Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Kan Tí Ìjì Kò Lè Gbé Lọ

Ohun Kan Tí Ìjì Kò Lè Gbé Lọ

Ohun Kan Tí Ìjì Kò Lè Gbé Lọ

LÁTỌWỌ́ ÀWỌN AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ JÁMÁNÌ, AUSTRIA, MẸ́SÍKÒ, ÀTI KÒRÍÀ

NÍNÚ ọdún 2002, àjálù wáyé ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè nítorí ipò ojú ọjọ́ tí kò dára. Ní ilẹ̀ Yúróòpù, omíyalé ṣẹlẹ̀ léraléra ó sì fa ọ̀pọ̀ jàǹbá. Láwọn apá ibòmíràn láyé, irú bí ilẹ̀ Mẹ́síkò, ìjì líle ṣẹlẹ̀, ó sì fa àdánù ńlá, bákan náà ni ìjì tó pa pọ̀ mọ́ òjò ńlá kan náà ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Kòríà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ṣe ọṣẹ́ ńláǹlà, ńṣe ni wọ́n túbọ̀ mú kí ìdè ìfẹ́ tó wà láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́ lágbára sí i.

Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé tó wáyé lọ́dún 2002 nílẹ̀ Yúróòpù, wọ́n béèrè lọ́wọ́ olórí ìjọba Ìwọ̀ Oòrùn Jámánì nígbà kan rí, ìyẹn Helmut Schmidt, nípa irú ìrànlọ́wọ́ táwọn tó kàgbákò omíyalé náà nílò. Ó dáhùn pé: “Àwọn èèyàn náà nílò oúnjẹ àti ibùgbé, wọ́n nílò owó díẹ̀ tí wọ́n á lè rí ná, wọ́n sì tún nílò àbójútó nípa tẹ̀mí.” Ipa kékeré kọ́ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó nínú pípèsè ìrànlọ́wọ́ tara àti tẹ̀mí fún àwọn tí ìjì náà ṣàkóbá fún. Gbé iṣẹ́ pípèsè ìrànwọ́ tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè Jámánì, Austria, Mẹ́síkò àti Kòríà yẹ̀ wò.

Àwọn Aṣèrànwọ́ Tó Múra Tán ní Ilẹ̀ Jámánì

Nígbà tó di pé ọ̀pọ̀ èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkíyèsí pé omíyalé ńlá fẹ́ ṣẹlẹ̀, yóò sì ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan jẹ́, ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Jámánì dara pọ̀ mọ́ àwọn aráàlú kí wọ́n bàa lè dènà omíyalé náà. Ọmọbìnrin ọlọ́dún mọ́kàndínlógún kan tó ń jẹ́ Kathleen, tó ń gbé ní ìlú Dresden, sọ pé: “Mi ò lè fọwọ́ lẹ́rán kí n sì máa wòran láìṣe nǹkan kan. Bí mo ṣe gbọ́ pé ó ṣeé ṣe kí àwọn kan pàdánù gbogbo ohun tí wọ́n ní, bẹ́ẹ̀ ni mo gbéra láti lọ ṣèrànwọ́.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí ní ilẹ̀ Jámánì bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò ara wọn láti pèsè ìrànwọ́ lọ́nà tó yá kánkán, èyí tó lè ṣe àwọn èèyàn láǹfààní. Níwọ̀n bí wọ́n ti jẹ́ Kristẹni, wọ́n gbà dájúdájú pé ohun àìgbọdọ̀máṣe ló jẹ́ fáwọn láti ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin àwọn nípa tẹ̀mí lọ́wọ́. Àmọ́, wọ́n tún fìfẹ́ hàn sí àwọn aládùúgbò wọn pẹ̀lú. (Máàkù 12:31) Èyí ló mú kí wọ́n ṣètò àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì sí àwùjọ ẹlẹ́ni mẹ́jọ sí méjìlá, tí wọ́n sì yan àwùjọ kọ̀ọ̀kan láti ṣe iṣẹ́ kan pàtó ní àgbègbè tí àjálù náà ti ṣẹlẹ̀. Ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú Selters, ní orílẹ̀-èdè Jámánì, ọ̀nà mẹ́tàlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ṣètò pé kí ìkésíni lórí tẹlifóònù máa gbà wọlé, láti dáhùn ìbéèrè ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó fẹ́ mọ̀ nípa àjálù náà, tí wọ́n sì fẹ́ láti ṣèrànwọ́.

Ronnie àti Dina jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n máa ń lo àkókò wọn láti ran àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́ láti mọ àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé omíyalé fẹ́ ṣẹlẹ̀, wọ́n kọ́kọ́ lọ sí àárín gbùngbùn ìlú Dresden láti lọ dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn láti dáàbò bo àwọn ilé àtayébáyé tó wà níbẹ̀. Bí omíyalé náà ti lọ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Ronnie àti Dina tún dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tó kù láti rí i pé Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní ìlú Freital, èyí tí omi ẹlẹ́gbin ti rọ́ kúnnú rẹ̀, di mímọ́ tónítóní. Lẹ́yìn náà ni àwùjọ yìí wá bẹ̀rẹ̀ sí ran àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́. Ẹni tó ni ilé àrójẹ kan tó dojú kọ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà mí kanlẹ̀, inú rẹ̀ sì dùn, nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí bá a palẹ̀ àwọn àwókù àti ẹrẹ̀ mọ́ kúrò nínú yàrá àjàalẹ̀ àti àjà kìíní tó ń lò.

Abúlé kan tó ń jẹ́ Colmnitz, tó wà ní nǹkan bí ogójì kìlómítà sí gúúsù ìlà oòrùn ìlú Dresden ni Siegfried àti Hannelore ń gbé. Odò kékeré kan tó rọra máa ń ṣàn kọjá láàárín abúlé náà tẹ́lẹ̀ di ńlá, ó sì ya bo ilé wọn àti ọgbà wọn. Nígbà tí omi náà lọ sílẹ̀, ẹnu ya àwọn aládùúgbò láti rí i tí nǹkan bí ọgbọ̀n àwọn Ẹlẹ́rìí, tí wọ́n jẹ́ àjèjì pátápátá ládùúgbò náà, rọ́ dé láti bá Siegfried àti Hannelore sọ ilé wọn di mímọ́ tónítóní. Lẹ́yìn èyí, àwùjọ náà wá bá àwọn aládùúgbò náà ṣètọ́jú ọgbà wọn. Àwọn kan lára àwọn ará abúlé náà béèrè lọ́wọ́ wọn pé kí ló sún wọn láti rìnrìn àjò ọgọ́rùn-ún kìlómítà láti wá ran àwọn èèyàn tí wọn ò bá pàdé rí lọ́wọ́. Èyí mú kó ṣeé ṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí náà láti fún àwọn tó kàgbákò ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní abúlé Colmnitz ní ìṣírí tẹ̀mí.

Àwọn àgbègbè tó wà láyìíká ìlú Wittenberg náà kò ṣàì fara gbá nínú ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé yìí. Tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan tó ń jẹ́ Frank àti Elfriede ṣiṣẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn aládùúgbò wọn fún ọjọ́ díẹ̀ kí omíyalé náà tó dé, wọ́n ń kó iyẹ̀pẹ̀ sínú àpò ìdọ̀họ wọ́n sì ń fi wọ́n dí àwọn etídò kí omi má bàa ya kọjá odò náà. Nígbà tí omi náà wá lọ sílẹ̀, Frank àti Elfriede bẹ̀rẹ̀ sí bẹ àwọn tí jàǹbá omíyalé náà kàn wò, wọ́n ń gbé oúnjẹ lọ fún wọn, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ìtùnú fún wọn. Frank sọ pé: “Ó ṣòro fún obìnrin kan tá a ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀ láti gbà gbọ́ pé àwa tá a jẹ́ àjèjì gbé oúnjẹ wá fún un láìsí pé ó ń san owó kankan. Ó sọ fún wa pé kò sí ẹnì kankan láti ṣọ́ọ̀ṣì òun tó wá wo òun. Gbogbo ìgbà tí ẹgbẹ́ kan tó ń gbé oúnjẹ wá fún un bá sì ṣe bẹ́ẹ̀ ni wọ́n máa ń gbowó. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún àwọn èèyàn láti rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n gbé oúnjẹ gbígbóná lọ́wọ́ dípò ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Nílẹ̀ Austria Ṣèrànwọ́ Láìjáfara

Omíyalé tún ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ jàǹbá ní ilẹ̀ Austria tó jẹ́ alámùúlégbè ilẹ̀ Jámánì. Wọ́n gbé ìgbìmọ̀ mẹ́ta kalẹ̀ láti bójú tó iṣẹ́ ìrànwọ́ náà. Títún àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́ta tó ti bà jẹ́ kọjá ààlà ṣe ni ohun tí wọ́n kọ́kọ́ gbájú mọ́. Bákan náà, láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí, àwọn ìdílé tí omíyalé náà ṣàkóbá fún fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún, àádọ́ta ilé sì ni omi bò mọ́lẹ̀ bámúbámú. Gbogbo nǹkan tí àwọn kan ní ni wọ́n pàdánù pátápátá àyàfi aṣọ tí wọ́n wọ̀ sọ́rùn nìkan ló kù. Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè Austria fi bí ipò nǹkan ṣe rí tó àwọn ìjọ tó wà ní àdúgbò náà létí, wọ́n sì ṣètò owó àkànlò láti fi ṣèrànwọ́. Nígbà tó fi máa di oṣù September, owó táwọn ará dá lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [$34,000] owó dọ́là ilẹ̀ Amẹ́ríkà.

Ìyá kan kọ̀wé pé: “Ọmọ mi ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ máa ń tọ́jú owó gan-an, ó sì ti ní nǹkan bíi dọ́là mẹ́rìnlá owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà nípamọ́. Àmọ́, nígbà tó gbọ́ pé àwọn kan lára àwọn arákùnrin wa ti pàdánù gbogbo ohun tí wọ́n ní, tinútinú ló fi fi gbogbo owó tó ní nípamọ́ náà ṣètọrẹ fún owó àkànlò tí wọ́n ṣètò nítorí àjálù náà.”

Lábẹ́ ìdarí Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn, èyí tó máa ń bójú tó iṣẹ́ kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n ṣètò àwọn ará sí àwùjọ-àwùjọ, láti ṣèrànwọ́ láti tún àwọn ilé tí omíyalé ti bà jẹ́ ṣe. Ẹnì kan tó ń wò wọ́n bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ náà sọ pé: “Ó yẹ kí àwọn ìwé ìròyìn jẹ́ kí aráyé mọ ohun tí ẹ̀yin èèyàn wọ̀nyí ń ṣe níbí.” Àwọn mìíràn tilẹ̀ yí èrò tí wọ́n ti ní tẹ́lẹ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà padà. Òbí kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí sọ pé: “Kí omíyalé yìí tó ṣẹlẹ̀, àwọn ọmọ mi, tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kì í fẹ́ tẹ́tí gbọ́ rárá bí mo bá fẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ìsìn mi. Àmọ́ ní báyìí, fún ìgbà àkọ́kọ́, wọ́n ti ń tẹ́tí sílẹ̀!”

Àwọn Ẹlẹ́rìí tún sapá láti ran ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí bíi tiwọn lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, nǹkan ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún obìnrin kan nígbà tí Ẹlẹ́rìí kan wá sí ilé rẹ̀ ní aago méje ààbọ̀ òwúrọ̀ tó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ó fẹ́ ìrànlọ́wọ́. Wọ́n ní láti mú obìnrin náà jáde, nítorí pé omi ti bẹ̀rẹ̀ sí ya wọnú ilé rẹ̀. Àmọ́, nígbà tó padà dé, ó bá ìwé kan lẹ́nu géètì ọgbà rẹ̀ táwọn Ẹlẹ́rìí fi há síbẹ̀. Ó kà pé: “Bó o bá fẹ́ ìrànlọ́wọ́, jẹ́ ká mọ̀ láìjáfara.” Àwọn Ẹlẹ́rìí bá a palẹ̀ ẹrẹ̀ àti àwókù tó wà nínú ilé rẹ̀ àti lórí ilẹ̀ àyíká ilé rẹ̀ mọ́.

Àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jẹ́ ọgọ́rùn-ún lọ sí ìlú Au láti lọ ran àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ àtàwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́. Àwọn tó ṣáájú àwùjọ náà bẹ̀rẹ̀ sí í lọ láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà, wọ́n sì ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tó ń gbébẹ̀ bóyá wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́. Ẹnu ya àwọn èèyàn gan-an láti rí àwọn Ẹlẹ́rìí pẹ̀lú àwọn ohun èlò tí wọ́n fi ń gbọ́n omi dà nù àtàwọn tí wọ́n fi ń palẹ̀ ìdọ̀tí mọ́ lọ́wọ́ wọn, àwọn nǹkan bíi pọ́ǹpù, ìgbálẹ̀, àti ṣọ́bìrì. Iṣẹ́ tí ì bá gba àwọn onílé náà tó ọ̀sẹ̀ kan kó tó parí kò gbà ju wákàtí díẹ̀ péré lọ. Pẹ̀lú omijé ayọ̀ lójú làwọn èèyàn ń wò wọ́n.

Nǹkan bí irínwó àwọn Ẹlẹ́rìí ló kópa nínú iṣẹ́ ìrànwọ́ náà, tòrutòru ni wọ́n sì fi ṣiṣẹ́ lọ́pọ̀ ìgbà láìdáwọ́dúró. Ẹ̀rí kedere gbáà nípa bí ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ ṣe lágbára tó lèyí jẹ́ fún àwọn tó ń wò wọ́n.

Ìjì Líle Isidore Kọ Lu Ilẹ̀ Mẹ́síkò

Láti apá àríwá orílẹ̀-èdè Venezuela ni ìjì líle kan tí wọ́n pè ní Isidore ti ń jà bọ̀. Ní September 22, 2002, àgbáàràgbá ìjì yìí kọ lu àgbègbè Yucatán, nílẹ̀ Mẹ́síkò. Ìjì líle tó pa pọ̀ mọ́ àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò yìí ṣe ọṣẹ́ tó tíì burú jù lọ nínú ìtàn fún àgbègbè Yucatán àti ìlú Campeche tí wọ́n jẹ́ ara àwọn ìpínlẹ̀ orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, bákan náà ló tún ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́ ní ìpínlẹ̀ Quintana Roo. Ní àgbègbè Yucatán nìkan, ilé bí ẹgbẹ̀rún márùnléláàádọ́rùn-ún [95,000] ló bà jẹ́ kọjá ààlà, èyí sì ṣàkóbá fún àwọn èèyàn tó ń lọ sí bí ìdajì mílíọ̀nù.

Ìrànlọ́wọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní àgbègbè Yucatán gbéṣẹ́ gan-an débi pé, àkọlé ìwé ìròyìn kan ní àríwá ilẹ̀ Mẹ́síkò kéde pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Dìde Ìrànwọ́.” Kí ìjì náà tó dé rárá ni wọ́n ti gbé ìgbìmọ̀ kan kalẹ̀. Wọ́n ti ṣe àwọn ètò pàjáwìrì sílẹ̀ láti wá ibi fi ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lágbègbè náà wọ̀ sí. Àwọn ìjọ tó wà nítòsí pèsè owó àkànlò ní pàjáwìrì. Wọ́n kó aṣọ, oògùn, àti ohun tó lé ní tọ́ọ̀nù méjìlélógún oúnjẹ lọ fún àwọn tó kàgbákò ìjì náà, títí kan àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Wọ́n yan àwọn alàgbà nínú àwọn ìjọ àdúgbò láti lọ bẹ àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ ìjì líle náà kàn wò, kí wọ́n sì fún wọn níṣìírí.

Lẹ́yìn tí ìjì náà dáwọ́ dúró, wọ́n dá àwọn ìgbìmọ̀ ìrànwọ́ sílẹ̀ ládùúgbò náà láti wá àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọn ò tíì mọ ibi tí wọ́n wà. Wọ́n rí àwọn díẹ̀ nínú igbó àti láwọn ibòmíràn, níbi tí wọ́n ti há sí fún bí ọjọ́ mẹ́ta láìsí oúnjẹ tàbí omi. Láwọn àgbègbè kan, omi lọ sókè débi pé, ó bo àwọn òpó iná mọ́lẹ̀! Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n lọ wá àwọn ọkọ̀ ojú omi ayára-bí-àṣá, wọ́n sì lò wọ́n láti wá àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kàn rí, wọ́n fún wọn lóúnjẹ, wọ́n sì kó wọn lọ síbi tí kò sí ewu.

Àwọn aláṣẹ àdúgbò yá àwọn Ẹlẹ́rìí ní ọkọ̀ ojú omi àtàwọn ohun èèlò mìíràn, àwọn Ẹlẹ́rìí náà sì lọ ṣèrànwọ́ tinútinú níbi tó jẹ́ pé ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló láyà láti dé. Ọ̀gá ológun kan kọ́kọ́ yarí pé àwọn Ẹlẹ́rìí náà kò gbọ́dọ̀ lọ sírú ibi eléwu bẹ́ẹ̀. Àmọ́, nígbà tó rí ẹ̀mí àìṣojo wọn, ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé ẹ ò kọ̀ láti gbé ọkọ̀ òfuurufú hẹlikóbítà láti lọ yọ àwọn èèyàn yín, bó bá jẹ́ ohun tó gbà nìyẹn. Àwọn ọkọ̀ wa wà nílẹ̀ fún yín láti fi gbé àwọn èèyàn yín lọ sí ibikíbi tẹ́ ẹ bá fẹ́.”

Oníṣọ́ọ̀bù kan fẹ́ láti mọ ìdí tí àwọn Ẹlẹ́rìí kan fi ń ra omi inú ike lọ́pọ̀ yanturu. Wọ́n wá ṣàlàyé fún un pé àwọn arákùnrin wọn nípa tẹ̀mí àtàwọn mìíràn tí wọ́n nílò rẹ̀ làwọ́n ń rà á fún. Ni ọkùnrin náà bá pinnu láti fún wọn ní gbogbo omi oníke tó ní láìgba kọ́bọ̀. Lọ́jọ́ kejì, ó tún fún wọn sí i. Ní ṣọ́ọ̀bù mìíràn, oníbàárà kan béèrè ohun tó fà á tí àwọn Ẹlẹ́rìí fi ń ra ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ. Nígbà tó gbọ́ pé nítorí àwọn tó kàgbákò omíyalé ni, ó fi owó ṣètọrẹ fún wọn láti rà sí i.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìdílé Ẹlẹ́rìí tó ń lọ sí bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àtààbọ̀ ló pàdánù àwọn ohun ìní wọn nítorí ìjì líle náà, kò sí ọ̀kankan nínú wọn tó dàwátì tàbí tó ṣòfò ẹ̀mí. Síbẹ̀, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ilé tó tó ọ̀ọ́dúnrún àti mọ́kànlélọ́gbọ̀n [331] tó jẹ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí ló bà jẹ́ díẹ̀ tàbí ló bà jẹ́ gan-an, ó pọn dandan láti ṣètò bí wọn yóò ṣe ṣàtúnkọ́ ilé náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó mọ̀ nípa iṣẹ́ ilé kíkọ́ ṣèbẹ̀wò sí ilé kọ̀ọ̀kan àti Gbọ̀ngàn Ìjọba kọ̀ọ̀kan láti lè mọ bí wọ́n ṣe bà jẹ́ tó. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ilé tó jẹ́ nǹkan bí àádọ́ta lé rúgba àti mẹ́jọ [258] ni wọ́n ti tún ṣe, wọ́n sì ti kọ́ àwọn méjìléláàádọ́sàn-án [172] mìíràn padà. Bákan náà, iṣẹ́ ń lọ lọ́wọ́ lórí ṣíṣàtúnkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba mọ́kàndínlógún tó ti bà jẹ́.

Inú alàgbà kan ní ìjọ kan ní ìpínlẹ̀ Yucatán dùn gan-an débi pé ó ní: “Mo ti máa ń kà nípa iṣẹ́ ìrànwọ́ táwọn ará ṣe láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa. Àmọ́, ìyẹn yàtọ̀ sí kéèyàn fojú ara rẹ̀ rí i. Ìgbàgbọ́ mi àti ti ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin wa ti lágbára sí i nígbà tá a rí i bí ètò àjọ Jèhófà àtàwọn arákùnrin wa ọ̀wọ́n ṣe fi ẹ̀mí ìbìkítà hàn, tí wọ́n sì wá ràn wá lọ́wọ́ láìjáfara.”

Obìnrin kan ní: “Inú mi ì bá dùn ká ní ṣọ́ọ̀ṣì mi náà ń ṣèrànwọ́ bí ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí ṣe ń ṣe.” Obìnrin mìíràn tí àwọn Ẹlẹ́rìí kó yọ nínú ewu ní tirẹ̀ sì sọ pé: “Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lára wa, àwọn ni wọn ò jẹ́ ká kú. Wọ́n fi ìfẹ́ wọn hàn sí wa, wọ́n sì fẹ̀mí ara wọn wewu láti yọ wá nígbà tí omi bo ilé wa mọ́lẹ̀.”

Ìjì Líle Ṣọṣẹ́ ní Orílẹ̀-Èdè Kòríà

Ní August 31 àti September 1, 2002, Ìjì Líle kan tí wọ́n pè ní Rusa ṣe ọṣẹ́ ńláǹlà ní ọ̀pọ̀ àgbègbè ní orílẹ̀-èdè Kòríà. Song-pil Cho, tó jẹ́ alàgbà kan nínú ìjọ sọ pé: “Ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn bá dúró sábẹ́ ọ̀ṣọ̀rọ̀. Ńṣe ni òjò yìí kàn ń rọ̀, tó ń rọ̀ ṣáá láìdáwọ́ dúró.” Kò tó wákàtí mẹ́rìnlélógún tí òjò náà fi rọ̀, àmọ́ àgbàrá òjò náà pọ̀ kọjá sísọ—èyí sì ni òjò tí àkọsílẹ̀ fi hàn pé ó tíì pọ̀ jù lọ lọ́jọ́ kan ṣoṣo ní orílẹ̀-èdè Kòríà.

Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Korea Herald ṣe sọ, jákèjádò orílẹ̀-èdè náà, ẹgbẹ̀rún méjìdínlọ́gbọ̀n àti ọgọ́rùn-ún [28,100] ilé, pẹ̀lú hẹ́kítà ilẹ̀ tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùndínláàádọ́rùn-ún [85,000] lomi bò mọ́lẹ̀ ráúráú. Àwọn èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin [70,000] ló di dandan fún láti fi ilé wọn sílẹ̀. Ìjì líle náà pa ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélọ́ọ̀ọ́dúnrún [301,000] ẹran ọ̀sìn, ó ri ọkọ̀ òkun mẹ́rìndínláàádóje [126], ó sì wó àìlóǹkà àwọn òpó iná lulẹ̀. Ó lé ní ọgọ́sàn-án èèyàn tí ìròyìn sọ pé wọ́n kú tàbí tí wọ́n dàwátì. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì wà lára àwọn wọ̀nyí.

Gẹ́gẹ́ bó ti ṣẹlẹ̀ nílẹ̀ Yúróòpù àti ní Mẹ́síkò, kíá làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí ṣèrànwọ́. Jákèjádò orílẹ̀-èdè náà ni àwọn Ẹlẹ́rìí ti fi oríṣiríṣi nǹkan ṣètọrẹ. Lára àwọn nǹkan náà ni aṣọ, bùláńkẹ́ẹ̀tì, àtàwọn nǹkan mìíràn tó jẹ́ kòṣeémáàní. Síbẹ̀, àwọn kan wà tó jẹ́ pé àgbègbè táwọn tó ń ṣèrànwọ́ náà kò lè dé, tó sì jẹ́ àdádó ni wọ́n ń gbé. Àwọn títì ti bà jẹ́, omi sì ti gbé àwọn afárá lọ. Kò sí iná mànàmáná bẹ́ẹ̀ ni tẹlifóònù kò ṣiṣẹ́ mọ́. Nítorí náà, wọ́n ṣètò pé kí àwọn àwùjọ tó ń ṣèrànwọ́ náà fẹsẹ̀ rìn láti lè lọ pèsè ìrànwọ́ táwọn arákùnrin náà nílò. Song-pil Cho, tó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀kan lára àwùjọ tó ń ṣèrànwọ́ náà sọ nípa àgbègbè kan tí wọ́n ti lọ ṣèrànwọ́ pé: “Afárá méje àti ibi púpọ̀ lójú ọ̀nà náà ni omi bà jẹ́ pátápátá. Nígbà tá a wá dé ìlú náà níkẹyìn, ńṣe là ń rí àwọn ilé tó ti bà jẹ́ káàkiri. Òórùn burúkú gba gbogbo ibẹ̀ kan, bẹ́ẹ̀ ni òkú àwọn ẹran wà káàkiri. Àmọ́, inú wa dùn gan-an nígbà tá a rí àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa mẹ́fẹ̀ẹ̀fà! Wọ́n ti pàdánù gbogbo ohun ìní wọn, àmọ́ àlááfíà ni gbogbo wọn wà nǹkan kan ò sì ṣe wọ́n.”

Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti múra sílẹ̀ dáadáa de àjálù yìí. Níwọ̀n bí omíyalé ti máa ń wọ́pọ̀ lásìkò tí òjò ẹlẹ́fùúùfù bá ń rọ̀, Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn tó wà lágbègbè ìlú Seoul ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò sílẹ̀ de àjálù tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Láti ọdún 1997 ni ìgbìmọ̀ yìí ti máa ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́dọọdún fún àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni kí wọ́n bàa lè wà ní ìmúrasílẹ̀ bí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì bá ṣàdéédéé yọjú.

Ní September 2, àwọn òṣìṣẹ́ tó ń ṣèrànwọ́ lábẹ́ ìdarí Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn náà dé sí ìlú Kangnŭng, tó wà létíkun ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè náà, wọ́n sì fi Gbọ̀ngàn Àpéjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè náà ṣe ojúkò ìgbòkègbodò wọn. Kí ni wọ́n kọ́kọ́ mójú tó? Rírí omi tó mọ́ fún àwọn tó la àjálù náà já ni. Bí omíyalé ńlá bá ṣẹlẹ̀, àwọn páìpù omi ẹ̀rọ sábà máa ń bà jẹ́; ẹ̀gbin tó máa ń wà nínú omi òjò kì í sì ṣe kékeré. Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn wá ṣètò fún àwọn ọkọ̀ ńlá tó ń gbé táǹkì omi sẹ́yìn láti gbé omi lọ sáwọn ibi tí àjálù náà ti wáyé.

Lẹ́yìn tí omíyalé náà ti lọ sílẹ̀, ńṣe ni ẹrẹ̀ tó ń rùn gan-an bo gbogbo nǹkan mọ́lẹ̀ bámúbámú. Síbẹ̀, ìgbìmọ̀ náà ti mọ ọ̀nà tó gbẹ́ṣẹ́ gan-an láti sọ àwọn nǹkan di mímọ́. Níwọ̀n bó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ilé tó wà níbẹ̀ ni wọ́n fi sìmẹ́ǹtì kọ́, wọ́n lè fọ̀ wọ́n mọ́ nípa ṣíṣí àwọn pépà tó máa ń wà lára ògiri àtàwọn ohun èlò tí wọ́n tẹ́ sórí ilẹ̀ kúrò, lẹ́yìn náà tí wọ́n á sì fi omi tó ń tú yàáyàá fọ àwọn yàrá náà mọ́.

Bí omíyalé bá ṣẹlẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan abánáṣiṣẹ́ ni kì í ṣiṣẹ́ mọ́. Àmọ́, bí àwọn tó mọ̀ nípa wọn dáadáa bá tètè tú àwọn nǹkan bí ẹ̀rọ amúǹkantutù àti ẹ̀rọ amómigbóná palẹ̀ láàárín ọjọ́ díẹ̀, tí wọ́n nù wọ́n dáadáa, tí wọ́n sá wọn sóòrùn, tí wọ́n sì tò wọ́n padà, lọ́pọ̀ ìgbà, irú àwọn ohun èlò bẹ́ẹ̀ á máa ṣiṣẹ́ lọ. Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn ní ètò fún irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Wọ́n máa ń lo àwọn ẹ̀rọ amómigbóná tí kò nílò pé wọ́n ń pààrọ̀ wọn láti fi mú ilé gbẹ. Ṣíṣe èyí máa ń gbà tó ọ̀sẹ̀ méjì sí mẹ́ta.

Bákan náà, wọ́n tún gbọ́dọ̀ fọ àwọn aṣọ àti bùláńkẹ́ẹ̀tì tí omíyalé ti bà jẹ́ láàárín ọjọ́ díẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn ò ní ṣeé lò mọ́. Àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni láti ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ládùúgbò náà ṣèrànwọ́ láti di aṣọ àwọn Kristẹni arákùnrin wọn tí ẹrẹ̀ ti bà jẹ́ sínú àpò. Ẹrẹ̀ tó ti mu àwọn aṣọ wọ̀nyí gbingbin kò rọrùn láti fọ̀ kúrò rárá, wọ́n sì ní láti fi ọwọ́ fọ̀ wọ́n nínú omi odò tó tutù gan-an. Nígbà tí akọ̀ròyìn ìwé ìròyìn kan gbọ́ nípa iṣẹ́ aláápọn tí ìfẹ́ sún wọn ṣe yìí, ó gbé àwòrán ńlá tó jẹ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń ṣe iṣẹ́ náà yọ nínú ìwé ìròyìn àdúgbò náà.

Omíyalé tó fa ọ̀pọ̀ jàǹbá ní ilẹ̀ Yúróòpù, ní Àríwá Amẹ́ríkà, àti Éṣíà gbé ilé àti àwọn nǹkan ìní lọ, ó sì tún gbẹ̀mí àìlóǹkà èèyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí bani nínú jẹ́ gidigidi, irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ láwọn “ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan tí à ń gbé yìí, èyí tí “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” jẹ́ ká rí kedere. (2 Tímótì 3:1) Irú àwọn àjálù bẹ́ẹ̀ sì tún lè jẹ́ ẹ̀rí ṣíṣe kedere tó ń rán wa létí kókó pàtàkì kan pé: Àwọn Kristẹni tòótọ́ nífẹ̀ẹ́ ara wọn àtàwọn aládùúgbò wọn. Irú ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun kan tí ìjì kankan kò lè gbé lọ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

JÁMÁNÌ Ilé kan tí ìjì bà jẹ́ pátápátá

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

JÁMÁNÌ Ó ju ẹgbẹ̀rún méjì àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni lọ tí wọ́n pèsè ìrànwọ́ láìjáfara

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

AUSTRIA Wọ́n ń ṣàtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn ní ìlú Ottensheim

Apá òsì: Àwùjọ àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni ṣẹ̀ṣẹ̀ padà dé láti ìlú Au, níbi tí wọ́n ti lọ ṣèrànwọ́ fún àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ àtàwọn aládùúgbò wọn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

MẸ́SÍKÒ Apá ọ̀tún: Ìgbìmọ̀ aṣèrànwọ́ kan ń pèsè omi tó ṣeé mu fún àwọn tó la àjálù ìjì líle náà já

Ìsàlẹ̀: Kíkọ́ ilé mìíràn láti fi rọ́pò èyí tó bà jẹ́

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

KÒRÍÀ Láti apá òsì sí apá ọ̀tún: Apá kan ìlú tí omi ti bò mọ́lẹ̀ bámúbámú; lílo omi tó ń tú yàáyàá láti fi fọ àwọn nǹkan mọ́; wọ́n ń fọ aṣọ nínú odò kan nítòsí