ẹnì kan fi òun sínú ipò kan tí kò ti ní lè ṣàkóso ìrònú rẹ̀, ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, àti kódà, ìṣesí rẹ̀ dáadáa? (1 Pétérù 3:16) Bíbélì ṣí wa létí pé: “Kí olúkúlùkù yín mọ bí yóò ti ṣèkáwọ́ ohun èlò tirẹ̀ nínú ìsọdimímọ́ àti ọlá.” (1 Tẹsalóníkà 4:4) Ó hàn gbangba pé, ìmúniníyè kò ní jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ẹnì kan láti tẹ̀ lé irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀.

Ìrètí Tó Wà fún Níní Ìlera Pípé

Lójú ìwòye àwọn ìlànà Bíbélì tá a mẹ́nu kàn lókè yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń yẹra fún àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú mímúni níyè tàbí ìmúra-ẹni-níyè. Wọ́n ń fi àṣẹ tó wà nínú Diutarónómì 18:10, 11 sọ́kàn, èyí tó sọ pé: “Kí a má ṣe rí láàárín rẹ ẹnikẹ́ni . . . tí ń fi èèdì di àwọn ẹlòmíràn.” Ní ti àwọn tí àìsàn ń yọ lẹ́nu, ọ̀pọ̀ àwọn ìtọ́jú mìíràn wà tí kò fi èèyàn sínú ewu lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òkùnkùn tàbí tí yóò mú kí ìrònú èèyàn di ohun tí ẹlòmíràn á máa ṣàkóso bó ṣe wù ú.

Nípa yíyàgò fún àwọn àṣà tó ta ko àwọn ìlànà Bíbélì, àwọn Kristẹni á lè ní ìrètí láti gbé títí láé nínú ayé tuntun òdodo Ọlọ́run. Nígbà yẹn, aráyé yóò gbádùn ìlera ara àti ìrònú tó pé pérépéré láìsí lílo ìmúniníyè.—Ìṣípayá 21:3, 4.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ pé ìmúniníyè ni “kéèyàn wà ní ipò kan tó dà bíi pé èèyàn ń sùn, èyí tó jẹ́ pé lọ́pọ̀ ìgbà, ẹlòmíràn ló máa ń sọ èèyàn dà bẹ́ẹ̀, tí olúwarẹ̀ ò ní rántí ohunkóhun mọ́ tàbí tí iyè rẹ̀ á ra, tí yóò máa ṣèrànrán, tí ẹni tó ń darí rẹ̀ sì lè mú kó ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́ kí ó ṣe.”—The American Heritage Dictionary.