Àwọn Nǹkan Tó Lè Nípa Lórí Ìlera Rẹ
Àwọn Nǹkan Tó Lè Nípa Lórí Ìlera Rẹ
JÍJẸ oúnjẹ tó ń ṣara lóore àti níní ìlera tó dára kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn rárá. Nítorí kòókòó jàn-án jàn-án òde òní, ó dà bíi pé ó rọrùn láti máa jẹ àwọn oúnjẹ tí wọ́n ti ṣe sílẹ̀, tàbí àwọn “oúnjẹ àyáragbọ́” dípò káwọn èèyàn ra èèlò oúnjẹ kí wọ́n sì sè é fúnra wọn. Bákan náà, ó dà bíi pé ó rọrùn láti máa lo àkókò ọwọ́-dilẹ̀ nídìí tẹlifíṣọ̀n tàbí nídìí kọ̀ǹpútà dípò ṣíṣe àwọn nǹkan tó ń béèrè lílo okun ara. Àmọ́ ṣá o, àwọn nǹkan wọ̀nyí lè mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn, lọ́mọdé àti lágbà, ní àwọn àìsàn tó burú jáì.
Nílẹ̀ Éṣíà, ìwé ìròyìn Asiaweek sọ pé: “Jíjẹ àwọn oúnjẹ ọlọ́ràá àti báwọn èèyàn ṣe túbọ̀ ń jókòó gẹlẹtẹ sójú kan ti ń mú kí àrùn àtọ̀gbẹ di àjàkálẹ̀ àrùn.” Èyí tó tún wá burú níbẹ̀ ni pé, àwọn tí ọjọ́ orí wọn kéré gan-an láwùjọ ti ń ní àrùn yìí. Ní orílẹ̀-èdè Kánádà sì rèé, ìwé ìròyìn The Globe and Mail sọ pé: “Àwọn olùṣèwádìí ti rí i pé bí a bá kó àwọn ọmọ méje tí kò tíì pé ọdún mẹ́tàlá jọ, ọ̀kan péré nínú wọn ló ń jẹ èso àti ewébẹ̀ ní ìwọ̀n tí ó tó fún ara wọn, [àti pé] díẹ̀ làwọn tó ń ṣeré àṣelàágùn lára wọn fi lé ní ìdajì. Ìròyìn náà sọ pé irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ lè mú “kí àwọn èwe tètè ní àrùn ọkàn nígbà tí wọ́n bá fi máa di ẹni ọgbọ̀n ọdún sókè.”
Bákan náà, àwọn onímọ̀ nípa oorun sọ pé àwọn àgbàlagbà á nílò tó oorun wákàtí mẹ́jọ lóru nígbà táwọn ọ̀dọ́ á nílò jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nínú ìwádìí kan tí wọ́n tiẹ̀ ṣe ní Yunifásítì Chicago, àwọn ọ̀dọ́kùnrin tára wọn le dáadáa àmọ́ tó jẹ́ pé oorun wákàtí mẹ́rin péré ni wọ́n sùn lọ́jọ́ mẹ́fà tẹ̀ léra bẹ̀rẹ̀ sí ní àwọn àìlera tí àwọn arúgbó sábà máa ń ní. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fi àwọn wákàtí oorun ṣíṣeyebíye du ara wọn nítorí àtilè túbọ̀ rí àkókò lò nídìí iṣẹ́, ní iléèwé tàbí fún ìgbádùn, wọ́n lè wá ṣàkóbá fún ara wọn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. James Maas, olùṣèwádìí nípa oorun ní Yunifásítì Cornell ní ìlú New York sọ pé: “Ọ̀tọ̀ ni kéèyàn kàn máa ṣiṣẹ́ ṣáá, àmọ́ ọ̀tọ̀ ni kí orí èèyàn jí pépé nídìí iṣẹ́, kéèyàn lè ronú dáadáa, kí oorun má sì ṣàdéédéé máa gbéni lọ ní títì márosẹ̀ béèyàn ṣe ń wakọ̀ lọ.”
Lóòótọ́, àwọn ohun mìíràn tún wà tó ń nípa lórí ìlera wa. Bí àpẹẹrẹ, níní èrò rere lọ́kàn nígbà gbogbo lè ṣàǹfààní fún ìlera wa. Bákan náà, níní ète gidi nínú ìgbésí ayé lè sún wa láti máa ṣe àwọn ohun tó máa mú ká ní ìlera tó dára.