Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdáhùn wọn sì wà ní ojú ìwé 28. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)

1. Ilẹ̀ ọba wo ni Kírúsì, Dáríúsì, Ahasuwérúsì, àti Atasásítà, ṣàkóso lé lórí? (Ẹ́sírà 4:5-7)

2. Nígbà tí Jákọ́bù ń ṣàkàwé agbára ńlá tí ahọ́n ní láti darí gbogbo ara ẹnì kan, kí ló fi wé? (Jákọ́bù 3:3, 4)

3. Ta lẹni àkọ́kọ́ tí Bíbélì sọ pé ó kọ́kọ́ lo orúkọ Ọlọ́run? (Jẹ́nẹ́sísì 4:1)

4. Inú ibo ni Bíbélì sọ pé à ń kọ orúkọ àwọn èèyàn tó fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ àti adúróṣinṣin sí Jèhófà sí? (Ìṣípayá 20:12)

5. Ẹranko wo ni àpèjúwe Léfíátánì tó wà nínú ìwé Jóòbù 41:1-34 bá mu jù lọ?

6. Kí ni Ayaba Fáṣítì ṣe tó bí Ọba Ahasuwérúsì nínú, èyí tó mú kí wọ́n yọ ọ́ nípò? (Ẹ́sítérì 1:12, 19)

7. Nínú àwọn ọkùnrin méjìlá tí Mósè rán láti lọ ṣe amí ilẹ̀ Kénáánì, àwọn wo ló mú ìròyìn rere padà wá? (Númérì 14:6-8)

8. Báwo ni àkókò tí a óò fi ti Sátánì mọ́ inú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ á ṣe gùn tó? (Ìṣípayá 20:1-3)

9. Kí ni Èlíjà lò láti fi yan Èlíṣà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò gba ipò rẹ̀? (1 Àwọn Ọba 19:16, 19)

10. Nígbà tí àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í ta ko ọlá àṣẹ Mósè àti Áárónì, báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé Áárónì àti agboolé rẹ̀ lòún yàn láti máa ṣe iṣẹ́ àlùfáà? (Númérì 17:1-11)

11. Ta ni Sọ́ọ̀lù kọ́kọ́ ṣèlérí pé òun máa fi fún Dáfídì láti fi ṣe aya? (1 Sámúẹ́lì 18:17-19)

12. Irú ìdáhùn wo ló máa “ń yí ìhónú padà”? (Òwe 15:1)

13. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ, ta ló sọ pé ọkùnrin kan àti aya rẹ̀ yóò “di ara kan”? (Mátíù 19:4-6)

14. Nígbà tí àwọn Júù fẹ̀sùn kan Pọ́ọ̀lù pé ó ń darí àwọn èèyàn sínú ẹ̀sìn mìíràn láti máa jọ́sìn Ọlọ́run, ta lẹni tó da ẹjọ́ yẹn rú lórí ìpìlẹ̀ pé ìyẹn kì í ṣe rírú òfin Róòmù? (Ìṣe 18:12-16)

15. Nínú àkàwé Jésù nípa ọkùnrin ọlọ́lá tó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀ “láti [lọ] gba agbára ọba,” kí lohun tó fún àwọn ẹrú náà? (Lúùkù 19:12-24)

16. Inú oṣù wo ni Sólómọ́nì parí kíkọ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù? (1 Àwọn Ọba 6:38)

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè

1. Páṣíà

2. Ìtọ́kọ̀ kékeré tí wọ́n fi ń darí ọkọ̀ òkun ńlá

3. Éfà

4. “Àkájọ ìwé ìyè”

5. Ọ̀nì

6. Ó kọ̀ láti fara hàn níwájú ọba

7. Jóṣúà àti Kálébù

8. Ẹgbẹ̀rún ọdún

9. Ẹ̀wù oyè rẹ̀

10. Nínú gbogbo ọ̀pá àwọn aṣáájú ẹ̀yà méjìlá náà, ọ̀pá Áárónì nìkan ló rudi tó sì so èso álímọ́ńdì pípọ́n

11. Mérábù, ọmọbìnrin rẹ̀ tó dàgbà jù

12. Ìdáhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́

13. Ọlọ́run

14. Gálíò, alákòóso ìbílẹ̀ Ákáyà

15. Mínà

16. Búlì, oṣù kẹjọ nínú kàlẹ́ńdà mímọ́