Èrò Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Tí Àwọn Èèyàn Ní Nípa Àwọn Ohun Arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè
Èrò Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Tí Àwọn Èèyàn Ní Nípa Àwọn Ohun Arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè
“Ó ń jẹ́ kéèyàn máa ní ìfẹ́ àìníjàánu tí kò yẹ kéèyàn ní, ó sì ń mú kí èròkerò téèyàn ò gbọ́dọ̀ ní máa gbani lọ́kàn ṣáá.”—Tony Parsons, akọ̀ròyìn.
JOHN ò ronú láé pé òún á sọ ‘wíwo ìran ìbálòpọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì’ di àṣà.’ a Bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn ẹlòmíràn tó máa ń ṣèèṣì rí àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ńṣe ni John kàn ń wá ìsọfúnni lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì lọ́jọ́ kan ló bá ṣàdéédéé já sí ibi kan tí wọ́n ti ń ṣe ìṣekúṣe. Láìpẹ́, wíwo ìṣekúṣe lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì wá di ohun tó gbà á lọ́kàn pátápátá. Ó sọ pé: “Màá rọra dúró títí dìgbà tí ìyàwó mi á lọ síbi iṣẹ́, màá wá fò dìde lórí bẹ́ẹ̀dì, màá sì lo ọ̀pọ̀ wákàtí nídìí kọ̀ǹpútà.” Nígbà tí àkókò tí wọ́n fi ṣeré ìbálòpọ̀ náà bá gùn gan-an, kò tiẹ̀ ní ṣíwọ́ láti jẹun tàbí láti mumi. Ó sọ pé: “Ebi kì í pa mí rárá.” Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí purọ́ fún ìyàwó rẹ̀ nípa ohun tó ń ṣe ní bòókẹ́lẹ́. Ìwòkuwò tó ń wò kò jẹ́ kó lè pọkàn pọ̀ mọ́ níbi iṣẹ́, ara rẹ̀ ò sì lélẹ̀ mọ́. Àṣà náà wá bẹ̀rẹ̀ sí pa ìgbéyàwó rẹ̀ lára gidigidi. Ìgbà tó pinnu láti lọ rí ọ̀kan lára àwọn tó ń wò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì lójúkojú ni ìyàwó rẹ̀ tó mọ̀ nípa rẹ̀. Ní báyìí, John ń gba ìtọ́jú nítorí àṣà tó ti di bárakú fún un yìí.
Àwọn ẹgbẹ́ tó ń bẹnu àtẹ́ lu ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè máa ń mẹ́nu kan irú àwọn ìrírí bíi ti òkè yìí láti fẹ̀rí hàn pé wíwo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè máa ń ní àwọn àbájáde búburú. Wọ́n sọ pé ó ń ba àjọṣe èèyàn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn jẹ́, kì í buyì kún àwọn obìnrin, ó ń sọ àwọn ọmọdé dìdàkudà, ó sì máa ń mú kéèyàn ní èrò tí kò dára nípa ìbálòpọ̀. Àmọ́, ní ìdàkejì, àwọn tó fara mọ́ àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè sọ pé, kò sóhun tó burú nínú wíwo eré ìbálòpọ̀, ojú aláìmọ̀kan ni wọ́n sì fi ń wo àwọn tó ń sọ pé ó lòdì. Ọ̀kan lára wọn kọ̀wé pé: “Kò yẹ kí àwọn èèyàn máa tijú nítorí èrò tí wọ́n ní nípa ìbálòpọ̀ tàbí ìfẹ́ tí wọ́n ní láti ní ìbálòpọ̀. A lè lo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè láti fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò aláìfọ̀rọ̀-sábẹ́-ahọ́n-sọ nípa ìbálòpọ̀, a sì lè fi mú kí irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ lárinrin sí i.” Àwọn díẹ̀ tiẹ̀ sọ pé, bí àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè ṣe pọ̀ yamùrá ń fi hàn pé àwọn èèyàn tó jẹ́ ọlọ́pọlọ pípé, tí kì í sì í fọ̀rọ̀ bò ló wà láwùjọ wa. Òǹkọ̀wé Brian McNair sọ pé: “Bí àwọn èèyàn tó wà láwùjọ kan ò bá rí ohun tó burú nínú wíwo ìran bí ìbálòpọ̀ ṣe ń wáyé láàárín àwọn àgbàlagbà méjì tó jọ fohùn ṣọ̀kan, yóò rọrùn fún irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ láti gbà pé kò sóhun tó burú nínú ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ àti èrò pé àwọn obìnrin bá àwọn ọkùnrin dọ́gba, nípa bẹ́ẹ̀ wọ́n lè máa bá ara wọn gbé bíi lọ́kọ láya.”
Ǹjẹ́ bi èrò àwọn èèyàn tó wà láwùjọ ò ṣe dọ́gba lórí ọ̀ràn wíwo ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè fi hàn pé ó bójú mu? Kí ló dé tí àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè fi wọ́pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ṣé lóòótọ́ ni wíwo ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè léwu? Àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò jíròrò àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ tá a lò padà.