Wíwo Ayé
Wíwo Ayé
Kí Ọmọdé Máa Sanra Jọ̀kọ̀tọ̀ Ti Di Ìṣòro Kárí Ayé
Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Kí ọmọdé máa sanra jọ̀kọ̀tọ̀ ti wá ń di ìṣòro tó kárí ayé báyìí, ojútùú ìṣòro ọ̀hún ò sì ju pé ká wá nǹkan ṣe sí àwọn oúnjẹ pàrùpárù tí wọ́n máa ń jẹ. Gẹ́gẹ́ bí Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe Lágbàáyé Lórí Ọ̀ràn Sísanra Jọ̀kọ̀tọ̀ ṣe sọ, ó lé ní ìdá kan nínú mẹ́rin àwọn ọmọ ọlọ́dún mẹ́wàá láwọn orílẹ̀-èdè kan jákèjádò ayé tí wọ́n sanra ju bó ṣe yẹ lọ.” Àwọn orílẹ̀-èdè tó ní iye àwọn ọmọ tó sanra jọ̀kọ̀tọ̀ jù lọ lágbàáyé ní ìpíndọ́gba rèé: Malta (ìdá mẹ́tàlélọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún), ilẹ̀ Ítálì (ìdá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún), àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà (ìdá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún). Ìdá kan nínú mẹ́rin àwọn ọmọ tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́rin sí mẹ́wàá nílẹ̀ Chile, Mẹ́síkò, àti Peru ló sanra kọjá bó ṣe yẹ. Láwọn ibì kan nílẹ̀ Áfíríkà, àwọn ọmọ tó sanra pọ̀ ju àwọn tó pẹ́lẹ́ńgẹ́ lọ. Kí ló dé tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé fi wá ń di bẹ̀ǹbẹ̀ kalẹ̀? Ìwé ìròyìn The Washington Post dáhùn pé: “Ọ̀pọ̀ ọmọ kékeré nílẹ̀ Amẹ́ríkà máa ń rí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ìpolówó oúnjẹ lọ́dún, ìdá márùnléláàádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ìpolówó yìí ló sì dá lórí àwọn oúnjẹ pàrùpárù, ọtí ẹlẹ́rìndòdò, midinmíìdìn, àtàwọn oúnjẹ oníyangan tí ṣúgà pàpọ̀jù nínú wọn, tí gbogbo wọn gbówó lórí àmọ́ tí wọn ò ní èròjà tó ń ṣara lóorè nínú páàpáà. Àwọn tó ń ṣe ìpolówó náà máa ń ṣàfihàn àwọn oúnjẹ pàrùpárù wọ̀nyí àtàwọn ọtí ẹlẹ́rìndòdò nígbà tí wọ́n bá ń polówó ohun ìṣiré ọmọdé, ohun èlò eré ìdárayá, àwọn nǹkan ìnàjú, tàbí fíìmù, wọ́n sì tún máa ń polówó wọn nígbà tí wọ́n bá ń ṣàfihàn àwọn èèyàn tó gbajúmọ̀ láwùjọ. . . . Ǹjẹ́ ó wá yani lẹ́nu nígbà náà pé ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú ọgọ́rùn-ún oúnjẹ àwọn ọmọdé ló jẹ́ oúnjẹ pàrùpárù, nígbà tí ìdá mẹ́wàá jẹ́ ọtí ẹlẹ́rìndòdò tí ṣùgà pọ̀ nínú rẹ̀, àmọ́ tó jẹ́ pé kìkì ìlàjì èso àti ẹ̀fọ́ tára wọn nílò ni wọ́n ń jẹ?”
Oyin Ń Lé Àwọn Erin Dà Nù
Àwọn erin tó wà ní orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà túbọ̀ ń pọ̀ sí i àmọ́ èyí ti fa ọ̀pọ̀ ìṣòro. Àwọn erin tó máa ń rìn kiri yìí máa ń ba igi àtàwọn nǹkan ọ̀gbìn jẹ́, wọ́n sì máa ń tẹ èèyàn kan pa lọ́sẹ̀ méjìméjì, ní ìpíndọ́gba. Àmọ́ o, ọ̀gbẹ́ni Fritz Vollrath tó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè ní Yunifásítì Oxford ti rí ohun kan tó lè lé wọn dà nù. Ó sọ pé, nígbà táwọn erin bá lọ kọlu ilé oyin kan, “wọn kì í fara re lọ. Bí wọ́n ti ń sá lọ làwọn oyin náà á máa gbá tọ̀ wọ́n lẹ́yìn fún ọ̀pọ̀ kìlómítà.” Àwọn apá ibi tó ti máa ká àwọn erin náà lára làwọn oyin náà sì ti máa ń ta wọ́n, irú bíi lẹ́bàá ojú, ẹ̀yìn etí, àyà àti ikùn. Ọ̀gbẹ́ni Vollrath fi àwọn ilé oyin tó ní oyin nínú àtèyí tí kò ní oyin nínú sára díẹ̀ lára àwọn igi tó ń dàgbà lágbègbè kan tí àwọn erin sábà máa ń lọ nínú igbó kan. Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé àwọn erin náà kò ya ìdí gbogbo igi tó ní ilé oyin tó ní oyin nínú àti ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn igi tó ní àwọn ilé oyin tí kò ní oyin nínú. Àmọ́, wọ́n ba mẹ́sàn-án jẹ́ nínú àwọn igi mẹ́wàá tí kò sí ilé oyin lára wọn. Ọ̀gbẹ́ni Vollrath tún ṣàkíyèsí pé àwọn erin máa ń sá tí wọ́n bá gbọ́ ohùn àwọn oyin tí wọ́n ń kùn yùnmùyùnmù pẹ̀lú ìbínú, kódà bó bá jẹ́ pé orí ẹ̀rọ gbohùngbohùn ni ohùn tí wọ́n ń gbọ́ náà ti ń wá.
Ó Pẹ́ Kí Wọ́n Tó Gbọ́ Ìròyìn àmọ́ Kíá Ni Wọ́n Gbégbèésẹ̀
Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Àwọn ẹ̀yà Masai tó ń gbé àgbègbè [Enoosaen], ní ìkangun orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà, kò mọ ohun tó ń jẹ́ ilé àwòṣífìlà, nítorí pé ní àgbègbè wọn, ohun tó ga jù lọ lójú sánmà tí wọ́n mọ̀ kò ju àwọn igi bọn-ọ̀n-ní àtàwọn àgùnfọn tó ń jẹ ewé orí wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tí Kimeli Naiyomah padà sí abúlé kékeré yìí lẹ́nu àìpẹ́ yìí, lẹ́yìn tó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó rí i pé àwọn ẹ̀yà Masai ẹgbẹ́ rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìlú jíjìnnà tùùnùtuunu tí wọ́n ń pè ní New York ní September 11, 2001. Àwọn kan nínú àwọn èèyàn tó máa ń ṣí kiri tí wọ́n jẹ́ darandaran yìí ò tiẹ̀ gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà rárá.” Nígbà tí Naiyomah, tó wà ní àdúgbò Manhattan níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé lọ́jọ́ kọkànlá oṣù September [ọdún 2001], sọ ohun tó fojú ara rẹ̀ rí ní nǹkan bí oṣù mẹ́jọ ṣẹ́yìn fún àwọn ará abúlé náà, ńṣe ni ìbànújẹ́ dorí wọn kodò, wọ́n sì fẹ́ ṣe nǹkan kan láti ṣèrànlọ́wọ́. Àbájáde èyí ni pé, wọ́n fi màlúù mẹ́rìnlá ṣètọrẹ, tó jẹ́ ọ̀kan lára ohun ṣíṣeyebíye jù lọ tí ẹnì kan tó jẹ́ ẹ̀yà Masai lè fúnni, láti fi ran àwọn tí àjálù náà kàn lọ́wọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Times ṣe sọ, níwọ̀n bí kò ti rọrùn láti kó àwọn màlúù náà ránṣẹ́, òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ tó ń ṣojú ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà tó tẹ́wọ́ gba àwọn ẹ̀bùn náà sọ pé, ó “ṣeé ṣe kí òun ta àwọn màlúù náà kí òun sì fi owó wọn ra àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ àwọn ẹ̀yà Masai láti fún ilẹ̀ Amẹ́ríkà.”
Àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin Tí Wọ́n Jẹ́ Ewèlè
Ìwé ìròyìn Toronto Star sọ pé: “Ìwà ìkà láàárín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sábà máa ń jẹ mọ́ líluni,” nígbà tó jẹ́ pé “láàárín àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin, fífara ṣe ohun tó máa ru ìmọ̀lára ẹlòmíràn sókè tàbí tó máa fa ẹ̀dùn ọkàn bá ẹlòmíràn ni tiwọn.” A gbọ́ pé bí àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin bá ṣe ń di ọmọ ọdún mẹ́tàlá sókè, bẹ́ẹ̀ ni ìbẹ̀rù àti àníyàn tí wọ́n ń ní á máa pọ̀ sí i, títí kan àníyàn nípa ojú táwọn ọkùnrin fi ń wò wọ́n. Àwọn ògbóǹkangí nípa ìhùwàsí ẹ̀dá sọ pé, “àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin lè máa bára wọn díje nípa bí wọ́n ṣe ‘lè fi ẹwà wọn fa ọkùnrin mọ́ra tó,’ àwọn àwòrán tó ń ru ìfẹ́ ìbálòpọ̀ sókè tí wọ́n ń rí lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí nínú àwọn ìwé ìròyìn ló sì ń sún wọn ṣe bẹ́ẹ̀.” Denise Andrea Campbell, tó jẹ́ ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí fún Ìgbìmọ̀ Ìjọba Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Àwọn Obìnrin sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin ni kò mọ ọ̀nà pàtó tí wọ́n lè gbà bójú tó àwọn ìmọ̀lára ìbínú àti owú tí wọ́n máa ń ní.” Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń fi àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí hàn “láwọn ọ̀nà mìíràn tí kò fara hàn gbangba àmọ́ tó lè dun ẹlòmíràn wọra.” Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin kan lè dájú sọ àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mìíràn, wọ́n á sì ṣe onírúurú nǹkan tó máa dùn wọ́n wọra, irú bíi kíkọ̀ láti sọ̀rọ̀ sí ẹni náà, fífi ojúkójú wò ó, ṣíṣe òfófó nípa rẹ̀, àti títan àhesọ kálẹ̀ nípa rẹ̀.
Ìdààmú Ọkàn Níbi Iṣẹ́
Ìwé ìròyìn The Globe and Mail sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá kan nínú márùn-ún àwọn ará Kánádà tó sọ pé ìdààmú ọkàn tí àwọ́n ń ní pọ̀ débi pé, àwọ́n ti gbèrò láti pa ara àwọn láti lè fòpin sí i.” Kí ló ń fa ìdààmú ọkàn yìí? Nígbà tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá ẹgbẹ̀rún kan àti méjì èèyàn lẹ́nu wò, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì lára wọn tó sọ pé iṣẹ́ wọn ni ìṣòro wọn. Shimon Dolan, tó jẹ́ afìṣemọ̀rònú nípa ọ̀ràn àwọn òṣìṣẹ́ tó sì tún jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n kan ní Yunifásítì Montreal, sọ pé: “Láwọn ibi iṣẹ́ lóde òní, ìlò omi òjò là ń lo àwọn èèyàn, agbára wọn àti ọpọlọ wọn kò sì lè gbé gbogbo ohun tá à ń fún wọn ṣe. Yàtọ̀ sí pé títì tí à ń tì wọ́n ti pàpọ̀jù, kò tún sí ìdánilójú rárá—ìyẹn ni pé ó lè dọ̀la kí wọ́n sọ pé kò síṣẹ́ mọ́.” Kí làwọn ará Kánádà fi ń kojú ìdààmú ọkàn náà? Ìwé ìròyìn Globe sọ pé, ṣíṣe eré ìmárale ló wọ́pọ̀ jù, “lẹ́yìn náà ló kan ìwé kíkà, àwọn ìgbòkègbodò àfipawọ́ àti ṣíṣe àwọn eré ìdárayá, nínajú pẹ̀lú àwọn èèyàn àti lílo àkókò pẹ̀lú ìdílé ẹni.”
Kíkàwé Pẹ̀lú Òbí Ń Mú Kí Ara Àwọn Ọmọdé Balẹ̀
Ìwé ìròyìn The Times ti ìlú London sọ pé: “Kíkàwé déédéé pẹ̀lú òbí lè dín ìwà jàgídíjàgan kù jọjọ láàárín àwọn ọmọdé oníjàngbọ̀n tí wọ́n máa ń jà, tí wọ́n ń jalè, tí wọ́n sì ń purọ́.” Nínú ìwádìí ọlọ́sẹ̀ mẹ́wàá kan tí Àjọ Tó Ń Rí sí Ìṣòro Ọpọlọ ṣe, èyí tí wọ́n ṣe nípa ọgọ́rùn-ún kan àwọn ọmọ ọlọ́dún márùn-ún sí mẹ́fà tí wọ́n ń gbé ní Àárín-Gbùngbùn ìlú London, wọ́n sọ fún àwọn òbí àwọn ọmọ náà pé kí wọ́n máa “yí tẹlifóònù alágbèéká wọn pa kí wọ́n tó jókòó láti kàwé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n máa sọ àwọn kókó tó wà nínú àwọn ìtàn náà kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í kà wọ́n, kí wọ́n sì tún rọra máa ṣí àwọn ojú ìwé náà láti wo àwọn àwòrán inú rẹ̀.” Ìwé ìròyìn náà sọ pé, àwọn àbájáde ìwádìí náà “fi ẹ̀rí hàn gbangba pé àwọn ìgbòkègbodò rírọrùn, tí àwọn òbí ṣètò láti jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn pọkàn pọ̀, lè ṣèrànwọ́ gidigidi láti mú kí àwọn ọmọ ní ìwà tó dára nígbà tí wọ́n ṣì kéré gan-an.” Dókítà Stephen Scott, tó jẹ́ aṣáájú nínú ìwádìí náà, sọ pé: “Ohun tí àwọn ọmọdé dìídì nílò ni àfiyèsí. Wọ́n sì lè rí èyí gbà nípa kíkàwé pẹ̀lú àwọn òbí wọn.”
Àwọn Olùyọ̀ǹda-Ara-Ẹni Máa Ń Láyọ̀ Nídìí Iṣẹ́ Wọn
Ìwé ìròyìn The Sydney Morning Herald sọ pé: “Àwọn èèyàn tó ń lo àkókò wọn fún iṣẹ́ tí wọn ò gbowó lórí ẹ̀ sọ pé inú àwọn máa ń dùn gan-an ju ti àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn lọ pẹ̀lú iṣẹ́ àwọn, iye wákàtí tí àwọ́n fi ṣe é, ìfararora tí àwọ́n ní pẹ̀lú àwọn èèyàn, àti ipò tẹ̀mí wọn.” Ìròyìn náà tún sọ pé, ìwádìí kan tí àwùjọ àwọn olùṣèwádìí kan ní Ọsirélíà ṣe fi hàn pé àwọn òṣìṣẹ́ tó jẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni “láyọ̀ gan-an pẹ̀lú bí ìlera wọn ṣe máa ń jí pépé, iye àkókò tí wọ́n ní láti fi gbafẹ́, àti bí wọ́n ṣe ń lo àkókò náà.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Bob Cummins ti Yunifásítì Deakin sọ pé, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ olùyọ̀ǹda–ara-ẹni ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà pọ̀ gidi gan-an, nítorí pé ìdá méjìlélọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará ilẹ̀ Ọsirélíà ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ tí wọn ò gbowó lórí ẹ̀. Ìwé ìròyìn Herald tún ròyìn pé, àwọn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún ohun tó lé ní ọgọ́ta wákàtí lọ́sẹ̀—pàápàá jù lọ àwọn obìnrin tí wọ́n ń tọ́jú àwọn aláìlera—“láyọ̀ gan-an pẹ̀lú ìlera wọn àti iṣẹ́ wọn ju àwọn èèyàn tí àkókò wọn dín sí tiwọn lọ.”
Títukọ̀ Gba Ọ̀nà Àríwá Ìlà Oòrùn Ayé
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé ìròyin The Independent ti ìlú London sọ, ìgbà kẹ́rin tí ikọ̀ àwọn olùṣàwárí ọmọ ilẹ̀ Jámánì kan ti ń gbìyànjú láti tukọ̀ kọjá ní Ọ̀nà Àríwá Ìlà Oòrùn ayé nínú ọkọ̀ ojú omi tó gùn ní mítà méjìdínlógún ni wọ́n tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàṣeyọrí. Ọ̀nà òju òkun yìí wà nítòsí etíkun tó wà ní àríwá ilẹ̀ Rọ́ṣíà tí yìnyín máa ń bò nígbà gbogbo. Ọdún 1879 nìgbà àkọ́kọ́ tẹ́nì kan máa la ọ̀nà náà kọjá, ìyẹn nígbà tí olùṣàwárí ọmọ ilẹ̀ Sweden náà, Adolf Nordenskjöld kọjá níbẹ̀ pẹ̀lú ọkọ̀ ojú omi kan tó ń lo ooru gbígbóná àti ìgbòkun. Arved Fuchs, tó jẹ́ aṣáájú ikọ̀ náà, sọ pé: “Mi ò tíì rí ìgbà kankan tí yìnyín ò bo ojú ọ̀nà náà bíi ti ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yìí. Nǹkan méjì la lérò pé ó fa èyí, bí ilẹ̀ ayé ṣe túbọ̀ ń móoru sí i àti bí afẹ́fẹ́ ṣe ń fẹ́ lódìlódì, èyí tó gbá òkìtì yìnyín kúrò ní etíkun náà tó sì jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti kọjá.” Nípa lílo ọkọ̀ òfuurufú fífúyẹ́ kan àti rírí àwòrán bí òkìtì yìnyín náà ṣe ń lọ síwá sẹ́yìn látinú sátẹ́láìtì, láìlo ẹ̀rọ tó ń gbá yìnyín kúrò lójú òkun, wọ́n parí ìrìn-àjò ojú omi ẹlẹ́gbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kìlómítà náà, láti ìlú Hamburg nílẹ̀ Jámánì, sí ibi omi Provideniya nílẹ̀ Rọ́ṣíà, lórí Òkun Bering, èyí sì gba ọjọ́ mẹ́tàdínláàádóje [127]. Ní gbogbo ìgbà tí wọ́n fi wà nínú ọkọ̀ ojú omi náà, irú oúnjẹ táwọn tó máa ń lọ sí gbangba ojúde òfuurufú ń jẹ làwọn ọkùnrin náà ń jẹ. Síbẹ̀, ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Ìnira kan ṣoṣo tó wà níbẹ̀ ni gbígbé nínú àyè tó há gádígádí fún oṣù mẹ́rin pẹ̀lú àwọn èèyàn mọ́kànlá mìíràn.”