Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìpalára Tí Ohun Arùfẹ́-Ìṣekúṣe-Sókè Ń Ṣe

Ìpalára Tí Ohun Arùfẹ́-Ìṣekúṣe-Sókè Ń Ṣe

Ìpalára Tí Ohun Arùfẹ́-Ìṣekúṣe-Sókè Ń Ṣe

Ó RỌRÙN láti rí onírúurú eré tó jẹ mọ́ ìbálòpọ̀ wò lórí tẹlifíṣọ̀n, nínú sinimá, nínú fídíò orin, àti lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ǹjẹ́ lóòótọ́ ni àwọn eré ìbálòpọ̀ tó ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè, èyí tó pọ̀ yamùrá yìí, jẹ́ ohun tí kò lè pani lára, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ èèyàn á ṣe fẹ́ ká gbà gbọ́?

Ipa Tí Ohun Arùfẹ́-Ìṣekúṣe-Sókè Ń Ní Lórí Àwọn Àgbàlagbà

Láìka ohun tí àwọn alágbàwí ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè lè máa sọ sí, ipa búburú ni àṣà yìí ń ní lórí irú ojú táwọn èèyàn fi ń wo ìbálòpọ̀. Àwọn olùṣèwádìí fún Àjọ Tó Ń Ṣèwádìí Tó sì Ń Pèsè Ìsọfúnni Nípa Ìdílé Nílẹ̀ Amẹ́ríkà sọ pé “wíwo ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè máa ń sún àwọn tó ń wò ó láti bẹ̀rẹ̀ sí ní èrò tí kò bójú mu nípa ìbálòpọ̀.” Gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ṣèwádìí náà ṣe sọ, “ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin tó máa ń wo ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè déédéé ló ní èrò tí kò tọ̀nà nípa ìfipábáni-lòpọ̀ (ìyẹn ni ríronú pé àwọn obìnrin ló ń fa ìfipábáni-lòpọ̀, wọ́n sì máa ń gbádùn rẹ̀, àti pé kò sóhun tó ṣe ọpọlọ wọn).”

Àwọn olùṣèwádìí kan sọ pé, wíwo ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè ní àwòtúnwò lè ṣàkóbá fún ọ̀nà tí àwọn tọkọtaya ń gbà ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ara wọn. Ọ̀mọ̀wé Victor Cline, tó jẹ́ ògbógi nínú ìtọ́jú àwọn tó ti sọ ìbálòpọ̀ di bárakú, ṣàkíyèsí pé, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ti máa ń wo ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè ní àwòtúnwò ṣáá. Béèyàn ò bá tètè mójú tó o, wíwo ìṣekúṣe díẹ̀díẹ̀ lè yọrí sí wíwo ìwà pálapàla tó burú jáì, tó sì lòdì gbáà. Ó sọ pé èyí lè sún irú ẹni bẹ́ẹ̀ sí níní ìbálòpọ̀ tí kò bójú mu. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó ń ṣèwádìí nípa ìhùwàsí èèyàn náà gbà bẹ́ẹ̀. Ọ̀mọ̀wé Cline sọ pé “ọ̀nà yìí lèèyàn fi lè gbà máa ní èyíkéyìí lára àwọn ìbálòpọ̀ tí kò bójú mu . . . kò sì sí bí ẹ̀rí ọkàn ṣe lè máa dáni lẹ́bi tó tó máa múni fi irú ìwà bẹ́ẹ̀ sílẹ̀.” Bí àkókò ti ń lọ, oníwòkuwò náà á fẹ́ fi gbogbo ìwà pálapàla tó ń rí dánra wò, èyí sì sábà máa ń mú àwọn àbájáde bíburú jáì wá.

Ọ̀mọ̀wé Cline wá kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa sísọ pé, ìṣòro yìí lè bẹ̀rẹ̀ díẹ̀díẹ̀, kó sì máa nípa lórí onítọ̀hún láìfura. Ó ní: “Bíi ti àrùn jẹjẹrẹ, ńṣe ni yóò túbọ̀ máa di ńlá sí i lára onítọ̀hún. Ìṣòro náà kì í sábà fi onítọ̀hún sílẹ̀, ó sì máa ń ṣòro láti mú kúrò. Gẹ́gẹ́ bó ṣe sábà máa ń ṣẹlẹ̀, ńṣe làwọn ọkùnrin tó ti sọ àṣà yìí di bárakú máa ń sẹ́, wọn kì í sì wá nǹkan ṣe sí ìṣòro náà. Lọ́pọ̀ ìgbà, èyí lè dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀ láàárín tọkọtaya, ó lè yọrí sí ìkọ̀sílẹ̀, tàbí kí àjọṣe téèyàn ní pẹ̀lú àwọn ẹni ọ̀wọ́n mìíràn bà jẹ́.”

Ìpalára Tó Ń Ṣe fún Àwọn Ọ̀dọ́

Ọ̀pọ̀ ìwádìí ló fi hàn pé àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún méjìlá sí mẹ́tàdínlógún ló sábà máa ń wo ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè jù. Àní, inú àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè ni èyí tó pọ̀ jù nínú wọn ti ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa ìbálòpọ̀. Èyí sì máa ń ní àbájáde bíburú jáì. Ìròyìn kan sọ pé: “Wọn kì í ṣàfihàn àwọn ọ̀dọ́ tó lóyún tàbí àwọn àrùn téèyàn ń kó nípasẹ̀ ìbálòpọ̀, irú bí àrùn éèdì, nínú àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè, èyí sì máa ń gbin èrò tí kò tọ̀nà sọ́kàn àwọn ọ̀dọ́ pé kò sí àbájáde búburú kankan tó máa tìdí wíwo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè jáde.”

Àwọn olùṣèwádìí kan sọ pé, wíwo ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè tún lè ṣàkóbá fún ìdàgbàsókè ọpọlọ àwọn ọmọdé. Ọ̀mọ̀wé Judith Reisman, tó jẹ́ olùdarí Ilé Ẹ̀kọ́ Nípa Iṣẹ́ Ìròyìn, sọ pé: “Àwọn àyẹ̀wò nípa bí ọpọlọ ṣe máa ń yára ṣiṣẹ́ lórí ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè téèyàn fojú rí tàbí fetí gbọ́ fi hàn pé wíwo irú àwọn ohun bẹ́ẹ̀ máa ń yí bí ọpọlọ ṣe máa ń ṣiṣẹ́ padà, kò sì ní jẹ́ kó ṣeé ṣe fún onítọ̀hún láti lo làákàyè rẹ̀ dáadáa. Ó lè ṣèpalára fún ọpọlọ tó tètè ń gba nǹkan sínú tí àwọn ọmọdé ní, kò sì ní jẹ́ kí wọ́n lè fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó jẹ́ gidi àti èyí tí kì í ṣe gidi, tí èyí á sì wá tipa bẹ́ẹ̀ ṣèpalára fún ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ronú, ìlera wọn, àti bí wọ́n á ṣe láyọ̀ sí.”

Ipa Tó Ń Ní Lórí Àjọṣe Ẹni Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíràn

Àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè máa ń nípa lórí ìhùwàsí ẹni. Lájorí ohun tó jẹ́ kó máa fani mọ́ra ni pé, ohun tí kì í ṣòótọ́ lèèyàn á máa wò, àmọ́ wọ́n máa ń ṣe é lọ́nà tí á fi dà bí ẹni pé ó gbádùn mọ́ni ju ìbálòpọ̀ tó bójú mu lọ. (Wo àpótí náà “Èwo Lo Gbà Pé Ó Jóòótọ́?”) Ìròyìn kan sọ pé: “Àwọn tó máa ń wo ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè máa ń dáwọ́ lé ohun tí kò lè ṣeé ṣe láé, èyí sì lè yọrí sí bíba àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn jẹ́.”

Wíwo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè kò ní jẹ́ kí ìgbọ́kànlé àti ìfọkàntánni wà nínú ìgbéyàwó, àwọn ànímọ́ méjì yìí sì ṣe kókó. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìkọ̀kọ̀ ni wọ́n ti sábà máa ń wò ó, ẹ̀tàn àti irọ́ pípa ni wíwo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè máa ń yọrí sí lọ́pọ̀ ìgbà. Ọkọ tàbí aya irú ẹni bẹ́ẹ̀ á máa wò ó pé ó ń da òun. Kò sì ní lóye ìdí tí òun ò fi dáa mọ́ lójú rẹ̀.

Ìpalára Tẹ̀mí

Àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè máa ń fa ìpalára tẹ̀mí tó burú jáì. Ó lè di ohun ìdènà gidi fún ẹnì kan tó fẹ́ ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run. a Bíbélì pe ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo ní ojúkòkòrò àti ìbọ̀rìṣà. (Kólósè 3:5) Ẹni tó bá ń ṣe ojúkòkòrò nǹkan máa ń nífẹ̀ẹ́ sí i débi pé á di ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ̀, ohun náà á gbà á lọ́kàn ju gbogbo nǹkan mìíràn lọ. Ká sòótọ́, ńṣe làwọn tí wíwo ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè ti di bárakú fún ka ìfẹ́ fún ìbálòpọ̀ sí ohun tó ṣe pàtàkì ju Ọlọ́run lọ. Wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ ọ́ di òrìṣà. Àṣẹ tí Jèhófà Ọlọ́run pa ni pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ní àwọn ọlọ́run èyíkéyìí mìíràn níṣojú mi.”—Ẹ́kísódù 20:3.

Àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè máa ń ba àjọṣe onífẹ̀ẹ́ jẹ́. Àpọ́sítélì Pétérù, tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́ ọkùnrin tó ti ṣègbéyàwó, rọ àwọn ọkọ tó jẹ́ Kristẹni láti máa fi ọlá fún àwọn aya wọn. Ọkọ tó bá kùnà láti ṣe bẹ́ẹ̀ á rí i pé àdúrà òun sí Ọlọ́run á ní ìdènà. (1 Pétérù 3:7) Ǹjẹ́ kí ọkùnrin kan wà ní ìkọ̀kọ̀ kó sì máa wo àwọn obìnrin tó wà níhòòhò á fi hàn pé irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ ní ọ̀wọ̀ fún aya rẹ̀? Báwo ni ọ̀rọ̀ náà ṣe máa rí lára ìyàwó rẹ̀ bó bá mọ̀ pé ọkọ òun ń wo ìwòkuwò? Síwájú sí i, ojú wo ni Ọlọ́run, ẹni tí yóò mú “gbogbo onírúurú iṣẹ́ wá sínú ìdájọ́,” tó sì tún ń “díwọ̀n àwọn ẹ̀mí” yóò fi wo irú ẹni bẹ́ẹ̀? (Oníwàásù 12:14; Òwe 16:2) Ǹjẹ́ ẹni tó ń wo ìwòkuwò lè retí láé pé kí Ọlọ́run fetí sí àdúrà òun?

Títẹ́ ìfẹ́ ọkàn ẹni lọ́rùn lọ́nàkọnà jẹ́ ìdí pàtàkì kan tí àwọn èèyàn fi máa ń wo ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè. Nípa bẹ́ẹ̀, wíwo ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè kò fi ìfẹ́ hàn rárá. Ó máa ń bẹ́gi dínà ìsapá Kristẹni kan láti jẹ́ oníwà mímọ́ lójú Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, . . . . pé kí ẹ ta kété sí àgbèrè; pé kí olúkúlùkù yín mọ bí yóò ti ṣèkáwọ́ ohun èlò tirẹ̀ nínú ìsọdimímọ́ àti ọlá, kì í ṣe nínú ìdálọ́rùn olójúkòkòrò fún ìbálòpọ̀ takọtabo . . . , pé kí ẹnì kankan má ṣe lọ títí dé àyè ṣíṣe ìpalára fún àti rírakakalé àwọn ẹ̀tọ́ arákùnrin rẹ̀.”—1 Tẹsalóníkà 4:3-7.

Àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé ló sábà máa ń forí fá àwọn àbájáde búburú tí àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè máa ń ní. Ó máa ń fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan, ó máa ń fi ẹ̀tọ́ wọn dù wọ́n, kì í sì í buyì kún wọn. Ẹni tó bá ń wo ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè ń lọ́wọ́ nínú lílo àwọn ẹlòmíràn ní ìlòkulò bẹ́ẹ̀, ó sì ń ṣètìlẹyìn fún ìwà ìbàjẹ́ náà. Steven Hill àti Nina Silver, tí wọ́n jẹ́ olùṣèwádìí, ṣàlàyé pé: “Láìka bí ọkùnrin kan ṣe lè rò pé òún jẹ́ ọmọlúwàbí tó, bó ṣe ń dọ́gbọ́n dá ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè láre nínú ọkàn rẹ̀ yóò nípa lórí rẹ̀ lọ́nà kan tàbí òmíràn, torí pé ó lè di ẹni tí kì í gba tẹni rò mọ́ tàbí kó di ẹni tó kórìíra àwọn obìnrin, ìyẹn àwọn ẹni tó ń sọ lẹ́nu pé òún bìkítà fún.”

Bí Ẹni Tí Ìṣòro Náà Ti Di Bárakú fún Ṣe Lè Ja Àjàbọ́

Bó o bá ń tiraka lọ́wọ́lọ́wọ́ láti ja àjàbọ́ lọ́wọ́ ìṣòro wíwo ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè tó ti di bárakú, ǹjẹ́ ohunkóhun wà tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́? Bíbélì pèsè ìrètí o! Ṣáájú kí àwọn kan lára àwọn Kristẹni ìjímìjí tó mọ Kristi, wọ́n ti jẹ́ alágbèrè, panṣágà, àti oníwọra rí. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ṣùgbọ́n a ti wẹ̀ yín mọ́.” Báwo ni ìyẹn ṣe ṣeé ṣe? Ó dáhùn pé: “A ti sọ yín di mímọ́ . . . pẹ̀lú ẹ̀mí Ọlọ́run wa.”—1 Kọ́ríńtì 6:9-11.

Má ṣe fojú kéré agbára tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ní. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra.” Láìsí àní-àní, òun yóò pèsè ọ̀nà àbáyọ fún ọ. (1 Kọ́ríńtì 10:13) Gbígbàdúrà àtọkànwá—ìyẹn ni sísọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ fún Ọlọ́run lemọ́lemọ́—yóò ràn ọ́ lọ́wọ́. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọ̀ wá pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.”—Sáàmù 55:22.

Àmọ́ o, o gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ lórí ohun tó ò ń gbàdúrà fún. O ní láti dìídì ṣe ìpinnu àtọkànwá, láti yàgò fún àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè. Ọ̀rẹ́ kan tó o fọkàn tán tàbí ẹnì kan nínú ìdílé rẹ lè ṣèrànwọ́ gan-an nípa pípèsè ìtìlẹyìn àti ìṣírí tó o nílò láti rọ̀ mọ́ ìpinnu rẹ. (Wo àpótí náà “Rírí Ìrànlọ́wọ́ Gbà.”) Rírántí pé gbígbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ yóò mú inú Ọlọ́run dùn lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rọ̀ mọ́ ìpinnu rẹ. (Òwe 27:11) Láfikún sí i, mímọ̀ pé wíwo ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú tún lè ràn ọ́ lọ́wọ́ síwájú sí i láti jáwọ́ nínú rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 6:5, 6) Kò ní rọrùn o, àmọ́ ohun téèyàn lè borí ni. Dájúdájú, àwọn tí wíwo ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè ti di bárakú fún lè jáwọ́ nínú rẹ̀!

Ewu kékeré kọ́ ló wà nínú wíwo ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè. Àṣà yìí lè ba tèèyàn jẹ́. Ó ń sọ àwọn tó ń ṣe é jáde àtàwọn tó ń wò ó dìdàkudà. Ó ń fàbùkù kan àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin, ewu ló jẹ́ fún àwọn ọmọdé, àṣà téèyàn sì gbọ́dọ̀ yẹra fún ni.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àlàyé síwájú sí i nípa ojú ìwòye Bíbélì nípa àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè, jọ̀wọ́ wo ìtẹ̀jáde Jí! ti July 8, 2002, ojú ìwé 25-27.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Rírí Ìrànlọ́wọ́ Gbà

A kò gbọ́dọ̀ fojú kéré ìsapá láti ja àjàbọ́ lọ́wọ́ wíwo ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè; ìsapá yìí lè nira láti ṣe. Ọ̀mọ̀wé Victor Cline, ẹni tó ti tọ́jú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó ti sọ ìbálòpọ̀ di bárakú, sọ pé: “Ṣíṣe ìlérí pé wàá jáwọ́ nìkan kò tó. Wíwulẹ̀ ní èrò tó dáa lọ́kàn kò lè ṣèrànlọ́wọ́ kankan. [Ẹni tó ti sọ ìbálòpọ̀ di bárakú] kò lè jáwọ́ fúnra rẹ̀.” Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọ̀mọ̀wé Cline, kí ìtọ́jú náà lè kẹ́sẹ járí, ohun tó dára kó ṣáájú ni pé kí ìyàwó onítọ̀hún náà kópa nínú rẹ̀, bó bá ti ṣègbéyàwó. Ó sọ pé: “Ìtọ́jú náà á gbéṣẹ́ á sì yá kánkán bí àwọn méjèèjì bá jọ kópa nínú rẹ̀. Àwọn méjèèjì ni ìṣòro náà ń bá fínra. Nítorí náà, àwọn méjèèjì ló nílò ìrànlọ́wọ́.”

Bí ẹni náà kò bá tíì ṣègbéyàwó, ọ̀rẹ́ kan tó fọkàn tán tàbí ẹnì kan nínú ìdílé rẹ̀ lè ṣèrànlọ́wọ́ ńláǹlà fún un. Láìka irú ẹni tó ń gba ìtọ́jú náà sí, Ọ̀mọ̀wé Cline máa ń sọ kókó kan tí kò sí irọ́ níbẹ̀ rárá, ìyẹn ni pé: Sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ láìfọ̀rọ̀ pa mọ́, kó o sì máa sọ̀rọ̀ jáde nígbàkigbà tí ìṣòro náà bá tún padà wá. Ó sọ pé: “Fífi ìṣòro náà bò lè ‘ba tìẹ jẹ́’. Èyí máa ń fa ìtìjú àti kí ẹ̀rí ọkàn máa dáni lẹ́bi.”

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 9]

Èwo Lo Gbà Pé Ó Jóòótọ́?

Ohun Tí Ohun Arùfẹ́- Ohun Tí Bíbélì Fi Ń Kọ́ni

Ìṣekúṣe-Sókè Fi Ń Kọ́ni

◼ Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn ◼ “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín

ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni, gbogbo ènìyàn, kí ibùsùn

nígbàkigbà, níbikíbi, àti ní ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin,

ọ̀nàkọnà tó bá ti wuni, àṣà nítorí Ọlọ́run yóò dá àwọn

yìí kò sì ní àbájáde bíburú àgbèrè àti àwọn panṣágà lẹ́jọ́.”

jáì kankan. ​—Hébérù 13:4.

 

“Ẹni tí ó bá ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀

sí ara òun fúnra rẹ̀.”

​—1 Kọ́ríńtì 6:18; tún wo

Róòmù 1:26, 27.

◼ Ìgbéyàwó máa ń dí èèyàn ◼ “Máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ

lọ́wọ́ láti gbádùn ìbálòpọ̀ . . . Kí o máa yọ ayọ̀ púpọ̀ jọjọ

bó ṣe yẹ. nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbà gbogbo.”

​—Òwe 5:18, 19; tún wo

Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:24;

1 Kọ́ríńtì 7:3.

◼ Ohun kan ṣoṣo táwọn obìnrin ◼ “Èmi [Jèhófà Ọlọ́run] yóò ṣe

wà fún ò ju pé kí wọ́n máa fi olùrànlọ́wọ́ kan fún un, gẹ́gẹ́

ìbálòpọ̀ tẹ́ àwọn ọkùnrin lọ́rùn. bí àṣekún rẹ̀.”

​—Jẹ́nẹ́sísì 2:18; tún wo

Éfésù 5:28.

◼ Kò ṣeé ṣe rárá àti rárá fún ◼ “Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà

àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé

láti kápá ìfẹ́ wọn fún ìbálòpọ̀. di òkú ní ti àgbèrè, ìwà

àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀

takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni

lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe

ìbọ̀rìṣà.”​—Kólósè 3:5.

 

“Kí olúkúlùkù yín mọ bí yóò

ti ṣèkáwọ́ ohun èlò tirẹ̀ nínú

ìsọdimímọ́ àti ọlá.”

​—1 Tẹsalóníkà 4:4.

 

Pàrọwà fún “àwọn àgbà

obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìyá, àwọn

ọ̀dọ́bìnrin gẹ́gẹ́ bí arábìnrin

pẹ̀lú gbogbo ìwà mímọ́.”

​—1 Tímótì 5:1, 2; tún wo

1 Kọ́ríńtì 9:27.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn olùṣèwádìí kan sọ pé wíwo ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè lè ṣàkóbá fún ìdàgbàsókè ọpọlọ àwọn ọmọdé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Wíwo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè kò ní jẹ́ kí ìgbọ́kànlé àti ìfọkàntánni wà nínú ìgbéyàwó

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Gbígbàdúrà àtọkànwá yóò ràn ọ́ lọ́wọ́