Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tí Àwọn Ohun Arùfẹ́-Ìṣekúṣe-Sókè Fi Gbilẹ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?

Kí Nìdí Tí Àwọn Ohun Arùfẹ́-Ìṣekúṣe-Sókè Fi Gbilẹ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?

Kí Nìdí Tí Àwọn Ohun Arùfẹ́-Ìṣekúṣe-Sókè Fi Gbilẹ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?

Ó TI lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ọdún tí àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè ti wà. Ṣùgbọ́n, ní èyí tó pọ̀ jù lọ nínú gbogbo àkókò tí wọ́n fi wà yìí, ó ṣòro láti ṣe wọn jáde, nípa bẹ́ẹ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ àtàwọn alákòóso ló sábà máa ń ní i lọ́wọ́. Àmọ́ ṣá o, ìwé títẹ̀ lọ́pọ̀ yanturu àti ayé ọ̀làjú tó jẹ́ kí fọ́tò yíyà àti sinimá di ohun tí tọmọdé tàgbà mọ̀, túbọ̀ wá jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn láti máa wò ó. Àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè wá di ohun tí àwọn tálákà lè ní níkàáwọ́, torí pé owó pọ́ọ́kú ni wọ́n ń tà wọ́n.

Ohun tó wá mú kí àṣà yìí túbọ̀ tàn kálẹ̀ ni ìmújáde ẹ̀rọ tó ń lo kásẹ́ẹ̀tì fídíò. Kásẹ́ẹ̀tì fídíò kò dà bí àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n ń lò fún sinimá tàbí àwọn fọ́tò tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ tó máa ń bà jẹ́ tó bá yá, nítorí pé òún rọrùn láti fi pa mọ́, kò ṣòro láti ṣe ẹ̀dà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò nira láti pín in kiri. Ó tún ṣeé ṣe fún ẹnikẹ́ni láti wò ó nílé. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, bí àwọn iléeṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n tó ń ta àtagbà ìsọfúnni fún àwọn oníbàárà ṣe ń pọ̀ rẹ́kẹrẹ̀kẹ àti bí Íńtánẹ́ẹ̀tì ṣe túbọ̀ ń gbajúmọ̀ sí i ti mú kó rọrùn gan-an fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti máa wo àwọn eré tó ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè. Lóde òní, ẹni tó bá fẹ́ràn wíwo àwọn eré tó ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè, àmọ́ tó ń bẹ̀rù pé aládùúgbò òun kan lè lọ rí òun níbi tí wọ́n ti ń ta àwọn fídíò oníṣekúṣe lè “jókòó sínú ilé rẹ̀ kó sì ta iléeṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n kan lólobó pé kí wọ́n fi eré ìbálòpọ̀ tóun nífẹ̀ẹ́ sí hàn lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí kó yan fídíò oníṣekúṣe tó bá fẹ́ láti iléeṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n mìíràn,” gẹ́gẹ́ bí ohun tí oníròyìn kan tó ń jẹ́ Dennis McAlpine sọ. Ọ̀gbẹ́ni McAlpine sọ pé, rírí irú àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n bẹ́ẹ̀ lárọ̀ọ́wọ́tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó ń mú kí “ọ̀pọ̀ èèyàn túbọ̀ máa wo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè bí ohun tí kò burú.”

Àwọn Ohun Arùfẹ́-Ìṣekúṣe-Sókè Ti Di Ohun Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Tẹ́wọ́ Gbà

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣiyèméjì nípa àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè torí pé tọmọdé tàgbà ló ń wò wọ́n lóde òní. Òǹkọ̀wé Germaine Greer sọ pé: “Ipa tó ń ní lórí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wa ju èyí tí ijó, orin, ìlù lílù, sinimá àti iṣẹ́ ọnà ń ní lọ, tá a bá pa gbogbo wọn pọ̀.” Èrò àwọn èèyàn òde òní nípa àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè tún ń fara hàn nínú irú ‘aṣọ aṣẹ́wó’ tí ọ̀pọ̀ àwọn gbajúgbajà òṣèré máa ń wọ̀, nínú onírúurú fídíò orin tó ń gbé ìbálòpọ̀ lárugẹ, àti nínú bí àwọn iléeṣẹ́ tó ń polówó ọjà ṣe ń lo “àwọn àwòrán tó ń gbé ìwà pálapàla lárugẹ láti polówó ọjà.” Ọ̀gbẹ́ni McAlpine wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ohunkóhun táwọn èèyàn bá ṣáà ti rí ni wọ́n ń tẹ́wọ́ gbà láìronú jinlẹ̀. . . . Èyí ló ń jẹ́ kí àwọn èèyàn máa ronú pé kò sóhun tó burú nínú wíwo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè.” Látàrí èrò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní yìí, òǹkọ̀wé Andrea Dworkin kédàárò pé, “kò jọ pé ohun tí àwọn èèyàn ń wò ń rí wọn lára. Kò jọ pé wọ́n kà á sí rárá.”

Ìdí Táwọn Èèyàn Fi Ń Wo Àwọn Ohun Arùfẹ́-Ìṣekúṣe-Sókè

Nígbà tí Roger Young, tó jẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ kan tó ti fẹ̀yìn tì ní Iléeṣẹ́ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ Amẹ́ríkà, ń ṣàtúnsọ ọ̀rọ̀ òǹṣèwé Dworkin, ó ní ọ̀pọ̀ èèyàn “kò mọ àwọn àbájáde bíburú jáì tí ìwà ìbàjẹ́ máa ń ní àtàwọn ìṣòro tó ń fà.” Àwọn tó jẹ́ alágbàwí ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè ló máa ń ti àwọn kan láti máa wò ó, torí wọ́n máa ń sọ pé kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé àwọn àwòrán ìṣekúṣe lè ní ipa búburú lórí àwọn èèyàn. Òǹṣèwé F. M. Christensen sọ pé: “Ohun téèyàn ń fojú rí lásán ni ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè jẹ́, àmọ́ kókó yìí kò yé àwọn tó ń bẹnu àtẹ lù ú.” Ṣùgbọ́n o, bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni ohun téèyàn ń fojú rí kì í nípa lórí ẹni, nígbà náà, kí nìdí táwọn iléeṣẹ́ tó ń polówó ọjà fi máa ń gbé ohun tó fani mọ́ra jáde? Kí nìdí táwọn oníṣòwò fi ń ná ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù dọ́là láti fi ṣe ìpolówó ọjà lórí tẹlifíṣọ̀n àti rédíò, àti láti fi ṣe àwọn fídíò àtàwọn bébà jáde fún ìpolówó ọjà bó bá jẹ́ pé kò ní nípa kan lọ títí lórí àwọn èèyàn?

Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, bíi ti gbogbo àwọn nǹkan gbígbajúmọ̀ mìíràn tí wọ́n ń polówó, ìdí pàtàkì tí wọ́n fi ń polówó ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè ni láti mú káwọn èèyàn tí kò mọ̀ nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀ máa yán hànhàn fún ohun tí kò tọ́. Àwọn olùṣèwádìí méjì kan tí orúkọ wọn ń jẹ́ Steven Hill àti Nina Silver sọ pé: “Ká má fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, kò sóhun méjì tó ń sún wọn láti mú ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè jáde bí kò ṣe owó. Bákan náà, nínú ètò ìṣòwò òde òní tí kò ní àbójútó, ohunkóhun tó bá ti lè mú èrè gọbọi wá làwọn èèyàn ń tà, pàápàá àwòrán ara obìnrin àti àwòrán tó ń fi ìbálòpọ̀ hàn.” Òǹkọ̀wé Greer fi ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè wé àwọn oúnjẹ pàrùpárù tí kò ní èròjà aṣaralóore nínú, tí wọ́n sì ti po àwọn èròjà atasánsán mọ́ kó lè máa wu èèyàn jẹ. Ó sọ pé: “Ìbálòpọ̀ téèyàn ń rí nínú ìpolówó kì í ṣe ìbálòpọ̀ tó bójú mu . . . Ìpolówó oúnjẹ pàrùpárù máa ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa jẹ oúnjẹ pàrùpárù, lọ́nà kan náà, pípolówó ìṣekúṣe máa ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ní ìbálòpọ̀ tí kò bójú mu.”

Àwọn dókítà kan sọ pé, wíwo ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè lè di bárakú fún èèyàn débi pé yóò ṣòro láti kápá rẹ̀ ju béèyàn á ṣe kápá oògùn olóró tó ti di bárakú lọ. Ìtọ́jú táwọn tó ti sọ oògùn olóró di bárakú máa ń gbà sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú mímú kí àwọn èròjà olóró tó ti wà nínú ara wọn kọ́kọ́ kúrò ná. Àmọ́ o, gẹ́gẹ́ bí àlàyé tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Mary Anne Layden, tó ń ṣiṣẹ́ ní Yunifásítì Pennsylvania ṣe, ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè “máa ń fi àwòrán tó máa wà lọ́kàn ẹni títí ayé sínú ọpọlọ ẹni tó ń wò ó, èyí á sì di ohun tí yóò máa rántí títí láé.” Ìdí nìyẹn tí àwọn èèyàn tó ń wò ó fi lè máa rántí ìwà pálapàla tí wọ́n ti wò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn bí ẹni pé wọ́n ń wò ó lọ́wọ́lọ́wọ́. Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Èyí ni ohun àkọ́kọ́ tó ń di bárakú fún èèyàn tó jẹ́ pé kò sí ìrètí pé ó lè kúrò nínú ọpọlọ ẹni náà pátápátá.” Àmọ́, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé kò ṣeé ṣe láti jáwọ́ nínú wíwo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè ni? Síwájú sí i, ìpalára wo ní pàtó ni ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè lè ṣe?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

Ìsọfúnni Nípa Àwọn Ohun Arùfẹ́-Ìṣekúṣe-Sókè Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì

◼ Nǹkan bí ìdá márùndínlọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni wọ́n ń mú jáde ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nǹkan bí ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni wọ́n ń mú jáde ní ilẹ̀ Yúróòpù.

◼ Wọ́n fojú díwọ̀n rẹ̀ pé àwọn èèyàn tó tó àádọ́rin mílíọ̀nù ló máa ń wo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Nǹkan bí ogún mílíọ̀nù lára àwọn wọ̀nyí ló wà ní orílẹ̀-èdè Kánádà àti Amẹ́ríkà.

◼ Ìwádìí kan fi hàn pé nínú oṣù kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ilẹ̀ Jámánì ni àwọn tó ń wo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tíì pọ̀ sí jù lọ ní gbogbo ilẹ̀ Yúróòpù, àwọn orílẹ̀-èdè tó sì tẹ̀ lé e ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ilẹ̀ Faransé, Ítálì àti Sípéènì.

◼ Ní ilẹ̀ Jámánì, àwọn tó ń wo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì sábà máa ń lo nǹkan bíi wákàtí kan àti ìṣẹ́jú mẹ́wàá lóṣooṣù nídìí ìwòkuwò.

◼ Ní ilẹ̀ Yúróòpù, àwọn tó ti lé ní ọmọ àádọ́ta ọdún ló ń lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí ìwòkuwò.

◼ Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn kan ti sọ, ìdá àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó ń wo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ló jẹ́ pé ọwọ́ ọ̀sán ni wọ́n máa ń wò ó.

◼ Wọ́n fojú díwọ̀n rẹ̀ pé, ibi táwọn èèyàn ti lè rí àwòrán bí wọ́n ṣe ń lo àwọn ọmọdé fún ìṣekúṣe lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000].

◼ Nǹkan bí ìdá ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwòrán nípa bí wọ́n ṣe ń lo àwọn ọmọdé fún ìṣekúṣe ni wọ́n ń mú jáde fún títà ní orílẹ̀-èdè Japan.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó báyìí ju ti ìgbàkigbà rí lọ