Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Gígé Lẹbẹ Àwọn Ẹja Ekurá

Jákèjádò ayé làwọn apẹja ti ń wá àwọn ẹja ekurá nínú àwọn agbami òkun, tí wọ́n á gé lẹbẹ ara wọn tí wọ́n á sì sọ òkú wọn sínú omi. Ìwé ìròyìn Science News sọ pé: “Bí wọ́n ṣe ń gé lẹbẹ ara àwọn ẹja yìí nírú ọ̀nà bíburú jáì bẹ́ẹ̀ kò ṣẹ̀yìn owó gegere tí wọ́n ń rí tí wọ́n bá tà á fún àwọn tó fẹ́ fi se ọbẹ̀ ẹja ekurá tó gbówó lórí gan-an.” Ní August 2002, Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Etíkun Ilẹ̀ Amẹ́ríkà gba ọkọ̀ òkun kan tó jẹ́ ti àwọn apẹja Hawaii sílẹ̀ níbi tí kò jìnnà sí etíkun ilẹ̀ Mẹ́síkò, lẹ́yìn tí wọ́n ṣàkíyèsí pé lẹbẹ ẹja ekurá tí ìwọ̀n rẹ̀ tó tọ́ọ̀nù méjìlélọ́gbọ̀n ló kún inú rẹ̀ bámúbámú. Kò sí ẹ̀ya ara ẹja náà mìíràn tó wà nínú ọkọ̀ náà. Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Ẹrù lẹbẹ ẹja ekurá tí wọ́n dì gàgàrà sínú ọkọ̀ náà fi hàn pé wọ́n ti pa ẹja ekurá tó tó ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [30,000], wọ́n sì ti fi ẹja tí ìwọ̀n rẹ̀ tó ọ̀kẹ́ mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [580,000] kìlógíráàmù ṣòfò dà nù. Kárí ayé, ẹja ekurá tó tó ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù ni wọ́n fojú bù pé àwọn apẹja yìí ń pa báyìí lọ́dọọdún.” Níwọ̀n bí wọ́n ti ń ta lẹbẹ ẹja ekurá tó bá wọ̀n tó àádọ́talénírínwó [450] gíráàmù ní igba owó dọ́là, àwọn tó ń fẹ́ ẹ pọ̀ ju iye ẹja ekurá tó wà lọ.

Ṣíṣọ́ Àkókò Lò

Ìwé ìròyìn The Australian sọ pé, ìwádìí kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé, “àwọn èèyàn tó máa ń ṣàròyé pé àwọn kò ní àkókò tó ń tan ara wọn jẹ ni.” Ìwé ìròyìn náà sọ̀rọ̀ lórí ìwádìí kan tí Yunifásítì New South Wales àti Yunifásítì Ìjọba Àpapọ̀ Ọsirélíà ṣètò, ó ní: “Ọ̀pọ̀ lára wa ló ń lo àkókò púpọ̀ jù níbi iṣẹ́ àti fún ṣíṣe iṣẹ́ ilé ju bó ṣe yẹ lọ.” Àwọn olùṣèwádìí gbéṣirò lé iye àkókò tí tọkọtaya kan tí àwọn méjèèjì ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ láìsí pé wọ́n ń bójú tó ọmọ nílò láti ṣiṣẹ́ kí wọ́n lè pèsè àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé. Wọ́n wá fi èyí wéra pẹ̀lú iye àkókò tí wọ́n máa ń lò láti fi ṣe àwọn iṣẹ́ náà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn náà ti sọ, ìwádìí náà fi hàn pé, àwọn tọkọtaya tí kò lọ́mọ “lo àpapọ̀ wákàtí mọ́kàndínlọ́gọ́rin [79] lọ́sẹ̀ níbi iṣẹ́, wọ́n lo wákàtí mẹ́tàdínlógójì [37] fún iṣẹ́ ilé, wọ́n sì lo wákàtí méjìdínlógóje [138] fún ìtọ́jú ara wọn, àmọ́ iye wákàtí tí wọ́n nílò fún iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ lọ́sẹ̀ kò ju ogún lọ [wákàtí mẹ́wàá ẹnì kọ̀ọ̀kan], wákàtí méjìdínlógún fún iṣẹ́ ilé, àti wákàtí mẹ́rìndínlọ́gọ́fà [116] fún ìtọ́jú ara wọn [títí kan oúnjẹ jíjẹ àti oorun].” Bí tọkọtaya kan bá múra tán láti mú ìgbésí ayé wọn rọrùn, wọ́n lè máa ní tó àfikún ọgọ́rùn-ún wákàtí sí i lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ìwé ìròyìn The Australian sọ pé, ìwádìí náà fi hàn pé, àwọn tọkọtaya tó ń ṣiṣẹ́ láìsí ọmọ “sọ pé àwọn kò ní àkókò tó pọ̀ tó ti àwọn ẹlòmíì, àmọ́ ká sòótọ́, àwọn gan-an ni ọwọ́ wọn kò fi bẹ́ẹ̀ dí rárá tó ti àwọn ẹlòmíì, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn òbí ni ọwọ́ wọn dí jù lọ tí wọn kò sì ní àkókò púpọ̀.”

Àrùn Àtọ̀gbẹ Ń Gbilẹ̀ Sí I ní Ilẹ̀ Íńdíà

Àjọ Ìlera Àgbáyé fojú bù ú pé, ó lé ní àádọ́sàn-án [170] mílíọ̀nù èèyàn kárí ayé tó ní àrùn àtọ̀gbẹ. Ìwé ìròyìn Deccan Herald sọ pé, orílẹ̀-èdè Íńdíà ni àwọn alárùn àtọ̀gbẹ pọ̀ sí jù lọ—torí pé mílíọ̀nù méjìlélọ́gbọ̀n èèyàn níbẹ̀ ló ní in—àfàìmọ̀ sì ni iye yìí kò ní ju mílíọ̀nù mẹ́tàdínlọ́gọ́ta lọ tó bá fi máa di ọdún 2005. Ní ibi àpérò àgbáyé kan lórí àrùn àtọ̀gbẹ ní ilẹ̀ Éṣíà, èyí tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè Sri Lanka, àwọn ògbógi sọ pé, bí irú oúnjẹ táwọn èèyàn ń jẹ àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbé ìgbésí ayé ṣe ń yí padà ni lájorí ohun tó ń ṣokùnfà bí àrùn yìí ṣe ń yára gbilẹ̀, wọ́n sì tún mẹ́nu kan àwọn nǹkan bíi másùnmáwo, ohun tó wà nínú àbùdá ẹni, kí ọmọ má fi bẹ́ẹ̀ tẹ̀wọ̀n nígbà tí wọ́n bí i, àti jíjẹ́ kí àwọn ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí máa jẹ àjẹjù. Ilẹ̀ Íńdíà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń fowó tó kéré gan-an tọ́jú àrùn àtọ̀gbẹ lágbàáyé. Síbẹ̀, ńṣe ni àwọn tí àrùn àtọ̀gbẹ ń yọ lẹ́nu àtàwọn tó ń ṣekú pa ń pọ̀ sí i, lára ohun tó sì fa èyí ni pé àwọn èèyàn kì í mọ̀ pé àwọ́n ní in, wọn kì í sì í tètè lọ ṣàyẹ̀wò rẹ̀. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní àwọn ìlú ńlá tó wà ní orílẹ̀-èdè Íńdíà fi hàn pé, ìdá méjìlá nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àgbàlagbà ló ní àrùn àtọ̀gbẹ, ìdá mẹ́rìnlá sì ni ara wọn kò lè lo èròjà gúlúkóòsì bó ṣe yẹ, èyí tó sábà máa ń yọrí sí níní àrùn àtọ̀gbẹ.

Àwọn Arúgbó Ń Pọ̀ Sí I ní Ilẹ̀ Yúróòpù

Ìwé ìròyìn El País ti ilẹ̀ Sípéènì sọ pé: “Ó dà bíi pé orúkọ tí wọ́n ń pe ilẹ̀ Yúróòpù ti ń rò ó báyìí o, ìyẹn ni Yúróòpù Ògbólógbòó.” Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ ara Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù, ìdá ogún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn olùgbé ibẹ̀ ó kéré tán, ló ti lé ní ọmọ ọgọ́ta ọdún. Àwọn elétò ìkànìyàn sọ pé, tó bá fi máa di ọdún 2050, èèyàn mẹ́rin nínú mẹ́wàá lára àwọn tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè kan, irú bí Austria, Ítálì, àti Sípéènì, ló ti máa lé ní ọmọ ọgọ́ta ọdún. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n sọ ní Àpérò Àgbáyé Ẹlẹ́ẹ̀kejì Lórí Ọjọ́ Ogbó, èyí tó wáyé ní ìlú Madrid, lórílẹ̀-èdè Sípéènì, bí ọ̀pọ̀ àwọn aráàlú ṣe ń darúgbó báyìí yóò béèrè pé kí a ṣe àtúnṣe sí ìpèsè àwọn ohun amáyédẹrùn àti ipò ọrọ̀ ajé lọ́nà tí yóò ṣe àwọn aráàlú láǹfààní. Á túbọ̀ ṣòro gan-an láti pèsè owó ìfẹ̀yìntì àti owó ìbánigbófò lórí ìlera. Bí àpẹẹrẹ, ó lè pọn dandan pé kí àwọn agbanisíṣẹ́ máa gba àwọn àgbàlagbà síṣẹ́, kí wọ́n ṣètò wákàtí iṣẹ́ tó yàtọ̀ síra tàbí kí wọ́n ṣètò pé kí ẹni méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ jọ máa pín iṣẹ́ tó tọ́ sí ẹnì kan ṣoṣo ṣe. Bákan náà, ó lè pọn dandan pé kí wọ́n máa ṣètò àkókò ìfẹ̀yìntì àwọn òṣìṣẹ́ wọn kó má bàa bọ́ sí ìgbà kan náà. Síwájú sí i, gẹ́gẹ́ bí oníṣòwò ilẹ̀ Sípéènì kan tó ń jẹ́ Josep Maria Riera ṣe sọ, “níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́ kò ní pọ̀ tó àwọn àgbàlagbà mọ́, àwọn iléeṣẹ́ tó fẹ́ kí iṣẹ́ wọn gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ yóò ní láti máa ṣe àwọn ohun tí àwọn àgbàlagbà nílò jáde.”

A Nílò Ẹ̀kọ́ Nípa Ìbálòpọ̀ ní Báyìí Ju Ti Ìgbàkígbà Rí Lọ

Ìwé ìròyìn Der Spiegel sọ pé, gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ní ilẹ̀ Jámánì ti fi hàn, láàárín ọdún 1996 sí 2001, iye ìṣẹ́yún fi nǹkan bí ìdá ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún lọ sókè sí i láàárín àwọn ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mẹ́tàdínlógún, ó sì fi nǹkan bí àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún lọ sókè sí i láàárín àwọn ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn kéré jù bẹ́ẹ̀ lọ. Norbert Kluge, tó ń ṣiṣẹ́ ní Yunifásítì Koblenz-Landau, sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọdé ń tètè bàlágà nígbà tí wọ́n ṣì kéré gan-an, wọn ‘kò gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ yíyẹ lórí ọ̀ràn ìbálòpọ̀—ní pàtàkì jù lọ, àwọn òbí kì í tètè bẹ̀rẹ̀ rárá.’ Ó yẹ ká dá àwọn ọmọdé lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa nípa ọ̀ràn ìbálòpọ̀ kí wọ́n tó pé ọmọ ọdún mẹ́wàá, àmọ́ ọ̀pọ̀ òbí ni kì í fọwọ́ pàtàkì mú ẹrù iṣẹ́ wọn, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ọ̀gbẹ́ni Kluge sọ. Ìwé ìròyìn Berliner Morgenpost sọ pé, ọ̀gá àgbà Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Àwọn Òbí Nílẹ̀ Jámánì, èyí tó wà ní ìlú Bonn, gba àwọn òbí nímọ̀ràn láti túbọ̀ máa tẹnu mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe kókó, irú bí “ọ̀ràn ìfẹ́ àti àjọṣe ọkùnrin àti obìnrin,” nígbà tí wọ́n bá ń fún àwọn ọmọ wọn ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀ràn ìbálòpọ̀, dípò kí wọ́n kàn máa sọ nípa ìbímọ nìkan.

Lẹ́tà Orí Kọ̀ǹpútà àti Àjọṣe Láàárín Àwọn Òṣìṣẹ́

Ìwé ìròyìn Globe and Mail ti ilẹ̀ Kánádà sọ pé, gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn olùṣèwádìí méjì sọ, ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ máa ń fi lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà bá òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ní àjà kan náà sọ̀rọ̀ bí ìgbà tí wọ́n ń bá àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn tó wà ní orílẹ̀-èdè jíjìnnà réré sọ̀rọ̀. Nígbà tí David Crystal, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìlò èdè ní Yunifásítì Wales, ń sọ̀rọ̀ nípa ipa tí lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà lè ní lórí àjọṣe àárín àwọn èèyàn, ó ní: “Gbígba èsì ọ̀rọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ béèyàn ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ jẹ́ ohun pàtàkì nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀,” àmọ́ lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà kì í fúnni nírú àǹfààní yìí nítorí pé àlàfo àkókò díẹ̀ máa ń wà láàárín ìgbà téèyàn á gba ìsọfúnni àti ìgbà tó máa fèsì. Síwájú sí i, ẹni tó ń kọ lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà lè máa dá sọ gbogbo ọ̀rọ̀ láìsí pé ẹnì kejì ń dá sí ọ̀rọ̀ náà. Ìwé ìròyìn Globe wá sọ pé: “Sísọ̀rọ̀ àti fífetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹni kejì jẹ́ ohun ṣíṣekókó nínú àjọṣe pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.”

Ṣé Òótọ́ Ni Pé Oríṣi Iṣan Méjì La Ní?

Ìwé ìròyìn ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kan ní ilẹ̀ Jámánì tó ń jẹ́ Bild der Wissenschaft sọ pé, Ẹlẹ́dàá dá àwa èèyàn pẹ̀lú àkànṣe ètò ìgbékalẹ̀ iṣan ara kan, tó ń jẹ́ ká mọ̀ pé ẹnì kan fọwọ́ kàn wá tìfẹ́tìfẹ́ àti lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ilẹ̀ Sweden ṣàwárí pé obìnrin kan tó ti pàdánù àwọn iṣan pàtàkì tó ń jẹ́ kéèyàn tètè mọ̀ pé ẹnì kan fọwọ́ kanni ṣì lè nímọ̀lára pé ohun kan kan òun lára lọ́nà gbígbádùn mọ́ni bí wọ́n bá fi búrọ́ọ̀ṣì tí wọ́n fi ń kunlé kàn án lára fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́. Wọ́n ṣàkíyèsí pé, ohun tó ń fa irú ìmọ̀lára pé nǹkan kanni lára lọ́nà tó gbádùn mọ́ni yìí ni àkójọpọ̀ iṣan oríṣi kejì tó wà nínú awọ ara wa, èyí tí àwọn fọ́nrán iṣan àkànṣe kan wà nínú rẹ̀. Àkójọpọ̀ iṣan wọ̀nyí máa ń ṣiṣẹ́ kìkì fún fífọwọ́ kanni lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, wọ́n sì máa ń sún àwọn iṣan ọpọlọ tó ń nípa lórí ìmọ̀lára ṣiṣẹ́. Nígbà tí ìwé ìròyìn International Herald Tribune ń sọ̀rọ̀ lórí ìdí tó fi ṣeé ṣe kí àwọn ẹ̀dá èèyàn ní oríṣi iṣan méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó ní: “Àwọn fọ́nrán iṣan tí kì í tètè nípa lórí ìmọ̀lára yìí máa ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti àwọn wákàtí àkọ́kọ́ tí wọ́n bá ti bí ọmọ kan, àfàìmọ̀ ni kò tiẹ̀ jẹ́ pé àtinú ilé ọlẹ̀ ni wọ́n ti ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pàápàá, nígbà tí àwọn fọ́nrán iṣan tó máa ń tètè nípa lórí ìmọ̀lára máa ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ díẹ̀díẹ̀ lẹ́yìn tí ọmọ bá dáyé. Àwọn ìkókó lè mọ̀ ọ́n lára pé bàbá tàbí ìyá wọn fọwọ́ kàn wọ́n tìfẹ́tìfẹ́ kí wọ́n tiẹ̀ tó lóye ohun tí fífọwọ́ kanni jẹ́ pàápàá.”