Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdáhùn wọn sì wà ní ojú ìwé 17. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)

1. Kí nìdí tí akónijọ fi sọ pé “okùn onífọ́nrán mẹ́ta ni a kò . . . lè tètè fà já sí méjì”? (Oníwàásù 4:12)

2. Lábẹ́ Òfin Mósè, àwọn nǹkan méjì wo làwọn ẹranko tí a gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láyè láti jẹ gbọ́dọ̀ ní? (Diutarónómì 14:6)

3. Ta ni bàbá Jóṣúà? (Jóṣúà 1:1)

4. Nígbà tí Jèhófà gba Sátánì láyè láti pọ́n Jóòbù lójú, kí ni Sátánì ṣe fún Jóòbù? (Jóòbù 2:7)

5. Ta ló sọ fún Ahasuwérúsì Ọba nípa òpó igi tó ga ní àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ tí Hámánì ṣe sílẹ̀ fún Módékáì, tí èyí sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ọba pàṣẹ pé kí a gbé Hámánì kọ́ sórí rẹ̀? (Ẹ́sítérì 7:9)

6. Báwo ni Jésù ṣe sọ pé a óò dá àwọn wòlíì èké mọ̀? (Mátíù 7:15, 16)

7. Orúkọ oyè Jèhófà wo, èyí tó ń fi ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ títóbi jù lọ tá a ní láti bọ̀wọ̀ fún hàn, ló jẹ́ pé inú ìwé Dáníẹ́lì nìkan la ti lè rí i? (Dáníẹ́lì 7:22)

8. Àwọn ohun ṣíṣeyebíye wo ni ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun Sólómọ́nì Ọba láti Táṣíṣì máa ń gbé wá fún un tí wọ́n bá dé láti ìrìn àjò wọn ẹlẹ́ẹ̀kan lọ́dún mẹ́ta? (1 Àwọn Ọba 10:22)

9. Ẹni wo lòun àti Áárónì jọ gbé ọwọ́ Mósè méjèèjì ró títí dìgbà tí Jèhófà fi jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámálékì? (Ẹ́kísódù 17:12)

10. Báwo ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe pinnu ẹni tí yóò rọ́pò Júdásì Ísíkáríótù? (Ìṣe 1:23-26)

11. Ta ni àlùfáà àgbà ní Ísírẹ́lì ní àkókò tí Sámúẹ́lì di wòlíì? (1 Sámúẹ́lì 3:1)

12. Nígbà tí à ń fi àwọn àlùfáà joyè ní Ísírẹ́lì, àwọn ibi mẹ́ta wo ni Mósè fi ẹ̀jẹ̀ sí lára Áárónì àtàwọn ọmọ rẹ̀? (Léfítíkù 8:23, 24)

13. Dípò tí Ọlọ́run ì bá fi dá Éfà gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀dá ọ̀tọ̀ látinú ilẹ̀, àtinú kí ni Ọlọ́run ti mú un jáde? (Jẹ́nẹ́sísì 2:21, 22)

14. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ pé ó jẹ́ “gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo”? (1 Tímótì 6:10)

15. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ, kí ni wọ́n fi ń díwọ̀n ilẹ̀ tí àwọn akọ màlúù méjì tí a fi sábẹ́ àjàgà kan náà lè tú ní ọjọ́ kan? (1 Sámúẹ́lì 14:14)

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè

1. Láti fi hàn kedere pé àwọn tó bá ń ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìṣọ̀kan, tí wọ́n sì ní ète kan náà máa ń ní okun àti agbára púpọ̀ láti kojú ìṣòro

2. Wọ́n ní láti jẹ́ ẹranko tí ó la pátákò, tí ó sì ń jẹ àpọ̀jẹ

3. Núnì

4. Ó “fi oówo afòòró-ẹ̀mí kọlu Jóòbù láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀”

5. Hábónà, ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ààfin

6. “Nípa àwọn èso wọn”

7. “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé”

8. Wúrà, fàdákà, eyín erin, àwọn ìnàkí àtàwọn ẹyẹ ológe

9. Húrì

10. Wọ́n gbàdúrà wọ́n sì ṣẹ́ kèké

11. Élì

12. Etí wọn ọ̀tún, àtàǹpàkò ọwọ́ wọn ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ wọn ọ̀tún

13. Egungun ìhà kan tí ó mú láti ara Ádámù

14. “Ìfẹ́ owó”

15. Sarè