Ǹjẹ́ Ohun Kan Wà Tó Lè Fòpin Sí Ìwà Ìkà Bíburú jáì?
Ǹjẹ́ Ohun Kan Wà Tó Lè Fòpin Sí Ìwà Ìkà Bíburú jáì?
Ó DÀ bíi pé ìwà ọ̀daràn ti di ìṣòro tí kò lè kásẹ̀ ńlẹ̀ nínú àwùjọ wa òde òní. Láìka gbogbo ìsapá táwọn òṣìṣẹ́ afẹ́dàáfẹ́re, àwọn agbófinró, àtàwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tó ń ran àwọn ọ̀daràn lọ́wọ́ láti tún dèèyàn gidi padà láwùjọ ń ṣe tọkàntara, ńṣe layé túbọ̀ ń di ibi eléwu sí i láti gbé. Ǹjẹ́ a lè rí nǹkan ṣe sí i?
Bíbélì fi hàn pé ìyípadà ńláǹlà ń bọ̀ lọ́nà. Àmọ́, èyí kò ní wá nípasẹ̀ ìsapá ìjọba èèyàn. Gbogbo àwọn alákòóso ẹ̀dá èèyàn pátá ló níbi tágbára wọn mọ láìka bí ohun tí wọ́n ní lọ́kàn láti ṣe ṣe lè dára tó. Wọn ò ní agbára bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ní ohun tá a nílò láti fa ìwà ọ̀daràn tu tigbòǹgbò-tigbòǹgbò
tàbí kí wọ́n mú kí ayé di ibi tí ààbò yóò máa wà títí lọ.Ẹlẹ́dàá wa ló máa mú kí ìyípadà tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ṣeé ṣe. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òun ni Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ayé, ó ní agbára àti ẹ̀tọ́ láti ṣe ohun tí ẹ̀dá èèyàn ò lè ṣe. Bíbélì pè é ní “Ẹni tí ń sọ àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga di aláìjámọ́ nǹkan kan, tí ó ti sọ àwọn onídàájọ́ ilẹ̀ ayé di òtúbáńtẹ́ lásán-làsàn . . . , àti ní ti pé òun ní okun inú nínú agbára.” (Aísáyà 40:23-26) Irú àwọn ìyípadà wo ni Ọlọ́run ṣèlérí, báwo ni àwọn ìyípadà náà sì ṣe fún wa ní ojúlówó ìrètí nípa ayé kan tó máa dára ju èyí lọ?
Sáàmù 37:10, 11 sọ ìlérí Ọlọ́run fún wa pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, [ẹni burúkú náà] kì yóò sì sí.” Ète Ọlọ́run ni láti mú ìparun bá àwọn tí ìwà burúkú ti jingíri mọ́ lára tí wọn ò sì ṣe tán láti yí padà. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo èèyàn ni Ọlọ́run máa pa run. Ní ti àwọn èèyàn tó múra tán láti di ọlọ́kàn tútù, onírẹ̀lẹ̀, àti ẹni àlàáfíà, onísáàmù náà ṣèlérí pé: “Ní ìrètí nínú Jèhófà, kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́, òun yóò sì gbé ọ ga láti gba ilẹ̀ ayé. Nígbà tí a bá ké àwọn ẹni burúkú kúrò, ìwọ yóò rí i.” Lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá ti mú àwọn ẹni burúkú kúrò, àwọn èèyàn tó bá ṣẹ́ kù yóò gbádùn “ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà,” ìyẹn ayé kan níbi tí kò ti ní sí ìwà ìkà kankan.—Sáàmù 37:11, 34.
Aráyé Nílò Ìyípadà Èrò Inú àti Ti Ọkàn
Mímú àwọn èèyàn búburú kúrò àti dídá àwọn èèyàn rere sí nìkan kò tó láti mú kí ìṣòro ìwà ọ̀daràn kásẹ̀ nílẹ̀ pátápátá. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó sábà máa ń fa ìwà ọ̀daràn ni pé, àwọn èèyàn kò dá ọkàn wọn àti ìrònú wọn lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa. Àmọ́, ibi tí Ìjọba Ọlọ́run ti máa fàgbà han gbogbo ìjọba yòókù nìyí. Ìjọba Ọlọ́run yóò pèsè ìtọ́ni àti ẹ̀kọ́ láti dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti fẹ́ràn òdodo. Aísáyà 54:13 sọ pé: “Gbogbo ọmọ rẹ yóò . . . jẹ́ àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò sì pọ̀ yanturu.”
Àwọn àbájáde tí èyí máa mú wá á ti lọ wà jù! Lọ́nà àpèjúwe, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìyípadà tó máa ṣẹlẹ̀ nínú àwọn tí wọ́n ti lè máa hùwà bí ẹranko nígbà kan rí. Ó sọ pé: “Ìkookò yóò . . . máa gbé ní ti tòótọ́ fún ìgbà díẹ̀ pẹ̀lú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, àmọ̀tẹ́kùn pàápàá yóò sì dùbúlẹ̀ ti ọmọ ewúrẹ́, àti ọmọ màlúù àti ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ àti ẹran tí a bọ́ dáadáa, gbogbo wọn pa pọ̀.” Kí nìdí? “Nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.” (Aísáyà 11:6, 9) Àmọ́ o, ìwọ àti ìdílé rẹ kò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní láti dúró fún àkókò pípẹ́ láti rí irú àwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀. Lọ́nà wo nìyẹn fi rí bẹ́ẹ̀?
O Lè Jàǹfààní Nísinsìnyí
Àwọn èèyàn kan wà tí wọ́n ń ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ nísinsìnyí ní ìmúrasílẹ̀ fún ayé kan tí kò ní sí ìwà ọ̀daràn mọ́. Wọ́n ti ń gbé àwọn ìwà tuntun wọ̀ báyìí, ìyẹn irú ìwà tí Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn tó máa gbé nínú ayé tuntun rẹ̀ máa hù. (2 Pétérù 3:13) Wọ́n ń ṣe èyí nípa fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé wọn. Kíyè sí àpèjúwe fífanimọ́ra tí Bíbélì ṣe: “Kí ẹ di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú yín ṣiṣẹ́, kí ẹ sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.”—Éfésù 4:23, 24.
Kólósè 3:12-14 tún sọ síwájú sí i nípa irú àwọn ànímọ́ dídára tí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó jẹ́ olóòótọ́ ọkàn ń fi kọ́ra báyìí. Ó sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ Ọlọ́run, mímọ́ àti olùfẹ́, ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ. Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe. Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”
Ṣé wàá fẹ́ ìrànlọ́wọ́ láti gbé àwọn ìwà tuntun ti Kristẹni wọ̀? Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn yíká ayé ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní àwọn ìpàdé tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe déédéé nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn, àti ní àwọn àpéjọ títóbi, kódà àwọn èèyàn to ti jẹ́ ọ̀daràn paraku nígbà kan rí ti kọ́ bí wọ́n ṣe lè jẹ́ ẹlẹ́mìí àlááfíà. a Bó o bá fẹ́ jàǹfààní nínú irú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ Bíbélì tí kò lẹ́gbẹ́ yìí, má ṣàì kàn sí àwọn tó ń tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde. Tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n á fi ràn ọ́ lọ́wọ́ láti wà lára àwọn èèyàn tó ń múra sílẹ̀ báyìí láti gbé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ń mú bọ̀, níbi tí kò ti ní sí ìwà ìkà kankan mọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àpẹẹrẹ, wo ìtẹ̀jáde Jí! ti May 8, 2001, ojú ìwé 8 sí 10.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ń kẹ́kọ̀ọ́ láti gbé nínú ayé kan tí kò ti ní sí ìwà ìkà