Àròkọ Rẹ̀ Wú Wọn Lórí Gan-an
Àròkọ Rẹ̀ Wú Wọn Lórí Gan-an
Nígbà tó kù díẹ̀ kí Ginny, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, gboyè jáde ní ilé ẹ̀kọ́, àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ kan ṣí sílẹ̀ fún un láti sọ̀rọ̀ nípa ìsìn rẹ̀. Ó sọ pé: “Olùkọ́ mi sọ fún gbogbo àwa ọmọ kíláàsì pé ká kọ àròkọ kan kó tó di pé a gboyè jáde. Mo sọ fún un pé mo fẹ́ láti kọ̀wé nípa ohun tí ojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìjọba Násì.”
Olùkọ́ náà yọ̀ọ̀da fún Ginny láti kọ àròkọ lórí kókó tí ó fúnra rẹ̀ yàn náà. Ginny sọ pé: “Àyà mi là gààrà nígbà tí wọ́n ní kí n mú àròkọ mi wá, kí n sì kà á níwájú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ mi. Mi ò mọ ohun tí wọ́n lè sọ nípa àròkọ náà, mi ò sì mọ̀ bóyá wọ́n á fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.”
Ohun tí Ginny fi bẹ̀rẹ̀ kíka àròkọ rẹ̀ ni pé: “Ǹjẹ́ ẹ mọ àwọn tí àmì Ìràwọ̀ Dáfídì wà lára aṣọ wọn ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìjọba Násì?” Gbogbo wọn dáhùn pé, “Àwọn Júù ni.” Lẹ́yìn náà ló bi wọ́n bóyá wọ́n mọ àwọn tí àmì onígun mẹ́ta elésè àlùkò wà lára aṣọ wọn. Kò sẹ́ni tó dáhùn. Ginny wá fèsì pé: “Mo sọ fún wọn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni.”
Ọ̀rọ̀ tí Ginny sọ wú olùkọ́ àtàwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ lórí. Ginny sọ pé: “Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún wọn pé ì bá ti ṣeé ṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti gba òmìnira wọn nípa wíwulẹ̀ fọwọ́ sí ìwé kan láti fi hàn pé wọ́n ti sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn. Lẹ́yìn ìgbà náà, àwọn ọmọ kíláàsì mi kan sọ fún mi pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ńṣe làwọn máa ń fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe yẹ̀yẹ́, àmọ́, nígbàkigbà tí èyíkéyìí lára wọn bá tún wá sílé àwọn, àwọ́n á tẹ́tí sílẹ̀.”
Ginny gba máàkì tó dára gan-an lórí àròkọ rẹ̀ àti kíkà tó kà á. Ó sọ pé: “Kì í ṣe pé mo gba máàkì tó dára nìkan ni, àmọ́ mo tún ní àǹfààní ńláǹlà láti sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ mi!”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n sọ fún pé wọ́n lè gba òmìnira bí wọ́n bá fọwọ́ sí ìwé yìí láti fi hàn pé wọ́n ti sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn
[Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda United States Holocaust Memorial Museum