Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ó Tọ́ Láti Kórìíra Ẹ̀yà Mìíràn?

Ǹjẹ́ Ó Tọ́ Láti Kórìíra Ẹ̀yà Mìíràn?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ǹjẹ́ Ó Tọ́ Láti Kórìíra Ẹ̀yà Mìíràn?

BÁWO ló ṣe máa rí lára rẹ bí àwọn kan bá ń fojú èèyànkéèyàn, oníwà ipá, òpònú, tàbí oníṣekúṣe wò ọ́, kìkì nítorí pé o wá látinú ẹ̀yà kan pàtó? a Ó dájú pé inú rẹ kò ní dùn sírú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ó bani nínú jẹ́ pé, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn nìyẹn. Síwájú sí i, látìgbà ìwáṣẹ̀, àìlóǹkà àwọn èèyàn tó jẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀ làwọn kan ti hùwà ìkà sí, àní tí wọ́n tiẹ̀ pa àwọn mìíràn pàápàá, kìkì nítorí pé ẹ̀yà tàbí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá yàtọ̀. Ká sòótọ́, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ogun tó ń fẹ̀mí àwọn èèyàn ṣòfò lónìí ló jẹ́ pé ìkórìíra láàárín ẹ̀yà ló ń fà á. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó fara mọ́ irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀ máa ń sọ pé àwọ́n gba Ọlọ́run gbọ́ àwọ́n sì tún gba Bíbélì gbọ́. Àwọn kan sì wà tí wọ́n máa ń sọ pé ẹ̀tanú ẹ̀yà ò lè kásẹ̀ nílẹ̀ láé—pé àdámọ́ èèyàn ni.

Ǹjẹ́ Bíbélì tiẹ̀ fàyè gba kíkórìíra ẹ̀yà mìíràn? Ǹjẹ́ àwọn ipò kan wà tó lè mú kí kíkórìíra àwọn èèyàn tí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn tàbí ẹ̀yà wọn yàtọ̀ jẹ́ ohun tó tọ̀nà? Ǹjẹ́ ìrètí kankan tiẹ̀ wà pé ìgbà kan ń bọ̀ tí kò ní sí ìkórìíra ẹ̀yà mọ́? Kí ni ojú ìwòye Bíbélì?

Ìwà Wọn Ni Ọlọ́run Fi Dá Wọn Lẹ́jọ́

Bó bá jẹ́ lóréfèé lèèyàn kàn ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà bá aráyé lò nígbà ìjímìjí, èyí lè ṣini lọ́nà, ìyẹn ni pé èèyàn á máa ronú pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ fọwọ́ sí ìkórìíra ẹ̀yà. Ǹjẹ́ àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì kan ò fi hàn pé Ọlọ́run pa odindi àwọn ẹ̀yà kan tàbí orílẹ̀-èdè kan run? Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ tá a bá gbé àwọn àkọsílẹ̀ náà yẹ̀ wò dáadáa, a óò rí i pé ohun tó mú kí Ọlọ́run dẹ́bi fún àwọn èèyàn wọ̀nyí ni pé wọn kò ka òfin rẹ̀ lórí ìwà pálapàla sí, kì í ṣe nítorí irú ẹ̀yà tí wọ́n jẹ́.

Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà Ọlọ́run dẹ́bi fún àwọn ara Kénáánì nítorí àṣà ìbálòpọ̀ wọn bíburú jáì àti rírúbọ tí wọ́n máa ń rúbọ sí àwọn ẹ̀mí èṣù. Kódà, wọ́n tún máa ń sun àwọn ọmọ wọn kéékèèké nínú iná láti fi wọ́n rúbọ sí àwọn ọlọ́run èké! (Diutarónómì 7:5; 18:9-12) Àmọ́, àwọn ará Kénáánì kan wà tí wọ́n fi ìgbàgbọ́ hàn nínú Ọlọ́run tí wọ́n sì ronú pìwà dà. Jèhófà sì torí bẹ́ẹ̀ dá wọn sí, ó sì tún bù kún wọn. (Jóṣúà 9:3, 25-27; Hébérù 11:31) Kódà, obìnrin kan tó jẹ́ ará Kénáánì, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ráhábù, di ìyá ńlá fún Jésù Kristi tí í ṣe Mèsáyà tá a ṣèlérí náà.—Mátíù 1:5.

Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi hàn pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó bìkítà gan-an nípa gbogbo èèyàn. Ní Léfítíkù 19:33, 34, a rí àṣẹ tó fi ìyọ́nú hàn yìí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èyí tó sọ pé: “Bí ó bá . . . ṣẹlẹ̀ pé àtìpó kan ń ṣe àtìpó lọ́dọ̀ rẹ ní ilẹ̀ yín, ẹ kò gbọ́dọ̀ fojú rẹ̀ gbolẹ̀. Kí àtìpó tí ń ṣe àtìpó lọ́dọ̀ yín dà bí ọmọ ìbílẹ̀ yín; kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ, nítorí ẹ di àtìpó ní ilẹ̀ Íjíbítì. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.” Àwọn àṣẹ tó fara jọ èyí tún wà nínú ìwé Ẹ́kísódù àti Diutarónómì. Nígbà náà, ó hàn gbangba pé, Jèhófà kò fọwọ́ sí ìkórìíra ẹ̀yà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó pàṣẹ pé kí àwọn ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wà ní ìrẹ́pọ̀.

Jésù Fẹ́ Ká Ní Àmúmọ́ra fún Àwọn Ẹ̀yà Mìíràn

Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, àwọn Júù àtàwọn ará Samáríà kì í rí ara wọn sójú. Nígbà kan, àwọn èèyàn abúlé kan ní ilẹ̀ Samáríà kọ̀ láti gba Jésù mọ́ra kìkì nítorí pé ó jẹ́ Júù ó sì ń lọ sí Jerúsálẹ́mù. Bó bá jẹ́ ìwọ làwọn kan kọ̀ láti tẹ́wọ́ gbà bẹ́ẹ̀, kí lò bá ṣe? Ó lè jẹ́ ẹ̀tanú tó gbilẹ̀ láyé ìgbà náà làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi hàn nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Olúwa, ṣé ìwọ fẹ́ kí a sọ fún iná kí ó sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, kí ó sì pa wọ́n rẹ́ ráúráú?” (Lúùkù 9:51-56) Ǹjẹ́ Jésù jẹ́ kí ẹ̀mí ẹ̀tanú tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní nípa lórí òun? Rárá o, ńṣe ló bá wọn wí, ó sì rọra wá abúlé mìíràn láti wọ̀ sí. Kò pẹ́ sígbà náà ni Jésù sọ àkàwé ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere. Èyí jẹ́ ká rí i gbangba pé, wíwá tẹ́nì kan wá láti ẹ̀yà kan pàtó kò sọ ọ́ di ọ̀tá wa. Kódà, ó lè jẹ́ ọmọlúwàbí èèyàn!

Onírúurú Ẹ̀yà Ló Wà Nínú Ìjọ Kristẹni

Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé, àwọn tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ̀ ló dìídì darí iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn sí. Àmọ́, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé bí àkókò ti ń lọ, àwọn èèyàn mìíràn náà ṣì máa di ọmọ ẹ̀yìn òun. (Mátíù 28:19) Ǹjẹ́ Ọlọ́run yóò tẹ́wọ́ gba àwọn èèyàn látinú gbogbo ẹ̀yà? Bẹ́ẹ̀ ni! Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Lẹ́yìn àkókò yìí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyí nípa sísọ ọ́ ní kedere pé ibi téèyàn ti ṣẹ̀ wá kò jẹ́ nǹkan kan nínú ìjọ Kristẹni.—Kólósè 3:11.

Ẹ̀rí mìíràn tó tún fi hàn pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba àwọn èèyàn látinú gbogbo ẹ̀yà la rí nínú ìwé Ìṣípayá nínú Bíbélì. Nínú ìran kan tí àpọ́sítélì Jòhánù rí láti ọ̀run, ó rí “ogunlọ́gọ̀ ńlá, . . . láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n,” tí wọ́n rí ìgbàlà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Ìṣípayá 7:9, 10) Àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” yìí ni yóò di ìpìlẹ̀ àwùjọ ẹ̀dá èèyàn tuntun, nínú èyí tí gbogbo èèyàn láti onírúurú ẹ̀yà yóò máa gbé pọ̀ lálàáfíà. Ìfẹ́ wọn fún Ọlọ́run ni yóò sì so wọ́n pọ̀ ṣọ̀kan.

Kí àkókò náà tó dé, ó bọ́gbọ́n mu kí àwọn Kristẹni yẹra fún ṣíṣèdájọ́ àwọn ẹlòmíràn nítorí inú ẹ̀yà tí wọ́n ti wá. Wíwo àwọn èèyàn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe jẹ́ gan-an, ìyẹn wíwò wọ́n lọ́nà tí Ọlọ́run ń gbà wò wọ́n lohun tó tọ́ tó sì fi ìfẹ́ hàn, dípò tí a óò fi máa ṣẹ̀tanú sí wọn nítorí ẹ̀yà wọn. Ǹjẹ́ irú ojú tí wàá fẹ́ káwọn èèyàn máa fi wò ọ́ kọ́ nìyẹn? Ìyẹn gan-an ni ìmọ̀ràn Jésù fún wa nígbà tó sọ pé: “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12) Gbígbé láìsí ìkórìíra ẹ̀yà máa ń mú kí ìgbésí ayé gbádùn mọ́ni gan-an. Ó máa ń jẹ́ kí ọkàn ẹni túbọ̀ balẹ̀, kéèyàn sì túbọ̀ wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ní pàtàkì jù lọ, ó máa ń jẹ́ ká wà nírẹ̀ẹ́pọ̀ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá wa tí kì í ṣe ojúsàájú. Ẹ ò rí i pé ìdí tó lágbára gan-an lèyí jẹ́ láti má ṣe fàyè gba ìkórìíra ẹ̀yà!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a “Ẹ̀yà,” gẹ́gẹ́ bí a ti lò ó nínú àpilẹ̀kọ yìí dúró fún àwọn èèyàn tí wọ́n wá látinú ẹ̀yà kan náà, ìran kan náà, orílẹ̀-èdè kan náà, tàbí tí wọ́n ní àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ kan náà.