Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àṣà Aṣọ Kò Dúró Sójú Kan

Àṣà Aṣọ Kò Dúró Sójú Kan

Àṣà Aṣọ Kò Dúró Sójú Kan

YÁLÀ a mọ̀ tàbí a ò mọ̀, dé ìwọ̀n àyè kan, àṣà aṣọ tó lòde ló ń pinnu irú aṣọ tí à ń wọ̀ lójoojúmọ́. Èyí náà ló tún ń pinnu irú aṣọ tó máa wà lọ́jà fún àwọn èèyàn láti rà.

Kódà, àwọn aṣọ tá ò kà sí mọ́ báyìí ló jẹ́ àwọn aṣọ tó lòde nígbà kan rí. Bí àpẹẹrẹ, ṣẹ́ẹ̀tì àti táì táwọn ọkùnrin ń wọ̀ báyìí ni aṣọ tó gbayì gan-an ní ohun tó lé ní ọ̀rúndún kan sẹ́yìn. Láwọn ọdún 1920 sì rèé, súwẹ́tà àwọn obìnrin ni aṣọ tó gbajúgbajà.

Ohun méjì pàtàkì ló ń sún àwọn iléeṣẹ́ tó ń ṣe aṣọ láti máa ṣe wọ́n jáde, ìyẹn ni ìfẹ́ àwọn èèyàn láti ní nǹkan tuntun tàbí èyí tó yàtọ̀, àti ìfẹ́ láti ṣe ohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló máa ń fẹ́ láti wọ nǹkan tuntun. Èyí ló fà á tá a fi máa ń ra aṣọ nígbà mìíràn, kì í ṣe torí pé èyí tá a ní sílé ti gbó, bí kò ṣe nítorí pé a ṣáà fẹ́ ní òmíràn. Lọ́wọ́ kan náà, a kì í fẹ́ káwọn èèyàn máa rò pé a ò rọ́ọ̀ọ́kán, ìyẹn la fi máa ń ra aṣọ tó jẹ́ pé, dé ìwọ̀n àyè kan, kì í fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí tàwọn ẹlẹgbẹ́ wa. Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni àwọn iléeṣẹ́ tó ń ṣe aṣọ ti ń tẹ́ ìfẹ́ táráyé ní fún aṣọ wíwọ̀ lọ́rùn. Nígbà mìíràn sì rèé, wọ́n tún máa ń lò ó láti fi gbowó ọwọ́ àwọn èèyàn.

Ìtàn Aṣọ ní Ṣókí

Kí àwọn aránṣọ tó rán irú aṣọ kan jáde, ohun márùn-ún pàtàkì ni wọ́n máa ń gbé yẹ̀ wò: àwọ̀, irú ohun tí a lè fi aṣọ rán, bó ṣe máa rí tí wọ́n bá rán an tán, bí aṣọ ṣe rí lọ́wọ́ àti ìlà (tàbí bátànì) ara aṣọ. Bí ọdún ti ń gorí ọdún, onírúurú ọ̀nà tí àwọn aránṣọ lè gbà lo àwọn nǹkan márùn-ún yìí ti pọ̀ sí i. Bí àpẹẹrẹ, ní ilẹ̀ Íjíbítì àtijọ́, aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí wọ́n ń ṣe jáde níbẹ̀ ló lòde, ó sì dára fún àgbègbè ilẹ̀ olóoru. Àmọ́, níwọ̀n bí kò ti rọrùn láti pa aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ láró, àwọ̀ kan ṣoṣo ló sábà máa ń ní, ìyẹn ni àwọ̀ funfun gbòò. Síbẹ̀, àwọn aránṣọ ní ilẹ̀ Íjíbítì máa ń ṣẹ́ aṣọ náà léra lọ́nà tó fi jẹ́ pé tí wọ́n bá rán an tán, ó máa ń gún régé ó sì máa ń dúró dáadáa lára. Bí àṣà aṣọ wíwọ̀ kan ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn, èyí táráyé ṣì ń gba tiẹ̀ dòní olónìí.

Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, àwọn aṣọ tuntun àtàwọn àwọ̀ tuntun ti wà. Àwọn ará Róòmù tó rí jájẹ máa ń kó aṣọ ṣẹ́dà (sílíìkì) wá láti ilẹ̀ Ṣáínà àti ilẹ̀ Íńdíà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó tí wọ́n fi ń kó aṣọ náà wọlé mú kó wọ́n bíi góòlù. Ẹ̀yà aṣọ mìíràn tó tún gbayì ni èyí tí wọ́n fi irun àgùntàn ṣe tí wọ́n sì pa láró, tí wọ́n máa ń kó wá láti ìlú Tírè, tí kílò kan rẹ̀ sì tó owó tí òṣìṣẹ́ kan máa gbà lọ́dún mẹ́fà. Àwọn aró tuntun àtàwọn aṣọ tuntun náà mú kó ṣeé ṣe fáwọn obìnrin Róòmù tó rí jájẹ láti máa wọ stola, ìyẹn aṣọ àlàbora gígùn tí wọ́n fi òwú aláwọ̀ búlúù láti ilẹ̀ Íńdíà tàbí ṣẹ́dà aláwọ̀ ìyeyè láti ilẹ̀ Ṣáínà ṣe.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé látìgbàdégbà ni irú aṣọ táwọn èèyàn ń wọ̀ máa ń yí padà, aṣọ tó bá wọ́n gan-an kì í lọ láyé àtijọ́, títí gbére làwọn èèyàn á sì máa lò ó. Díẹ̀díẹ̀ ni ìyípadà bẹ̀rẹ̀ sí í dé, àwọn ọ̀tọ̀kùlú nìkan ló sì sábà máa ń lo àwọn aṣọ tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé. Àmọ́ o, nígbà táyé wá dáyé ká máa fi ẹ̀rọ ṣe gbogbo nǹkan, bí ojú àwọn tí kì í ṣe olówó náà ṣe wá là sí aṣọ nìyẹn.

Ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, àwọn iléeṣẹ́ ńláńlá bẹ̀rẹ̀ sí yọjú, wọ́n sì ń ṣe aṣọ fún àtolówó àti tálákà. Nígbà tí àwọn iléeṣẹ́ tó ń fi ẹ̀rọ ṣe òwú ìhunṣọ wá di èyí tó pọ̀ rẹ́kẹrẹ̀kẹ, ẹ̀dínwó bá iye tí wọ́n ń ta aṣọ. Nígbà táwọn maṣíìnì ìránṣọ sì dé, ńṣe ni aṣọ kúkú wá di ọ̀pọ̀kúyọ̀kú. Àwọn aró àtọwọ́dá tó pọ̀ lóríṣiríṣi tún mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ahunṣọ láti lè máa ṣe aṣọ jáde lónírúurú àwọ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ.

Bí ojú àwọn èèyàn ṣe ń là sí i àti ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tún wá mú kí wọ́n máa ṣe aṣọ púpọ̀ sí i fún àwọn èèyàn láti wọ̀. Ní Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù àti ní Àríwá Amẹ́ríkà, àwọn èèyàn túbọ̀ rówó ná. Nígbà tó sì di àwọn ọdún 1850, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tẹ àwọn ìwé ìròyìn tó wà fún àwọn obìnrin jáde, kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà tí àwọn ilé ìtajà ìgbàlódé bẹ̀rẹ̀ sí ta onírúurú aṣọ tí wọ́n ti rán sílẹ̀. Bákan náà, ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, Charles Frederick Worth bẹ̀rẹ̀ sí ṣàfihàn àwọn tó máa ń fi ìmúra polówó aṣọ, láti fi ru ìfẹ́ àwọn èèyàn sókè kí wọ́n lè di oníbàárà wọn.

Ní ọ̀rúndún ogún, àwọn òwú yọ́lọ́yọ́lọ́ tuntun, bí irú àwọn tí wọ́n fi ń hun àwọn aṣọ bíi láílọ́ọ̀nù àtàwọn aṣọ onírọ́bà, mú kó ṣeé ṣe fún àwọn iléeṣẹ́ aṣọ láti máa ṣe onírúurú aṣọ jáde lọ́pọ̀ yanturu. Síwájú sí i, ìlò kọ̀ǹpútà tún mú kó ṣeé ṣe láti dá àrà oríṣiríṣi sára àwọn aṣọ tí wọ́n ń ṣe jáde, nítorí ayé tó sì ti lu jára, kíá lèèyàn ti lè rí àwọn aṣọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dóde láwọn òpópónà àwọn ìlú ńláńlá bíi Tokyo, New York, Paris àti São Paulo. Àmọ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí o, àwọn aránṣọ àtàwọn tó ń ṣe aṣọ jáde tún ti rí àwọn ọ̀nà tuntun tí ọjà wọn á fi máa tà wẹ̀rẹ̀wẹ̀rẹ̀.

Lóde òní, àwọn ọ̀dọ́ ti gbapò mọ́ àwọn olówó lọ́wọ́ nínú kíkó aṣọ jọ. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ wọn ló jẹ́ pé wọn ò lè ṣe kí wọ́n má ra aṣọ lóṣù kan, aṣọ táwọn iléeṣẹ́ aṣọ sì ń ṣe jáde lọ́dún máa ń wọ ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ owó dọ́là. a Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ àwọn ewu kan wà tó fara sin?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní ọdún kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí, aṣọ tí owó rẹ̀ tó òjì lé lọ́ọ̀ọ́dúnrún ó dín márùn-ún [335] bílíọ̀nù dọ́là ni wọ́n ṣe jáde.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]

Àwọn Tó Ń Dá Àṣà Tuntun Sílẹ̀

Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ló fi jẹ́ pé àwọn ọba àtàwọn ọ̀tọ̀kùlú làwọn èèyàn ń wò kọ́ṣe tó bá di ọ̀ràn aṣọ wíwọ̀. Ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, Ọba Louis Kẹtàlá bẹ̀rẹ̀ sí lo wíìgì láti fi bo orí rẹ̀ tó pá. Ká tó wí, ká tó fọ̀, àwọn ọ̀tọ̀kùlú ilẹ̀ Yúróòpù náà ti bẹ̀rẹ̀ sí fá irun orí wọn wọ́n sì ń dé wíìgì—ó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún tí àṣà yìí fi wà.

Ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, àwọn ìwé ìròyìn tó wà fún àwọn obìnrin bẹ̀rẹ̀ sí gbé àwọn àṣà aṣọ tuntun sójú táyé, kódà wọ́n tún máa ń ní àwọn bátànì aṣọ tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbówó lórí nínú, kí àwọn obìnrin lè máa lò ó láti fi rán aṣọ fúnra wọn. Ní ọ̀rúndún ogún, bí sinimá àti tẹlifíṣọ̀n ṣe túbọ̀ ń gbajúmọ̀ sí i, àwọn èèyàn sọ àwọn ògbóǹtarìgì eléré orí ìtàgé di òrìṣà, irú aṣọ tí wọ́n bá sì rí lára wọn ni wọ́n máa ń fẹ́ láti wọ̀. Làwọn gbajúmọ̀ olórin náà bá ní kí ló ṣubú tẹ àwọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wọ aṣọkáṣọ, kíá ni ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fara wé wọn. Lónìí, nǹkan ò tíì fi bẹ́ẹ̀ yí padà o, nítorí pé ńṣe ni àwọn tó ń polówó ń lo àwọn afìmúra polówó, àwọn ìwé ìròyìn fífanimọ́ra, pátákó ìpolówó, àwọn ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ń pàtẹ aṣọ rírán sí, àtàwọn ìpolówó orí tẹlifíṣọ̀n láti mú kí àwọn èèyàn lè túbọ̀ máa ra aṣọ tuntun.

[Àwòrán]

Ọba Louis Kẹtàlá

[Credit Line]

Látinú ìwé The Historian’s History of the World

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ yìí, tí àwọn ará Íjíbítì ayé ọjọ́un máa ń wọ̀, ṣì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn aṣọ tí aráyé ń gba tiẹ̀ dòní olónìí

[Credit Line]

A ya fọ́tò yìí nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda British Museum

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ní ilẹ̀ Róòmù ayé ọjọ́un, aṣọ “stola” làwọn obìnrin máa ń wọ̀

[Credit Line]

Látinú ìwé Historia del Traje, 1917

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]

Láti nǹkan bí ọdún 650 Sànmánì Tiwa ni wọ́n ti ń lo aṣọ “kimono”

[Credit Line]

Látinú ìwé ìròyìn La Ilustración Artística, Apá Kẹwàá, 1891

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Láyé àtijọ́, aṣọ tó bá wọ́n gan-an kì í lọ, títí gbére làwọn èèyàn á sì máa lò ó

[Credit Line]

EclectiCollections

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Nígbà táyé dayé ká máa fi ẹ̀rọ ṣe gbogbo nǹkan, àwọn tí kì í ṣe olówó náà wá di ẹni tó ń wọṣọ gan-an

[Credit Line]

EclectiCollections